Book of Common Prayer
Ti Dafidi. Saamu.
101 Èmi yóò kọrin ìfẹ́ àti òdodo;
sí ọ Olúwa, èmi yóò máa kọrin ìyìn.
2 Èmi yóò máa rin ìrìn mi pẹ̀lú ọgbọ́n láìlẹ́ṣẹ̀,
ìgbà wo ni ìwọ yóò wá sí ọ̀dọ̀ mi?
Èmi yóò máa rìn ní ilé mi
pẹ̀lú àyà pípé.
3 Èmi kì yóò gbé ohun búburú sí iwájú mi:
iṣẹ́ àwọn tí ó yapa ni èmi kórìíra.
Wọn kì yóò rọ̀ mọ́ mi.
4 Agídí ọkàn yóò kúrò lọ́dọ̀ mi;
Èmi kì yóò mọ ènìyàn búburú.
5 Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ ẹnìkejì rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀,
òun ní èmi yóò gé kúrò
ẹni tí ó bá gbé ojú rẹ̀ ga tí ó sì ní ìgbéraga àyà,
òun ní èmi kì yóò faradà fún.
6 Ojú mi yóò wà lára àwọn olóòtítọ́ lórí ilẹ̀,
kí wọn kí ó lè máa bá mi gbé;
ẹni tí ó bá n rin ọ̀nà pípé
òun ni yóò máa sìn mí.
7 Ẹni tí ó bá ń ṣe ẹ̀tàn, kì yóò gbé ilé mi,
kò sí ẹni tí ń ṣèké tí yóò dúró ní iwájú mi.
8 Ní ojoojúmọ́ ní èmi yóò wá máa pa a lẹ́nu mọ
gbogbo àwọn ènìyàn búburú ilẹ̀ náà;
èmi yóò gé àwọn olùṣe búburú
kúrò ní ìlú Olúwa.
Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu.
109 Ọlọ́run, ti èmi ń fi ìyìn fún
Má ṣe dákẹ́
2 Nítorí àwọn ènìyàn búburú àti ẹlẹ́tàn
ti ya ẹnu wọn sí mi
wọ́n ti fi ahọ́n èké sọ̀rọ̀ sí mi
3 Wọ́n fi ọ̀rọ̀ ìríra yí mi káàkiri;
wọ́n bá mi jà láìnídìí
4 Nípò ìfẹ́ mi, wọn ń ṣe ọ̀tá mi,
ṣùgbọ́n èmi ń gba àdúrà.
5 Wọ́n sì fi ibi san ìre fún mi
àti ìríra fún ìfẹ́ mi.
6 Yan àwọn ènìyàn búburú láti dojúkọ
jẹ́ kí àwọn olùfisùn
dúró ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀.
7 Kí a dá a lẹ́bi nígbà tí a bá ṣe ìdájọ́
kí àdúrà rẹ̀ kí ó lè di ìkọ̀sílẹ̀
8 (A)Kí ọjọ́ rẹ̀ kí ó kúrú
kí ẹlòmíràn kí ó rọ́pò iṣẹ́ rẹ̀
9 Kí àwọn ọmọ rẹ̀ di aláìní baba
kí aya rẹ̀ sì di opó
10 Jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ̀ máa ṣagbe kiri
kí wọn máa tọrọ oúnjẹ jìnnà sí ibi ahoro wọn
11 Jẹ́ kí alọ́nilọ́wọ́gbà kí ó mú ohun gbogbo tí ó ní
jẹ́ kí àlejò kí o kó èrè iṣẹ́ rẹ̀ lọ
12 Má ṣe jẹ́ kí ẹnìkan ṣe àánú fún un
tàbí kí wọn káàánú lórí
àwọn ọmọ rẹ̀ aláìní baba
13 Kí a gé àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ kúrò
kí orúkọ wọn kí ó parẹ́ ní ìran tí ń bọ̀
14 Kí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba rẹ̀ kí
ó wà ní ìrántí ní ọ̀dọ̀ Olúwa
Má ṣe jẹ́ kí a yọ ẹ̀ṣẹ̀ ìyá wọn kúrò
15 Jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ wọn kí ó wà ní ìrántí níwájú Olúwa
kí ó lè gé ìrántí wọn kúrò lórí ilẹ̀.
16 Nítorí kò rántí láti ṣàánú,
ṣùgbọ́n ó ṣe inúnibíni sí ọkùnrin tálákà àti olùpọ́njú,
kí ó lè pa oníròbìnújẹ́ ọkàn.
17 Ó fẹ́ràn láti máa mú ègún wá sí orí rẹ̀:
bi inú rẹ̀ kò ti dùn si ìre, bẹ́ẹ̀ ni kí ó jìnnà sí.
18 Bí ó ti fi ègún wọ ará rẹ̀ láṣọ bí ẹ̀wù
bẹ́ẹ̀ ni kí ó wá sí inú rẹ̀ bí omi
19 Jẹ́ kí ó rí fún un bí aṣọ tí a dà bò ó ní
ara, àti fún àmùrè tí ó fi gba ọ̀já nígbà gbogbo
20 Èyí ni èrè àwọn ọ̀tá mi láti ọwọ́ Olúwa wá;
àti ti àwọn tí ń sọ̀rọ̀ ibi sí ọkàn mi.
21 Ṣùgbọ́n ìwọ, ìwọ ṣe fún mi Olúwa Olódùmarè,
ṣe rere fún mi nítorí orúkọ rẹ
Nítorí tí àánú rẹ dára, ìwọ gbà mí
22 Nítorí pé tálákà àti aláìní ni mí,
àyà mi sì gbọgbẹ́ nínú mi.
23 Èmi ń kọjá lọ bí òjìji tí àṣálẹ́,
mo ń gbọ̀n sókè bí eṣú.
24 Eékún mi di aláìlera nítorí àwẹ̀ gbígbà
ẹran-ara mi sì gbẹ nítorí àìlera mi.
25 (B)Mo dàbí ẹ̀gàn fún àwọn olùfisùn mi;
nígbà tí wọn wò mí, wọ́n gbọn orí wọn.
26 Ràn mí lọ́wọ́, Olúwa Ọlọ́run mi;
gbà mí gẹ́gẹ́ bí ìṣeun ìfẹ́ rẹ.
27 Jẹ́ kí wọn mọ̀ pé ọwọ́ rẹ ni èyí
wí pé ìwọ, Olúwa, ni ó ṣe é.
28 Wọ́n ó máa gégùn ún, ṣùgbọ́n ìwọ máa súre;
Nígbà tí wọn bá dìde kí ojú kí ó tì wọ́n,
ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ rẹ yóò yọ̀
29 Jẹ́ kí a wọ àwọn ọ̀tá mi ní aṣọ ìtìjú
kí á sì fi ìdàrúdàpọ̀ bọ̀ wọ́n lára bí ẹ̀wù.
30 Pẹ̀lú ẹnu mi èmi yóò máa yin Olúwa gidigidi
ní àárín ọ̀pọ̀ ènìyàn èmi yóò máa yìn ín
Olórin pa òfin Olúwa mọ́
121 Èmi ti ṣe ohun tí i ṣe òdodo àti ẹ̀tọ́:
má ṣe fi mí sílẹ̀ fún àwọn tó ń ni mí lára.
122 Mú kí àlàáfíà ìránṣẹ́ rẹ dájú:
má ṣe jẹ́ kí àwọn agbéraga ni mi lára.
123 Ojú mi kùnà, fún wíwo ìgbàlà rẹ,
fún wíwo ìpinnu òdodo rẹ.
124 Ṣe pẹ̀lú ìránṣẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí dídúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ
kí o sì kọ́ mi ní àṣẹ rẹ.
125 Èmi ni ìránṣẹ́ rẹ; ẹ fún mi ní òye
kí èmi lè ní òye òfin rẹ
126 Ó tó àsìkò fún ọ láti ṣe iṣẹ́, Olúwa;
nítorí òfin rẹ ti fọ́.
127 Nítorí èmi fẹ́ràn àṣẹ rẹ
ju wúrà, àní ju wúrà dídára lọ,
128 Nítorí èmi kíyèsi gbogbo ẹ̀kọ́ òtítọ́ rẹ̀,
èmi kórìíra gbogbo ipa ọ̀nà búburú.
Àdúrà láti lè pa òfin Olúwa mọ́
129 Òfin rẹ̀ ìyanu ni:
nítorí náà èmi gbà wọ́n gbọ́.
130 Ìṣípayá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú ìmọ́lẹ̀ wá;
ó fi òye fún àwọn òpè.
131 Èmi ya ẹnu mi mo sì mí hẹlẹ,
nítorí èmi fojú ṣọ́nà sí àṣẹ rẹ.
132 Yí padà sí mi kí o sì ṣàánú fún mi,
bí ìwọ ṣe máa ń ṣe nígbà gbogbo sí àwọn
tí ó fẹ́ràn orúkọ rẹ.
133 Fi ìṣísẹ̀ mi múlẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ rẹ,
má ṣe jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ borí mi.
134 Rà mí padà lọ́wọ́ aninilára ènìyàn,
kí èmi lè gbọ́ ẹ̀kọ́ rẹ.
135 Jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tàn sí ìránṣẹ́ rẹ lára
kí ó sì kọ́ mi ní àṣẹ rẹ.
136 Omijé sàn jáde ní ojú mi,
nítorí wọn kò gba pé òfin rẹ̀ jẹ́ òtítọ́.
137 Olódodo ni ìwọ Olúwa
ìdájọ́ rẹ sì dúró ṣinṣin
138 Òfin ti ìwọ gbé kalẹ̀ jẹ́ òdodo:
wọ́n yẹ ni ìgbẹ́kẹ̀lé.
139 Ìtara mi ti pa mí run,
nítorí àwọn ọ̀tá mi fi ojú fo ọ̀rọ̀ rẹ dá.
140 Wọ́n ti dán ìpinnu rẹ wò pátápátá
ìránṣẹ́ rẹ sì fẹ́ràn wọ́n.
141 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ àti ẹni ẹ̀gàn
èmi kò ni gbàgbé ẹ̀kọ́ rẹ.
142 Òdodo rẹ wà títí láé
òtítọ́ ni òfin rẹ̀.
143 Ìyọnu àti ìpọ́njú wá sórí mi,
ṣùgbọ́n àṣẹ rẹ ni inú dídùn mi,
144 Òfin rẹ jẹ́ òtítọ́ láé;
fún mi ní òye kí èmi lè yè.
9 Ní ọdún kẹrin ọba Hesekiah, nígbà tí ó jẹ́ ọdún keje Hosea ọmọ Ela ọba Israẹli. Ṣalamaneseri ọba Asiria yàn lára Samaria ó sì tẹ̀dó tì í. 10 Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta Asiria gbé e. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kó Samaria ní ọdún kẹfà Hesekiah tí ó sì jẹ́ ọdún kẹsànán Hosea ọba Israẹli. 11 Ọba Asiria lé Israẹli kúrò ní Asiria, wọ́n sì ṣe àtìpó wọn ní Hala, ní Gosani létí odò Habori àti ní ìlú àwọn ará Media. 12 Èyí ṣẹlẹ̀ nítorí wọn kò pa àṣẹ Olúwa Ọlọ́run wọn mọ́. Ṣùgbọ́n wọ́n ti dà májẹ̀mú rẹ̀ gbogbo èyí tí Mose ìránṣẹ́ Olúwa ti pàṣẹ. Wọn kò fi etí wọn sílẹ̀ sí òfin wọn kò sì gbé wọn jáde.
13 Ní ọdún kẹrìnlá tí Hesekiah jẹ ọba, Sennakeribu ọba Asiria kọlu gbogbo ìlú olódi ti Juda ó sì pa wọ́n run. 14 Bẹ́ẹ̀ ni Hesekiah ọba Juda sì ránṣẹ́ yìí sí ọba Asiria ní Lakiṣi, wí pé, “Mo ti ṣẹ̀, padà lẹ́yìn mi: èmi yóò sì san ohunkóhun tí ìwọ bá béèrè lọ́wọ́ mi.” Ọba Asiria sì bu fún Hesekiah ọba Juda ọ̀ọ́dúnrún tálẹ́ǹtì fàdákà àti ọgbọ̀n tálẹ́ǹtì wúrà. 15 Hesekiah fún un ní gbogbo fàdákà tí a rí nínú ilé Olúwa àti nínú ìṣúra ilé ọba.
16 Ní àkókò yìí Hesekiah ọba Juda ké wúrà tí ó wà ní ẹnu ìlẹ̀kùn ilé Olúwa, kúrò àti ti òpó tí Hesekiah ọba Juda ti gbéró ó sì fi fún ọba Asiria.
Sennakeribu halẹ̀ mọ́ Jerusalẹmu
17 Ọba Asiria rán alákòóso gíga jùlọ, ìjòyè pàtàkì àti àwọn adarí pápá pẹ̀lú àwọn ọmọ-ogun tí ó pọ̀, láti Lakiṣi sí ọba Hesekiah ní Jerusalẹmu. Wọ́n wá sí òkè Jerusalẹmu wọ́n sì dúró ní etí ìdarí omi àbàtà òkè, ní ojú ọ̀nà tó lọ sí òpópó pápá Alágbàfọ̀. 18 Wọ́n sì pe ọba; àti Eliakimu ọmọ Hilkiah ẹni tí í ṣe ilé olùtọ́jú, Ṣebna akọ̀wé, àti Joah ọmọkùnrin Asafu tí ó jẹ́ akọ̀wé ìrántí jáde pẹ̀lú wọn.
19 Olùdarí pápá wí fún wọn pé, “Sọ fún Hesekiah pé:
“ ‘Èyí ni ohun tí ọba ńlá, ọba Asiria sọ: kí ni ìgbẹ́kẹ̀lé yìí tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé? 20 Ìwọ wí pé ìwọ ni ìmọ̀ àti agbára láti jagun—ṣùgbọ́n ìwọ sọ̀rọ̀ òfìfo lásán. Ǹjẹ́ ta ni ìwọ gbẹ́kẹ̀ rẹ lé, tí ìwọ fi ń ṣe ọ̀tẹ̀ sí mi? 21 Wò ó, nísinsin yìí, ìwọ gbẹ́kẹ̀ rẹ lé Ejibiti, ẹ̀rún ọ̀pá pẹlẹbẹ ìyè fífọ́ yìí, èyí tí yóò wọ inú ọwọ́ ẹni tí ó sì bá fi ara tì í. Bẹ́ẹ̀ ni Farao ọba Ejibiti ṣe rí fún gbogbo àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀ wọn lé e. 22 Tí ìwọ bá sì sọ fún mi pé, “Àwa gbẹ́kẹ̀ wa lé Olúwa Ọlọ́run.” Òun ha kọ́ ní ẹnìkan náà tí ibi gíga àti àwọn pẹpẹ tí Hesekiah mú kúrò, tí ó wí fún Juda àti Jerusalẹmu pé, “O gbọdọ̀ sìn níwájú pẹpẹ yìí ní Jerusalẹmu”?
23 “ ‘Wá nísinsin yìí, ṣe àdéhùn pẹ̀lú ọ̀gá mi, ọba Asiria: Èmi yóò sì fún ọ ní ẹgbàá ẹṣin (2,000) tí ìwọ bá lè kó àwọn tí yóò gùn ún sí orí rẹ! 24 Báwo ni ìwọ yóò ha ti ṣe le yí ojú balógun kan tí ó kéré jùlọ padà nínú àwọn ìránṣẹ́ olúwa mi, tí ìwọ sì gbẹ́kẹ̀ rẹ lé Ejibiti fún àwọn kẹ̀kẹ́ àti ẹlẹ́ṣin? 25 Síwájú sí i, èmi ti wá láti mú àti láti parun ibí yìí láìsí ọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa? Olúwa fún rara rẹ̀ sọ fún mi pé kí n yára láti yan lórí ìlú yìí, kí n sì pa á run.’ ”
Oúnjẹ tí a fi rú ẹbọ sí òrìṣà
8 (A)Ní ìsinsin yìí, nípa tí oúnjẹ ti a fi rú ẹbọ sí òrìṣà, a mọ̀ pé gbogbo wa ni a ní ìmọ̀. Imọ̀ a máa fẹ́ mu ní gbéraga, ṣùgbọ́n ìfẹ́ ní gbé ni ró. 2 (B)Bí ẹnikẹ́ni bá ró pé òun mọ ohun kan, kò tí ì mọ̀ bí ó ti yẹ kí ó mọ̀. 3 (C)Ṣùgbọ́n ẹni tí ó fẹ́ràn Ọlọ́run nítòótọ́, òun ni ẹni tí Ọlọ́run mọ.
4 (D)Nítorí náà, ǹjẹ́ ó yẹ kí a jẹ àwọn oúnjẹ ti a fi rú ẹbọ sí àwọn òrìṣà bí? Láìṣe àní àní, gbogbo wá mọ̀ pé àwọn ère òrìṣà kì í ṣe Ọlọ́run rárá, ohun asán ni wọn ni ayé. A sì mọ̀ dájúdájú pé Ọlọ́run kan ṣoṣo ní ń bẹ, kò sì ṣí ọlọ́run mìíràn bí kò ṣe ọ̀kan ṣoṣo. 5 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, à ní ọ̀pọ̀ ọlọ́run kéékèèkéé mìíràn ní ọ̀run àti ní ayé (gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ “ọlọ́run” ṣe wa náà ní ọ̀pọ̀ “olúwa” wa). 6 (E)Ṣùgbọ́n fún àwa Ọlọ́run kan ní ó wa, Baba, lọ́wọ́ ẹni tí ó dá ohun gbogbo, àti ti ẹni tí gbogbo wa í ṣe, àti Olúwa kan ṣoṣo Jesu Kristi, nípasẹ̀ ẹni tí ohun gbogbo wà, àti àwa nípasẹ̀ rẹ̀.
7 (F)Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo ènìyàn lo mọ èyí: Ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn tí ó ti ń bọ̀rìṣà lọ́jọ́ tó ti pẹ́ títí di ìsinsin yìí jẹ ẹ́ bí ohun tí a fi rú ẹbọ sí òrìṣà; àti ẹ̀rí ọkàn wọn tí ó ṣe àìlera sì di aláìmọ́. 8 (G)Ṣùgbọ́n oúnjẹ kò mú wa súnmọ́ Ọlọ́run, nítorí pé kì í ṣe bí àwa bá jẹun ni àwa burú jùlọ tàbí nígbà tí a kò jẹ ni àwa dára jùlọ.
9 (H)Ṣùgbọ́n ẹ máa kíyèsi ara gidigidi nípa ìlò òmìnira yín kí ẹ má ba à mú kí àwọn arákùnrin mìíràn tí í ṣe onígbàgbọ́, tí ọkàn wọn ṣe aláìlera, ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀. 10 Ẹ kíyèsára, nítorí bi ẹnìkan ba rí i ti ìwọ ti o ni ìmọ̀ bá jókòó ti oúnjẹ ní ilé òrìṣà, ǹjẹ́ òun kò ha ni mú ọkàn le, bi ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ bá ṣe aláìlera, láti jẹ oúnjẹ tí a fi rú ẹbọ sí òrìṣà? 11 (I)Nítorí náà, nípa ìmọ̀ rẹ ni arákùnrin aláìlera náà yóò ṣe ṣègbé, arákùnrin ẹni tí Kristi kú fún. 12 (J)Bí ẹ bá dẹ́ṣẹ̀ sí arákùnrin rẹ̀ tí ẹ sì ń pa ọkàn àìlera wọn lára, ẹ̀yìn ǹ dẹ́ṣẹ̀ sí Kristi jùlọ. 13 (K)Nítorí nà án, bí oúnjẹ bá mú arákùnrin mi kọsẹ̀, èmi kì yóò sì jẹ ẹran mọ́ títí láé, kí èmi má ba à mú arákùnrin mi kọsẹ̀.
Ọ̀nà tóóró àti ọnà gbòòrò
13 (A)“Ẹ ba ẹnu-ọ̀nà tóóró wọlé; gbòòrò ni ẹnu-ọ̀nà náà, àti oníbùú ni ojú ọ̀nà náà tí ó lọ sí ibi ìparun, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn ẹni tí ń bá ibẹ̀ wọlé. 14 Nítorí kékeré ni ẹnu-ọ̀nà náà, tóóró sì ni ojú ọ̀nà náà, ti ó lọ sí ibi ìyè, díẹ̀ ni àwọn ẹni tí ó ń rìn ín.
Igi àti èso rẹ̀
15 (B)“Ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn èké wòlíì tí wọ́n ń tọ̀ yín wá ní àwọ̀ àgùntàn, ṣùgbọ́n ní inú wọn apanijẹ ìkookò ni wọ́n. 16 Nípa èso wọn ni ẹ̀yin ó fi mọ̀ wọn. Ǹjẹ́ ènìyàn ha lè ká èso àjàrà lára igi ọ̀gàn tàbí èso ọ̀pọ̀tọ́ lára ẹ̀gún òṣùṣú? 17 Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo igi rere a máa so èso rere ṣùgbọ́n igi búburú a máa so èso búburú. 18 Igi rere kò le so èso búburú, bẹ́ẹ̀ ni igi búburú kò lè so èso rere. 19 Gbogbo igi tí kò bá so èso rere, a gé e lulẹ̀, à wọ́ ọ jù sínú iná, 20 Nítorí náà, nípa èso wọn ni ẹ̀yin yóò mọ̀ wọn.
21 (C)“Kì í ṣe gbogbo ẹni tó ń pè mí ní, ‘Olúwa, Olúwa,’ ni yóò wọ ìjọba ọ̀run, bí kò ṣe ẹni tó bá ń ṣe ìfẹ́ baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.