Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 41

Fún adarí orin. Saamu Dafidi.

41 Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ń ro ti aláìní:
    Olúwa yóò gbà á ní ìgbà ìpọ́njú.
Olúwa yóò dáàbò bò ó yóò sì pa ọkàn rẹ̀ mọ́:
    yóò bùkún fún un ní orí ilẹ̀
kò sì ní fi sílẹ̀ fún ìfẹ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀.
Olúwa yóò gbà á lórí àkéte àìsàn rẹ̀
    yóò sì mú un padà bọ̀ sípò kúrò nínú àìsàn rẹ̀.

Ní ti èmi, mo wí pé “Olúwa, ṣàánú fún mi;
    wò mí sàn, nítorí pé mo ti ṣẹ̀ sí ọ”.
Àwọn ọ̀tá mi ń sọ̀rọ̀ mi nínú àrankàn, pé
    “Nígbà wo ni yóò kú, ti orúkọ rẹ̀ yóò sì run?”
Nígbàkígbà tí ẹnìkan bá wá wò mí,
    wọn ń sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn, nígbà tí àyà rẹ̀ bá kó ẹ̀ṣẹ̀ jọ sí ara rẹ̀;
nígbà tí ó bá jáde lọ yóò sì máa tàn án kálẹ̀.

Àwọn ọ̀tá mi gbìmọ̀ papọ̀ nípa mi;
    èmi ni wọ́n ń gbìmọ̀ ibi sí,
wọ́n wí pé, “Ohun búburú ni ó dì mọ́ ọn ṣinṣin
    àti ní ibi tí ó dùbúlẹ̀ sí,
kì yóò dìde mọ́.”
(A)Pàápàá, ọ̀rẹ́ mi tímọ́tímọ́, ẹni tí mo gbẹ́kẹ̀lé,
    ẹni tí ó ń jẹ nínú oúnjẹ mi,
tí gbé gìgísẹ̀ rẹ̀ sókè sí mi.

10 Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa, ṣàánú fún mi;
    gbé mi sókè, kí ń ba lè san fún wọn.
11 Èmi mọ̀ pé inú rẹ̀ dùn sí mi,
    nítorí ọ̀tá mi kò borí mi.
12 Bí ó ṣe tèmi ni
    ìwọ dì mímú nínú ìwà òtítọ́ mi
ìwọ sì gbé mi kalẹ̀ níwájú rẹ títí láé.

13 Olùbùkún ni Olúwa, Ọlọ́run Israẹli
    láé àti láéláé.
Àmín àti Àmín.

Saamu 52

Fún adarí orin. Maskili ti Dafidi. Nígbà tí Doegi ará Edomu tọ Saulu lọ láti sọ fún pé, “Dafidi wà ní ilé Ahimeleki.”

52 Èéṣe tí ìwọ fi ń ṣe féfé nínú ìwà ìkà, ìwọ alágbára ọkùnrin?
    Èéṣe tí ìwọ fi ń gbéraga nígbà gbogbo,
    ìwọ ẹni ẹ̀gàn níwájú Ọlọ́run?
Ahọ́n rẹ̀ ń gbìmọ̀ ìparun;
    ó dàbí abẹ mímú,
    ìwọ ẹni tí ń hùwà ẹ̀tàn.
Ìwọ fẹ́ràn ibi ju ìre lọ,
    àti èké ju kí ó sọ òtítọ́ lọ.
Ìwọ fẹ́ràn ọ̀rọ̀ ìpanilára gbogbo,
    ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn!

Ọlọ́run yóò sì lù ọ́ bolẹ̀ láéláé,
    yóò sì dì ọ́ mú,
yóò sì já ọ kúrò ni ibùjókòó rẹ,
    yóò sì fà ọ́ tu kúrò lórí ilẹ̀ alààyè. Sela.
Àwọn olódodo yóò rí, wọn yóò sì bẹ̀rù
    wọn yóò sì rẹ́rìn-ín rẹ̀, wí pé,
“Èyí ni ọkùnrin náà ti kò fi Ọlọ́run ṣe agbára rẹ̀,
    bí kò ṣe ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ rẹ̀ ni ó gbẹ́kẹ̀lé,
    ó sì mu ara rẹ̀ le nínú ìwà búburú rẹ̀.”

Ṣùgbọ́n èmi dàbí igi Olifi
    tí ó gbilẹ̀ nínú ilé Ọlọ́run;
Èmi gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ Ọlọ́run tí kì í kùnà
    láé àti láéláé.
Èmi yóò yìn ọ títí fún ohun tí ó ti ṣe;
    èmi ní ìrètí nínú orúkọ rẹ,
nítorí orúkọ rẹ dára.
    Èmi yóò yìn ọ́ níwájú àwọn ènìyàn mímọ́.

Saamu 44

Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Maskili.

44 À ti fi etí wa gbọ́, Ọlọ́run
    àwọn baba wa tí sọ fún wa
ohun tí ìwọ ṣe ní ọjọ́ wọn,
    ní ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn.
Ìwọ fi ọwọ́ rẹ lé orílẹ̀-èdè jáde
    Ìwọ sì gbin àwọn baba wa;
Ìwọ run àwọn ènìyàn náà
    Ìwọ sì mú àwọn baba wa gbilẹ̀.
Kì í ṣe nípa idà wọn ni wọ́n gba ilẹ̀ náà,
    bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe apá wọn ní ó gbà wọ́n bí kò ṣe;
ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti, apá rẹ;
    àti ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ̀, nítorí ìwọ fẹ́ wọn.

Ìwọ ni ọba àti Ọlọ́run mi,
    ẹni tí ó pàṣẹ ìṣẹ́gun fún Jakọbu.
Nípasẹ̀ rẹ ni àwa ó bi àwọn ọ̀tá wa ṣubú;
    nípasẹ̀ orúkọ rẹ ni àwa ó tẹ àwọn ọ̀tá tí ó dìde sí wa mọ́lẹ̀
Èmi kì yóò gbẹ́kẹ̀lé ọrun mi
    idà mi kì yóò mú ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá wá,
Ṣùgbọ́n ìwọ fún wa ní ìṣẹ́gun lórí àwọn ọ̀tá wa,
    ìwọ sì ti dójúti àwọn tí ó kórìíra wa.
Nínú Ọlọ́run àwa ń ṣògo ní gbogbo ọjọ́,
    àwa ó sì yin orúkọ rẹ títí láé. Sela.

Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ìwọ ti kọ̀ wá, ìwọ sì ti dójútì wá;
    Ìwọ kò sì bá àwọn ọmọ-ogun wa jáde mọ́.
10 Ìwọ ti bá wa jà,
    ìwọ sì ti ṣẹ́gun wa níwájú àwọn ọ̀tá wa,
àwọn ọ̀tá wa ti gba ilẹ̀ wa,
    wọ́n sì fi ipá gba oko wa.
11 Ìwọ fi wá fún jíjẹ bí ẹran àgùntàn
    Ìwọ sì ti tú wa ká sí àárín àwọn kèfèrí.
12 Ìwọ ta àwọn ènìyàn rẹ fún owó kékeré,
    Ìwọ kò sì jẹ èrè kankan lórí iye tí ìwọ tà wọ́n.

13 Ìwọ sọ wá di ẹni ẹ̀sín ní ọ̀dọ̀ àwọn aládùúgbò wa,
    ẹlẹ́yà àti ẹni àbùkù sí àwọn tí ó yí wa ká.
14 Ìwọ ti sọ wá di ẹni ìfisọ̀rọ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè;
    àwọn ènìyàn ń mi orí wọn sí wa.
15 Ìdójútì mi ń bẹ pẹ̀lú mi ní gbogbo ọjọ́,
    ìtìjú sì bojú mi mọ́lẹ̀,
16 nítorí ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn àti ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn
    ní ojú àwọn ọ̀tá àti olùgbẹ̀san.

17 Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ń ṣẹlẹ̀ sí wa,
    síbẹ̀ àwa kò gbàgbé rẹ
bẹ́ẹ̀ ni a kò ṣèké sí májẹ̀mú rẹ̀.
18 Ọkàn wa kò padà sẹ́yìn;
    bẹ́ẹ̀ ni ẹsẹ̀ wa kò yẹ̀ kúrò ní ọ̀nà rẹ̀.
19 Ṣùgbọ́n wọ́n kọlù wá,
    ìwọ sì sọ wá di ẹran ọdẹ fún àwọn ẹranko búburú,
tí wọn sì fi òkùnkùn biribiri bò wá mọ́lẹ̀.

20 Bí àwa bá ti gbàgbé orúkọ Ọlọ́run wa
    tàbí tí a na ọwọ́ wa sí ọlọ́run àjèjì.
21 Ǹjẹ́ Ọlọ́run kì yóò rí ìdí rẹ̀,
    níwọ̀n ìgbà tí ó mọ ohun ìkọ̀kọ̀ inú ọkàn?
22 (A)Síbẹ̀, nítorí rẹ̀ àwa da àyà kọ ikú, ní ojoojúmọ́
    a ń kà wá sí bí àgùntàn fún pípa.

23 Jí, Olúwa! Èéṣe tí ìwọ ń sùn?
    Dìde fúnrarẹ̀! Má ṣe kọ̀ wá sílẹ̀ láéláé.
24 Èéṣe tí ìwọ ń pa ojú rẹ mọ́
    tí ìwọ sì gbàgbé ìpọ́njú àti ìnira wa?

25 Nítorí a tẹrí ọkàn wa ba sínú eruku;
    ara wa sì dì mọ́ erùpẹ̀ ilẹ̀.
26 Dìde kí o sì ràn wá lọ́wọ́;
    rà wá padà nítorí ìfẹ́ rẹ tí ó dúró ṣinṣin.

1 Ọba 13:1-10

Ènìyàn Ọlọ́run kan láti Juda

13 Sì kíyèsi i, ènìyàn Ọlọ́run kan wá láti Juda sí Beteli nípa ọ̀rọ̀ Olúwa, bì Jeroboamu sì ti dúró lẹ́bàá a pẹpẹ láti fi tùràrí jóná. Ó sì kígbe sí pẹpẹ náà nípa ọ̀rọ̀ Olúwa wí pé, “Pẹpẹ! Pẹpẹ! Báyìí ni Olúwa wí: ‘A ó bí ọmọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Josiah ní ilé Dafidi. Lórí rẹ ni yóò sì fi àwọn àlùfáà ibi gíga wọ̀n-ọn-nì tí ń fi tùràrí lórí rẹ̀ rú ẹbọ, a ó sì sun egungun ènìyàn lórí rẹ.’ ” Ní ọjọ́ kan náà ènìyàn Ọlọ́run sì fún wọn ní ààmì kan wí pé: “Èyí ni ààmì tí Olúwa ti kéde: kíyèsi i, pẹpẹ náà yóò ya, eérú tí ń bẹ lórí rẹ̀ yóò sì dànù.”

Nígbà tí Jeroboamu ọba sì gbọ́ ọ̀rọ̀ ènìyàn Ọlọ́run, tí ó kígbe sí pẹpẹ náà ní Beteli, ó sì na ọwọ́ rẹ̀ jáde nínú pẹpẹ, ó sì wí pé, “Ẹ mú un” ṣùgbọ́n ọwọ́ rẹ̀ tí ó nà sí i sì kákò, bẹ́ẹ̀ ni kò sì le fà á padà mọ́. Lẹ́sẹ̀kan náà, pẹpẹ ya, eérú náà sì dànù kúrò lórí pẹpẹ náà gẹ́gẹ́ bí ààmì tí ènìyàn Ọlọ́run ti fi fún un nípa ọ̀rọ̀ Olúwa.

Nígbà náà ní ọba sì wí fún ènìyàn Ọlọ́run náà pé, “Bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú Olúwa Ọlọ́run rẹ, kí o sì gbàdúrà fún mi kí ọwọ́ mi lè padà bọ̀ sípò.” Bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn Ọlọ́run náà bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ Olúwa, ọwọ́ ọba sì padà bọ̀ sípò, ó sì padà sí bí ó ti wà tẹ́lẹ̀.

Ọba sì wí fún ènìyàn Ọlọ́run náà pé, “Wá bá mi lọ ilé, kí o sì wá nǹkan jẹ, èmi yóò sì fi ẹ̀bùn fún ọ.”

Ṣùgbọ́n ènìyàn Ọlọ́run náà dá ọba lóhùn pé, “Bí ìwọ yóò bá tilẹ̀ fún mi ní ìdajì ìní rẹ, Èmi kì yóò lọ pẹ̀lú rẹ tàbí kí èmi jẹ oúnjẹ tàbí mu omi ní ibí yìí. Nítorí a ti pa á láṣẹ fún mi nípa ọ̀rọ̀ Olúwa wí pé: ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ oúnjẹ tàbí mu omi tàbí padà ní ọ̀nà náà tí o gbà wá.’ ” 10 Bẹ́ẹ̀ ni ó gba ọ̀nà mìíràn, kò sì padà gba ọ̀nà tí ó gbà wá sí Beteli.

Filipi 1:1-11

(A)Paulu àti Timotiu, àwọn ìránṣẹ́ Jesu Kristi.

Sí gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ nínú Kristi Jesu tí ó wà ní Filipi, pẹ̀lú àwọn alábojútó àti àwọn díákónì.

(B)Oore-ọ̀fẹ́ sí yín, àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa, àti Olúwa wa Jesu Kristi.

Àdúrà àti Ọpẹ́

Mo ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run mi ní gbogbo ìgbà tí mo bá rántí yín: Nínú gbogbo àdúrà mi fún un yín, èmi ń fi ayọ̀ gbàdúrà, nítorí ìdàpọ̀ yín nínú ìhìnrere láti ọjọ́ kìn-ín-ní wá títí di ìsinsin yìí. (C)Ohun kan yìí sá à dá mi lójú pé, ẹni tí ó ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rere nínú yín, yóò ṣe àṣepé rẹ̀ títí di ọjọ́ náà tí Jesu Kristi yóò dé:

(D)Gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ fún mi láti ro èyí nípa gbogbo yín, nítorí tí mo fi yín sọ́kàn, bí mo tilẹ̀ wà nínú ìdè tàbí ìdáhùn ẹjọ́, àti ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ìhìnrere, gbogbo yín jẹ́ alábápín oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run pẹ̀lú mi. Nítorí Ọlọ́run ni ẹlẹ́rìí mi, bí mo ti ń ṣàfẹ́rí yín gidigidi nínú ìfẹ́ Jesu Kristi.

Èyí sì ni àdúrà mi: pé kí ìfẹ́ yín lè máa pọ̀ síwájú àti síwájú sí i nínú ìfẹ́ àti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀, 10 kí ẹ̀yin kí ó lè ní òye ohun tí ó dára jùlọ; kí ó sì jásí òdodo àti aláìjẹ́ ohun ìkọ̀sẹ̀ títí di ọjọ́ dídé Jesu Kristi: 11 Lẹ́yìn ìgbà ti ẹ ti kún fún àwọn ìwà òdodo láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi, fún ògo àti ìyìn Ọlọ́run.

Marku 15:40-47

40 (A)Àwọn obìnrin kan wà níbẹ̀ pẹ̀lú, tí wọ́n ń wò ó láti òkèèrè. Maria Magdalene wà lára àwọn obìnrin náà, àti Maria ìyá Jakọbu kékeré àti ti Jose, àti Salome. 41 (B)Àwọn wọ̀nyí, nígbà tí ó wà ní Galili máa ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, wọ́n a sì máa ṣe ìránṣẹ́ fún un àti ọ̀pọ̀ obìnrin mìíràn tí wọ́n sì bá a gòkè wá sí Jerusalẹmu.

Ìsìnkú Jesu

42 (C)(D) Ọjọ́ yìí jẹ́ ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́ (èyí tí ṣe, ọjọ́ tó ṣáájú ọjọ́ ìsinmi). Nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ náà sì ṣú, 43 Josẹfu ará Arimatea wá, ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn ọmọ ìgbìmọ̀, ẹni tí ń retí ìjọba Ọlọ́run, ó fi ìgboyà lọ sí iwájú Pilatu láti tọrọ òkú Jesu. 44 Ẹnu ya Pilatu láti gbọ́ pé Jesu ti kú. Nítorí náà ó pe balógun ọ̀rún, ó sì bí i léèrè bóyá Jesu ti kú nítòótọ́. 45 Nígbà tí balógun ọ̀rún náà sì fún Pilatu ni ìdánilójú pé Jesu ti kú, Pilatu jọ̀wọ́ òkú rẹ̀ fún Josẹfu. 46 Josẹfu sì ti ra aṣọ ọ̀gbọ̀ wá. Ó sọ òkú Jesu kalẹ̀: ó sì fi aṣọ ọ̀gbọ̀ náà dì í. Ó sì tẹ́ ẹ sí inú ibojì, tí wọ́n gbẹ́ sí ara àpáta. Ó wá yí òkúta dí ẹnu ibojì náà. 47 Maria Magdalene àti Maria ìyá Jose ń wò ó bi Josẹfu ti n tẹ́ Jesu sí ibojì.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.