Chronological
Ẹ̀kọ́ Daniẹli ní Babeli
1 Ní ọdún kẹta tí Jehoiakimu jẹ ọba Juda, Nebukadnessari ọba Babeli wá sí Jerusalẹmu, ó sì kọlù ú pẹ̀lú àwọn ọmọ-ogun rẹ̀. 2 Olúwa sì fa Jehoiakimu ọba Juda lé e lọ́wọ́, pẹ̀lú àwọn ohun èlò ilé Ọlọ́run. Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ó kó lọ sí ilé òrìṣà ní Babeli, sí inú ilé ìṣúra òrìṣà rẹ̀.
3 Nígbà náà ni ọba pàṣẹ fún Aṣipenasi, olórí àwọn ìwẹ̀fà ààfin rẹ̀ pé, kí ó mú nínú àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wá láti ìdílé ọba àti lára àwọn tí ó wá láti ilé ọlá. 4 Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tí kò ní àbùkù ara, tí wọ́n rẹwà, tí wọ́n sì fi ìfẹ́ sí ẹ̀kọ́ hàn, tí wọ́n sì ní ìmọ̀, tí òye tètè ń yé àti àwọn tí ó kún ojú òṣùwọ̀n láti ṣiṣẹ́ ní ààfin ọba kí ó kọ́ wọ́n ní èdè àti onírúurú ẹ̀kọ́ ìwé ti àwọn Babeli. 5 Ọba pèsè oúnjẹ ojoojúmọ́ àti wáìnì láti orí tábìlì i rẹ̀ fún wọn, ó sì kọ́ wọn fún ọdún mẹ́ta. Lẹ́yìn náà ni wọn yóò bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ fún ọba.
6 Lára àwọn wọ̀nyí ni àwọn tó wá láti Juda: Daniẹli, Hananiah, Miṣaeli àti Asariah. 7 Olórí àwọn ìwẹ̀fà fún wọn ní orúkọ tuntun: Ó fún Daniẹli ní Belteṣassari, ó fún Hananiah ní Ṣadraki, ó fún Miṣaeli ní Meṣaki àti Asariah ní Abednego.
8 Ṣùgbọ́n Daniẹli pinnu ní ọkàn ara rẹ̀ pé òun kò ní ba ara òun jẹ́ pẹ̀lú oúnjẹ àti wáìnì ọba, nígbà náà ni ó gba ààyè lọ́wọ́ olórí àwọn ìwẹ̀fà wí pé òun kò fẹ́ ba ara òun jẹ́ ní ọ̀nà yìí. 9 Ọlọ́run mú kí Daniẹli rí ojúrere àti àánú gbà láti ọwọ́ olórí àwọn ìwẹ̀fà, 10 Ṣùgbọ́n olórí àwọn ìwẹ̀fà sọ fún Daniẹli pé, “Mo bẹ̀rù olúwa mi, ẹni tí o ti pèsè oúnjẹ àti ohun mímu rẹ. Báwo ni ìrísí rẹ yóò ṣe burú jù ti àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin ẹlẹgbẹ́ ẹ̀ rẹ lọ? Nígbà náà ni èmi yóò fi orí mi wéwu lọ́dọ̀ ọba.”
11 Nígbà náà ni Daniẹli sọ fún olùṣọ́ tí olórí àwọn ìwẹ̀fà yàn lórí i Daniẹli, Hananiah, Miṣaeli àti Asariah pé, 12 Jọ̀wọ́ dán àwa ìránṣẹ́ rẹ wò fún ọjọ́ mẹ́wàá: Má ṣe fún wa ní ohun kankan, àfi ewébẹ̀ láti jẹ àti omi láti mu. 13 Nígbà náà ni kí o fi ìrísí i wa wé ti àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tí wọ́n ń jẹ oúnjẹ ọba, kí o sì ṣe àwa ìránṣẹ́ rẹ ní ìbámu pẹ̀lú u bí o bá ṣe rí i sí. 14 Bẹ́ẹ̀ ni ó sì gbà láti dán wọn wò fún ọjọ́ mẹ́wàá.
15 Lẹ́yìn ọjọ́ kẹwàá ara wọn le, wọ́n sì sanra ju àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tí wọ́n ń jẹ oúnjẹ ọba lọ. 16 Bẹ́ẹ̀ ni olùṣọ́ mú oúnjẹ àdídùn àti wáìnì tí ó yẹ kí wọ́n mu kúrò, ó sì fún wọn ní ewébẹ̀ dípò rẹ̀.
17 Ọlọ́run fún àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wọ̀nyí ní ìmọ̀ àti òye nínú gbogbo onírúurú ìwé àti ẹ̀kọ́ ọ wọn: Daniẹli sì ní òye ìran àti àlá ní oríṣìíríṣìí.
18 Ní òpin ìgbà tí ọba dá, pé kí a mú wọn wá sínú ààfin, olórí àwọn ìwẹ̀fà mú wọn wá síwájú ọba Nebukadnessari. 19 Ọba sì bá wọn sọ̀rọ̀, ó sì rí i pé kò sí ẹni tí ó dàbí i Daniẹli, Hananiah, Miṣaeli àti Asariah; Nítorí náà wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe iṣẹ́ ọba. 20 Nínú gbogbo ọ̀ràn ọgbọ́n àti òye tí ọba ń béèrè lọ́wọ́ wọn, ó rí i pé wọ́n sàn ní ìlọ́po mẹ́wàá ju gbogbo àwọn amòye àti ọlọ́gbọ́n tí ó wà ní gbogbo ìjọba rẹ̀.
21 Daniẹli sì wà níbẹ̀ títí di ọdún kìn-ín-ní ọba Kirusi.
Àlá Nebukadnessari
2 Ní ọdún kejì ìjọba Nebukadnessari, ó lá àlá, èyí tí ó mú kí ọkàn an rẹ̀ dàrú, kò sì le è sùn. 2 Nígbà náà ni ọba yára pe àwọn onídán, àwọn aláfọ̀ṣẹ, àwọn oṣó àti àwọn awòràwọ̀; àwọn tó ní ìmọ̀ àti àṣírí i títúmọ̀ ìràwọ̀, ọba pè wọ́n kí wọn wá sọ àlá tí ó lá. Nígbà tí wọ́n dé, tí wọ́n dúró níwájú ọba, 3 ọba sì wí fún wọn pé, “Mo ti lá àlá kan èyí tí ó mú kí ọkàn mi dàrú, mo sì fẹ́ mọ ìtumọ̀ àlá náà.”
4 Nígbà náà ni àwọn awòràwọ̀ dá ọba lóhùn ní èdè Aramaiki pé, “Kí ọba kí ó pẹ́! Sọ àlá yìí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ àwa yóò sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún ọ.”
5 Ọba dá àwọn awòràwọ̀ lóhùn pé, “Ohun náà ti kúrò lórí mi: tí ẹ̀yin kò bá sọ àlá náà àti ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, èmi yóò gé e yín sí wẹ́wẹ́, ilé e yín yóò sì di ààtàn. 6 Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá sọ àlá náà àti ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, èmi yóò fún un yín ní ẹ̀bùn, ọrẹ àti ọláńlá tí ó pọ̀. Nítorí náà, ẹ sọ àlá náà àti ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi.”
7 Lẹ́ẹ̀kan sí i, “Wọ́n tún dáhùn pé, jẹ́ kí ọba sọ àlá náà fún ìránṣẹ́ rẹ̀, àwa yóò sì túmọ̀ rẹ̀.”
8 Nígbà náà ni ọba sọ pé, “Èmi mọ̀ dájú wí pé ẹ̀yin fẹ́ fi àkókò ṣòfò nítorí pé ẹ̀yin ti mọ̀ pé nǹkan ti lọ ní orí mi: 9 Tí ẹ̀yin kò bá lè sọ àlá mi, ìjìyà kan ṣoṣo ló wà fún un yín. Ẹ̀yin ti gbèrò láti pa irọ́ àti láti sọ àwọn ọ̀rọ̀ ti ó lè si ni lọ́nà fún mi, títí tí nǹkan yóò fi yí wọ́. Nítorí náà ẹ rọ́ àlá náà fún mi, èmi yóò sì mọ̀ pé ẹ lè túmọ̀ rẹ̀ fún mi.”
10 Àwọn awòràwọ̀ sì dá ọba lóhùn pé, “Kò sí ènìyàn kan ní ayé tí ó lè sọ nǹkan tí ọba béèrè! Kò sí ọba náà bí ó ti wù kí ó tóbi àti kí ó lágbára tó, tí í béèrè irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ àwọn onídán tàbí aláfọ̀ṣẹ tàbí awòràwọ̀. 11 Nǹkan tí ọba béèrè yìí ṣòro púpọ̀. Kò sí ẹni tí ó lè fihan ọba àfi àwọn òrìṣà, tí wọn kì í gbé láàrín ènìyàn.”
12 Èyí mú kí ọba bínú, ó sì kanra, nítorí náà ó pàṣẹ kí a pa gbogbo àwọn amòye Babeli run. 13 Nítorí náà àṣẹ yìí jáde lọ wí pé kí a pa àwọn amòye, wọ́n ránṣẹ́ pe Daniẹli pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ láti pa wọ́n.
14 Nígbà tí Arioku, olórí àwọn olùṣọ́ ọba, jáde láti lọ pa àwọn amòye Babeli, Daniẹli sọ̀rọ̀ fún un pẹ̀lú ọgbọ́n àti òye. 15 Ó béèrè lọ́wọ́ olórí àwọn olùṣọ́ ọba wí pé, “Èéṣe tí àṣẹ ọba fi yá kánkán bẹ́ẹ̀?” Arioku sì ṣe àlàyé ọ̀rọ̀ náà fún Daniẹli. 16 Nígbà náà ni Daniẹli wọlé tọ ọba lọ, ó sì tọrọ kí ọba fún òun ní ààyè, òun yóò fi ìtumọ̀ àlá náà hàn fún ọba.
17 Nígbà náà ni Daniẹli padà lọ sí ilé e rẹ̀, ó sì sọ fún àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ Hananiah, Miṣaeli àti Asariah. 18 Ó sọ fún wọn pé kí wọn béèrè fún àánú Ọlọ́run, Olúwa ọ̀run, nítorí àṣírí yìí, kí Daniẹli pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ má ba ṣègbé pẹ̀lú àwọn ọlọ́gbọ́n Babeli yòókù, tí ó wà ní Babeli. 19 Ní òru, àṣírí náà hàn sí Daniẹli ní ojú ìran. Nígbà náà ni Daniẹli fi ògo fún Ọlọ́run ọ̀run 20 Daniẹli wí pé:
“Ọpẹ́ ni fún orúkọ Ọlọ́run láé àti láéláé;
tirẹ̀ ni ọgbọ́n àti agbára
21 Ó yí ìgbà àti àkókò padà;
ó mú ọba jẹ, ó ń mú wọn kúrò.
Ó fún àwọn amòye ní ọgbọ́n
àti ìmọ̀ fún àwọn tí ó ní òye.
22 Ó fi ohun ìjìnlẹ̀ àti àṣírí hàn;
ó mọ ohun tí ó pamọ́ nínú òkùnkùn
àti ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìmọ́lẹ̀ wà
23 Mo dúpẹ́, mo sì fi ìyìn fún ọ, ìwọ Ọlọ́run àwọn baba mi:
ó ti fún mi ní ọgbọ́n àti agbára
ó ti fi àwọn nǹkan tí a béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ hàn fún mi
nítorí tí ìwọ ti fi àlá ọba hàn wá.”
Daniẹli túmọ̀ àlá
24 Nígbà náà ni Daniẹli tọ́ Arioku lọ, ẹni tí ọba yàn láti pa àwọn amòye Babeli run, Daniẹli wí fún un pé, “Má ṣe pa àwọn amòye Babeli run. Mú mi lọ sí ọ̀dọ̀ ọba, èmi yóò sísọ ìtumọ̀ àlá rẹ̀ fún un.”
25 Lẹ́sẹ̀kan náà, Arioku yára mú Daniẹli lọ sí iwájú ọba, ó sọ fún ọba pé, “Èmi ti rí ọkùnrin kan lára àwọn àjèjì tí ó wá láti Juda, ẹni tí ó lè sọ ìtumọ̀ àlá náà fún ọba.”
26 Ọba béèrè lọ́wọ́ Daniẹli ẹni tí a tún ń pè ní Belṣassari pé, “Ṣé ìwọ lè sọ ohun tí mo rí nínú àlá mi àti ìtumọ̀ ọ rẹ̀ fún mi?”
27 Daniẹli dá ọba lóhùn pé, “Kò sí awòràwọ̀ kan, apògèdè, onídán tàbí aláfọ̀ṣẹ tí ó lè ṣe àlàyé àṣírí tí ọba béèrè fún 28 ṣùgbọ́n, Ọlọ́run kan ń bẹ ní ọ̀run tí ó ń fi àṣírí hàn. Ó ti fihan ọba Nebukadnessari, ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ìkẹyìn ọjọ́. Àlá àti ìran tí o rí nígbà tí o dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ ni ìwọ̀nyí:
29 “Ọba, bí ìwọ ṣe sùn sórí ibùsùn rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ọkàn rẹ ń ro àwọn ohun tó ń bọ̀, olùfihàn àṣírí ń fi ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ fún ọ. 30 Ṣùgbọ́n fún èmi, a fi àṣírí yìí hàn mí, kì í ṣe pé mo ní ọgbọ́n tí ó pọ̀ ju ti alààyè kankan lọ, ṣùgbọ́n nítorí kí ọba lè mọ ìtumọ̀ àlá àti kí ó lè mọ ohun tí ó wà ní ọkàn rẹ̀.
31 “Ìwọ ọba ń wo, ère ńlá kan tí ó dúró níwájú rẹ, ère náà ga, ó sì dára láti wò, ìrísí i rẹ̀ ba ni lẹ́rù jọjọ. 32 Orí ère náà jẹ́ kìkì wúrà, àyà rẹ̀ àti ọwọ́ rẹ̀ jẹ́ fàdákà, inú àti ẹ̀gbẹ́ itan rẹ̀ jẹ́ idẹ, 33 àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀ jẹ́ irin, àwọn àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ jẹ́ apá kan irin àti apá kan amọ̀. 34 Bí ó ṣe ń wò, òkúta kan wá, tí kò wá láti ọwọ́ ẹnìkankan. Ó kọlu ère náà ní àtẹ́lẹsẹ̀ irin àti amọ̀, ó sì fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́. 35 Nígbà náà ni irin, amọ̀, idẹ, fàdákà àti wúrà fọ́ sí wẹ́wẹ́ lẹ́sẹ̀kan náà, ó sì dàbí ìyàngbò tí a fẹ́ kúrò lórí ọkà ní àsìkò ẹ̀ẹ̀rùn. Afẹ́fẹ́ gbé gbogbo rẹ̀ lọ láìṣẹ́ku ọ̀kan mọ́, òkúta tí ó fọ́ ère náà sì di òkè ńlá, ó sì gba gbogbo ayé.
36 “Èyí ni àlá náà, nígbà yìí ni a ó wá sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún ọba. 37 Ìwọ ọba jẹ́ ọba àwọn ọba. Ọlọ́run ọ̀run ti fi ìjọba agbára, títóbi àti ògo fún ọ; 38 ní ọwọ́ rẹ ló fi gbogbo ènìyàn, àwọn ẹranko igbó àti ẹyẹ ojú ọ̀run sí. Ní ibi gbogbo tí wọ́n ń gbé, ó ti fi ọ́ ṣe olórí i wọn. Ìwọ ni orí wúrà náà.
39 “Lẹ́yìn èyí ni ìjọba mìíràn yóò dìde, tí kò ní lágbára tó tìrẹ, lẹ́yìn in rẹ̀, ìjọba kẹta tí yóò dàbí idẹ, èyí tí yóò jẹ ọba lórí i gbogbo ayé. 40 Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ìjọba kẹrin yóò wà, ìjọba náà yóò lágbára bí irin, gẹ́gẹ́ bí irin ti í fọ́, tó sì ń lọ gbogbo nǹkan àti bí irin ti í fọ́ nǹkan sí wẹ́wẹ́, bẹ́ẹ̀ ni yóò fọ́ tí yóò sì lọ gbogbo àwọn tókù. 41 Bí o ṣe rí i tí àtẹ́lẹsẹ̀ àti ọmọ ìka ẹsẹ̀ jẹ́ apá kan amọ̀ àti apá kan irin, bẹ́ẹ̀ ni ìjọba yóò ṣe pín; ṣùgbọ́n yóò sì ní agbára irin díẹ̀ nínú rẹ̀, bí ó ṣe rí i tí irin dàpọ̀ mọ́ amọ̀. 42 Bí ọmọ ìka ẹsẹ̀ ṣe jẹ́ apá kan irin àti apá kan amọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìjọba yìí yóò lágbára lápákan tí kò sì ní lágbára lápákan. 43 Gẹ́gẹ́ bí o ti rí i tí irin dàpọ̀ mọ́ amọ̀, báyìí ni àwọn ènìyàn yóò ṣe dàpọ̀ mọ́ ara wọn ní ti ìgbéyàwó, ṣùgbọ́n wọn kò ní wà ní ìṣọ̀kan, bí irin kò ṣe dàpọ̀ mọ́ amọ̀.
44 “Ní àsìkò àwọn ọba náà, Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba èyí tí kò le è bàjẹ́ kalẹ̀, èyí tí a kò ní fi lé ẹlòmíràn lọ́wọ́. Yóò sì run gbogbo ìjọba, yóò sì mú wọn wá sí òpin, ṣùgbọ́n ìjọba yìí yóò dúró láéláé.” 45 Gẹ́gẹ́ bí o ṣe rí i pé a gé òkúta láti ara òkè, láì ti ọwọ́ ẹnikẹ́ni wá, òkúta èyí tí ó fọ́ irin, idẹ, amọ̀, fàdákà àti wúrà sí wẹ́wẹ́.
“Ọlọ́run tí ó tóbi ti fihan ọba, ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ iwájú. Òtítọ́ ni àlá náà, bẹ́ẹ̀ ni ìtumọ̀ rẹ̀ ṣe é gbẹ́kẹ̀lé.”
46 Nígbà náà, ni Nebukadnessari ọba dojúbolẹ̀ níwájú u Daniẹli ó sì fi orí balẹ̀ fún un, ó sì pàṣẹ pé kí wọn kí ó mu ọrẹ àti òórùn tùràrí fún Daniẹli 47 Ọba wí fún Daniẹli pé, “Dájúdájú Ọlọ́run rẹ ni Ọlọ́run àwọn ọlọ́run àti Olúwa àwọn ọba gbogbo àti olùfihàn àwọn àṣírí, nítorí tí ìwọ lè fi àṣírí yìí hàn.”
48 Nígbà náà ni ọba gbé Daniẹli ga, ó sì fún un ní ẹ̀bùn ńlá tí ó pọ̀. Ó sì fi ṣe olórí i gbogbo agbègbè ìjọba Babeli àti olórí gbogbo àwọn amòye Babeli. 49 Daniẹli béèrè lọ́wọ́ ọba, ó sì yan Ṣadraki, Meṣaki, àti Abednego gẹ́gẹ́ bí alábojútó ìgbèríko Babeli ṣùgbọ́n Daniẹli fúnrarẹ̀ wà ní ààfin ọba.
Ère wúrà àti iná ìléru
3 Nebukadnessari ọba gbẹ́ ère wúrà kan, èyí tí gíga rẹ̀ tó àádọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́, tí fífẹ̀ rẹ̀ tó ẹsẹ̀ mẹ́fà, ó sì gbé e kalẹ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Dura ní agbègbè ìjọba Babeli. 2 Nígbà náà ni ọba ránṣẹ́ pe àwọn ọmọ-aládé, àwọn olóyè, àwọn ìgbìmọ̀, àwọn baálẹ̀, àwọn balógun, àwọn onídàájọ́, àwọn olùtọ́jú ìṣúra àti gbogbo àwọn olórí agbègbè ìjọba láti wá sí ibi ìyàsímímọ́ ère tí ọba Nebukadnessari gbé kalẹ̀. 3 Nígbà náà ni àwọn ọmọ-aládé, àwọn olóyè, àwọn onímọ̀ràn, àwọn olùtọ́jú ìṣúra, àwọn onídàájọ́ àti gbogbo àwọn olórí agbègbè ìjọba, wọn péjọ láti ya ère tí Nebukadnessari ọba gbé kalẹ̀ sí mímọ́, gbogbo wọn sì dúró síwájú u rẹ̀.
4 Nígbà náà ni a kéde kígbe sókè wí pé, “Ohun tí a paláṣẹ fún un yín láti ṣe nìyìí, gbogbo ènìyàn, orílẹ̀-èdè àti èdè gbogbo: 5 (A)Bí ẹ̀yin bá ti gbọ́ ohùn ìwo, fèrè, dùùrù, ohun èlò, kí ẹ wólẹ̀ fún ère wúrà tí ọba Nebukadnessari gbé kalẹ̀. 6 Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ tí kò bá wólẹ̀, kí ó fi orí balẹ̀, kí a ju ẹni náà sínú iná ìléru.”
7 Nítorí náà, bí wọ́n ṣe gbọ́ ohùn ìwo, fèrè, dùùrù, ohun èlò orin olókùn, ìpè àti onírúurú orin, gbogbo ènìyàn, orílẹ̀-èdè, àti èdè gbogbo wólẹ̀, wọ́n sì fi orí balẹ̀ fún ère wúrà tí ọba Nebukadnessari gbé kalẹ̀.
8 Ní àsìkò yìí ni àwọn awòràwọ̀ bọ́ síwájú, wọ́n sì fi ẹ̀sùn kan àwọn ará Juda. 9 Wọ́n sọ fún ọba Nebukadnessari pé, “Kí ọba kí ó pẹ́. 10 Ìwọ ọba ti pàṣẹ pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá ti gbọ́ ohùn ìwo, fèrè, dùùrù, ohun èlò orin olókùn, ìpè àti onírúurú orin gbọdọ̀ wólẹ̀ kí ó fi orí balẹ̀ fún ère wúrà 11 àti ẹnikẹ́ni tí kò bá wólẹ̀, kí ó foríbalẹ̀, a ó sọ irú ẹni bẹ́ẹ̀ sínú iná ìléru. 12 Ṣùgbọ́n àwọn ará Juda kan wà, àwọn tí a yàn láti ṣe olórí agbègbè ìjọba Babeli: Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego, wọ́n ò ka ìwọ ọba sí. Wọn kò sin òrìṣà rẹ, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fi orí balẹ̀ fún ère wúrà tí ìwọ gbé kalẹ̀.”
13 Nígbà náà ni Nebukadnessari pàṣẹ ní ìrunú àti ìbínú pé kí a mú Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego wá, wọ́n sì mú wọn wá síwájú ọba. 14 Nebukadnessari wí fún wọn wí pé, “Ṣé òtítọ́ ni, Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego wí pé ẹ̀yin kò sin òrìṣà mi àti pé ẹ̀yin kò fi orí balẹ̀ fún ère wúrà tí èmi gbé kalẹ̀. 15 Ní ìsinsin yìí, tí ẹ̀yin bá ti gbọ́ ohùn ìwo, fèrè, dùùrù, ohun èlò orin olókùn, ìpè àti onírúurú orin, bí ẹ̀yin bá ṣetán láti wólẹ̀ kí ẹ̀yin fi orí balẹ̀ fún ère tí mo gbé kalẹ̀ ó dára. Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yìn bá kọ̀ láti sìn ín, lójúkan náà ni a ó gbé e yín jù sínú iná ìléru. Ǹjẹ́, ta ni Ọlọ́run náà tí yóò gbà yín kúrò lọ́wọ́ mi?”
16 Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego dá ọba lóhùn wí pé, “Nebukadnessari, kì í ṣe fún wa láti gba ara wa sílẹ̀ níwájú u rẹ nítorí ọ̀rọ̀ yìí. 17 Bí ẹ̀yin bá jù wá sínú iná ìléru, Ọlọ́run tí àwa ń sìn lágbára láti gbà wá kúrò nínú rẹ̀, yóò sì gbà wá lọ́wọ́ ọ̀ rẹ, ìwọ ọba. 18 Ṣùgbọ́n tí kò bá rí bẹ́ẹ̀, a fẹ́ kí ìwọ ọba mọ̀ dájú wí pé àwa kò ní sin òrìṣà rẹ bẹ́ẹ̀ ni a kò ní fi orí balẹ̀ fún ère wúrà tí ìwọ gbé kalẹ̀.”
19 Nígbà náà ni Nebukadnessari bínú gidigidi sí Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego, ojú u rẹ̀ sì yípadà, ó sì pàṣẹ pé, kí wọn dá iná ìléru náà kí ó gbóná ní ìlọ́po méje ju èyí tí wọn ń dá tẹ́lẹ̀, 20 ó sì pàṣẹ fún àwọn alágbára nínú ogun rẹ̀ pé, kí wọ́n de Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego, kí wọn sì jù wọ́n sínú iná ìléru. 21 Nígbà náà ni a dè wọ́n pẹ̀lú àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọn, ṣòkòtò, ìbòrí àti àwọn aṣọ mìíràn, a sì jù wọ́n sínú iná ìléru. 22 Nítorí bí àṣẹ ọba ṣe le tó, tí iná ìléru náà sì gbóná, ọwọ́ iná pa àwọn ọmọ-ogun tí wọ́n mú Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego lọ. 23 Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego ṣubú lulẹ̀ sínú iná ìléru náà pẹ̀lú bí a ṣe dè wọ́n.
24 Nígbà náà ni ó ya Nebukadnessari ọba lẹ́nu, ó sì yára dìde dúró, ó béèrè lọ́wọ́ àwọn ìgbìmọ̀ rẹ̀ pé, “Ṣe bí àwọn mẹ́ta ni a gbé jù sínú iná?”
Wọ́n wí pé, “Òtítọ́ ni ọba.”
25 Ó sì wí pé, “Wò ó! Mo rí àwọn mẹ́rin tí a kò dè tí wọ́n ń rìn ká nínú iná, ẹni kẹrin dàbí ọmọ Ọlọ́run.”
26 Nígbà náà, ni Nebukadnessari dé ẹnu-ọ̀nà iná ìléru, ó sì kígbe pé, “Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego, ìránṣẹ́ Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo, ẹ jáde, ẹ wá níbi!”
Nígbà náà ni Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego jáde láti inú iná. 27 Àwọn ọmọ-aládé, ìjòyè, baálẹ̀, àwọn ìgbìmọ̀ ọba péjọ sí ọ̀dọ̀ ọ wọn. Wọ́n rí i wí pé iná kò ní agbára lára wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò jó wọn lára, bẹ́ẹ̀ ni irun orí wọn kò jóná, àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọn kò jóná, òórùn iná kò rùn ní ara wọn rárá.
28 Nígbà náà, ni Nebukadnessari sọ wí pé, “Ìbùkún ni fún Ọlọ́run Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego, ẹni tí ó rán angẹli rẹ̀ láti gba àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó gbẹ́kẹ̀lé e, wọn kọ àṣẹ ọba, dípò èyí, wọ́n fi ara wọn lélẹ̀ ju kí wọn sìn tàbí foríbalẹ̀ fún ọlọ́run mìíràn yàtọ̀ sí Ọlọ́run wọn. 29 Nítorí náà, mo pa àṣẹ pé, ẹnikẹ́ni, orílẹ̀-èdè tàbí èdè kan tí ó bá sọ ọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego kí a gé wọn sí wẹ́wẹ́ kí a sì sọ ilé e wọn di ààtàn; nítorí kò sí ọlọ́run mìíràn tí ó lè gba ènìyàn bí irú èyí.”
30 Nígbà náà ni ọba gbé Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego ga ní gbogbo agbègbè ìjọba Babeli.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.