Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 137

137 Ní ẹ̀bá odò Babeli, níbẹ̀ ni àwa gbé jókòó
    àwa sì sọkún nígbà tí àwa rántí Sioni.
Àwa fi dùùrù wa kọ́ sí orí igi wílò,
    tí ó wà láàrín rẹ̀.
Nítorí pé níbẹ̀ ni àwọn
    tí ó kó wa ní ìgbèkùn béèrè orin lọ́wọ́ wa,
àti àwọn tí ó ni wá lára béèrè ìdárayá wí pé;
    ẹ kọ orin Sioni kan fún wa.

Àwa ó ti ṣe kọ orin
    Olúwa ní ilẹ̀ àjèjì
Jerusalẹmu, bí èmi bá gbàgbé rẹ
    jẹ́ kí ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó gbàgbé ìlò rẹ̀.
Bí èmi kò bá rántí rẹ,
    jẹ́ kí ahọ́n mi kí ó lẹ̀ mọ́ èrìgì mi;
bí èmi kò bá fi Jerusalẹmu ṣáájú
    olórí ayọ̀ mi gbogbo.

Olúwa rántí ọjọ́ Jerusalẹmu,
    lára àwọn ọmọ Edomu,
àwọn ẹni tí ń wí pé,
    “Wó o palẹ̀, wó o palẹ̀ dé ìpìlẹ̀ rẹ̀!”
Ìwọ, ọmọbìnrin Babeli, ẹni tí a ó parun;
    ìbùkún ni fún ẹni tí ó san án fún ọ
    bí ìwọ ti rò sí wa.
Ìbùkún ni fún ẹni tí ó mú ọmọ wẹ́wẹ́ rẹ
    tí ó sì fi wọ́n ṣán òkúta.

Saamu 144

Ti Dafidi.

144 Ìyìn sí Olúwa àpáta mi,
    ẹni tí ó kọ́ ọwọ́ mi fún ogun,
    àti ìka mi fún ìjà.
Òun ni Ọlọ́run ìfẹ́ mi àti odi alágbára mi,
    ibi gíga mi àti olùgbàlà mi, asà mi,
ẹni tí èmi gbẹ́kẹ̀lé,
    ẹni tí ó tẹrí àwọn ènìyàn ba lábẹ́ mi.

Olúwa, kí ni ènìyàn tí ìwọ fi ń ṣàníyàn fún un,
    tàbí ọmọ ènìyàn tí ìwọ fi ń ronú nípa rẹ̀?
Ènìyàn rí bí èmi;
    ọjọ́ rẹ̀ rí bí òjìji tí ń kọjá lọ.

Tẹ ọ̀run rẹ ba, Olúwa, kí o sì sọ̀kalẹ̀;
    tọ́ àwọn òkè ńlá wọn yóò sí rú èéfín.
Rán mọ̀nàmọ́ná kí ó sì fọ́n àwọn ọ̀tá ká;
    ta ọfà rẹ kí ó sì dà wọ́n rú.
Na ọwọ́ rẹ sílẹ̀ láti ibi gíga;
    gbà mí kí o sì yọ mí nínú ewu
kúrò nínú omi ńlá:
    kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ àjèjì.
Ẹnu ẹni tí ó kún fún èké
    ẹni tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ jẹ́ ìrẹ́jẹ.

Èmi yóò kọ orin tuntun sí ọ
    Ọlọ́run; lára ohun èlò orin
olókùn mẹ́wàá èmi yóò
    kọ orin sí ọ
10 Òun ni ó fi ìgbàlà fún àwọn ọba,
    ẹni tí ó gba Dafidi ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ idà ìpanilára.

Lọ́wọ́ pípanirun. 11 Gbà mí kí o sì yọ mí nínú ewu
    kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ àjèjì
tí ẹnu wọn kún fún èké,
    tí ọwọ́ ọ̀tún wọn jẹ́ ọwọ́ ọ̀tún èké.

12 Kí àwọn ọmọkùnrin wa
    kí ó dàbí igi gbígbìn tí ó dàgbà ni ìgbà èwe wọn,
àti ọmọbìnrin wa yóò dàbí òpó ilé
    tí a ṣe ọ̀nà sí bí àfarawé ààfin.
13 Àká wa yóò kún
    pẹ̀lú gbogbo onírúurú oúnjẹ
àgùntàn wa yóò pọ̀ si ní ẹgbẹ̀rún,
    ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ní oko wa:
14 Àwọn màlúù wa yóò ru ẹrù wúwo
    kí ó má sí ìkọlù,
kí ó má sí ìkólọ sí ìgbèkùn,
    kí ó má sí i igbe ìpọ́njú ní ìgboro wa.
15 Ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn náà tí ó wà ní irú ipò bẹ́ẹ̀,
    Ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn náà,
    tí ẹni tí Ọlọ́run Olúwa ń ṣe.

Saamu 104

104 Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi.

Olúwa Ọlọ́run mi, ìwọ tóbi jọjọ;
    ọlá àti ọláńlá ni ìwọ wọ̀ ní aṣọ.

Ìwọ fi ìmọ́lẹ̀ bo ara rẹ gẹ́gẹ́ bí aṣọ;
    ó tẹ ọ̀run bí títẹ́ ẹní
Ìwọ tí ó fi omi ṣe ìtì igi àjà ìyẹ̀wù rẹ.
    Ìwọ tí o ṣe àwọsánmọ̀ ní kẹ̀kẹ́ ogun rẹ
    ìwọ tí ó ń rìn lórí apá ìyẹ́ afẹ́fẹ́.
(A)Ó fi ẹ̀fúùfù ṣe àwọn ìránṣẹ́ rẹ,
    Ọ̀wọ́-iná ni àwọn olùránṣẹ́ rẹ.

O fi ayé gúnlẹ̀ lórí àwọn ìpìlẹ̀;
    tí a kò le è mì láéláé.
Ìwọ fi ibú omi bò ó mọ́lẹ̀ bí aṣọ;
    àwọn omi sì dúró lórí àwọn òkè ńlá.
Ṣùgbọ́n nípa ìbáwí rẹ ni àwọn omi lọ,
    nípa ohùn àrá rẹ ni wọ́n sálọ;
Wọ́n sàn kọjá lórí àwọn òkè,
    wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ sí àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀,
    sí ibi tí ìwọ ti yàn fún wọn.
Ìwọ gbé òpin tí wọn kò lè kọjá rẹ̀ kálẹ̀;
    láéláé ni wọ́n kò ní lè bo ayé mọ́lẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i.

10 Ìwọ mú kí ìsun da omi sí àwọn Àfonífojì;
    tí ó ń sàn láàrín àwọn òkè.
11 Wọ́n fún gbogbo àwọn ẹranko igbó ní omi
    àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ń pa òǹgbẹ wọn.
12 Àwọn ẹyẹ ojú òfúrufú tẹ́ ìtẹ́ wọn lẹ́gbẹ̀ẹ́ omi
    wọ́n ń kọrin láàrín àwọn ẹ̀ka.
13 Ó bu omi rin àwọn òkè láti ìyẹ̀wù rẹ̀ wá;
    a tẹ́ ayé lọ́rùn nípa èso iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
14 Ó mú kí koríko hù jáde fún àwọn ẹranko láti jẹ
    àti àwọn ewébẹ̀ fún ènìyàn láti lò
    kí ó lè mú oúnjẹ jáde láti ilẹ̀ wá:
15 Ọtí wáìnì tí ó ń mú ọkàn ènìyàn yọ̀,
    òróró láti mú ojú rẹ̀ tan,
    àti àkàrà láti ra ọkàn rẹ̀ padà.
16 Àwọn igi Olúwa ni a bu omi rin dáradára,
    kedari ti Lebanoni tí ó gbìn.
17 Níbẹ̀ ní àwọn ẹyẹ ṣe ìtẹ́ wọn
    bí ó ṣe tí àkọ̀ ni, orí igi gíga ni ilé rẹ̀.
18 Àwọn òkè gíga ni ààbò fún àwọn ewúrẹ́ igbó;
    àti àwọn àlàpà jẹ́ ààbò fún àwọn ehoro.

19 Òṣùpá jẹ́ ààmì fún àkókò
    oòrùn sì mọ ìgbà tí yóò wọ̀.
20 Ìwọ mú òkùnkùn wá, ó sì di òru,
    nínú èyí tí gbogbo ẹranko igbó ń rìn kiri.
21 Kìnnìún ń bú ramúramù fún ohun ọdẹ wọn
    wọ́n sì ń wá oúnjẹ wọn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.
22 Oòrùn ràn, wọ́n sì kó ara wọn jọ,
    wọn padà lọ dùbúlẹ̀ sí ihò wọn.
23 Ọkùnrin jáde lọ sí iṣẹ́ wọn,
    àti sí làálàá rẹ̀ títí di àṣálẹ́.

24 Iṣẹ́ rẹ ti pọ̀ tó, Olúwa!
    Nínú ọgbọ́n ni ìwọ ṣe gbogbo wọn:
    ayé kún fún àwọn ìṣẹ̀dá á rẹ.
25 Bẹ́ẹ̀ ni Òkun yìí tí ó tóbi, tí ó sì ni ìbú,
    tí ó kún fún àwọn ẹ̀dá alààyè ní ìsàlẹ̀ láìníye
    ohun alààyè tí tóbi àti kékeré.
26 Níbẹ̀ ni ọkọ̀ ń lọ síwá sẹ́yìn,
    àti Lefitani, tí ìwọ dá láti ṣe àríyá nínú rẹ̀.

27 Àwọn wọ̀nyí ń wò ọ́
    láti fún wọn ní oúnjẹ wọn lákòókò rẹ̀.
28 Nígbà tí ìwọ bá fi fún wọn,
    wọn yóò kó jọ;
nígbà tí ìwọ bá la ọwọ́ rẹ̀,
    a tẹ́ wọn lọ́rùn pẹ̀lú ohun rere.
29 Nígbà tí ìwọ bá pa ojú rẹ mọ́
    ara kò rọ̀ wọ́n
nígbà tí ìwọ bá mú ẹ̀mí wọn lọ,
    wọn ó kú, wọn ó sì padà sí erùpẹ̀.
30 Nígbà tí ìwọ rán ẹ̀mí rẹ,
    ni a dá wọn,
    ìwọ sì tún ojú ayé ṣe.

31 Jẹ́ kí ògo Olúwa wà pẹ́ títí láé;
    kí inú Olúwa kí ó dùn ní ti iṣẹ́ rẹ̀
32 Ẹni tí ó wo ayé, tí ó sì wárìrì,
    ẹni tí ó fọwọ́ tọ́ àwọn òkè, tí wọ́n yọ èéfín.

33 Ní gbogbo ayé mi ní n ó kọrin sí Olúwa:
    èmi ó kọrin ìyìn sí Olúwa
níwọ̀n ìgbà tí mo wà láààyè.
34 Jẹ́ kí ẹ̀kọ́ mi kí ó tẹ́ ọ lọ́rùn
    bí mo ti ń yọ̀ nínú Olúwa.
35 Ṣùgbọ́n kí ẹlẹ́ṣẹ̀ kúrò láyé
    kí ènìyàn búburú má sì sí mọ́.

Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi.

Yin Olúwa.

Jeremiah 35

Àwọn Rekabu

35 Ọ̀rọ̀ tí ó tọ Jeremiah wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa ní ọjọ́ Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda wí pé: “Lọ sí ilé àwọn ọmọ Rekabu, kí o sì bá wọn sọ̀rọ̀, kí o sì mú wọn wá sí ilé Olúwa, sí ọ̀kan nínú iyàrá wọ̀n-ọn-nì, kí o sì fún wọn ní ọtí wáìnì mu.”

Nígbà náà ni mo mu Jaaṣaniah ọmọ Jeremiah, ọmọ Habasiniah àti àwọn arákùnrin rẹ̀; àti gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀, àti gbogbo ilé àwọn ọmọ Rekabu. Mo sì mú wọn wá sí ilé Olúwa sínú iyàrá Hanani ọmọ Igdaliah, ènìyàn Ọlọ́run, tí ó wà lẹ́bàá yàrá àwọn ìjòyè, tí ó wà ní òkè yàrá Maaseiah, ọmọ Ṣallumu olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà. Mo sì gbé ìkòkò tí ó kún fún ọtí wáìnì pẹ̀lú ago ka iwájú àwọn ọmọ Rekabu. Mo sì wí fún wọn pé, “Mu ọtí wáìnì.”

Ṣùgbọ́n wọ́n wí pé, “Àwa kì yóò mu ọtí wáìnì nítorí Jonadabu ọmọ Rekabu, baba wa pàṣẹ fún wa pé: ‘Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ mu ọtí wáìnì ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín láéláé Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ kọ́ ilé tàbí kí ẹ fúnrúgbìn, tàbí kí ẹ gbin ọgbà àjàrà. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò gbọdọ̀ ní ọ̀kankan nínú àwọn ohun wọ̀nyí, ṣùgbọ́n ní gbogbo ọjọ́ yín ni ẹ̀yin ó máa gbé inú àgọ́; kí ẹ̀yin kí ó lè wá ní ọjọ́ púpọ̀ ní ilẹ̀ náà; níbi tí ẹ̀yin ti ń ṣe àtìpó.’ Báyìí ni àwa gba ohùn Jehonadabu ọmọ Rekabu baba wa gbọ́ nínú gbogbo èyí tí ó pàṣẹ fún wa, kí a má mu ọtí wáìnì ní gbogbo ọjọ́ ayé wa; àwa, àwọn aya wa, àwọn ọmọkùnrin wa, àti àwọn ọmọbìnrin wa. Àti kí a má kọ́ ilé láti gbé; bẹ́ẹ̀ ni àwa kò ní ọgbà àjàrà tàbí oko, tàbí ohun ọ̀gbìn. 10 Ṣùgbọ́n àwa ń gbé inú àgọ́, a sì gbọ́rọ̀, a sì ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí Jonadabu baba wa pàṣẹ fún wa. 11 Ó sì ṣe, nígbà tí Nebukadnessari ọba Babeli gòkè wá sí ilẹ̀ náà; àwa wí pé, ‘Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a lọ sí Jerusalẹmu, nítorí ìbẹ̀rù ogun àwọn ara Siria.’ Bẹ́ẹ̀ ni àwa sì ń gbé Jerusalẹmu.”

12 Nígbà yìí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wá wí pé: 13 “Báyìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí pé, lọ, kí o sì sọ fún àwọn ọkùnrin Juda, àti àwọn olùgbé Jerusalẹmu pé, ‘Ẹ̀yin kì yóò ha gba ẹ̀kọ́ láti fetí sí ọ̀rọ̀ mi,’ ni Olúwa wí. 14 ‘Ọ̀rọ̀ Jehonadabu ọmọ Rekabu tí ó pàṣẹ fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé wọn kò gbọdọ̀ mu ọtí wáìnì, ni a mú ṣẹ, wọn kò sì mu ọtí wáìnì títí di òní yìí, nítorí tí wọ́n gba òfin baba wọn. Èmi sì ti ń sọ̀rọ̀ fún un yín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fetí sí mi. 15 Èmi rán gbogbo àwọn ìránṣẹ́ àti àwọn wòlíì mí sí yín pẹ̀lú wí pé, “Ẹ yípadà nísinsin yìí kúrò ní ọ̀nà búburú yín, kí ẹ sì tún ìṣe yín ṣe sí rere. Kí ẹ ma sì ṣe bọ òrìṣà tàbí sìn wọ́n; ẹ̀yin ó sì máa gbé ní ilẹ̀ náà tí mo fi fún un yín àti fún àwọn baba ńlá yín.” Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fetí sí mi. 16 Nítòótọ́, àwọn ọmọ Jehonadabu ọmọ Rekabu pa òfin baba wọn mọ́ tí ó pàṣẹ fún wọn, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn wọ̀nyí kò pa òfin mi mọ́.’

17 “Nítorí náà, báyìí ni, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí: ‘Fetísílẹ̀! Èmi ó mú gbogbo ohun búburú tí èmi ti sọ wá sórí Juda, àti sórí gbogbo olùgbé Jerusalẹmu nítorí èmi ti bá wọn sọ̀rọ̀: Ṣùgbọ́n wọn kò sì dáhùn.’ ”

18 Nígbà náà ni Jeremiah wí fún ìdílé Rekabu pé, “Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí pé: ‘Nítorí tí ẹ̀yin gba òfin Jehonadabu baba yín, tí ẹ sì pa gbogbo rẹ̀ mọ́, tí ẹ sì ṣe gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó pàṣẹ fún un yín.’ 19 Nítorí náà, báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí, pé: ‘Jonadabu ọmọ Rekabu kì yóò fẹ́ ọkùnrin kan kù láti sìn mí.’ ”

1 Kọrinti 12:27-13:3

27 (A)Gbogbo yín jẹ́ ara Kristi, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín sì jẹ́ ẹ̀yà ara ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú ara Kristi. 28 (B)Ọlọ́run sì gbé àwọn mìíràn kalẹ̀ nínú ìjọ, èkínní àwọn aposteli, èkejì àwọn wòlíì, ẹ̀kẹta àwọn olùkọ́ni, lẹ́yìn náà, àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìyanu, lẹ́yìn náà àwọn tí ó ní ẹ̀bùn ìmúláradá, àwọn olùrànlọ́wọ́ àti àwọn agbani nímọ̀ràn, àwọn tí ń sọ onírúurú èdè. 29 Ǹjẹ́ gbogbo ènìyàn ni ó jẹ́ aposteli bi? Tàbí gbogbo ènìyàn ni wòlíì bí? Ṣe gbogbo ènìyàn ní olùkọ́ni? Ṣé gbogbo ènìyàn ló ní agbára láti ṣe iṣẹ́ ìyanu bí? 30 Ṣé gbogbo ènìyàn ló lè wonisàn bí? Rárá. Ǹjẹ́ gbogbo wa ni Ọlọ́run fún ní ẹ̀bùn láti le sọ̀rọ̀ ní èdè tí a kò ì tí ì gbọ́ rí bí? Ṣé ẹnikẹ́ni ló lè túmọ̀ èdè tí wọ́n sọ tí kò sì yé àwọn ènìyàn bí? 31 Ṣùgbọ́n, ẹ máa fi ìtara ṣàfẹ́rí ẹ̀bùn ti ó tóbi jù.

Síbẹ̀ èmi o fi ọ̀nà kan tí ó tayọ rékọjá hàn yín.

Ìfẹ́

13 (C)Bí èmi tilẹ̀ lè sọ oríṣìíríṣìí èdè tí ènìyàn àti ti angẹli, tí n kò bá sì ní ìfẹ́, mo kàn ń pariwo bí ago lásán ni tàbí bí i kimbali olóhùn gooro. (D)Bí mo bá ní ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀, tí mo sì ní òye gbogbo ohun ìjìnlẹ̀, àti gbogbo ìmọ̀, bí mo sì ni gbogbo ìgbàgbọ́ tó bẹ́ẹ̀ tí mo lè ṣí àwọn òkè ńlá nídìí, tí èmi kò sì ní ìfẹ́, èmi kò jẹ nǹkan kan. Bí mo bá fi gbogbo nǹkan tí mo ní tọrẹ fún àwọn aláìní, tí mo sì fi ara mi fún ni láti sùn ṣùgbọ́n tí n kò ní ìfẹ́, kò ní èrè kan fún mi.

Matiu 9:35-10:4

Àwọn Alágbàṣe Kéré

35 (A)Jesu sì rìn yí gbogbo ìlú ńlá àti ìletò ká, ó ń kọ́ni nínú Sinagọgu wọn, ó sì ń wàásù ìhìnrere ìjọba ọrun, ó sì ń ṣe ìwòsàn ààrùn àti gbogbo àìsàn ní ara àwọn ènìyàn. 36 (B)Nígbà tí ó rí ọ̀pọ̀ ènìyàn, àánú wọn ṣe é, nítorí àárẹ̀ mú wọn, wọn kò sì rí ìrànlọ́wọ́, bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́. 37 (C)Nígbà náà ni ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Lóòótọ́ ni ìkórè pọ̀ ṣùgbọ́n àwọn alágbàṣe kò tó nǹkan 38 Nítorí náà, ẹ gbàdúrà sí Olúwa ìkórè kí ó rán àwọn alágbàṣe sínú ìkórè rẹ̀.”

Jesu rán àwọn méjìlá jáde

10 (D)Jesu sì pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá sí ọ̀dọ̀; ó fún wọn ní àṣẹ láti lé ẹ̀mí àìmọ́ jáde àti láti ṣe ìwòsàn ààrùn àti àìsàn gbogbo.

Orúkọ àwọn aposteli méjèèjìlá náà ni wọ̀nyí:

ẹni àkọ́kọ́ ni Simoni ẹni ti a ń pè ni Peteru àti arákùnrin rẹ̀ Anderu;

Jakọbu[a] ọmọ Sebede àti arákùnrin rẹ̀ Johanu.

Filipi àti Bartolomeu;

Tomasi àti Matiu agbowó òde;

Jakọbu ọmọ Alfeu àti Taddeu;

Simoni ọmọ ẹgbẹ́ Sealoti, Judasi Iskariotu, ẹni tí ó da Jesu.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.