Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Chronological

Read the Bible in the chronological order in which its stories and events occurred.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Esekiẹli 46-48

46 “ ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Ẹnu-ọ̀nà àgbàlá ti inú tí ó dojúkọ ìhà ìlà-oòrùn ni kí a tì pa fún ọjọ́ mẹ́fà tí a fi ń ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ ìsinmi àti ní ọjọ́ oṣù tuntun ni kí a ṣí i. Ọmọ-aládé ni kí ó wọlé láti ìta tí ó kángun sí àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà, kí ó sì dúró ní ẹnu-ọ̀nà. Àwọn àlùfáà ni yóò rú ọrẹ ẹbọ sísun rẹ̀ àti ọrẹ ìdàpọ̀. Òun ni yóò jọ́sìn ní ìloro ilé ní ẹnu-ọ̀nà, lẹ́yìn náà ni wọn yóò jáde, ṣùgbọ́n wọn kò ni ti ìlẹ̀kùn títí ìrọ̀lẹ́. Ní àwọn ọjọ́ ìsinmi àti àwọn oṣù tuntun ni kí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà jọ́sìn ní iwájú Olúwa ní àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà. Ọrẹ ẹbọ sísun tí ọmọ-aládé mú wá fún Olúwa ni ọjọ́ ìsinmi ní láti jẹ́ ọ̀dọ́ àgbò mẹ́fà àti àgbò kan, gbogbo rẹ̀ gbọdọ̀ jẹ́ aláìlábùkù. Ọrẹ ẹbọ jíjẹ tí a mú papọ̀ mọ́ àgbò gbọdọ̀ jẹ́ efa kan, ọrẹ ẹbọ jíjẹ tí a mú pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn ni kí ó pò gẹ́gẹ́ bí ó bá ṣe fẹ́, papọ̀ mọ hínì òróró kan pẹ̀lú efa kọ̀ọ̀kan. Àti ni ọjọ́ oṣù tuntun, ẹgbọrọ màlúù kan àìlábàwọ́n, àti ọ̀dọ́-àgùntàn mẹ́fà, àti àgbò kan: wọn o wà láìlábàwọ́n. Yóò si pèsè ọrẹ ẹbọ jíjẹ efa fun ẹgbọrọ akọ màlúù, àti efa kan fun àgbò kan, àti fun àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn gẹ́gẹ́ bi èyí ti ipá rẹ̀ ká, àti hínì òróró kan fún efa kan. Nígbà tí ọmọ-aládé bá wọlé, ó gbọdọ̀ gbá àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà wọ inú, kí ó sì gba ibẹ̀ jáde.

“ ‘Nígbà tí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà bá wá síwájú Olúwa ni àwọn àjọ̀dún tí a yàn, ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ti ẹnu-ọ̀nà ìhà àríwá wọlé láti jọ́sìn gbọdọ̀ gba ti ẹnu-ọ̀nà ìhà gúúsù jáde; ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ti ẹnu-ọ̀nà ìhà gúúsù wọlé yóò gba tí ẹnu-ọ̀nà ìhà àríwá jáde. Kò sí ẹni tí ó gbọdọ̀ gba ibi tí ó bá wọlé jáde, ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù gba òdìkejì ẹnu-ọ̀nà tí ó gbà wọlé jáde. 10 Ọmọ-aládé gbọdọ̀ wà ní àárín wọn, kí ó wọlé nígbà tí wọn bá wọlé, kí ó sì jáde nígbà tí wọn bá jáde.

11 “ ‘Níbi àwọn àjọ̀dún àti àwọn àjọ̀dún tí a yàn, ọrẹ ẹbọ jíjẹ gbọdọ̀ jẹ́ efa kan fún ẹgbọrọ akọ màlúù kan, efa kan fún àgbò kan, àti fún àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn gẹ́gẹ́ bí ó bá ti wu onílúlùkù, pẹ̀lú òróró hínì kan fún efa kan. 12 Nígbà tí ọmọ-aládé bá pèsè ọrẹ àtinúwá fún Olúwa yálà ọrẹ ẹbọ sísun tàbí ọrẹ ẹbọ ìdàpọ̀ ojú ọ̀nà tí ó dojúkọ ìhà ìlà-oòrùn ni kí ó wà ni ṣíṣí sílẹ̀ fún un Òun yóò rú ọrẹ ẹbọ sísun rẹ̀ tàbí ọrẹ ẹbọ ìdàpọ̀ gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣe ní ọjọ́ ìsinmi. Lẹ́yìn náà, òun yóò jáde, lẹ́yìn ìgbà tí ó bá jáde tán wọn yóò ti ẹnu-ọ̀nà.

13 “ ‘Ní ojoojúmọ́ ni ìwọ yóò pèsè ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan aláìlábùkù fún ọrẹ ẹbọ sísun sí Olúwa; àràárọ̀ ni ìwọ yóò máa pèsè rẹ̀. 14 Ìwọ yóò sì máa pèsè ọrẹ ẹbọ jíjẹ pẹ̀lú rẹ̀ ní àràárọ̀, èyí yóò ni ìdámẹ́fà nínú efa àti ìdámẹ́fà nínú òróró hínì láti fi po ìyẹ̀fun. Gbígbé ọrẹ ẹbọ jíjẹ fún Olúwa jẹ́ ìlànà tí ó wà títí. 15 Nítorí náà ọ̀dọ́-àgùntàn àti ọrẹ ẹbọ jíjẹ àti òróró ni wọn yóò pèsè ní àràárọ̀ fún ọrẹ ẹbọ sísun ìgbà gbogbo.

16 “ ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè sọ: Tí ọmọ-aládé bá mú ọrẹ láti inú ogún ìní rẹ̀ fún ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, yóò jẹ́ ìní tiwọn nípa ogún jíjẹ. 17 Tí ó bá mú ọrẹ láti inú ogún ìní rẹ̀ fún ọ̀kan lára àwọn ọmọ ọ̀dọ̀, ọmọ le pamọ́ títí di ọdún ìdásílẹ̀; Lẹ́yìn náà yóò padà sí ọ̀dọ̀ ọmọ-aládé. Ogún ìní rẹ̀ jẹ́ ti àwọn ọmọ rẹ̀ nìkan; ó jẹ́ tiwọn. 18 Ọmọ-aládé kò gbọdọ̀ mú nǹkan kan lára ogún ìní àwọn ènìyàn, tàbí mú wọn kúrò níbi ohun ìní wọn. Ó ní láti fi ogún ìní rẹ̀ láti inú ìní rẹ̀ fún àwọn ọmọ rẹ̀, kí a ma ba à ya nǹkan kan kúrò lára ìní rẹ̀.’ ”

19 Lẹ́yìn náà ọkùnrin náà mú mi kọjá ní àbáwọlé tí ó wà lẹ́bàá ẹnu-ọ̀nà, sí àwọn yàrá mímọ́ tí ó kọjú sí ìhà àríwá, èyí tí ó jẹ́ tí àwọn àlùfáà, ó sì fi ibi kan hàn mí ní apá ìwọ̀-oòrùn. 20 O sọ fún mi pé, “Èyí yìí ni ibi tí àwọn àlùfáà yóò ti ṣe ọrẹ ẹbọ ìdálẹ́bi àti ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àti tí wọn yóò ti ṣe ọrẹ ẹbọ jíjẹ, láti má ṣe jẹ́ kí wọn mú wọn wá sí ìta àgbàlá, kí wọn sì ya àwọn ènìyàn sí mímọ́.”

21 Ó sì mú mi lọ sí ìta àgbàlá, ó sì mú mi yí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ ká, mo sì ri àgbàlá mìíràn ní igun kọ̀ọ̀kan. 22 Ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ìta àgbàlá tí ó pẹnu pọ̀, ogójì ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn àti ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú; àgbàlá kọ̀ọ̀kan ni igun kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìwọ̀n kan náà. 23 Ní agbègbè inú ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú àgbàlá náà ni ọwọ́ ilẹ̀ kan wà yíká wọn, a sì ṣe ibi ìdáná si abẹ́ ọwọ́ náà yípo. 24 Ó sì wí fún mi pé, “Ìwọ̀nyí ni àwọn ilé ìdáná níbi tí ó ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ nínú tẹmpili yóò ti ṣe ẹbọ fún àwọn ènìyàn.”

Odò láti inú tẹmpili náà

47 (A)Ọkùnrin náà mú mi padà lọ sí àbáwọlé tẹmpili náà, mo sì rí omi tí ó ń tú jáde láti abẹ́ ìloro tẹmpili náà sí apá ìhà ìlà-oòrùn (nítorí tẹmpili náà dojúkọ ìhà ìlà-oòrùn) Omi náà ń tú jáde sí ìsàlẹ̀ láti abẹ́, ní ìhà gúúsù tẹmpili náà, ní ìhà gúúsù pẹpẹ. Ó wá mú mi gba ojú ọ̀nà àríwá jáde, ó sì mú mi yí ìta ojú ọ̀nà ìta tí ó dojúkọ ìhà ìlà-oòrùn, omi náà sì ń sàn láti ìhà gúúsù wá.

Bí ọkùnrin náà ti lọ sí apá ìhà ìlà-oòrùn pẹ̀lú okùn wíwọ̀n nǹkan lọ́wọ́ rẹ̀, ó wọn ẹgbẹ̀rún ìgbọ̀nwọ́, ó sì mú mi gba ibi odò kan tí kò jì jù kókósẹ̀ lọ. Ó sì wọn ẹgbẹ̀rún ìgbọ̀nwọ́ mìíràn kúrò, ó sì mú mi gba ibi odò tí ó jì ní ìwọ̀n orúnkún. Ó tún wọn ẹgbẹ̀rún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́ mìíràn kúrò, ó sì mú mi gba odò tí ó dé ìbàdí. Ó wọn ẹgbẹ̀rún ìgbọ̀nwọ́ mìíràn kúrò, ṣùgbọ́n nísinsin yìí odò tí ń kò lè kọjá rẹ̀ ni, Nítorí pé odò tí ó kún, ó sì jì tó èyí tí wọ́n le lúwẹ̀ẹ́ nínú rẹ̀ odò tí ẹnikẹ́ni kò le dá kọjá ni. Ó bi mí léèrè pé: “Ọmọ ènìyàn, ǹjẹ́ o rí èyí?”

Lẹ́yìn náà, ó mú mi padà sí etí odò. Nígbà tí mo dé ibẹ̀, mo rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ igi ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì odò. Ó sọ fún mi pé, “Odò yìí ń tú jáde sí ìhà ìlà-oòrùn, wọ́n sì ń sọ̀kalẹ̀ lọ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀, wọ́n sì wọ inú Òkun lọ, a sì mú omi wọn láradá. Àwọn ohun alààyè tí ó ń rákò yóò máa gbé ní ibikíbi tí odò ti ń sàn. Ẹja yóò pọ̀ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀, nítorí pé odò ń sàn síbẹ̀, ó sì mú kí omi iyọ̀ tutù nini; nítorí náà níbi tí omi ti ń sàn, gbogbo nǹkan ni yóò wà ni ààyè. 10 Àwọn apẹja yóò dúró ní etí bèbè odò; láti En-Gedi títí dé En-Eglaimu ààyè yóò wa láti tẹ́ àwọ̀n wọn sílẹ̀. Oríṣìíríṣìí ẹja ni yóò wà gẹ́gẹ́ bí ẹja omi Òkun ńlá. 11 Ṣùgbọ́n ẹrẹ̀ àti àbàtà kò ní tòrò; àwa yóò fi wọn sílẹ̀ fún iyọ̀. 12 Àwọn igi eléso ní oríṣìíríṣìí ni yóò máa hù ní bèbè odò ní ìhà ìhín àti ní ìhà ọ̀hún. Ewé wọn kì yóò sì rọ, bẹ́ẹ̀ ní èso wọn kì yóò run, wọn yóò máa ṣe èso tuntun rẹ̀ ní oṣù nítorí pé omi láti ibi mímọ́ ń sàn sí wọn. Èso wọn yóò sì jẹ́ fún jíjẹ àti ewé wọn fún ìwòsàn.”

Àwọn ààlà ilẹ̀ náà

13 Èyí yìí ní ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: “Ìwọ̀nyí ni àwọn ààlà tí ìwọ yóò fi pín ilẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí ogún ìní ní àárín àwọn ẹ̀yà méjìlá Israẹli, pẹ̀lú ìpín méjì fún Josẹfu. 14 Ìwọ yóò pín ilẹ̀ náà déédé ní àárín wọn. Nítorí pé mo búra nípa nína ọwọ́ sókè láti fi fún àwọn baba ńlá yin, ilẹ̀ yìí yóò di ogún ìní yín.

15 “Èyí yìí ni yóò jẹ́ ààlà ilẹ̀ náà:

“Ní ìhà àríwá yóò lọ láti omi Òkun ńlá ní ibi ọ̀nà Hetiloni gbà tí Hamati lọ sí Ṣedadi, 16 Berota àti Sibraimu, èyí tí ó wà ní ààlà láàrín Damasku àti Hamati títí dé Hasari Hatikonu, èyí tí ó wà ní agbègbè Haurani. 17 Ààlà yóò fẹ̀ láti Òkun lọ sí Hasari Enanu, ní apá ààlà ti Damasku, pẹ̀lú ààlà tí Hamati lọ sí apá àríwá. Èyí ni yóò jẹ́ ààlà ní apá ìhà àríwá.

18 Ní ìhà ìlà-oòrùn ààlà yóò wá sí àárín Haurani àti Damasku, lọ sí apá Jordani láàrín Gileadi àti ilẹ̀ Israẹli, títí dé Òkun, àti títí dé Tamari. Èyí ní yóò jẹ́ ààlà ìlà-oòrùn.

19 Ní ìhà gúúsù yóò lọ láti Tamari títí dé ibi omi Meriba Kadeṣi, lẹ́yìn náà ni ìhà Wadi tí Ejibiti lọ sí Òkun ńlá. Èyí ni yóò jẹ́ ààlà gúúsù.

20 Ní ìhà ìwọ̀-oòrùn, Òkun ńlá ni yóò jẹ́ ààlà títí dé ibi kan ni òdìkejì lẹ́bàá Hamati. Èyí yìí ni yóò jẹ ààlà ìhà ìwọ̀-oòrùn.

21 “Ìwọ ní láti pín ilẹ̀ yìí ní àárín ara yín gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹ̀yà Israẹli. 22 Ìwọ yóò pín gẹ́gẹ́ bí ìní fún ara yín àti fún àwọn àjèjì tí ó ń gbé ní àárín yín tí ó sì ní àwọn ọmọ. Ìwọ yóò sì ṣe sí wọn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìbílẹ̀ àwọn ará Israẹli; papọ̀ mọ́ yin ni kí ẹ pín ìní fún wọn ní àárín àwọn ẹ̀yà Israẹli. 23 Ní àárín gbogbo ẹ̀yà tí àwọn àlejò ń gbé; wọn gbọdọ̀ fi ìní tirẹ̀ fún un,” ní Olúwa Olódùmarè wí.

Pínpín ilẹ̀ náà

48 “Ìwọ̀nyí ni àwọn ẹ̀yà tí a kọ sílẹ̀ pẹ̀lú orúkọ wọn:

“Ní òpin àríwá, Dani yóò ni ìpín kan; èyí yóò tẹ̀lé ọ̀nà Hetiloni lọ sí Lebo-Hamati; Hasari-Enani àti ààlà àríwá tí Damasku tí ó kángun sí Hamati yóò jẹ́ ara ààlà rẹ̀ láti ìhà ìlà-oòrùn títí lọ sí ìhà ìwọ̀-oòrùn.

Aṣeri yóò ní ìpín kan; yóò jẹ́ ààlà agbègbè Dani láti ìlà-oòrùn lọ sí ìwọ̀-oòrùn.

Naftali yóò ní ìpín kan; èyí yóò jẹ́ ààlà agbègbè Aṣeri láti ìlà-oòrùn lọ sí ìwọ̀-oòrùn.

Manase yóò ní ìpín; èyí yóò jẹ́ ààlà ti agbègbè Naftali láti ìlà-oòrùn sí ìwọ̀-oòrùn.

Efraimu yóò ní ìpín kan; èyí yóò jẹ́ ààlà agbègbè Manase láti ìlà-oòrùn lọ sí ìwọ̀-oòrùn.

Reubeni yóò ní ìpín kan; èyí yóò jẹ́ ààlà agbègbè Efraimu láti ìlà-oòrùn títí dé ìwọ̀-oòrùn.

Juda yóò ní ìpín kan; èyí yóò jẹ́ ààlà agbègbè Reubeni láti ìlà-oòrùn lọ sí ìwọ̀-oòrùn.

“Ní agbègbè Juda, láti ìhà ìlà-oòrùn dé ìhà ìwọ̀-oòrùn ni yóò jẹ́ ìpín tí ìwọ yóò gbé kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn pàtàkì. Èyí tí yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ (25,000) ní ìbú, gígùn rẹ̀ láti ìlà-oòrùn lọ sí ìwọ̀-oòrùn yóò jẹ́ bákan náà bí ọ̀kan nínú àwọn ìpín ìyókù; láti ìhà ìlà-oòrùn dé ìhà ìwọ̀-oòrùn, ibi mímọ́ yóò sì wà ní àárín gbùngbùn rẹ̀.

“Ìpín pàtàkì tí ìwọ yóò fi fún Olúwa yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ní gígùn àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́ ni ìbú. 10 Èyí yóò jẹ́ ìpín ibi mímọ́ fún àwọn àlùfáà. Èyí yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn ní ìhà àríwá, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́ ni ìhà ìlà-oòrùn, ó sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn ní ìhà gúúsù. Ní àárín gbùngbùn rẹ̀ ní ilé fún Olúwa yóò wà. 11 Èyí yóò wà fún àwọn àlùfáà tí a yà sí mímọ́, àwọn ọmọ Sadoku tí wọn jẹ́ olóòtítọ́ nínú sí sìn mí, tiwọn kò sì ṣáko lọ bí ti àwọn Lefi ṣe ṣe nígbà tí àwọn Israẹli ṣáko lọ. 12 Èyí yóò jẹ́ ọrẹ pàtàkì fún wọn láti ara ìpín ibi mímọ́ ilẹ̀ náà, ìpín tí ó jẹ́ mímọ́ jùlọ, tí ó jẹ́ ààlà agbègbè àwọn Lefi.

13 “Ní àkọjúsí agbègbè àwọn àlùfáà, àwọn Lefi yóò pín ìpín kan tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú. Gígùn rẹ̀ ní àpapọ̀ yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹẹdọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́, àti inú rẹ̀ yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́. 14 Wọn kò gbọdọ̀ tà tàbí pààrọ̀ ọ̀kankan nínú rẹ̀. Èyí yìí ni ó dára jùlọ lára ilẹ̀ náà, a kò sì gbọdọ̀ fi fún ẹlòmíràn nítorí pé ó jẹ́ mímọ́ fún Olúwa.

15 “Agbègbè tí o ṣẹ́kù, tí ń ṣe ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ìgbọ̀nwọ́ ni ìbú àti ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, yóò jẹ́ ibi àìmọ́ fun ìlú ńlá náà fún ilé gbígbé àti fún agbègbè: Ìlú ńlá náà yóò wà ní àárín rẹ̀, 16 (B)Ìwọ̀nyí sì níbi a ṣe wọ́n ọ́n: ní ìhà àríwá ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (4,500) ìgbọ̀nwọ́, ni ìhà gúúsù ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (4,500) ìgbọ̀nwọ́, ní ìhà ìlà-oòrùn ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (4,500) ìgbọ̀nwọ́ àti ní ìhà ìwọ̀-oòrùn ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (4,500) ìgbọ̀nwọ́. 17 Ilẹ̀ ìjẹ fún àwọn ẹran ọ̀sìn fún ìlú ńlá náà yóò jẹ igba àti àádọ́ta (250) ìgbọ̀nwọ́ ní ìhà gúúsù, ìgbà àti ìgbà pẹ̀lú àádọ́ta (250) ìgbọ̀nwọ́ ní ìhà ìwọ̀-oòrùn. 18 Èyí tí ó kù ní agbègbè náà, tí ó jẹ́ àkọjúsí ìpín ibi mímọ́, gígùn rẹ̀ yóò sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́ ni ìhà ìlà-oòrùn àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́ ní ìhà ìwọ̀-oòrùn. Ìpèsè rẹ̀ yóò fi kún oúnjẹ fún àwọn òṣìṣẹ́ ìlú ńlá náà. 19 Àwọn òṣìṣẹ́ láti ìlú ńlá náà, tí ó ń dá oko níbẹ̀ yóò wá láti gbogbo àwọn ẹ̀yà Israẹli. 20 Gbogbo ìpín náà yóò rí bákan náà ní ẹ̀gbẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, èyí yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn pàtàkì ìwọ yóò fi ìpín ibi mímọ́ sí ẹ̀gbẹ́ kan, papọ̀ mọ́ ohun ìní ìlú ńlá náà.

21 “Èyí tí ó ṣẹ́kù ni ẹ̀gbẹ́ méjèèjì agbègbè tí ó jẹ́ ìpín ibi mímọ́ àti ohun ìní ìlú ńlá náà yóò jẹ́ ti àwọn ọmọ-aládé. Èyí yóò lọ títí dé ìhà ìlà-oòrùn láti ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ ti ìpín ibi mímọ́ títí dé ààlà ìlà-oòrùn. Agbègbè méjèèjì wọ̀nyí ni gígùn àwọn ìpín ẹlẹ́yàmẹ́yà yóò jẹ́ ti àwọn ọmọ-aládé, àti ìpín ibi mímọ́ pẹ̀lú tẹmpili yóò wa ní àárín wọn. 22 Ilẹ̀ ìní àwọn Lefi àti ohun ìní ìlú ńlá náà yóò wà ni àárín agbègbè tí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ-aládé. Agbègbè tí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ-aládé yóò wà ní àárín ààlà tí Juda àti ààlà tí Benjamini.

23 “Ní ti àwọn ẹ̀yà tí ó kù:

“Benjamini yóò ní ìpín kan; èyí yóò wà láti ìhà ìlà-oòrùn títí dé ìhà ìwọ̀-oòrùn.

24 Simeoni yóò ní ìpín kan: èyí yóò jẹ́ ààlà agbègbè Benjamini láti ìlà-oòrùn lọ sí ìwọ̀-oòrùn.

25 Isakari yóò ní ìpín kan: èyí yóò jẹ́ ààlà agbègbè Simeoni láti ìlà-oòrùn sí ìwọ̀-oòrùn.

26 Sebuluni yóò ní ìpín kan; èyí yóò jẹ́ ààlà agbègbè Isakari láti ìlà-oòrùn sí ìwọ̀-oòrùn.

27 Gadi yóò ní ìpín; èyí yóò jẹ́ ààlà agbègbè Sebuluni láti ìlà-oòrùn sí ìwọ̀-oòrùn.

28 Ààlà tí gúúsù Gadi yóò dé gúúsù láti Tamari lọ sí odò Meriba Kadeṣi lẹ́yìn náà títí dé odo ti Ejibiti lọ sí Òkun ńlá fún àwọn ẹ̀yà Israẹli, ìwọ̀nyí ní yóò sì jẹ́ ìpín wọn” ní Olúwa Ọlọ́run wí.

29 “Èyí ni ilẹ̀ tí ẹ̀yin yóò fi ìbò pín ní ogún fún àwọn ẹ̀yà Israẹli, wọ̀nyí sì ni ìpín wọn,” ní Olúwa Olódùmarè wí.

Àwọn ẹnu-ọ̀nà ìlú ńlá náà

30 “Ìwọ̀nyí ní yóò jẹ́ ẹnu-ọ̀nà àbájáde ìlú ńlá náà:

“Bẹ̀rẹ̀ láti ìhà àríwá, ti ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lè ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (4,500) ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn, 31 (C)ẹnu-ọ̀nà ìlú ńlá náà ní àwa yóò fi orúkọ àwọn ẹ̀yà Israẹli pè. Àwọn ọ̀nà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ní ìhà àríwá ní yóò jẹ́ ọ̀nà tí Reubeni, ọ̀nà tí Juda ọ̀nà tí Lefi.

32 Ní ìhà ìlà-oòrùn, èyí tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ni ojú ọ̀nà mẹ́ta yóò wà: ọ̀nà Josẹfu, ọ̀nà tí Benjamini àti ọ̀nà tí Dani.

33 Ní ìhà gúúsù, èyí tí wíwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lè ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (4,500) ìgbọ̀nwọ́ ní ojú ọ̀nà mẹ́ta yóò wà: ojú ọ̀nà Simeoni, ojú ọ̀nà Isakari àti ojú ọ̀nà Sebuluni.

34 Ní ìhà ìwọ̀-oòrùn, èyí tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (4,500) ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn, ní ojú ọ̀nà mẹ́ta yóò wà: ojú ọ̀nà Gadi, ojú ọ̀nà Aṣeri àti ojú ọ̀nà Naftali.

35 “Jíjìnnà rẹ̀ yípo yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì-dínlógún (18,000) ìgbọ̀nwọ́.

“Orúkọ ìlú náà láti ìgbà náà yóò jẹ́: ‘Olúwa wà níbẹ̀.’ ”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.