Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Chronological

Read the Bible in the chronological order in which its stories and events occurred.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Esekiẹli 28-31

Àsọtẹ́lẹ̀ òdì sí ọba Tire

28 Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé: (A)“Ọmọ ènìyàn, sọ fún ọmọ-aládé Tire pé, ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí:

“ ‘Nítorí tí ọkàn rẹ gbé sókè sí mi,
    ìwọ wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run;
Èmi jókòó sí orí ìtẹ́ òrìṣà,
    ní àárín gbùngbùn Òkun.”
Ṣùgbọ́n ènìyàn ni ọ́, kì i ṣe òrìṣà,
    bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ìwọ rò pé ìwọ gbọ́n bí Ọlọ́run.
Ìwọ gbọ́n ju Daniẹli lọ bí?
    Ṣé kò sí àṣírí kan tí ó pamọ́ fún ọ?
Pẹ̀lú ọgbọ́n àti ìmọ̀ rẹ,
    ìwọ tí jèrè ọrọ̀ fún ara rẹ,
àti àkójọpọ̀ wúrà àti fàdákà,
    nínú àwọn ilé ìṣúra rẹ.
Nípa ọgbọ́n rẹ ńlá àti nípa òwò rẹ,
    ìwọ ti sọ ọrọ̀ rẹ di púpọ̀,
àti nítorí ọrọ̀ rẹ di púpọ̀,
    ọkàn rẹ gbé sókè,
    nítorí ọrọ̀ rẹ.

“ ‘Nítorí náà èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí:

“ ‘Nítorí pé ìwọ rò pé o gbọ́n,
    pé ìwọ gbọ́n bí Ọlọ́run.
Èmi yóò mú kí àwọn àjèjì dìde sí ọ,
    ẹlẹ́rù nínú àwọn orílẹ̀-èdè;
wọn yóò yọ idà wọn sí ọ,
    ẹwà rẹ àti ọgbọ́n rẹ,
    wọn yóò sì ba dídán rẹ̀ jẹ́.
Wọn yóò mú ọ sọ̀kalẹ̀ wá sínú ihò,
    ìwọ yóò sì kú ikú gbígbóná,
    àwọn tí a pa ní àárín Òkun.
Ṣé ìwọ yóò wá wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run,”
    ní ojú àwọn tí ó pa ọ́?
Ìwọ yóò jẹ́ ènìyàn, kì í ṣe Ọlọ́run,
    ní ọwọ́ àwọn ti yóò pa ọ́.
10 Ìwọ yóò kú ikú aláìkọlà,
    ní ọwọ́ àwọn àjèjì.

Èmi ni ó ti sọ ọ́, ní Olúwa Olódùmarè wí.’ ”

11 Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé: 12 “Ọmọ ènìyàn, pohùnréré ẹkún sórí ọba Tire kí ó sì sọ fún un pé: ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí:

“ ‘Ìwọ jẹ́ àpẹẹrẹ ìjẹ́pípé náà,
    o kún fún ọgbọ́n,
    o sì pé ní ẹwà.
13 Ìwọ ti wà ní Edeni, ọgbà Ọlọ́run;
    onírúurú òkúta oníyebíye ni ìbora rẹ;
sardiu, topasi àti diamọndi, berili, óníkìsì,
    àti jasperi, safire, emeradi,
turikuoṣe, àti karbunkili, àti wúrà,
    ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ àti àwọn òkè rẹ ní a dà,
láti ara wúrà,
    ní ọjọ́ tí á dá ọ ní a pèsè wọn.
14 A fi ààmì òróró yàn ọ́ gẹ́gẹ́ bí olùtọ́jú kérúbù,
    torí èyí ni mo fi yàn ọ́.
Ìwọ wà lórí òkè mímọ́ Ọlọ́run;
    ìwọ rìn ni àárín òkúta a mú bí iná,
15 Ìwọ pé ní ọ̀nà rẹ,
    láti ọjọ́ tí a ti dá ọ,
    títí a fi rí àìṣedéédéé ní inú rẹ.
16 Nípa ìtànkálẹ̀ òwò rẹ,
    ìwọ kún fún ìwà ipá;
ìwọ sì dẹ́ṣẹ̀.
    Nítorí náà ni mo ṣe sọ ọ nù,
    bí ohun àìlọ́wọ̀ kúrò lórí òkè Ọlọ́run.
Èmi sì pa ọ run,
    ìwọ kérúbù, tí ó bọ́ kúrò ní àárín òkúta a mú bí iná.
17 Ọkàn rẹ gbéraga,
    nítorí ẹwà rẹ.
Ìwọ sì ba ọgbọ́n rẹ jẹ́,
    nítorí dídára rẹ.
Nítorí náà mo le ọ sórí ayé;
    mo sọ ọ di awòojú níwájú àwọn ọba.
18 Nípa ẹ̀ṣẹ̀ púpọ̀ rẹ àti òwò àìṣòótọ́ rẹ,
    ìwọ ti ba àwọn ibi mímọ́ rẹ jẹ́.
Nítorí náà mo mú kí iná jáde wá,
    láti inú rẹ, yóò sì jó ọ run,
èmi yóò sì sọ ọ́ di eérú lórí ilẹ̀,
    lójú gbogbo àwọn tí ó ń wò ọ́.
19 Gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó mọ̀ ọ́n,
    ní ẹnu ń yà sí ọ;
ìwọ yóò sì jẹ́ ẹ̀rù,
    ìwọ kì yóò sì ṣí mọ́ láéláé.’ ”

Àsọtẹ́lẹ̀ òdì sí Sidoni

20 (B)Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé: 21 “Ọmọ ènìyàn, kọ ojú sí Sidoni; kí o sì sọtẹ́lẹ̀ sí i 22 Kí ó sì wí pé: ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí:

“ ‘Èmi lòdì sí ọ, ìwọ Sidoni,
    a ó sì ṣe mí lógo láàrín rẹ.
Wọn yóò mọ̀ pé èmi ní Olúwa,
    Nígbà tí mo bá mú ìdájọ́ mi ṣẹ nínú rẹ,
    tí a sì yá mí sí mímọ́ nínú rẹ,
23 Èmi yóò sì rán àjàkálẹ̀-ààrùn sínú rẹ,
    èmi yóò sì mú kí ẹ̀jẹ̀ sàn ní ìgboro rẹ,
ẹni ti á pa yóò ṣubú ní àárín rẹ,
    pẹ̀lú idà lára rẹ ní gbogbo ẹ̀gbẹ́,
    nígbà náà wọn yóò mọ̀ wí pé èmi ni Olúwa.

24 “ ‘Kì yóò sì ṣí ẹ̀gún tí ń gun ni ní ilẹ̀ Israẹli mọ́, tàbí ẹ̀gún bíbani nínú jẹ́ ti gbogbo àwọn tí wọn wà ní àyíká wọn, tí wọ́n sì ń fi ojú yẹpẹrẹ wò wọ́n, nígbà náà ni wọn yóò mọ́ wí pé èmi ni Olúwa Olódùmarè.

25 “ ‘Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Nígbà tí èmi yóò bá sa àwọn ènìyàn Israẹli jọ kúrò ní gbogbo orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti fọ́nká sí, tí a ó sì yà mí sí mímọ́ láàrín wọn lójú àwọn aláìkọlà; Nígbà náà ni wọn yóò gbé ní ilẹ̀ àwọn tìkálára wọn, èyí tí mo fún ìránṣẹ́ mi Jakọbu. 26 Wọn yóò sì máa gbé ní inú rẹ̀ ní àìléwu, wọn yóò sì kọ́lé, wọn yóò sì gbin ọgbà àjàrà; nítòótọ́ wọn yóò wà ní ìbàlẹ̀ àyà, nígba tí èmi bá ti mú ìdájọ́ mi ṣẹ̀ sí ara àwọn tí ń ṣátá wọn ní gbogbo àyíká wọn; Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn.’ ”

Àsọtẹ́lẹ̀ òdì sí Ejibiti

29 (C)Ní ọjọ́ kejìlá, oṣù kẹwàá, ọdún kẹwàá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: “Ọmọ ènìyàn, kọjú sí Farao ọba Ejibiti kí ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí i àti sí gbogbo Ejibiti. Sọ̀rọ̀, kí ó sì wí pé: ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí:

“ ‘Èmi lòdì sí ọ, Farao ọba Ejibiti
    ìwọ ẹ̀mí búburú ńlá inú Òkun tí ó dùbúlẹ̀ sí
àárín àwọn odò ṣíṣàn rẹ
    èyí tí ó sọ wí pé, “Tèmi ni odò Naili;
    èmi ni ó sì ṣe é fún ara mi.”
Ṣùgbọ́n èmi yóò fi ìwọ̀ mú ẹnu rẹ
    èmi yóò sì mú ẹja inú odò rẹ
gbogbo lẹ̀ mọ́ ìpẹ́ ara rẹ.
    Èmi yóò fà ọ́ síta kúrò láàrín àwọn odò rẹ,
    àti gbogbo ẹja odò rẹ yóò lẹ̀ mọ́ ìpẹ́ ara rẹ.
Èmi yóò sọ ọ́ nù sí aginjù
    ìwọ àti gbogbo ẹja inú odò rẹ:
ìwọ yóò ṣubú sí gbangba oko
    a kì yóò sì ṣà ọ́ jọ tàbí gbé ọ sókè.
Èmi ti fi ọ ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹranko igbó
    àti fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run láti jẹ.

Nígbà náà gbogbo àwọn olùgbé ni Ejibiti yóò mọ pé Èmi ni Olúwa.

“ ‘Ìwọ ti jẹ́ ọ̀pá ìyè fún ilé Israẹli. Nígbà tí wọn fi ọwọ́ agbára wọn dì ọ́ mú. Ìwọ fọ́, ìwọ sì ya gbogbo èjìká wọn; nígbà tí wọn fi ara tì ọ́, ìwọ sẹ́, ìwọ sì mú gbogbo ẹ̀gbẹ́ wọn gbọ̀n.

“ ‘Nítorí náà, èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: kéyèsi Èmi yóò mú idà kan wá sórí rẹ tí yóò sì gé ènìyàn àti ẹran kúrò nínú rẹ. Ilẹ̀ Ejibiti yóò di aginjù àti ahoro, nígbà náà ní wọn yóò sì mọ̀ wí pé èmi ní Olúwa.

“ ‘Nítorí tí ìwọ wí pé, “Tèmi ni odò Naili; Èmi ni mo ṣe é,” 10 Nítorí náà, mo lòdì sí ọ àti sí àwọn odò rẹ, èmi yóò sì mú kí ilẹ̀ Ejibiti di píparun àti ahoro, pátápátá, láti Migdoli lọ dé Siene, dé ààlà ilẹ̀ Kuṣi. 11 Kò sí ẹsẹ̀ ènìyàn tàbí tí ẹranko tí yóò gba ibẹ̀ kọjá; ẹni kankan kò ní gbé ibẹ̀ fún ogójì ọdún. 12 Èmi yóò sọ ilẹ̀ Ejibiti di ọ̀kan ní àárín àwọn ìlú tí ó di ahoro, fún ogójì ọdún, Èmi yóò sì fọ́n àwọn ara Ejibiti ká sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè, èmi yóò sì tú wọn ká sáàárín gbogbo ilẹ̀.

13 “ ‘Ṣùgbọ́n báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Ní òpin ogójì ọdún, èmi yóò ṣa àwọn ará Ejibiti jọ láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn níbi tí a fọ́n wọn ká sí. 14 Èmi yóò sì tún mú ìgbèkùn Ejibiti padà bọ̀, èmi yóò sì dá wọn padà sí ilẹ̀ Paturosi, ilẹ̀ àwọn baba ńlá wọn. Wọn yóò wà níbẹ̀ bí ìjọba tí a rẹ̀ sílẹ̀. 15 Ibẹ̀ yóò jẹ́ ìjọba tí ó rẹlẹ̀ jùlọ nínú àwọn ìjọba, kì yóò sì gbé ara rẹ̀ ga mọ́ sórí àwọn orílẹ̀-èdè: nítorí èmi ni ó dín wọn kù, tiwọn kì yóò fi ṣe olórí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù mọ́. 16 Ejibiti kí yóò sì jẹ orísun ìgbẹ́kẹ̀lé fún ilé Israẹli mọ́ ṣùgbọ́n, yóò jẹ́ ìrántí fún àìṣedéédéé wọn, nígbà tí yóò bá wò wọ́n fún ìrànlọ́wọ́. Nígbà náà, wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa Olódùmarè.’ ”

Èrè Nebukadnessari

17 Ó sì ṣe ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù kìn-ín-ní, ọdún kẹtà-dínlọ́gbọ̀n, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: 18 “Ọmọ ènìyàn, Nebukadnessari ọba Babeli mú kí ogun rẹ sin ìrú ńlá fún Tire. Gbogbo orí pá, àti gbogbo èjìká bó, síbẹ̀, òun àti àwọn ogun rẹ̀, kò rí owó ọ̀yà gbà láti Tire fún wa, fún ìrú ti a ti sìn. 19 Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Kíyèsi i, Èmi yóò fi Ejibiti fún Nebukadnessari ọba Babeli, òun yóò sì kó ọrọ̀ rẹ̀ lọ. Òun yóò bo ilé, yóò sì ṣe ìkógun ilẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí owó iṣẹ́ tí a san fún ológun rẹ̀. 20 Èmi ti fi Ejibiti fún un gẹ́gẹ́ bí èrè wàhálà rẹ̀ nítorí òun àti àwọn ológun rẹ ṣe é fún mi, ni Olúwa Olódùmarè wí.

21 “Ní ọjọ́ náà, èmi yóò mú kí ìwo Israẹli ru jáde, èmi yóò sì fún ọ ní ẹnu ọ̀rọ̀ ní àárín wọn. Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.”

Ìpohùnréré ẹkún fún Ejibiti

30 Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá: wí pé: “Ọmọ ènìyàn, sọtẹ́lẹ̀ kí o sì wí pé: ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí:

“ ‘Hu, kí o sì wí pé,
    “Ó ṣe fún ọjọ́ náà!”
Nítorí ọjọ́ náà súnmọ́ tòsí
    àní ọjọ́ Olúwa súnmọ́ tòsí
Ọjọ́ tí ọjọ́ ìkùùkuu ṣú dúdú,
    àsìkò ìparun fún àwọn kèfèrí.
Idà yóò wá sórí Ejibiti
    ìrora ńlá yóò sì wá sórí Kuṣi
Nígbà tí àwọn tí a pa yóò ṣubú ní Ejibiti
    wọn yóò kò ọrọ̀ rẹ̀ lọ
    ìpìlẹ̀ rẹ̀ yóò sì wó lulẹ̀.

Kuṣi àti Puti, Libia, Ludi àti gbogbo Arabia, Kubu àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà tí ó mulẹ̀ yóò ṣubú nípa idà pẹ̀lú Ejibiti.

“ ‘Èyí yìí ní Olúwa wí:

“ ‘Àwọn àlejò Ejibiti yóò ṣubú
    agbára ìgbéraga rẹ yóò kùnà
láti Migdoli títí dé Siene,
    wọn yóò ti ipa idà ṣubú nínú rẹ;
    Olúwa Olódùmarè wí.
Wọn yóò sì wà
    lára àwọn ilẹ̀ tí ó di ahoro,
ìlú rẹ yóò sì wà
    ní ara àwọn ìlú tí ó di ahoro.
Lẹ́yìn náà wọn yóò mọ̀ pé èmi ní Olúwa,
    nígbà tí mo bá gbé iná kalẹ̀ ní Ejibiti
    tí gbogbo àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ bá parun.

“ ‘Ní ọjọ́ náà oníṣẹ́ yóò ti ọ̀dọ̀ mi jáde nínú ọkọ̀ ojú omi láti dẹ́rùbà Kuṣi tí ó wà nínú àlàáfíà. Ìrora yóò wá sórí wọn gẹ́gẹ́ bí ti ọjọ́ ìparun Ejibiti: Kíyèsi i, ó dé.

10 “ ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí:

“ ‘Èmi yóò mú òpin bá ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn
    ènìyàn Ejibiti láti ọwọ́ Nebukadnessari ọba Babeli.
11 Òun àti àwọn ológun rẹ̀
    ẹ̀rù àwọn orílẹ̀-èdè
ní a o mú wá láti pa ilẹ̀ náà run.
    Wọn yóò fa idà wọn yọ sí Ejibiti
    ilẹ̀ náà yóò sì kún fún àwọn tí a pa.
12 Èmi yóò mú kí àwọn odò Naili gbẹ
    Èmi yóò sì ta ilẹ̀ náà fún àwọn ènìyàn búburú:
láti ọwọ́ àwọn àjèjì ènìyàn
    Èmi yóò jẹ́ kí ilẹ̀ náà àti gbogbo ohun tí ó wá nínú rẹ ṣòfò.

Èmi Olúwa ni ó ti sọ ọ́.

13 “ ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí:

“ ‘Èmi yóò pa àwọn òrìṣà run
    Èmi yóò sì mú kí òpin dé bá ère gbígbẹ́ ni Memfisi.
    Kò ní sí ọmọ-aládé mọ́ ní Ejibiti,
    Èmi yóò mú kí ìbẹ̀rù gba gbogbo ilẹ̀ náà.
14 Èmi yóò sì mú kí Paturosi di ahoro
    èmi yóò fi iná sí Ṣoani
    èmi yóò sì fi ìyà jẹ Tebesi.
15 Èmi yóò tú ìbínú mi jáde sórí Pelusiumu
    ìlú odi Ejibiti
    èmi yóò sì ké àkójọpọ̀ Tebesi kúrò
16 Èmi yóò ti iná bọ Ejibiti
    Pelusiumu yóò japoró ní ìrora
Ìjì líle yóò jà ní Tebesi
    Memfisi yóò wà ìpọ́njú ní ìgbà gbogbo
17 Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin ní Heliopolisi àti Bubasiti
    yóò ti ipa idà ṣubú
    wọn yóò sì kó àwọn ìlú wọn ní ìgbèkùn
18 Ojú ọjọ́ yóò ṣókùnkùn ní Tafanesi
    nígbà tí mo bá já àjàgà Ejibiti kúrò;
níbẹ̀ agbára iyì rẹ̀ yóò dópin
    wọn yóò fi ìkùùkuu bò ó
    àwọn abúlé rẹ ní wọn yóò lọ sí ìgbèkùn.
19 Nítorí náà Èmi yóò mú ki ìjìyà wá sórí Ejibiti,
    wọn yóò sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.’ ”

20 Ní ọjọ́ keje oṣù kìn-ín-ní ọdún kọkànlá ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá: 21 “Ọmọ ènìyàn, Èmi ti ṣẹ́ apá Farao ọba Ejibiti. A kò ì tí ì di apá náà papọ̀ láti mu kí ó san, a kò sì ti di i si àárín igi pẹlẹbẹ kí o lè ni agbára tó láti di idà mú. 22 Nítorí náà, báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Èmi lòdì sí Farao ọba Ejibiti. Èmi yóò sẹ́ apá rẹ̀ méjèèjì, èyí tí ó dára àti èyí tí a ti ṣẹ́ pẹ̀lú, yóò sì mú kí idà bọ́ sọnù ní ọwọ́ rẹ̀. 23 Èmi yóò sì fọ́n àwọn ènìyàn Ejibiti ká sí àárín àwọn orílẹ̀-èdè, èmi yóò sì tú wọn ká gbogbo ilẹ̀. 24 Èmi yóò mú kí apá ọba Babeli ní agbára, èmi yóò sì fi idà mi sí ọwọ́ rẹ, ṣùgbọ́n èmi yóò ṣẹ́ apá Farao, yóò sì kérora níwájú rẹ̀ bí ọkùnrin tí a sá ní àṣápa. 25 Èmi yóò mú kí apá ọba Babeli lé, ṣùgbọ́n apá Farao yóò sì rọ. Nígbà náà wọn yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa, nígbà tí mo bá mú idà mi sí ọwọ́ ọba Babeli yóò sì fi idà náà kọlu Ejibiti. 26 Èmi yóò fọ́n àwọn ara Ejibiti ká sí àárín orílẹ̀-èdè, èmi yóò sì tú wọn ká sí àárín orílẹ̀-èdè, èmi yóò sì tú wọn ká sí gbogbo ilẹ̀. Nígbà náà wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.”

Òpépé igi Sedari ni Lebanoni

31 Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù kẹta ọdún kọkànlá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá: “Ọmọ ènìyàn, sọ fún Farao ọba Ejibiti àti sí ìjọ rẹ̀:

“ ‘Ta ní a le fiwé ọ ní ọláńlá?
Kíyèsi Asiria, tí ó jẹ́ igi kedari ni
    Lebanoni ní ìgbà kan rí,
pẹ̀lú àwọn ẹ̀ka dáradára tí ó ṣẹ́ ìji bo igbó náà;
    tí ó ga sókè,
    òkè rẹ̀ lókè ni ewé tí ó nípọn wà.
Omi mú un dàgbàsókè:
    orísun omi tí ó jinlẹ̀ mú kí o dàgbàsókè;
àwọn odo rẹ̀ ń sàn yí ìdí rẹ̀ ká,
    ó sì rán ìṣàn omi rẹ̀ sí gbogbo igi orí pápá.
Nítorí náà ó ga sí òkè fíofío
    ju gbogbo igi orí pápá lọ;
ẹ̀ka rẹ̀ pọ̀ sí i:
    àwọn ẹ̀ka rẹ̀ sì gùn,
    wọn tẹ́ rẹrẹ nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi.
(D)Ẹyẹ ojú ọ̀run
    kọ ilé sí ẹ̀ka rẹ̀
gbogbo ẹranko igbó
    ń bímọ ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀;
gbogbo orílẹ̀-èdè ńlá
    ń gbé abẹ́ ìji rẹ̀.
Ọláńlá ní ẹwà rẹ̀ jẹ́,
    pẹ̀lú títẹ́ rẹrẹ ẹ̀ka rẹ̀,
nítorí gbòǹgbò rẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀
    sí ibi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi wà.
(E)Àwọn igi kedari nínú ọgbà Ọlọ́run
    kò lè è bò ó mọ́lẹ̀;
tàbí kí àwọn igi junifa
    ṣe déédé pẹ̀lú ẹ̀ka rẹ̀,
tàbí kí a fi igi títẹ́ rẹrẹ wé ẹ̀ka rẹ̀,
    kò sí igi nínú ọgbà Ọlọ́run
    tí ó dà bí rẹ̀ ní ẹwà rẹ̀.
Mo mú kí ó ní ẹwà
    pẹ̀lú ẹ̀ka lọ́pọ̀lọpọ̀
tó fi jẹ́ ìlara àwọn igi gbogbo ní Edeni
    tí í ṣe ọgbà Ọlọ́run.

10 “ ‘Nítorí náà, èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí; Nítorí pé ó ga lọ sókè fíofío, tí ó sì gbé òkè rẹ̀ ga ju ewé tí ó nípọn lọ, àti nítorí pé gíga rẹ mú kí ó gbéraga, 11 Mo fi lé alákòóso àwọn orílẹ̀-èdè náà lọ́wọ́, fún un láti fi ṣe ẹ̀tọ́ fún un gẹ́gẹ́ bí ìwà búburú rẹ̀. Mo pa á tì sí ẹ̀gbẹ́ kan, 12 àwọn orílẹ̀-èdè àjèjì aláìláàánú jùlọ ké e lulẹ̀, wọn sì fi kalẹ̀. Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ ṣubú sórí òkè àti sí gbogbo àárín àwọn òkè; àwọn ẹ̀ka rẹ̀ tí ó ṣẹ nà sílẹ̀ ní gbogbo àlàfo jíjìn ilẹ̀. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé jáde kúrò ní abẹ́ ìji rẹ̀ wọn sì fi sílẹ̀. 13 Gbogbo àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ṣe àtìpó ni orí igi tí ó ṣubú lulẹ̀ náà, gbogbo àwọn ẹranko igbó wà ní àárín ẹ̀ka rẹ̀. 14 Nítorí náà kò sí igi mìíràn lẹ́gbẹ̀ẹ́ omi tí ó lè fi ìgbéraga ga sókè fíofío, tí yóò sì gbé sókè rẹ̀ ga ju ewé tí ó nípọn lọ. Kò sí igi mìíràn tí ó ní omi tó bẹ́ẹ̀ tí ó lè ga tó bẹ́ẹ̀; gbogbo wọn ni a kádàrá ikú fún, fún ìsàlẹ̀ ilẹ̀, ní àárín àwọn alààyè ènìyàn, pẹ̀lú àwọn tí o lọ sí ọ̀gbun ní ìsàlẹ̀.

15 “ ‘Èyí ni Olúwa Olódùmarè wí: ní ọjọ́ ti a mú u wá sí isà òkú mo fi ọ̀fọ̀ ṣíṣe bo orísun omi jíjìn náà; Mo dá àwọn ìṣàn omi rẹ̀ dúró, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi rẹ̀ ní a dí lọ́nà. Nítorí rẹ̀ mo fi ìwúwo ọkàn wọ Lebanoni ní aṣọ, gbogbo igi igbó gbẹ dànù. 16 Mo mú kí orílẹ̀-èdè wárìrì sì ìró ìṣubú rẹ̀ nígbà tí mo mú un wá sí ìsàlẹ̀ isà òkú pẹ̀lú àwọn tí ó lọ sí ọ̀gbun ìsàlẹ̀. Nígbà náà gbogbo igi Edeni, àṣàyàn àti èyí tí ó dára jùlọ nínú Lebanoni, gbogbo igi tí ó ní omi dáradára ni a tù nínú ni ayé ìsàlẹ̀. 17 Àwọn tí ó ń gbé ní abẹ́ òjìji rẹ̀, àwọn àjèjì rẹ ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè náà, ti lọ sí ìsàlẹ̀ isà òkú pẹ̀lú rẹ̀, ní dídárapọ̀ mọ́ àwọn tí a fi idà pa.

18 “ ‘Èwo lára igi Edeni ní a lè fiwé ọ ní dídán àti ọláńlá? Síbẹ̀ ìwọ, gan an wá sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn igi Edeni lọ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀; ìwọ yóò sùn ni àárín àwọn aláìkọlà, pẹ̀lú àwọn tí a fi idà pa.

“ ‘Èyí yìí ní Farao àti ìjọ rẹ̀, ní Olúwa Olódùmarè wí.’ ”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.