Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 16-17

Miktamu ti Dafidi.

16 Pa mí mọ́, Ọlọ́run,
    nítorí nínú rẹ ni ààbò mi wà.

Mo sọ fún Olúwa, “ìwọ ni Olúwa mi,
    lẹ́yìn rẹ èmi kò ní ìre kan.”
Sí àwọn ènìyàn tí ó wà ní ayé,
    àwọn ni ológo nínú èyí tí ayọ̀ mí wà.
Ìṣòro àwọn wọ̀n-ọn-nì yóò pọ̀ sí i, àní àwọn tí ń tọ ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn.
    Ẹbọ ohun mímu ẹ̀jẹ̀ wọn ni èmi kì yóò ta sílẹ̀,
    bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò dá orúkọ wọn lẹ́nu mi.

Olúwa, ni ìpín ìní mi tí mo yàn àti ago mi,
    ó ti pa ohun tí í ṣe tèmi mọ́.
Okùn ààlà ilẹ̀ ti bọ́ sí ọ̀dọ̀ mi ní ibi dídára;
    nítòótọ́ mo ti ní ogún rere.
Èmi yóò yin Olúwa, ẹni tí ó gbà mí ní ìyànjú;
    ní òru, ọkàn mí ń bá mi sọ̀rọ̀.
(A)Mo ti gbé Ọlọ́run síwájú mi ní ìgbà gbogbo.
    Nítorí tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi, a kì yóò mì mí.

Nítorí èyí, ọkàn mi yọ̀, ahọ́n mi pẹ̀lú ń fò fáyọ̀;
    ara mi pẹ̀lú yóò sinmi ní ààbò,
10 (B)nítorí ìwọ kò ní fi ọ̀kan sílẹ̀ nínú isà òkú,
    tàbí kí ìwọ jẹ́ kí ẹni mímọ́ rẹ kí ó rí ìdíbàjẹ́.
11 Ìwọ ti fi ipa ọ̀nà ìyè hàn mí;
    Ìwọ yóò kún mi pẹ̀lú ayọ̀ ní iwájú rẹ,
    pẹ̀lú ìdùnnú ayérayé ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.

Àdúrà ti Dafidi

17 Gbọ́, Olúwa, ẹ̀bẹ̀ òtítọ́ mi;
    fi etí sí igbe mi.
Tẹ́tí sí àdúrà mi
    tí kò ti ètè ẹ̀tàn jáde.
Kí ìdáláre mi wá láti ọ̀dọ̀ rẹ;
    kí ojú rẹ kí ó rí ohun tí ó tọ́.

Ìwọ ti dán àyà mi wò,
    ìwọ sì bẹ̀ mí wò ní òru, o sì ti wádìí mi,
ìwọ kì yóò rí ohunkóhun èmi ti pinnu pé,
    ẹnu mi kì yóò ṣẹ̀.
Bí ó ṣe ti iṣẹ́ ènìyàn nípa ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ,
    èmi ti pa ara mi mọ́
    kúrò ní ọ̀nà àwọn ìkà.
Ìrìn mí ti jẹ mọ́ ọ̀nà rẹ;
    ẹsẹ̀ mi kì yóò yọ̀.

Èmi ké pè ọ́, Ọlọ́run, nítorí tí ìwọ yóò dá mi lóhùn
    dẹ etí rẹ sí mi kí o sì gbọ́ àdúrà mi.
Fi ìṣeun ìyanu ìfẹ́ ńlá rẹ hàn
    ìwọ tí ó fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ gba àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ là
    lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá tí ó dìde sí wọn.
Pa mí mọ́ bí ẹyin ojú rẹ;
    fi mí pamọ́ sí abẹ́ òjìji ìyẹ́ apá rẹ,
lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú tí ń fóròó mi,
    kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá apani tí ó yí mi ká.

10 Wọ́n pa ọkàn aláìláàánú wọn mọ́,
    wọ́n sì fi ẹnu wọn sọ̀rọ̀ ìgbéraga.
11 Wọ́n sì mú mi mọ́lẹ̀, wọ́n sì yí mi ká,
    pẹ̀lú ojú ìṣọ́ra láti ṣọ́ mi sílẹ̀.
12 Wọn dàbí i kìnnìún tí ebi ń pa fún ìjẹ,
    àní bí kìnnìún ńlá tí ó ń ba níbi ìkọ̀kọ̀.

13 Dìde, Olúwa, dojúkọ wọ́n, rẹ̀ wọ́n sílẹ̀;
    gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹni búburú nípa idà rẹ.
14 Olúwa, nípa ọwọ́ rẹ, gbà mí kúrò lọ́wọ́ irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀,
    kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn ayé yìí, tí èrè wọn wà nínú ayé yìí.
Ìwọ ń pa ebi àwọn tí ìwọ fẹ́ràn lẹ́nu mọ́;
    àwọn ọmọ wọn sì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀,
    wọ́n sì kó ọrọ̀ jọ fún àwọn ọmọ wọn.

15 Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi yóò máa wo ojú rẹ ní òdodo;
    nígbà tí èmi bá jí, èmi yóò ní ìtẹ́lọ́rùn nígbà tí èmi bá rí àwòrán rẹ.

Saamu 22

Fún adarí orin. Tí ohùn orin “àgbọ̀nrín òwúrọ̀.” Saamu ti Dafidi.

22 (A)Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀?
    Èéṣe tí o fi jìnnà láti gbà mí là,
    àní sí igbe ìkérora mi?
Ọlọ́run mi, ní ọ̀sán gangan ni mo kígbe, ṣùgbọ́n ìwọ kò dá mi ní ohùn:
    àti ní òru èmi kò dákẹ́.

Ṣùgbọ́n síbẹ̀ ẹni mímọ́ ni ìwọ;
    ẹni tí ó tẹ ìyìn Israẹli dó;
Àwọn baba ńlá wa ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ;
    wọ́n ní ìgbẹ́kẹ̀lé, ìwọ sì gbà wọ́n.
Ìwọ ni wọ́n sun ẹkún sí, wọ́n sì ní ìgbàlà;
    ìwọ ni wọ́n gbẹ́kẹ̀lé, a kò sì dójútì wọ́n.

Ṣùgbọ́n kòkòrò ní mo jẹ́, kì í sì í ṣe ènìyàn;
    mo di ẹlẹ́gàn àwọn ènìyàn, ẹlẹ́yà àwọn ènìyàn
Gbogbo àwọn tí ó rí mí fi mí ṣe ẹlẹ́yà;
    wọ́n yọ ètè ẹ̀gàn wọn sí mi, wọ́n sì ń mi orí wọn pé.
“Ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé Olúwa;
    jẹ́ kí Olúwa gbà á là.
Jẹ́ kí ó gbà á là,
    nítorí pé, ó ní ayọ̀ nínú rẹ̀.”

Síbẹ̀ ìwọ ni ó ti mú mi wá láti inú;
    ìwọ ni ó mú mi wà láìléwu, nígbà tí mo rọ̀ mọ́ ọmú ìyá mi.
10 Ìwọ ni a fi mí lé lọ́wọ́ láti inú ìyá mi wá,
    nígbà tí ìyá mí sì ti bí mi, ìwọ ni Ọlọ́run mi.

11 Má ṣe jìnnà sí mi,
    nítorí pé ìyọnu súnmọ́ tòsí
    kò sì ṣí ẹnìkan tí yóò ṣe ìrànlọ́wọ́.

12 Ọ̀pọ̀ akọ màlúù yí mi ká;
    àwọn màlúù alágbára Baṣani rọ̀gbà yí mi ká.
13 Wọ́n ya ẹnu wọn sì mi bí i kìnnìún tí ń dọdẹ kiri,
    tí ń ké ramúramù.
14 A dà mí jáde gẹ́gẹ́ bí omi,
    gbogbo egungun mi ti yẹ̀ kúrò ní oríkèé rẹ̀.
Ọkàn mi sì dàbí i ìda;
    tí ó yọ́ láàrín inú mi.
15 Agbára mí ti gbẹ bí àpáàdì,
    ahọ́n mí sì tilẹ̀ mọ́ párí ẹ̀rẹ̀kẹ́ ẹ mi;
    ìwọ ti tẹ́ mi sínú eruku ikú.

16 Àwọn ajá yí mi ká;
    ìjọ àwọn ènìyàn ibi ti ká mi mọ́,
    Wọ́n gún mi lọ́wọ́, wọ́n sì gún mi lẹ́sẹ̀
17 Mo lè ka gbogbo àwọn egungun mi;
    àwọn tìkára wọn ń wò, wọ́n dójú lé mi.
18 Wọ́n pín aṣọ mi láàrín ara wọn
    àní lórí aṣọ mi ni wọ́n ṣẹ́ gègé.

19 Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, má ṣe jìnnà sí mi;
    Háà! Olùrànlọ́wọ́ ọ̀ mi, yára wá fún àtìlẹ́yìn mi!
20 Gba ọkàn mi sílẹ̀ lọ́wọ́ idà,
    àní ẹ̀mí mi lọ́wọ́ agbára àwọn ajá.
21 Gba ọkàn mi sílẹ̀ lọ́wọ́ kìnnìún;
    Kí o sì gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ ìwo àgbáǹréré.

22 Èmi yóò kéde orúkọ rẹ láàrín arákùnrin àti arábìnrin mi;
    nínú ìjọ ni èmi yóò máa yìn ọ́.
23 Ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù Olúwa, ẹ yìn ín!
    Gbogbo ẹ̀yin ìran Jakọbu, ẹ fi ògo fún un!
    Ẹ dìde fún un tẹ̀rù tẹ̀rù, ẹ̀yin irú-ọmọ Israẹli!
24 Nítorí pé òun kò ṣátá, bẹ́ẹ̀ ni kò sì kórìíra
    ìpọ́njú àwọn tí a ni lára;
kò sì fi ojú rẹ̀ pamọ́ fún mi
    ṣùgbọ́n ó gbọ́ nígbà tí mo ké pè é.

25 Láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìyìn mi yóò ti wá nínú àjọ ńlá;
    ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ni èmi yóò san níwájú àwọn tí o bẹ̀rù rẹ̀
26 tálákà yóò jẹ yóò sì yó;
    àwọn tí n wá Olúwa yóò yin
    jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ̀ wà láààyè títí ayérayé!

27 Gbogbo òpin ayé ni yóò rántí
    wọn yóò sì yípadà sí Olúwa,
àti gbogbo ìdílé orílẹ̀-èdè
    ni wọn yóò jọ́sìn níwájú rẹ̀,
28 Nítorí ìjọba ni ti Olúwa.
    Òun ni ó ń pàṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè.

29 Bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo àwọn olówó ayé wọn yóò ṣe àsè, wọn yóò sì sìn;
    gbogbo àwọn tí ó wọ inú ilẹ̀ lọ yóò kúnlẹ̀ ní iwájú rẹ̀
    àti ẹni tí kò lè pa ọkàn ara rẹ̀ mọ́ ni ààyè.
30 Irú-ọmọ rẹ̀ yóò sìn ín;
    a ó sọ fún àwọn ìran tí ń bọ̀ nípa Olúwa,
31 Wọn yóò polongo òdodo rẹ̀
    sí àwọn ọmọ tí a kò tí ì bí,
    wí pé, òun ni ó ṣe èyí.

1 Ọba 5:1-6

Ìmúrasílẹ̀ láti kọ́ ilé fún Olúwa

Nígbà tí Hiramu ọba Tire sì gbọ́ pé, a ti fi òróró yan Solomoni ní ọba ní ipò Dafidi baba rẹ̀, ó sì rán àwọn ikọ̀ rẹ̀ sí Solomoni, nítorí ó ti fẹ́ràn Dafidi ní ọjọ́ rẹ̀ gbogbo. (A)Solomoni sì ránṣẹ́ yìí padà sí Hiramu pé:

“Ìwọ mọ̀ pé Dafidi baba mi kò le kọ́ ilé fún orúkọ Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, nítorí ogun tí ó wà yí i káàkiri, títí Olúwa fi fi gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ sábẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí Olúwa Ọlọ́run mi ti fún mi ní ìsinmi ní ibi gbogbo, bẹ́ẹ̀ ni kò sì sí ọ̀tá tàbí ìjàǹbá kan tí ó ṣe. (B)Nítorí náà mo gbèrò láti kọ́ ilé fún orúkọ Olúwa Ọlọ́run mi, bí Olúwa ti sọ fún Dafidi baba mi, nígbà tí ó wí pé, ‘Ọmọ rẹ tí èmi yóò gbé ka orí ìtẹ́ rẹ ní ipò rẹ ni yóò kọ́ ilé náà fún orúkọ mi.’

“Nítorí náà ni kí o pàṣẹ pé kí wọn kí ó gé igi kedari Lebanoni fún mi wá. Àwọn ènìyàn mi yóò ṣiṣẹ́ pẹ̀lú tìrẹ, Èmi yóò sì san owó ọ̀yà tí ìwọ bá ránṣẹ́ fún àwọn ènìyàn rẹ. Ìwọ mọ̀ pé, a kò ní ẹnìkan nínú wa tí ó mọ bí a ti ń gé igi bí àwọn ará Sidoni.”

Nígbà tí Hiramu sì gbọ́ iṣẹ́ Solomoni, inú rẹ̀ sì dùn gidigidi, ó sì wí pé, “Ògo ni fún Olúwa lónìí, nítorí tí ó ti fún Dafidi ní ọlọ́gbọ́n ọmọ láti ṣàkóso àwọn ìlú ńlá yìí.”

Hiramu sì ránṣẹ́ sí Solomoni pé:

“Èmi ti gbọ́ iṣẹ́ tí ìwọ rán sí mi, èmi yóò sì ṣe gbogbo èyí tí o fẹ́ ní pípèsè igi kedari àti ní ti igi firi. Àwọn ènìyàn mi yóò mú igi náà sọ̀kalẹ̀ láti Lebanoni wá sí Òkun, èmi ó sì fi wọ́n ránṣẹ́ sí ọ ní fífò lójú omi Òkun títí dé ibi tí ìwọ ó na ìka sí fún mi. Níbẹ̀ ni èmi yóò ti yà wọ́n sọ́tọ̀, ìwọ yóò sì kó wọn lọ. Ìwọ yóò sì gba ìfẹ́ mi nípa pípèsè oúnjẹ fún ilé mi.”

10 Báyìí ni Hiramu sì pèsè igi kedari àti igi firi tí Solomoni ń fẹ́ fún un, 11 Solomoni sì fún Hiramu ní ẹgbàáwàá (20,000) òṣùwọ̀n ọkà oúnjẹ fún ilé rẹ̀, àti ogún (20) òṣùwọ̀n òróró dáradára. Solomoni sì ń tẹ̀síwájú láti ṣe èyí fún Hiramu lọ́dọọdún. 12 Olúwa sì fún Solomoni ní ọgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fún un. Ìrẹ́pọ̀ àlàáfíà sì wà láàrín Hiramu àti Solomoni, àwọn méjèèjì sì ṣe àdéhùn.

13 Solomoni ọba sì ṣa asìnrú ènìyàn jọ ní gbogbo Israẹli; àwọn tí ń sìnrú náà jẹ́ ẹgbàá-mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ènìyàn (30,000). 14 Ó sì rán wọn lọ sí Lebanoni, ẹgbàárùn-ún (10,000) lóṣooṣù, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n lo oṣù kan ní Lebanoni, wọn a sì gbé ilé ní oṣù méjì. Adoniramu ni ó ṣe olórí àwọn asìnrú náà. 15 (C)Solomoni sì ní ẹgbàá-márùn-dínlógójì (70,000) ènìyàn tí ń ru ẹrù àti ọ̀kẹ́ mẹ́rin (80,000) gbẹ́nàgbẹ́nà lórí òkè, 16 àti àwọn ìjòyè nínú àwọn tí a fi ṣe olórí iṣẹ́ Solomoni jẹ́ ẹgbẹ̀rìndínlógún ó-lé-ọgọ́rùn-ún (3,300) ènìyàn, tí ó ń ṣe aláṣẹ àwọn ènìyàn tí ń ṣiṣẹ́ náà. 17 Ọba sì pàṣẹ, wọ́n sì mú òkúta wá, òkúta iyebíye, àti òkúta gbígbẹ́ láti fi ìpìlẹ̀ ilé náà lé ilẹ̀. 18 Àwọn oníṣọ̀nà Solomoni àti Hiramu àti àwọn òṣìṣẹ́ láti Gebali sì gbẹ́ wọn, wọ́n sì pèsè igi àti òkúta láti fi kọ́ ilé náà.

Solomoni kọ́ ilé náà

(D)Ní ìgbà tí ó pe ọ̀rìnlénírinwó ọdún (480) lẹ́yìn ìgbà tí àwọn ọmọ Israẹli ti jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, ní ọdún kẹrin ìjọba Solomoni lórí Israẹli, ní oṣù Sifi, tí ń ṣe oṣù kejì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé Olúwa.

1 Ọba 6:7

Ní kíkọ́ ilé náà, òkúta tí a ti gbẹ́ sílẹ̀ kí a tó mú un wá ibẹ̀ nìkan ni a lò, a kò sì gbúròó òòlù tàbí àáké tàbí ohun èlò irin kan nígbà tí a ń kọ́ ọ lọ́wọ́.

Ìṣe àwọn Aposteli 28:1-16

Erékùṣù ni Mẹlita

28 Nígbà tí gbogbo wa sì yọ tan ni àwa tó mọ̀ pé, Mẹlita ni a ń pè erékùṣù náà. Kì í ṣe oore díẹ̀ ni àwọn aláìgbédè náà ṣe fún wa: nítorí ti wọ́n dáná, wọ́n sì gbà gbogbo wa sí ọ̀dọ̀ nítorí òjò ń rọ nígbà náà, àti nítorí òtútù. Nígbà tí Paulu sì ṣa ìdí ìṣẹ́pẹ́ igi jọ, ti ó sì kó o sínú iná, paramọ́lẹ̀ kan ti inú oru-iná jáde, ó di mọ́ ọn ní ọwọ́. Bí àwọn aláìgbédè náà sì ti rí ẹranko olóró náà tí ó dì mọ́ ọn lọ́wọ́, wọ́n bá ara wọn sọ pé, “Dájúdájú apànìyàn ni ọkùnrin yìí, ẹni ti ó yọ nínú Òkun tan, ṣùgbọ́n tí ẹ̀san kò sì jẹ́ kí ó wà láààyè.” Òun sì gbọn ẹranko náà sínú iná ohunkóhun kan kò sì ṣe é. Ṣùgbọ́n wọn ń wòye ìgbà tí yóò wù, tàbí tí yóò sì ṣubú lulẹ̀ láti kú lójijì: nígbà tí wọ́n wò títí, tí wọn kò sì rí nǹkan kan kí ó ṣe é, wọ́n pa èrò wọn dà pé, òrìṣà kan ni ọkùnrin yìí.

Ní agbègbè ibẹ̀ ni ilé ọkùnrin ọlọ́lá erékùṣù náà wà, orúkọ ẹni tí a ń pè ní Pọbiliu; ẹni tí ó ti ipa inú rere gbà wá sí ọ̀dọ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta. Ó sì ṣe, baba Pọbiliu dùbúlẹ̀ àìsàn ibà àti ìgbẹ́-ọ̀rìn; ẹni tí Paulu wọlé tọ̀ lọ, tí ó sì gbàdúrà fún, nígbà tí ó sì fi ọwọ́ lé e, ó sì mú un láradá. Nígbà tí èyí sì ṣetán, àwọn ìyókù tí ó ni ààrùn ni erékùṣù náà tọ̀ ọ́ wá, ó sì mú wọn láradá. 10 Wọ́n sì bu ọlá púpọ̀ fún wa; nígbà tí a ń lọ, wọ́n sì fún wa ní ohun púpọ̀ tí a nílò ní ọ̀nà àjò wa.

Paulu dé sí Romu

11 Lẹ́yìn oṣù mẹ́ta, a wọ ọkọ̀ ojú omi kan èyí tí ó lo àkókò òtútù ní erékùṣù náà. Ó jẹ́ ọkọ̀ ojú omi ti Alekisandiria, èyí tí ààmì rẹ̀ jẹ́ tí òrìṣà ìbejì ti Kasitoru òun Polukisu. 12 Nígbà tí a sì gúnlẹ̀ ní Sirakusi, a gbé ibẹ̀ fún ọjọ́ mẹ́ta. 13 Láti ibẹ̀ nígbà tí a lọ yíká; a dé Regiomu: nígbà tí ó sì di ọjọ́ kejì, afẹ́fẹ́ gúúsù bẹ̀rẹ̀ sí ní fẹ́, ní ọjọ́ kejì rẹ̀ a sì dé Puteoli. 14 A sì rí àwọn arákùnrin kan níbẹ̀, tí wọ́n sì bẹ̀ wá láti bá wọn gbé fún ọjọ́ méje: bẹ́ẹ̀ ni a sì lọ sí ìhà Romu. 15 Àwọn arákùnrin ibẹ̀ gbúròó pé a ń bọ̀, wọ́n sì rìnrìn àjò títí wọ́n fi dé Apii Foroni àti sí ilé èrò mẹ́ta láti pàdé wa: nígba tí Paulu sì rí wọn, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ó sì mú ọkàn le. 16 Nígbà tí a sì dé Romu, olórí àwọn ọmọ-ogun fi àwọn òǹdè lé olórí ẹ̀ṣọ́ lọ́wọ́: ṣùgbọ́n wọ́n gba Paulu láààyè láti máa dágbé fún ara rẹ̀ pẹ̀lú ọmọ-ogun tí ó ń ṣọ́ ọ.

Marku 14:27-42

Jesu sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé Peteru yóò sẹ́ òun

27 (A)Jesu sì wí fún wọn pé, “Gbogbo yín ni ẹ ó sa kúrò lọ́dọ̀ mi, a ti kọ̀wé rẹ pé:

“ ‘Èmi yóò lu olùṣọ́-àgùntàn
    àwọn agbo àgùntàn yóò sì fọ́nká.’

28 (B)Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà ti mo ba jíǹde tan, Èmi yóò síwájú yin lọ sí Galili.”

29 Ṣùgbọ́n Peteru dá a lóhùn, ó wí pé, “Bí gbogbo ènìyàn tilẹ̀ sá kúrò lẹ́yìn rẹ, èmi kò ní sá.”

30 (C)Jesu si wí fún un pé, “Jẹ́ kí ń sọ òótọ́ fún ọ. Kí àkùkọ tó ó kọ lẹ́ẹ̀kejì ní òwúrọ̀ ọ̀la, ìwọ, pàápàá yóò ti sọ lẹ́ẹ̀mẹ́ta wí pe ìwọ kò mọ̀ mí rí.”

31 Ṣùgbọ́n Peteru fa ara ya, ó wí pé, “Bí mo tilẹ̀ ní láti kú pẹ̀lú rẹ̀, èmi kò jẹ́ sọ pé n kò mọ̀ ọ́n rí.” Ìlérí yìí kan náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ìyókù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe.

Ọgbà Getsemane

32 (D)Nígbà tí wọ́n dé ibi kan tí wọ́n ń pè ní ọgbà Getsemane. Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ jókòó dè mí níhìn-ín títí n ó fi lọ gbàdúrà.” 33 Ó sì mú Peteru àti Jakọbu àti Johanu lọ pẹ̀lú rẹ̀. Òun sì kún fún ìrẹ̀wẹ̀sì àti ìbànújẹ́ gidigidi. 34 (E)Ó sì wí fún wọn pé, “ọkàn mi ń káàánú gidigidi títí dé ojú ikú. Ẹ dúró níhìn-ín kí ẹ sì máa bá mi ṣọ́nà.”

35 Ó sì lọ síwájú díẹ̀, ó dojúbo ilẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí i gbàdúrà pé, bí ó bá ṣe e ṣe kí wákàtí tí ó bọ̀ náà ré òun kọjá. 36 (F)Ó sì wí pé, “Ábbà, Baba, ìwọ lè ṣe ohun gbogbo, mú ago yìí kúrò lórí mi, ṣùgbọ́n kì í ṣe èyí tí èmi fẹ́, bí kò ṣe èyí tí ìwọ fẹ́.”

37 Nígbà tí ó sì padà dé ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́ta, ó bá wọn lójú oorun. Ó sì wí fún Peteru pé, “Simoni, o ń sùn ni? Ìwọ kò lè bá mi ṣọ́nà fún wákàtí kan? 38 (G)Ẹ máa ṣọ́nà, kí ẹ sì máa gbàdúrà, ki ẹ má ba à bọ́ sínú ìdánwò. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ‘Ẹ̀mí ń fẹ́ ṣùgbọ́n ó ṣe àìlera fún ara.’ ”

39 Ó sì tún lọ lẹ́ẹ̀kan sí i. Ó sì gbàdúrà gẹ́gẹ́ bí ó ti gbà á ti ìṣáájú. 40 Nígbà tí ó sì tún padà dé, ó bá wọn wọ́n ń sùn, nítorí pé ojú wọn kún fún oorun. Wọn kò sì mọ irú èsì tí wọn ìbá fún un.

41 Ó sì wá nígbà kẹta, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa sùn kí ẹ sì máa sinmi ó tó bẹ́ẹ̀, wákàtí náà ti dé, wò ó, a fi Ọmọ Ènìyàn lé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́. 42 Ẹ dìde, Ẹ jẹ́ kí a máa lọ. Ẹ wò ó, ẹni tí yóò fi mí hàn wà ní tòsí!”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.