Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 5-6

Fún adarí orin. Fún ohun èlò orin fífọn. Saamu ti Dafidi.

Fi etí sí ọ̀rọ̀ mi, Olúwa,
    kíyèsi àròyé mi.
Fi etí sílẹ̀ sí igbe mi fún ìrànlọ́wọ́,
    ọba mi àti Ọlọ́run mi,
    nítorí ìwọ ni mo gba àdúrà sí.

Ní òwúrọ̀, Olúwa, ìwọ yóò gbọ́ ohùn mi;
    ní òwúrọ̀, èmi yóò gbé ẹ̀bẹ̀ mi sí iwájú rẹ̀
    èmi yóò sì dúró ní ìrètí.
Nítorí ìwọ kì í ṣe Ọlọ́run tí ó ní inú dídùn sí búburú;
    bẹ́ẹ̀ ni ẹni ibi kò le è bá ọ gbé.
Àwọn agbéraga kò le è dúró
    níwájú rẹ̀.
Ìwọ kórìíra gbogbo àwọn aṣebi;
    ìwọ yóò pa àwọn tí ń ṣe èké run.
Apani àti ẹni ẹ̀tàn ènìyàn
    ni Olúwa yóò kórìíra.
Ṣùgbọ́n èmi, nípa títóbi àánú rẹ̀,
    èmi yóò wá sínú ilé rẹ̀;
ní tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ni èmi yóò tẹríba
    sí ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ̀.

Tọ́ mi, Olúwa, nínú òdodo rẹ,
    nítorí àwọn ọ̀tá mi,
    mú ọ̀nà rẹ tọ́ níwájú mi.
(A)Kò sí ọ̀rọ̀ kan ní ẹnu wọn tí a lè gbàgbọ́;
    ọkàn wọn kún fún ìparun.
Ọ̀nà ọ̀fun wọn ni isà òkú tí ó ṣí sílẹ̀;
    pẹ̀lú ahọ́n wọn ni wọ́n ń sọ ẹ̀tàn.
10 Dá wọn lẹ́bi Ọlọ́run!
    Jẹ́ kí rìkíṣí wọn jẹ́ ìṣubú wọn.
Lé wọn jáde nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ wọn,
    nítorí wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ.
11 Ṣùgbọ́n, jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ó sádi ọ́ kí ó yọ̀;
    jẹ kí wọn máa kọrin fún ayọ̀ títí.
Tan ààbò rẹ sórí wọn,
    àti àwọn tí ó fẹ́ràn orúkọ rẹ yóò máa yọ̀ nínú rẹ.

12 Dájúdájú, Olúwa, ìwọ bùkún olódodo;
    ìwọ fi ojúrere rẹ yí wọn ká bí asà.

Fún adarí orin. Fún ohun èlò orin olókùn. Gẹ́gẹ́ bí ti ṣeminiti. Saamu ti Dafidi.

Olúwa, má ṣe bá mi wí nínú ìbínú rẹ
    kí ìwọ má ṣe nà mí nínú gbígbóná ìrunú rẹ
Ṣàánú fún mi, Olúwa, nítorí èmi ń kú lọ;
    Olúwa, wò mí sán, nítorí egungun mi wà nínú ìnira.
Ọkàn mi wà nínú ìrora.
    Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa, yóò ti pẹ́ tó?

Yípadà, Olúwa, kí o sì gbà mí;
    gbà mí là nípa ìfẹ́ rẹ tí kì í ṣákì í.
Ẹnikẹ́ni kò ni rántí rẹ nígbà tí ó bá kú.
    Ta ni yóò yìn ọ́ láti inú isà òkú?

Agara ìkérora mi dá mi tán.

Gbogbo òru ni mo wẹ ibùsùn mi pẹ̀lú ẹkún,
    mo sì fi omi rin ibùsùn mi pẹ̀lú omijé.
Ojú mi di aláìlera pẹ̀lú ìbànújẹ́;
    wọ́n kùnà nítorí gbogbo ọ̀tá mi.

(B)Kúrò lọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe iṣẹ́ ibi,
    nítorí Olúwa ti gbọ́ igbe mi.
Olúwa ti gbọ́ ẹkún mi fún àánú;
    Olúwa ti gba àdúrà mi.
10 Gbogbo àwọn ọ̀tá mi lójú yóò tì, wọn yóò sì dààmú;
    wọn yóò sì yípadà nínú ìtìjú àìròtẹ́lẹ̀.

Saamu 10-11

10 Èéha ti ṣe, Olúwa, tí ìwọ fi dúró ní òkè réré?
    Èéha ti ṣe, tí ìwọ fi ara rẹ pamọ́ ní ìgbà ìpọ́njú?

Nínú àrékérekè ni ènìyàn búburú tí mu aláìlera,
    ẹni ti ó mú nínú ìdẹ̀kùn àrékérekè rẹ̀.
Nítorí ènìyàn búburú ń ṣògo ìfẹ́ inú ọkàn rẹ̀;
    Ó bùkún olójúkòkòrò, ó sì ń kẹ́gàn Olúwa
Ènìyàn búburú kò lè rí nínú ìgbéraga rẹ̀;
    kò sí ààyè fún Ọlọ́run nínú gbogbo èrò rẹ̀;
Ọ̀nà rẹ̀ ń gún régé nígbà gbogbo;
    òun ń gbéraga, òfin rẹ̀ sì jìnnà sí i;
    òun kẹ́gàn àwọn ọ̀tá rẹ̀.
O wí fún ara rẹ̀, “Kò sí ohun tí ó lè mì mí;
    Inú mi yóò máa dùn nígbà gbogbo, èmi kò sì ní ní wàhálà.”

(A)Ẹnu rẹ̀ kún fún ègún àti irọ́ àti ìtànjẹ;
    wàhálà àti ohun búburú wà lábẹ́ ahọ́n rẹ̀.
Ó lúgọ ní bùba nítòsí ìletò;
    Ògo níbi ìkọ̀kọ̀ láti pa aláìṣẹ̀.
Ojú rẹ̀ ń ṣọ́ àwọn tálákà ní ìkọ̀kọ̀.
    Ó ba ní ní bùba bí i kìnnìún nínú pàǹtí;
Ó ba ní bùba láti mú àwọn aláìní ìrànwọ́;
    ó mú àwọn aláìlólùrànlọ́wọ́, ó sì wọ́ wọn lọ sínú àwọ̀n rẹ̀.
10 Ó ba, ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀;
    kí tálákà ba à le bọ́ sí ọwọ́ agbára rẹ̀.
11 Ó wí fún ara rẹ̀, “Ọlọ́run ti gbàgbé;
    Ó pa ojú rẹ̀ mọ́, òun kì yóò rí i láéláé.”

12 Dìde, Olúwa! Gbé ọwọ́ rẹ sókè, Ọlọ́run.
    Má ṣe gbàgbé àwọn olùpọ́njú.
13 Èéṣe tí ènìyàn búburú ṣe ń kẹ́gàn Ọlọ́run?
    Èéṣe tí o fi wí nínú ọkàn ara rẹ̀,
    “Kò ní pè mí láti ṣe ìṣirò”?
14 Ṣùgbọ́n ìwọ, Ọlọ́run, ni ó rí wàhálà àti ìrora;
    Ìwọ rò láti fi sí ọwọ́ rẹ.
Tálákà fi ara rẹ̀ jì fún ọ;
    Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àwọn aláìní baba.
15 Ṣẹ́ apá àwọn ènìyàn búburú àti ènìyàn ibi;
    pè é láti wá ṣírò fún ìwà ìkà rẹ̀
    tí a kò le è rí.

16 Olúwa ń jẹ ọba láé àti láéláé;
    àwọn orílẹ̀-èdè yóò ṣègbé lórí ilé rẹ.
17 Ìwọ́ gbọ́, Olúwa, ìfẹ́ àwọn tí a ni lára;
    Ìwọ gbà wọ́n níyànjú, ó sì gbọ́ igbe wọn,
18 Láti ṣe ìdájọ́ àwọn aláìní baba àti àwọn ti a ni lára,
    kí ọkùnrin, tí ó wà ní ayé,
    kí ó má ṣe dẹ́rùbà ni mọ́.

Fún adarí orin. Ti Dafidi.

11 Ìgbẹ́kẹ̀lé mi wà nínú Olúwa.
    Báwo ní ẹ̀yin ó ṣe sọ fún ọkàn mi pé:
    “Fò gẹ́gẹ́ bi ẹyẹ lọ si orí òkè rẹ.
Wò ó nítorí náà, ènìyàn búburú fa ọfà rẹ̀;
    wọn ti fi ọfà wọn sí ojú okùn
láti tafà níbi òjìji
    sí àyà ẹni ìdúró ṣinṣin.
Nígbà tí ìpìlẹ̀ bá bàjẹ́
    kí ni olódodo yóò ṣe?”

Olúwa ń bẹ nínú tẹmpili mímọ́ rẹ̀;
    Olúwa ń bẹ lórí ìtẹ́ rẹ̀ ní ọ̀run.
Ó ń wo àwọn ọmọ ènìyàn;
    ojú rẹ̀ ń yẹ̀ wọ́n wò.
Olúwa ń yẹ olódodo wò,
    ṣùgbọ́n ènìyàn búburú àti àwọn tí o fẹ́ ìwà ipá
    ni ọkàn rẹ̀ kórìíra.
Sí orí àwọn ènìyàn búburú ni yóò rọ̀jò
    ẹ̀yín iná àti imí-ọjọ́ tí ń jó;
    àti ìjì gbígbóná ní yóò jẹ ìpín wọn.

Nítorí, olódodo ní Olúwa,
    o fẹ́ràn òdodo;
    ẹni ìdúró ṣinṣin yóò sì rí i.

Jeremiah 36:27-37:2

27 Lẹ́yìn tí ọba fi ìwé kíká náà tí ọ̀rọ̀ tí Baruku kọ láti ẹnu Jeremiah jóná tán, ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jeremiah wá: 28 “Wí pé, tún mú ìwé kíká mìíràn kí o sì kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú ìwé kíká èkínní tí Jehoiakimu ọba Juda fi jóná. 29 Kí o sì wí fún Jehoiakimu ọba Juda pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí: Ìwọ ti fi ìwé kíká náà jóná, o sì wí pé, “Èéṣe tí ìwọ fi kọ̀wé sínú rẹ̀, pé lóòtítọ́ ni ọba Babeli yóò wá, yóò sì pa ilẹ̀ run, àti ènìyàn, àti ẹranko kúrò nínú rẹ̀.” 30 Nítorí náà, báyìí ni Olúwa wí ní ti Jehoiakimu ọba Juda pé: Òun kì yóò ní ẹni tí yóò jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi, à ó sì sọ òkú rẹ̀ nù fún ooru ní ọ̀sán àti fún òtútù ní òru. 31 Èmi ó sì jẹ òun àti irú-ọmọ rẹ̀, ìránṣẹ́ rẹ̀ ní ìyà nítorí àìṣedéédéé wọn; èmi ó sì mú gbogbo ibi tí èmi ti sọ sí wọn wá sórí wọn, àti sórí àwọn olùgbé Jerusalẹmu àti àwọn ènìyàn Juda, nítorí tí wọn kò fetísí mi.’ ”

32 Nígbà náà ni Jeremiah mú ìwé kíká mìíràn fún Baruku akọ̀wé ọmọ Neriah, ẹni tí ó kọ̀wé sínú rẹ̀ láti ẹnu Jeremiah gbogbo ọ̀rọ̀ inú ìwé tí Jehoiakimu ọba Juda ti sun níná. A sì fi onírúurú ọ̀rọ̀ bí irú èyí kún pẹ̀lú.

Jeremiah nínú túbú

37 Sedekiah ọmọ Josiah sì jẹ ọba ní ipò Jehoiakini ọmọ Jehoiakimu ẹni tí Nebukadnessari ọba Babeli fi jẹ ọba ní ilẹ̀ Juda. Ṣùgbọ́n àti òun àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà kò fetísí ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó sọ nípa wòlíì Jeremiah.

1 Kọrinti 14:1-12

Ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀ àti ìfèdèfọ̀

14 Ẹ máa lépa ìfẹ́, ki ẹ sí máa fi ìtara ṣàfẹ́rí ẹ̀bùn tí í ṣe ti Ẹ̀mí, ṣùgbọ́n ki ẹ kúkú lé máa sọtẹ́lẹ̀. Nítorí ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ní èdè àìmọ̀, kò bá ènìyàn sọ̀rọ̀ bì ko ṣe Ọlọ́run: nítorí kó sí ẹni tí ó gbọ́; ṣùgbọ́n nípá ti Ẹ̀mí ó ń sọ ohun ìjìnlẹ̀; Ṣùgbọ́n ẹni tí ń sọtẹ́lẹ̀ ń ba àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ fún ìmúdúró, àti ìgbani-níyànjú, àti ìtùnú. Ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ni èdè àìmọ̀ ń fi ẹsẹ̀ ara rẹ̀ mulẹ̀; ṣùgbọ́n ẹni ti ń sọtẹ́lẹ̀ ń fi ẹsẹ̀ ìjọ múlẹ̀. Ṣùgbọ́n ìbá wù mí ki gbogbo yín lè máa sọ onírúurú èdè, ṣùgbọ́n kí ẹ kúkú máa sọtẹ́lẹ̀: Ẹni tí ń sọtẹ́lẹ̀ pọ̀ jú ẹni ti ń fèdèfọ̀ lọ, bi kọ ṣe pé ó bá ń ṣe ìtumọ̀, kí ìjọ bá à lè kọ́ ẹ̀kọ́.

Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ará, bí mo bá wá sí àárín yín, tí mo sì ń sọ̀rọ̀ ní èdè àìmọ̀, èrè kín ni èmi yóò jẹ́ fún yin, bi ko ṣe pé mo bá ń bá yín sọ̀rọ̀, yálà nípa ìṣípayá, tàbí ìmọ̀ tàbí nípá ìsọtẹ́lẹ̀, tàbí nípa ẹ̀kọ́? Bẹ́ẹ̀ ní pẹ̀lú àwọn nǹkan tí kò ní ẹ̀mí tí ń dún, ìbá à ṣe fèrè tàbí dùùrù bí kò ṣe pé ìyàtọ̀ bá wà nínú wọn, a ó tí ṣe mọ ohùn tí fèrè tàbí tí dùùrù ń wí? Nítorí pé bi ohùn ìpè kò bá dájú, ta ni yóò múra fún ogun? Bẹ́ẹ̀ sí ni ẹ̀yin, bí kò ṣe pé ẹ̀yin bá ń fi ahọ́n yín sọ̀rọ̀ tí ó yé ni, a ó ti ṣe mọ ohun ti ẹ ń wí? Nítorí pé ẹ̀yin yóò kàn máa sọ̀rọ̀ si afẹ́fẹ́ lásán. 10 Ó lé jẹ́ pé onírúurú ohùn èdè ní ń bẹ ní ayé, kò sí ọ̀kan tí kò ní ìtumọ̀ 11 Ǹjẹ́ bí èmí kò mọ ìtumọ̀ ohùn èdè náà, èmí ó jásí aláìgbédè sí ẹni tí ń sọ̀rọ̀, ẹni tí ń sọ̀rọ̀ yóò sí jásí aláìgbédè sí mi. 12 Bẹ́ẹ̀ sì ní ẹ̀yin, bí ẹ̀yin ti ní ìtara fún ẹ̀bùn Ẹ̀mí, ẹ máa ṣe àfẹ́rí àti máa pọ̀ sí i fún ìdàgbàsókè ìjọ.

Matiu 10:16-23

16 “Mò ń rán yín lọ gẹ́gẹ́ bí àgùntàn sáàrín ìkookò. Nítorí náà, kí ẹ ní ìṣọ́ra bí ejò, kí ẹ sì ṣe onírẹ̀lẹ̀ bí àdàbà. 17 (A)Ẹ ṣọ́ra lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn nítorí wọn yóò fi yín le àwọn ìgbìmọ̀ ìgbèríko lọ́wọ́ wọn yóò sì nà yín nínú Sinagọgu. 18 Nítorí orúkọ mi, a ó mú yín lọ síwájú àwọn baálẹ̀ àti àwọn ọba, bí ẹlẹ́rìí sí wọn àti àwọn aláìkọlà. 19 Nígbà tí wọ́n bá mú yín, ẹ má ṣe ṣàníyàn ohun tí ẹ ó sọ tàbí bí ẹ ó ṣe sọ ọ́. Ní ojú kan náà ni a ó fi ohun tí ẹ̀yin yóò sọ fún yín. 20 Nítorí pé kì í ṣe ẹ̀yin ni ó sọ ọ́, bí kò ṣe Ẹ̀mí Baba yín tí ń sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ yín.

21 (B)“Arákùnrin yóò sì fi arákùnrin fún pípa. Baba yóò fi àwọn ọmọ rẹ̀ fún ikú pa. Àwọn ọmọ yóò ṣọ̀tẹ̀ sí òbí wọn, wọn yóò sì mú kí a pa wọ́n. 22 Gbogbo ènìyàn yóò sì kórìíra yín nítorí mi, ṣùgbọ́n gbogbo ẹni tí ó bá dúró ṣinṣin dé òpin ni a ó gbàlà. 23 Nígbà tí wọn bá ṣe inúnibíni sì i yín ní ìlú kan, ẹ sálọ sì ìlú kejì. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ẹ̀yin kò tì í le la gbogbo ìlú Israẹli já tán kí Ọmọ Ènìyàn tó dé.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.