Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 24

Ti Dafidi. Saamu.

24 (A)Ti Olúwa ni ilẹ̀, àti ẹ̀kún rẹ̀,
    ayé àti àwọn tí ó tẹ̀dó sínú rẹ̀;
Nítorí ó fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ lórí Òkun
    ó sì gbé e kalẹ̀ lórí àwọn ìṣàn omi.

Ta ni yóò gun orí òkè Olúwa lọ?
    Ta ni yóò dúró ní ibi mímọ́ rẹ̀?
(B)Ẹni tí ó ní ọwọ́ mímọ́ àti àyà funfun,
    ẹni tí kò gbé ọkàn rẹ̀ sókè sí asán
    tí kò sì búra èké.

Òun ni yóò rí ìbùkún gbà láti ọ̀dọ̀ Olúwa,
    àti òdodo lọ́wọ́ Ọlọ́run ìgbàlà rẹ̀.
Èyí ni ìran àwọn tí ń ṣe àfẹ́rí rẹ̀,
    tí ń ṣe àfẹ́rí rẹ̀, Ọlọ́run Jakọbu. Sela.

Ẹ gbé orí yín sókè, háà! Ẹ̀yin ọ̀nà;
    Kí á sì gbe yín sókè, ẹyin ìlẹ̀kùn ayérayé!
    Kí ọba ògo le è wọlé.
Ta ni ọba ògo náà?
    Olúwa tí ó lágbára tí ó sì le,
    Olúwa gan an, tí ó lágbára ní ogun.
Gbé orí yín sókè, ẹyin ọ̀nà;
    kí a sì gbé e yín sókè, ẹ̀yin ìlẹ̀kùn ayérayé,
    kí Ọba ògo le è wọlé wá.
10 Ta ni Ọba ògo náà?
    Olúwa àwọn ọmọ-ogun
    Òun ni Ọba ògo náà. Sela.

Saamu 29

Saamu ti Dafidi.

29 Ẹ fi fún Olúwa, ẹ̀yin ẹ̀dá ọ̀run,
    Ẹ fi fún Olúwa, ògo àti alágbára.
Fi fún Olúwa, àní ògo orúkọ rẹ̀;
    sin Olúwa nínú ẹwà ìwà mímọ́.

Ohùn Olúwa n ré àwọn omi kọjá;
    Ọlọ́run ògo sán àrá,
    Olúwa san ara.
Ohùn Olúwa ní agbára;
    ohùn Olúwa kún fún ọláńlá.
Ohùn Olúwa fa igi kedari;
    Olúwa náà ló fọ́ igi kedari Lebanoni ya.
Ó mú Lebanoni fo bí i ọmọ màlúù,
    àti Sirioni bí ọmọ àgbáǹréré.
Ohùn Olúwa ń ya
    bí ọwọ́ iná mọ̀nà
Ohùn Olúwa ń mi aginjù.
    Olúwa mi aginjù Kadeṣi.
Ohùn Olúwa ní ó lọ igi óákù, ó n mú abo àgbọ̀nrín bí,
    ó sì bọ́ igi igbó sí ìhòhò.
Àti nínú tẹmpili rẹ̀ gbogbo ohùn wí pé “Ògo!”

10 Olúwa jókòó, Ó sì jẹ ọba lórí ìṣàn omi;
    Olúwa jókòó lórí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba títí láéláé.
11 Olúwa fi agbára fún àwọn ènìyàn rẹ̀;
    bùkún àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú àlàáfíà.

Saamu 8

Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti gittiti. Saamu ti Dafidi.

Olúwa, Olúwa wa,
    orúkọ rẹ̀ ti ní ìyìn tó ní gbogbo ayé!

Ìwọ ti gbé ògo rẹ ga
    ju àwọn ọ̀run lọ.
(A)Láti ẹnu ọmọ ọwọ́ àti ọmọ ọmú
    ni o ti yan ìyìn nítorí àwọn ọ̀tá rẹ,
    láti pa àwọn ọ̀tá àti àwọn olùgbẹ̀san lẹ́nu mọ́.
Nígbà tí mo ro ọ̀run rẹ,
    iṣẹ́ ìka rẹ,
òṣùpá àti ìràwọ̀,
    tí ìwọ tí gbé kalẹ̀,
kí ni ènìyàn tí ìwọ ń rò nípa rẹ̀,
    àní ọmọ ènìyàn tí ìwọ ń ṣe ìtọ́jú rẹ̀?

Ìwọ ṣe é ní onírẹ̀lẹ̀ díẹ̀ ju Ọlọ́run lọ,
    ìwọ sì dé e ní adé ògo àti ọlá.
Ìwọ mú un jẹ ọba lórí gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ;
    ìwọ sì fi ohun gbogbo sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀:
àwọn agbo àgùntàn àti àwọn màlúù,
    àti ẹranko igbó,
ẹyẹ ojú ọrun,
    àti ẹja inú Òkun,
    àti ohun tí ń wẹ nínú ipa Òkun.

Olúwa, Olúwa wa,
    Orúkọ rẹ ti ní ìyìn tó ní gbogbo ayé!

Saamu 84

Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti gittiti. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu.

84 Ibùgbé rẹ̀ ti lẹ́wà tó,
    Olúwa àwọn ọmọ-ogun!
Ọkàn mi ń ṣàfẹ́rí nítòótọ́
    ó tilẹ̀ pòǹgbẹ fún àgbàlá Olúwa
àyà mi àti ara mi ń kọrin ayọ̀
    sí Ọlọ́run alààyè.
Nítòótọ́ ológoṣẹ́ ri ilé,
    ẹyẹ alápáǹdẹ̀dẹ̀ tẹ́ ìtẹ́ fún ara rẹ̀,
    níbi tí yóò máa pa ọmọ rẹ̀ mọ́ sí:
ibùgbé ní tòsí pẹpẹ rẹ̀,
    Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ọba mí àti Ọlọ́run mi.
Ìbùkún ní fún àwọn tí ó ń gbé inú ilé rẹ;
    wọn ó máa yìn ọ́ títí láé.

Ìbùkún ni fún àwọn tí agbára wọn wà nínú rẹ
    àwọn tí wọ́n gbé ọkàn lé bíbẹ ibi mímọ́ wò.
Àwọn tí ń la Àfonífojì omijé lọ
    wọn sọ ọ́ di kànga
    àkọ́rọ̀ òjò sì fi ìbùkún bò ó;
Wọ́n ń lọ láti ipa dé ipá
    títí tí ọ̀kọ̀ọ̀kan fi farahàn níwájú Ọlọ́run ní Sioni.

Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa Ọlọ́run Alágbára;
    tẹ́tí sí mi, Ọlọ́run Jakọbu.
Wo asà wa, Ọlọ́run;
    fi ojú àánú wò àwọn ẹni ààmì òróró rẹ.

10 Dídára ní ọjọ́ kan ní ààfin rẹ
    ju ẹgbẹ̀rún ọjọ́ lọ;
èmi o kúkú máa ṣe aṣọ́nà nínú ilé Ọlọ́run mi
    jù láti gbé ní àgọ́ àwọn ènìyàn búburú.
11 Nítorí Olúwa Ọlọ́run jẹ́ òòrùn àti asà;
    Olúwa fún ni ní ojúrere àti ọlá;
kò sí ohun rere kan tí yóò fàsẹ́yìn
    fún àwọn tí ó rìn ní àìlábùkù.

12 Olúwa àwọn ọmọ-ogun,
    ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ.

1 Ọba 19:8-21

Ó si dìde, ó sì jẹ, ó mu, o sì fi agbára oúnjẹ yìí lọ ní ogójì ọ̀sán àti ogójì òru sí Horebu, òkè Ọlọ́run. Níbẹ̀, ó lọ sí ibi ihò òkúta, ó sì wọ̀ níbẹ̀.

Olúwa farahan Elijah

Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Elijah wá wí pé, “Kí ni ìwọ ń ṣe níhìn-ín yìí, Elijah?”

10 (A)Ó sì dáhùn wí pé, “Èmi ti ń jowú fún Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun. Àwọn ọmọ Israẹli ti kọ májẹ̀mú rẹ sílẹ̀, wọ́n sì ti wó àwọn pẹpẹ rẹ lulẹ̀, wọ́n sì ti fi idà pa àwọn wòlíì rẹ. Èmi nìkan ṣoṣo ni ó kù, wọ́n sì ń wá ẹ̀mí mi láti gbà á kúrò báyìí.”

11 Olúwa sì wí pé, “Jáde lọ, kí o sì dúró lórí òkè níwájú Olúwa, nítorí Olúwa fẹ́ rékọjá.”

Nígbà náà ni ìjì ńlá àti líle sì fa àwọn òkè ńlá ya, ó sì fọ́ àwọn àpáta túútúú níwájú Olúwa; ṣùgbọ́n Olúwa kò sí nínú ìjì náà. Lẹ́yìn ìjì náà ni ìṣẹ̀lẹ̀-ìrilẹ̀, ṣùgbọ́n Olúwa kò sí nínú ìṣẹ̀lẹ̀-ìrilẹ̀ náà. 12 Lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀-ìrilẹ̀ náà ni iná wá, ṣùgbọ́n Olúwa kò sí nínú iná náà. Àti lẹ́yìn iná náà ni ohùn kẹ́lẹ́ kékeré wá. 13 Nígbà tí Elijah sì gbọ́ ọ, ó sì fi agbádá rẹ̀ bo ojú rẹ̀, ó sì jáde lọ, ó dúró ní ẹnu ihò òkúta náà.

Nígbà náà ni ohùn kan tọ̀ ọ́ wá wí pé, “Kí ni ìwọ ń ṣe níhìn-ín, Elijah?”

14 Ó sì dáhùn pé, “Èmi ti ń jowú fún Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun. Àwọn ọmọ Israẹli ti kọ májẹ̀mú rẹ sílẹ̀, wọ́n sì ti wó pẹpẹ rẹ lulẹ̀, wọ́n sì ti fi idà pa àwọn wòlíì rẹ. Èmi nìkan ṣoṣo ni ó kù, wọ́n sì ń gbìyànjú láti pa èmi náà báyìí.”

15 Olúwa sì wí fún un pé, “Padà lọ sí ọ̀nà tí ìwọ ti wá, kí o sì lọ sí aginjù Damasku. Nígbà tí ìwọ bá dé ibẹ̀, fi òróró yan Hasaeli ní ọba lórí Aramu. 16 Tún fi òróró yan Jehu ọmọ Nimṣi ní ọba lórí Israẹli, àti kí o fi òróró yan Eliṣa ọmọ Ṣafati, ará Abeli-Mehola ní wòlíì ní ipò rẹ. 17 Jehu yóò pa ẹni tí ó bá sálà kúrò lọ́wọ́ idà Hasaeli, Eliṣa yóò sì pa ẹni tí ó bá sálà kúrò lọ́wọ́ idà Jehu. 18 Síbẹ̀, èmi ti pa ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) ènìyàn mọ́ fún ara mi ní Israẹli, àní gbogbo eékún tí kò ì tí ì kúnlẹ̀ fún òrìṣà Baali, àti gbogbo ẹnu tí kò ì tí ì fi ẹnu kò ó ní ẹnu.”

Ìpè Eliṣa

19 Bẹ́ẹ̀ ni Elijah lọ kúrò níbẹ̀, ó sì rí Eliṣa ọmọ Ṣafati. Ó ń fi àjàgà màlúù méjìlá tulẹ̀ níwájú rẹ̀, àti òun náà níwájú èkejìlá. Elijah sì tọ̀ ọ́ lọ, ó sì da agbádá rẹ̀ bò ó. 20 Nígbà náà ni Eliṣa sì fi àwọn màlúù sílẹ̀, ó sì sáré tọ Elijah lẹ́yìn. Ó wí pé, “Èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí èmi lọ fi ẹnu ko baba àti ìyá mi ní ẹnu. Nígbà náà ni èmi yóò tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.”

Elijah sì dáhùn wí pé, “Padà sẹ́yìn, kí ni mo fi ṣe ọ́?”

21 Eliṣa sì fi í sílẹ̀, ó padà sẹ́yìn. Ó sì mú àjàgà màlúù rẹ, ó sì pa wọ́n. Ó sì fi ohun èlò àwọn màlúù náà bọ́ ẹran wọn, ó sì fi fún àwọn ènìyàn, wọ́n sì jẹ. Nígbà náà ni ó sì dìde láti tọ Elijah lẹ́yìn, ó sì ṣe ìránṣẹ́ fún un.

Ìṣe àwọn Aposteli 5:34-42

34 Ṣùgbọ́n ọ̀kan nínú àjọ ìgbìmọ̀, tí a ń pè ni Gamalieli, Farisi àti amòfin, tí ó ní ìyìn gidigidi lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn, ó dìde dúró, ó ni kí a mú àwọn aposteli bì sẹ́yìn díẹ̀. 35 Ó sì wí fún wọn pé “Ẹ̀yin ènìyàn Israẹli, ẹ kíyèsi ara yín lóhùn tí ẹ̀yin ń pète láti ṣe sí àwọn ọkùnrin wọ̀nyí. 36 Nítorí ṣáájú ọjọ́ wọ̀nyí ni Teuda dìde, ó ń wí pé, ẹni ńlá kan ní òun; ẹni tí ìwọ̀n irínwó ọkùnrin dara wọn pọ̀ mọ́; ṣùgbọ́n a pa á; àti gbogbo iye àwọn tí ó gba tirẹ̀ sì túká, tí wọn sí di asán. 37 Lẹ́yìn ọkùnrin yìí ni Judasi ti Galili dìde ni àkókò kíka àwọn ènìyàn, ó sì ni ẹni púpọ̀ lẹ́yìn rẹ̀; òun pẹ̀lú ṣègbé; àti gbogbo iye àwọn tí ó gba tirẹ̀ ni a fọ́nká. 38 Ǹjẹ́ èmi wí fún un yín nísinsin yìí, ṣọ́ra fún àwọn ọkùnrin wọ̀nyí, kí ẹ sí fi wọn sílẹ̀, nítorí bí ìmọ̀ tàbí iṣẹ́ yìí bá jẹ́ ti ènìyàn, a ó bì í ṣubú. 39 Ṣùgbọ́n bí ti Ọlọ́run bá ní, ẹ̀yin kì yóò lè bì í ṣubú; kí ó má ba à jẹ́ pé, a rí yín bí ẹni tí ń bá Ọlọ́run jà.”

40 Wọ́n sì gbà ìmọ̀ràn rẹ̀. Wọn pe àwọn aposteli wọlé, wọ́n si lù wọ́n. Wọn sí kìlọ̀ fún wọn pé kí wọn má ṣe sọ̀rọ̀ ni orúkọ Jesu mọ́, wọ́n sì jọ̀wọ́ wọn sílẹ̀ lọ.

41 Nítorí náà wọn sì lọ kúrò níwájú àjọ ìgbìmọ̀; wọn ń yọ̀ nítorí tí a kà wọ́n yẹ láti jìyà nítorí orúkọ rẹ̀. 42 Ní ojoojúmọ́ nínú tẹmpili àti ni ojúlé dé ojúlé, wọn kò dẹ́kun kíkọ́ni àti láti wàásù ìhìnrere náà pé Jesu ni Kristi.

Johanu 11:45-47

Àwọn alábojútó pinnu láti pa Jesu

45 Nítorí náà ni ọ̀pọ̀ àwọn Júù tí ó wá sọ́dọ̀ Maria, tí wọ́n rí ohun tí Jesu ṣe, ṣe gbà á gbọ́. 46 Ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn nínú wọn tọ àwọn Farisi lọ, wọ́n sì sọ fún wọn ohun tí Jesu ṣe. 47 Nígbà náà ni àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisi pe ìgbìmọ̀ jọ.

Wọ́n sì wí pé, “Kín ni yóò jẹ àṣeyọrí wa? Nítorí ọkùnrin yìí ń ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ààmì.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.