Chronological
Ọlọ́run ṣe ìpinnu láti bùkún Jerusalẹmu
8 Ọ̀rọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun si tún tọ́ mí wá.
2 Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Owú ńláńlá ni mo jẹ fún Sioni, pẹ̀lú ìbínú ńláńlá ni mo fi jowú fún un.”
3 Báyìí ni Olúwa wí: “Mo yípadà sí Sioni èmi ó sì gbé àárín Jerusalẹmu: Nígbà náà ni a ó sì pé Jerusalẹmu ni ìlú ńlá òtítọ́; àti òkè ńlá Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ni a ó pè ní òkè ńlá mímọ́.”
4 Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Arúgbó ọkùnrin, àti arúgbó obìnrin, yóò gbé ìgboro Jerusalẹmu, àti olúkúlùkù pẹ̀lú ọ̀pá ni ọwọ́ rẹ̀ fún ogbó. 5 Ìgboro ìlú yóò sì kún fún ọmọdékùnrin, àti ọmọdébìnrin, tí ń ṣiré ní ìta wọn.”
6 Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Bí ó bá ṣe ìyanu ní ojú ìyókù àwọn ènìyàn yìí ni ọjọ́ wọ̀nyí, ǹjẹ́ ó ha lè jẹ́ ìyanu ni ojú mi bí?” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
7 Báyìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Kíyèsi i, èmi ó gba àwọn ènìyàn mi kúrò ni ilẹ̀ ìlà-oòrùn, àti kúrò ni ilẹ̀ ìwọ̀-oòrùn. 8 Èmi ó sì mú wọn padà wá, wọn ó sì máa gbé àárín Jerusalẹmu. Wọn ó sì jẹ́ ènìyàn mi, èmi ó sì jẹ́ Ọlọ́run wọn, ní òtítọ́, àti ní òdodo.”
9 Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Jẹ́ kí ọwọ́ yín le ẹ̀yin ti ń gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní ọjọ́ wọ̀nyí ni ẹnu àwọn wòlíì tí ó wà ni ọjọ́ tí a fi ìpìlẹ̀ ilé Olúwa àwọn ọmọ-ogun lélẹ̀, jẹ́ ki ọwọ́ rẹ̀ le kí a bá lè kọ́ tẹmpili. 10 Nítorí pé, ṣáájú ọjọ́ wọ̀nyí, owó ọ̀yà ènìyàn kò tó nǹkan, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀yà ẹran pẹ̀lú, bẹ́ẹ̀ ni kò sí àlàáfíà fún ẹni ń jáde lọ, tàbí ẹni ti ń wọlé bọ, nítorí ìpọ́njú náà: nítorí mo dojú gbogbo ènìyàn, olúkúlùkù kọ aládùúgbò rẹ̀. 11 Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí èmi kì yóò ṣè sí ìyókù àwọn ènìyàn yìí gẹ́gẹ́ bí tí ìgbà àtijọ́,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
12 “Nítorí irúgbìn yóò gbilẹ̀: àjàrà yóò ṣo èso rẹ̀, ilẹ̀ yóò sì hu ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan rẹ̀ jáde, àwọn ọ̀run yóò sì mu ìrì wọn wá; èmi ó sì mu kí èyí jẹ ogún ìní àwọn ìyókù ènìyàn yìí ni gbogbo nǹkan wọ̀nyí. 13 Yóò sì ṣe, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin tí jẹ́ ègún láàrín àwọn kèfèrí, ẹ̀yin ilé Juda, àti ilé Israẹli, bẹ́ẹ̀ ni èmi ó gbà yín sílẹ̀; ẹ̀yin o sì jẹ́ ìbùkún: ẹ má bẹ̀rù, ṣùgbọ́n jẹ́ ki ọwọ́ yín le.”
14 Nítorí báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Gẹ́gẹ́ bí mo ti rò láti ṣe yín níbi nígbà tí àwọn baba yín mú mi bínú,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, tí èmi kò sì ronúpìwàdà. 15 “Bẹ́ẹ̀ ni èmi sì ti ro ọjọ́ wọ̀nyí láti ṣe rere fún Jerusalẹmu, àti fún ilé Juda: ẹ má bẹ̀rù. 16 (A)Wọ̀nyí ni nǹkan tí ẹ̀yin ó ṣe: ki olúkúlùkù yín kí ó máa ba ọmọnìkejì rẹ̀ sọ òtítọ́; ṣe ìdájọ́ tòótọ́ àti àlàáfíà ní àwọn ibodè yín. 17 Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnìkan ro ibi ni ọkàn rẹ̀ sí ẹnìkejì rẹ̀; ẹ má fẹ́ ìbúra èké; nítorí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni mo kórìíra,” ni Olúwa wí.
18 Ọ̀rọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun sì tọ mi wá wí pé.
19 Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Àwẹ̀ oṣù kẹrin, karùn-ún, keje, àti tí ẹ̀kẹwàá, yóò jẹ́ ayọ̀ àti dídùn inú, àti àpéjọ àríyá fún ilé Juda; nítorí náà, ẹ fẹ́ òtítọ́ àti àlàáfíà.”
20 Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Àwọn ènìyàn yóò sá à tún wa, àti ẹni tí yóò gbe ìlú ńlá púpọ̀. 21 Àwọn ẹni tí ń gbé ìlú ńlá kan yóò lọ sí òmíràn, wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí a yára lọ gbàdúrà kí a sì wá ojúrere Olúwa, àti láti wá Olúwa àwọn ọmọ-ogun. Èmi pẹ̀lú yóò sì lọ.’ 22 Nítòótọ́, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn àti àwọn alágbára orílẹ̀-èdè yóò wá láti wá Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní Jerusalẹmu; àti láti gbàdúrà, àti láti wá ojúrere Olúwa.”
23 Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí ni ọkùnrin mẹ́wàá láti inú gbogbo èdè àti orílẹ̀-èdè yóò dìímú, àní yóò di etí aṣọ ẹni tí i ṣe Júù mú, wí pé, ‘Àwa yóò ba ọ lọ, nítorí àwa tí gbọ́ pé, Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ.’ ”
Ìdájọ́ lórí àwọn ọ̀tá Israẹli
9 Ọ̀rọ̀-ìmọ̀:
Ọ̀rọ̀ Olúwa kọjú ìjà sí Hadiraki,
Damasku ni yóò sì jẹ́ ibi ìsinmi rẹ̀;
nítorí ojú Olúwa ń bẹ lára ènìyàn,
àti lára gbogbo ẹ̀yà Israẹli.
2 Àti Hamati pẹ̀lú yóò ṣe ààlà rẹ̀
Tire àti Sidoni bí o tilẹ̀ ṣe ọlọ́gbọ́n gidigidi.
3 Tire sì mọ odi líle fún ara rẹ̀,
ó sì kó fàdákà jọ bí eruku,
àti wúrà dáradára bí ẹrẹ̀ ìgboro.
4 Ṣùgbọ́n, Olúwa yóò kó gbogbo ohun ìní rẹ̀ lọ,
yóò sì pa agbára rẹ̀ run ní ojú Òkun,
a ó sì fi iná jó o run.
5 Aṣkeloni yóò rí í, yóò sì bẹ̀rù;
Gasa pẹ̀lú yóò rí í, yóò sì káàánú gidigidi,
àti Ekroni: nítorí tí ìrètí rẹ̀ yóò ṣákì í.
Gasa yóò pàdánù ọba rẹ̀,
Aṣkeloni yóò sì di ahoro.
6 Ọmọ àlè yóò sì gbé inú Aṣdodu,
Èmi yóò sì gé ìgbéraga àwọn Filistini kúrò.
7 Èmi yóò sì mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ kúrò ni ẹnu rẹ̀,
àti àwọn ohun èèwọ̀ kúrò láàrín eyín rẹ̀:
ṣùgbọ́n àwọn tó ṣẹ́kù yóò jẹ́ tí Ọlọ́run wa,
wọn yóò sì jẹ baálẹ̀ ní Juda,
àti Ekroni ni yóò rí bí Jebusi.
8 Èmi yóò sì dó yí ilẹ̀ mi ká
nítorí ogun àwọn tí wọ́n ń wá ohun tí wọn yóò bàjẹ́ kiri,
kò sí aninilára tí yóò bori wọn mọ́:
nítorí ni ìsinsin yìí ni mo fi ojú ṣọ́ wọn.
Ọba sioni ń bọ̀
9 (B)Kún fún ayọ̀, ìwọ ọmọbìnrin Sioni,
hó ìhó ayọ̀, ìwọ ọmọbìnrin Jerusalẹmu:
Wo ọba rẹ ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ:
òdodo ni òun, ó sì ní ìgbàlà;
ó ní ìrẹ̀lẹ̀, ó sì ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,
àní ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.
10 Èmi ó sì gbé kẹ̀kẹ́ kúrò ni Efraimu,
àti ẹṣin ogun kúrò ni Jerusalẹmu,
a ó sì ṣẹ́ ọrun ogun.
Òun yóò sì kéde àlàáfíà sí àwọn kèfèrí.
Ìjọba rẹ̀ yóò sì gbilẹ̀ láti Òkun dé Òkun,
àti láti odò títí de òpin ayé.
11 Ní tìrẹ, nítorí ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú mi pẹ̀lú rẹ,
Èmi ó dá àwọn ìgbèkùn rẹ̀ sílẹ̀ kúrò nínú ọ̀gbun.
12 Ẹ padà sínú odi agbára yín, ẹ̀yin òǹdè ti o ni ìrètí:
àní lónìí yìí èmi sọ pé, èmi o san án fún ọ ni ìlọ́po méjì.
13 Èmi ó fa Juda le bí mo ṣe fa ọrun mi le,
mo sì fi Efraimu kún un,
Èmi yóò gbé àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin dìde, ìwọ Sioni,
sí àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, ìwọ Giriki,
mo ṣe ọ́ bí idà alágbára.
Olúwa yóò farahàn
14 Olúwa yóò sì fi ara hàn ní orí wọn;
ọfà rẹ̀ yóò sì jáde lọ bí mọ̀nàmọ́ná.
Olúwa Olódùmarè yóò sì fọn ìpè,
Òun yóò sì lọ nínú atẹ́gùn ìjì gúúsù.
15 Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò dáàbò bò wọ́n;
wọn ó sì jẹ ni run,
wọn ó sì tẹ òkúta kànnàkànnà mọ́lẹ̀;
wọn ó sì mu ẹ̀jẹ̀ wọn bí wáìnì,
wọn ó sì kún bí ọpọ́n,
wọn ó sì rin ṣinṣin bí àwọn igun pẹpẹ.
16 Olúwa Ọlọ́run wọn yóò sì gbà wọ́n là ni ọjọ́ náà
bí agbo ènìyàn rẹ̀:
nítorí wọn ó dàbí àwọn òkúta adé,
tí a gbé sókè bí ààmì lórí ilẹ̀ rẹ̀.
17 Nítorí oore rẹ̀ tí tóbi tó, ẹwà rẹ̀ sì tí pọ̀!
Ọkà yóò mú ọ̀dọ́mọkùnrin dárayá,
àti ọtí wáìnì tuntun yóò mú àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.
Olúwa yóò gba Juda
10 Ẹ béèrè òjò nígbà àrọ̀kúrò ni ọwọ́ Olúwa;
Olúwa tí o dá mọ̀nàmọ́ná,
tí ó sì fi ọ̀pọ̀ òjò fún ènìyàn,
fún olúkúlùkù koríko ní pápá.
2 Nítorí àwọn òrìṣà tí sọ̀rọ̀ asán,
àwọn aláfọ̀ṣẹ sì tí rí èké,
wọn sì tí rọ àlá èké;
wọ́n ń tu ni nínú lásán,
nítorí náà àwọn ènìyàn náà ṣáko lọ bí àgùntàn,
a ṣẹ wọn níṣẹ̀ẹ́, nítorí Olùṣọ́-àgùntàn kò sí.
3 “Ìbínú mi ru sí àwọn darandaran,
èmi o sì jẹ àwọn olórí ní yà
nítorí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti bẹ agbo rẹ̀,
ilé Juda wò,
yóò sì fi wọn ṣe ẹṣin rẹ̀ dáradára ní ogun.
4 Láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni òkúta igun ilé ti jáde wá,
láti ọ̀dọ̀ rẹ ni èèkàn àgọ́ tí wá,
láti ọ̀dọ̀ rẹ ni ọrún ogun tí wá,
láti ọ̀dọ̀ rẹ ni àwọn akóniṣiṣẹ́ gbogbo tí wá.
5 Gbogbo wọn yóò sì dàbí ọkùnrin
alágbára ni ogun tí ń tẹ àwọn ọ̀tá wọn mọ́lẹ̀ ní ìgboro, wọn ó sì jagun,
nítorí Olúwa wà pẹ̀lú wọn,
wọn ó sì dààmú àwọn tí ń gun ẹṣin.
6 “Èmi o sì mú ilé Juda ní agbára,
èmi o sì gba ilé Josẹfu là,
èmi ó sì tún mú wọn padà
nítorí mo tí ṣàánú fún wọn,
ó sì dàbí ẹni pé èmi kò ì tì í ta wọ́n nù;
nítorí èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn,
èmi o sì gbọ́ tiwọn
7 Efraimu yóò sì ṣe bí alágbára,
ọkàn wọn yóò sì yọ̀ bi ẹni pé nípa ọtí wáìnì:
àní àwọn ọmọ wọn yóò rí í,
wọn o sì yọ̀, inú wọn ó sì dùn nínú Olúwa.
8 Èmi ó kọ sí wọn, èmi ó sì ṣà wọ́n jọ;
nítorí èmi tí rà wọ́n padà;
wọn ó sì pọ̀ sí i gẹ́gẹ́ bí
wọ́n tí ń pọ̀ sí í rí.
9 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo tú wọn káàkiri orílẹ̀-èdè:
síbẹ̀ wọn ó sì rántí mi ni ilẹ̀ jíjìn;
wọn ó sì gbé pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn,
wọn ó sì tún padà.
10 Èmi ó sì tún mú wọn padà kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti
pẹ̀lú, èmi ó sì ṣà wọn jọ kúrò ni ilẹ̀ Asiria:
èmi ó sì mú wọn wá sí ilẹ̀ Gileadi àti Lebanoni; a
a kì yóò sì rí ààyè fún wọn bí ó ti yẹ.
11 Wọn yóò sì la Òkun wàhálà já,
yóò sì bori rírú omi nínú Òkun,
gbogbo ibú odò ni yóò sì gbẹ,
a ó sì rẹ ìgbéraga Asiria sílẹ̀,
ọ̀pá aládé Ejibiti yóò sí lọ kúrò.
12 Èmi ó sì mú wọn ní agbára nínú Olúwa;
wọn ó sì rìn sókè rìn sódò ni orúkọ rẹ̀,”
ni Olúwa wí.
11 Ṣí àwọn ìlẹ̀kùn rẹ sílẹ̀, ìwọ Lebanoni,
kí iná bá lè jẹ igi kedari rẹ run,
2 Hu, igi junifa; nítorí igi kedari ṣubú,
nítorí tí a ba àwọn igi tí o lógo jẹ́:
hu, ẹ̀yin igi óákù tí Baṣani,
nítorí gé igbó àjàrà lulẹ̀.
3 Gbọ́ ohun igbe àwọn olùṣọ́-àgùntàn;
ògo wọn bàjẹ́;
gbọ́ ohùn bíbú àwọn ọmọ kìnnìún
nítorí ògo Jordani bàjẹ́.
Olùṣọ́-àgùntàn méjì
4 Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run mi wí: “Bọ́ ọ̀wọ́ ẹran àbọ́pa. 5 Tí àwọn olúwa wọn ń pa wọ́n, tí wọn kò sì ka ara wọn sí pé wọn jẹ̀bi: àti àwọn tí ń tà wọ́n wí pé, ‘Ìbùkún ni fún Olúwa, nítorí tí mo dí ọlọ́rọ̀!’ Àwọn olùṣọ́-àgùntàn wọn kò sì ṣàánú wọn. 6 Nítorí èmi kì yóò ṣàánú fún àwọn ara ilẹ̀ náà mọ́,” ni Olúwa wí, “Ṣí kíyèsi í, èmi yóò fi olúkúlùkù ènìyàn lé aládùúgbò rẹ̀ lọ́wọ́, àti lé ọwọ́ ọba rẹ̀, wọn yóò sì fọ́ ilẹ̀ náà, èmi kì yóò sì gbà wọ́n lọ́wọ́ wọn.”
7 Èmi yóò sì bọ́ ẹran àbọ́pa, àní ẹ̀yin òtòṣì nínú ọ̀wọ́ ẹran. Mo sì mu ọ̀pá méjì sọ́dọ̀; mo pè ọ̀kan ni Oore-ọ̀fẹ́, mo pè èkejì ni Àmùrè; mo sì bọ́ ọ̀wọ́ ẹran náà. 8 Olùṣọ́-àgùntàn mẹ́ta ni mo sì gé kúrò ní oṣù kan.
Ọkàn mi sì kórìíra wọn, ọkàn wọn pẹ̀lú sì kórìíra mi. 9 Mo sì wí pé, “Èmi kì yóò bọ́ yin: èyí ti ń ku lọ, jẹ́ kí òkú o kú; èyí tí a o ba sì gé kúrò, jẹ́ kí a gé e kúrò; ki olúkúlùkù nínú àwọn ìyókù jẹ́ ẹran-ara ẹnìkejì rẹ̀.”
10 Mo sì mu ọ̀pá mi, ti a ń pè ní Oore-ọ̀fẹ́, mo ṣẹ́ si méjì, ki èmi bá lè da májẹ̀mú mi tí mo tí bá gbogbo àwọn ènìyàn náà dá. 11 Ó sì dá ni ọjọ́ náà, bẹ́ẹ̀ ni àwọn òtòṣì nínú ọ̀wọ́ ẹran náà tí ó dúró tì mí mọ̀ pé, ọ̀rọ̀ Olúwa ni.
12 (C)Mo sì wí fún wọn pé, “Bí ó bá dára ní ojú yin, ẹ fún mi ni owó ọ̀yà mi; bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ mú un lọ́wọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n wọn ọgbọ̀n owó fàdákà fún iye owó ọ̀yà mi.
13 Olúwa sì wí fún mi pé, “Sọ ọ sí amọ̀kòkò.” Iye dáradára náà, tí wọn yọ owó mi sí. Mo sì mu ọgbọ̀n owó fàdákà náà, mo sì sọ wọ́n sí àpótí ìṣúra ní ilé Olúwa.
14 Mo sì ṣẹ́ ọ̀pá mi kejì, àní Àmùrè, sí méjì, kí èmi lè ya ìbátan tí ó wà láàrín Juda àti láàrín Israẹli.
15 Olúwa sì wí fún mi pé, “Tún mú ohun èlò aṣiwèrè olùṣọ́-àgùntàn kan sọ́dọ̀ rẹ̀. 16 Nítorí Èmi o gbé olùṣọ́-àgùntàn kan dìde ni ilẹ̀ náà, tí kí yóò bẹ àwọn tí ó ṣègbé wò, ti kì yóò sì wá èyí tí ó yapa; tí kì yóò ṣe ìtọ́jú èyí tí a pa lára tàbí kí ó bọ́ àwọn tí ara wọn dá pépé: Ṣùgbọ́n òun yóò jẹ ẹran èyí tí ó ni ọ̀rá, àwọn èyí tiwọn fi èékánná wọn ya ara wọn pẹ́rẹpẹ̀rẹ.
17 “Ègbé ni fún olùṣọ́-àgùntàn asán náà,
tí ó fi ọ̀wọ́ ẹran sílẹ̀!
Idà yóò gé apá rẹ̀ àti ojú ọ̀tún rẹ̀:
apá rẹ̀ yóò gbẹ pátápátá,
ojú ọ̀tún rẹ̀ yóò sì fọ́ pátápátá!”
A o pa àwọn ọ̀tá Jerusalẹmu run
12 Ọ̀rọ̀-ìmọ̀: Ọ̀rọ̀ Olúwa fún Israẹli ni.
Olúwa wí, ẹni tí ó na àwọn ọ̀run, tí ó sì fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀, tí ó sì da ẹ̀mí ènìyàn tí ń bẹ ni inú rẹ̀: 2 “Kíyèsi í, èmi yóò sọ Jerusalẹmu dí àgọ́ ìwárìrì sí gbogbo ènìyàn yíká, nígbà tí wọn yóò dó ti Juda àti Jerusalẹmu. 3 Ní ọjọ́ náà, nígbà tí gbogbo orílẹ̀-èdè ayé bá parapọ̀ sí i, ni èmi yóò sọ Jerusalẹmu di òkúta ti ko ṣe yí kúrò fún gbogbo ènìyàn: gbogbo àwọn tí ó bá sì fẹ́ yí i ni a ó gé sí wẹ́wẹ́, 4 ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa wí, “Ni èmi yóò fi ìdágìrì lu gbogbo ẹṣin, àti fi òmùgọ̀ kọlu ẹni tí ń gun un; èmi yóò sì ṣí ojú mi sí ilé Juda, èmi yóò sì bu ìfọ́jú lu gbogbo ẹṣin tí orílẹ̀-èdè. 5 Àti àwọn baálẹ̀ Juda yóò sì wí ni ọkàn wọn pé, ‘Àwọn ara Jerusalẹmu ni agbára mi nípa Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni Ọlọ́run wọn.’
6 “Ní ọjọ́ náà, ni èmi yóò ṣe àwọn baálẹ̀ Juda bí ààrò iná kan láàrín igi, àti bi ẹ̀fúùfù iná láàrín ìtí; wọn yóò sì jẹ gbogbo àwọn ènìyàn run yíká lápá ọ̀tún àti lápá òsì: a ó sì tún máa gbé inú Jerusalẹmu ní ipò rẹ̀.
7 “Olúwa pẹ̀lú yóò kọ́ tètè gba àgọ́ Juda là ná, kí ògo ilé Dafidi àti ògo àwọn ara Jerusalẹmu má ba gbé ara wọn ga sí Juda. 8 Ní ọjọ́ náà ni Olúwa yóò dáàbò bò àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu; ẹni tí ó bá sì ṣe àìlera nínú wọn ní ọjọ́ náà, yóò dàbí Dafidi; ilé Dafidi yóò sì dàbí Ọlọ́run, bí angẹli Olúwa níwájú wọn. 9 Yóò sì ṣe ni ọjọ́ náà, èmi yóò wá láti pa gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè run tí ó wá kọjú ìjà sí Jerusalẹmu.”
Ìṣọ̀fọ̀ fún ọba wọn tí wọn gún lọ́kọ̀
10 (D)“Èmi ó sì tu ẹ̀mí oore-ọ̀fẹ́ àti ẹ̀bẹ̀ sórí ilé Dafidi àti sórí Jerusalẹmu: wọn ó sì máa wo ẹni tí wọn tí gún ni ọ̀kọ̀, wọn ó sì máa ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, bí ẹnìkan ti ń ṣọ̀fọ̀ fún ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo àti gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí wọn yóò sì wà ni ìbànújẹ́, bí ẹni tí ń banújẹ́ fún àkọ́bí rẹ̀. 11 Ní ọjọ́ náà ni ẹkún, ńláńlá yóò wà ni Jerusalẹmu, gẹ́gẹ́ bí ọ̀fọ̀ Hadadi Rimoni ni Àfonífojì Megido. 12 Ilẹ̀ náà yóò ṣọ̀fọ̀, ìdílé, kọ̀ọ̀kan fun ara rẹ, lọ́tọ̀ọ̀tọ̀; ìdílé Dafidi lọ́tọ̀; àti àwọn aya wọn lọ́tọ̀; ìdílé Natani lọ́tọ̀, àti àwọn aya wọn lọ́tọ́. 13 Ìdílé Lefi lọ́tọ̀, àti àwọn aya wọn lọ́tọ̀; ìdílé Ṣimei lọ́tọ̀, àti àwọn aya wọn lọ́tọ̀. 14 Gbogbo àwọn ìdílé tí o kù, ìdílé, ìdílé, lọ́tọ̀ọ̀tọ̀, àti àwọn aya wọn lọ́tọ̀ọ̀tọ̀.
Ìwẹ̀nùmọ́ kúrò nínú ẹsẹ̀
13 “Ní ọjọ́ náà ìsun kan yóò ṣí sílẹ̀ fún ilé Dafidi àti fún àwọn ará Jerusalẹmu, láti wẹ̀ wọ́n mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti àìmọ́ wọn.
2 “Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ni èmi ó gé orúkọ àwọn òrìṣà kúrò ni ilẹ̀ náà, a kì yóò sì rántí wọn mọ́: àti pẹ̀lú èmi ó mú àwọn wòlíì èké àti àwọn ẹ̀mí àìmọ́ kúrò ni ilẹ̀ náà. 3 Yóò sì ṣe, nígbà tí ẹnìkan yóò sọtẹ́lẹ̀ síbẹ̀, ni baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ tí ó bí í yóò wí fún un pé, ‘Ìwọ ki yóò yè: nítorí ìwọ ń sọ ọ̀rọ̀ èké ni orúkọ Olúwa.’ Àti baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ tí o bí í yóò gun un ni àgúnpa nígbà tí ó bá sọtẹ́lẹ̀.
4 “Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà, ojú yóò tí àwọn wòlíì èké olúkúlùkù nítorí ìran rẹ̀, nígbà tí òun ba tí sọtẹ́lẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò sì wọ aṣọ wòlíì onírun rẹ̀ tí o fi ń tan ní jẹ. 5 Ṣùgbọ́n òun o wí pé, ‘Èmi kí í ṣe wòlíì, àgbẹ̀ ni èmi; nítorí tí a ti fi mí ṣe ìránṣẹ́ láti ìgbà èwe mi wá.’ 6 Ẹnìkan ó sì wí fún un pé, ‘Ọgbẹ́ kín ní wọ̀nyí ni ẹ̀yìn rẹ?’ Òun o sì dáhùn pé, ‘Wọ̀nyí ni ibi tí a ti sá mi ní ilé àwọn ọ̀rẹ́ mi.’
A lu olùṣọ́-àgùntàn, agbo ẹran fọ́nká
7 (E)“Dìde, ìwọ idà, sí olùṣọ́-àgùntàn mi,
àti sí ẹni tí í ṣe ẹnìkejì mi,”
ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí:
“Kọlu Olùṣọ́-àgùntàn,
àwọn àgùntàn a sì túká:
èmi o sì yí ọwọ́ mi sí àwọn kéékèèkéé.
8 Yóò sì ṣe, ni gbogbo ilẹ̀,” ni Olúwa wí,
“a ó gé apá méjì nínú rẹ̀ kúrò yóò sì kú;
ṣùgbọ́n apá kẹta yóò kù nínú rẹ̀.
9 Èmi ó sì mú apá kẹta náà la àárín iná,
èmi yóò sì yọ́ wọn bí a ti yọ́ fàdákà,
èmi yóò sì dán wọn wò, bi a tí ń dán wúrà wò:
wọn yóò sì pé orúkọ mi,
èmi yóò sì dá wọn lóhùn:
èmi yóò wí pé, ‘Àwọn ènìyàn mi ni,’
àwọn yóò sì wí pé, ‘Olúwa ni Ọlọ́run wa.’ ”
Olúwa Wa Jọba
14 Kíyèsi i, ọjọ́ Olúwa ń bọ̀, a ó sì pín ìkógun rẹ̀ láàrín rẹ̀.
2 Nítorí èmi ó kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ sí Jerusalẹmu fún ogun; a ó sì ko ìlú naà, a ó sì kó àwọn ilé, a ó sì ba àwọn obìnrin jẹ́, ààbọ̀ ìlú náà yóò lọ sí ìgbèkùn, a kì yóò sì gé ìyókù àwọn ènìyàn náà kúrò ni ìlú náà. 3 Nígbà náà ni Olúwa yóò jáde lọ, yóò sì bá àwọn orílẹ̀-èdè náà jà, gẹ́gẹ́ bí í ti ìjà ní ọjọ́ ogun. 4 Ẹsẹ̀ rẹ̀ yóò sì dúró ni ọjọ́ náà lórí òkè Olifi, tí ó wà níwájú Jerusalẹmu ni ìlà-oòrùn, òkè Olifi yóò sì là á sí méjì, sí ìhà ìlà-oòrùn àti ìhà ìwọ̀-oòrùn, Àfonífojì ńláńlá yóò wà: ìdajì òkè náà yóò sì ṣí síhà àríwá, àti ìdajì rẹ̀ síhà gúúsù. 5 Ẹ̀yin ó sì sá sí àfonífojì àwọn òkè mi: nítorí pé àfonífojì òkè náà yóò dé Aseli: nítòótọ́, ẹ̀yin ó sá bí ẹ tí sá fún ìmìmì-ilẹ̀ ni ọjọ́ Ussiah ọba Juda: Olúwa Ọlọ́run mi yóò sì wá, àti gbogbo àwọn Ẹni mímọ́ pẹ̀lú rẹ̀.
6 Yóò sì ṣe ni ọjọ́ náà, ìmọ́lẹ̀ kì yóò mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ṣókùnkùn. 7 Ṣùgbọ́n yóò jẹ́ ọjọ́ kan mímọ́ fún Olúwa, kì í ṣe ọ̀sán, kì í ṣe òru; ṣùgbọ́n yóò ṣe pé, ni àṣálẹ́ ìmọ́lẹ̀ yóò wà.
8 Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà, omi ìyè yóò tí Jerusalẹmu sàn lọ; ìdajì wọn síhà Òkun ìlà-oòrùn, àti ìdajì wọn síhà okùn ẹ̀yìn: nígbà ẹ̀rùn àti nígbà òtútù ni yóò rí bẹ́ẹ̀.
9 Olúwa yóò sì jẹ ọba lórí gbogbo ayé; ni ọjọ́ náà ni Olúwa kan yóò wa orúkọ rẹ̀ nìkan náà ni orúkọ.
10 A ó yí gbogbo ilẹ̀ padà bi pẹ̀tẹ́lẹ̀ kan láti Geba dé Rimoni lápá gúúsù Jerusalẹmu: yóò di bí aginjù, ṣùgbọ́n a ó sì gbé Jerusalẹmu sókè, yóò sì gbe ipò rẹ̀, láti ibodè Benjamini títí dé ibi ibodè èkínní, dé ibodè igun nì, àti láti ilé ìṣọ́ Hananeli dé ibi ìfúntí wáìnì ọba. 11 (F)Ènìyàn yóò sì máa gbé ibẹ̀, kì yóò sì sí ìparun mọ́; ṣùgbọ́n a ó máa gbé Jerusalẹmu láìléwu.
12 Èyí ni yóò sì jẹ́ ààrùn tí Olúwa yóò fi kọlu gbogbo àwọn ènìyàn ti ó tí ba Jerusalẹmu jà; ẹran-ara wọn yóò rù nígbà tí wọn dúró ni ẹsẹ̀ wọn, ojú wọn yóò sì rà ni ihò wọn, ahọ́n wọn yóò sì bàjẹ́ ni ẹnu wọn. 13 Yóò sì ṣe ni ọjọ́ náà, ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ńlá láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá yóò wà láàrín wọn; wọn ó sì di ọwọ́ ara wọn mú, ọwọ́ èkínní yóò sì dìde sì ọwọ́ èkejì rẹ̀. 14 Juda pẹ̀lú yóò sì jà ni Jerusalẹmu: ọrọ̀ gbogbo àwọn kèfèrí tí ó wà káàkiri ni a ó sì kójọ, wúrà àti fàdákà, àti aṣọ, ní ọ̀pọ̀lọpọ̀. 15 Bẹ́ẹ̀ ni ààrùn ẹṣin, ìbáaka, ìbákasẹ, àti tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, yóò sì wà, àti gbogbo ẹranko tí ń bẹ nínú àgọ́.
16 Yóò sì ṣe, olúkúlùkù ẹni tí o kù nínú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó dìde sí Jerusalẹmu yóò máa gòkè lọ lọ́dọọdún láti sìn ọba, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, àti láti ṣe àjọyọ̀ àsè àgọ́ náà. 17 Yóò sì ṣe, ẹnikẹ́ni tí kì yóò gòkè wá nínú gbogbo ìdílé ayé sí Jerusalẹmu láti sín ọba, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, òjò kì yóò rọ̀ fún wọn. 18 (G)Bí ìdílé Ejibiti kò bá sì gòkè lọ, tí wọn kò sì wá, fi ara wọn hàn tí wọn kò ní òjò; ààrùn náà yóò wà, tí Olúwa yóò fi kọlù àwọn kèfèrí tí kò gòkè wá láti ṣe àjọyọ̀ àsè àgọ́ náà 19 Èyí ni yóò sì jẹ́ ìyà Ejibiti, àti ìyà gbogbo orílẹ̀-èdè tí kò gòkè wá láti pa àsè àgọ́ mọ́.
20 Ní ọjọ́ náà ni “mímọ́ sí Olúwa” yóò wà lára ṣaworo ẹṣin: àti àwọn ìkòkò ni ilé Olúwa yóò sì dàbí àwọn ọpọ́n tí ń bẹ níwájú pẹpẹ. 21 Nítòótọ́, gbogbo ìkòkò ni Jerusalẹmu àti ni Juda yóò jẹ́ mímọ́ sí Olúwa àwọn ọmọ-ogun: àti gbogbo àwọn tí ń rú ẹbọ yóò wá, wọn ó sì mú ìkòkò díẹ̀, wọn ó sì bọ ẹran wọn nínú rẹ̀, ni ọjọ́ náà ni àwọn Kenaani kò ní sí mọ́ ni ilé Olúwa àwọn ọmọ-ogun.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.