Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 87

Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu. Orin.

87 Ó ti fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ sórí òkè mímọ́;
Olúwa fẹ́ràn ẹnu-ọ̀nà Sioni
    ju gbogbo ibùgbé Jakọbu lọ.

Ohun ológo ni a sọ nípa rẹ̀,
    ìlú Ọlọ́run;
“Èmi ó dárúkọ Rahabu àti Babeli
    láàrín àwọn tí ó jẹ́wọ́ mi:
Filistia pẹ̀lú, àti Tire, pẹ̀lú Kuṣi
    yóò sọ pé, ‘Èyí ni a bí ní Sioni.’ ”
Nítòótọ́, ti Sioni ni a ó sọ,
    “Eléyìí àti eléyìí ni a bí nínú rẹ̀,
    àti Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo ni yóò fìdí rẹ̀ múlẹ̀.”
Olúwa yóò kọ nínú àkọsílẹ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀:
    “Eléyìí ni a bí ní Sioni.”

Àti àwọn olórin àti àwọn tí ń lu
    ohun èlò orin yóò wí pé,
    “Gbogbo orísun mi ń bẹ nínú rẹ.”

Saamu 90

ÌWÉ KẸRIN

Saamu 90–106

Àdúrà Mose ènìyàn Ọlọ́run

90 Olúwa, ìwọ ti jẹ́ ibùgbé wa ní gbogbo ìran dé ìran.
Kí a tó bí àwọn òkè ńlá
    àti kí ìwọ tó dá ilẹ̀ àti ayé,
láti ayérayé dé ayérayé ìwọ ni Ọlọ́run.

Ìwọ yí ènìyàn padà sí erùpẹ̀,
    wí pé “Padà sí erùpẹ̀, ìwọ ọmọ ènìyàn.”
(A)Nítorí pé ìgbà tí ẹgbẹ̀rún ọdún bá kọjá lójú rẹ,
    bí àná ni ó rí, bí ìgbà ìṣọ́ kan lóru.
Ìwọ gbá ènìyàn dànù nínú oorun ikú;
    wọ́n dàbí koríko tuntun ní òwúrọ̀.
Lóòtítọ́, ní òwúrọ̀, ó yọ tuntun
    ní àṣálẹ́ ni yóò gbẹ, tí yóò sì rẹ̀ dànù.

A pa wá run nípa ìbínú rẹ
    nípa ìbínú rẹ ara kò rọ̀ wá.
Ìwọ ti gbé ẹ̀ṣẹ̀ wa ka iwájú rẹ,
    àti ohun ìkọ̀kọ̀ wa nínú ìmọ́lẹ̀ iwájú rẹ,
Gbogbo ọjọ́ wa ń kọjá lọ lábẹ́ ìbínú rẹ;
    àwa ń lo ọjọ́ wa lọ bí àlá tí à ń rọ́.
10 Àádọ́rin ọdún ni iye ọjọ́ ọdún wá,
    bi ó sì ṣe pé nípa agbára
tí wọn bá tó ọgọ́rin ọdún,
    agbára nínú làálàá pẹ̀lú ìbànújẹ́ ni,
nítorí pé a kò ní pẹ́ gé e kúrò,
    àwa a sì fò lọ.
11 Ta ni ó mọ agbára ìbínú rẹ?
    Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rù rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ìbínú rẹ.
12 Kọ́ wa bí a ti ń kaye ọjọ́ wa dáradára,
    kí àwa ba à lè fi ọkàn wa sípa ọgbọ́n.

13 Yípadà, Olúwa! Yóò ti pẹ́ tó?
    Ṣàánú fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ.
14 Tẹ́ wa lọ́rùn ní òwúrọ̀ nínú ìṣeun ìfẹ́ rẹ,
    kí àwa kí ó lè kọrin fún ayọ̀
    kí inú wa sì dùn ní gbogbo ọjọ́.
15 Mú inú wa dùn bí ọjọ́ tí ìwọ ti pọ́n wa lójú,
    fún ọjọ́ púpọ̀ tí àwa ti rí wàhálà.
16 Jẹ́ kí a fi iṣẹ́ rẹ̀ han àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀,
    ògo rẹ̀ sí àwọn ọmọ wọn.

17 Jẹ́ kí ẹwà Olúwa Ọlọ́run wa wà lára wa;
    fi ìdí iṣẹ́ ọwọ́ wa múlẹ̀ lára wa
    bẹ́ẹ̀ ni, kí ó sì fi ìdí iṣẹ́ ọwọ́ wa múlẹ̀.

Saamu 136

136 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí tí ó ṣeun;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run àwọn ọlọ́run:
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa àwọn olúwa,
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

Fún Òun nìkan tí ń ṣiṣẹ́ ìyanu ńlá;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
Fún ẹni tí ó fi ọgbọ́n dá ọ̀run;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
(A)Fún ẹni tí ó tẹ́ ilẹ̀ lórí omi;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
(B)Fún ẹni tí ó dá àwọn ìmọ́lẹ̀ ńlá;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
Òòrùn láti jẹ ọba ọ̀sán;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
Òṣùpá àti ìràwọ̀ láti jẹ ọba òru;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

10 (C)Fún ẹni tí ó kọlu Ejibiti lára àwọn àkọ́bí wọn;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
11 (D)Ó sì mú Israẹli jáde kúrò láàrín wọn;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
12 Pẹ̀lú ọwọ́ agbára àti apá nínà;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

13 (E)Fún ẹni tí ó pín Òkun pupa ní ìyà;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
14 Ó sì mú Israẹli kọjá láàrín rẹ̀
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
15 Ṣùgbọ́n ó bi Farao àti ogun rẹ̀ ṣubú nínú Òkun pupa;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

16 Fún ẹni tí ó sin àwọn ènìyàn rẹ̀ la aginjù já
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

17 Fún ẹni tí ó kọlu àwọn ọba ńlá;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
18 Ó sì pa àwọn ọba olókìkí
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
19 Sihoni, ọba àwọn ará Amori
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
20 Àti Ogu, ọba Baṣani;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
21 Ó sì fi ilẹ̀ wọn fún ni ní ìní,
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
22 Ìní fún Israẹli, ìránṣẹ́ rẹ̀,
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

23 Ẹni tí ó rántí wa ní ìwà ìrẹ̀lẹ̀ wa;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
24 Ó sì dá wa ní ìdè lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.
25 Ẹni tí ó fi oúnjẹ fún àwọn ẹ̀dá gbogbo
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

26 Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run ọ̀run;
nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

2 Ọba 11:1-20

Ataliah àti Joaṣi

11 (A)Nígbà tí Ataliah ìyá Ahasiah rí i wí pé ọmọ rẹ̀ ti kú, ó tẹ̀síwájú láti pa gbogbo ìdílé ọba náà run. Ṣùgbọ́n Jehoṣeba ọmọbìnrin ọba Jehoramu àti arábìnrin Ahasiah, mú Joaṣi ọmọ Ahasiah, ó sì jí i lọ kúrò láàrín àwọn ọmọ-aládébìnrin ti ọba náà, tí ó kù díẹ̀ kí a pa. Ó gbé òhun àti olùtọ́jú rẹ̀ sínú ìyẹ̀wù láti fi pamọ́ kúrò fún Ataliah; bẹ́ẹ̀ ni a kò pa á. Ó wà ní ìpamọ́ pẹ̀lú olùtọ́jú ní ilé tí a kọ́ fún Olúwa fún ọdún mẹ́fà nígbà tí Ataliah fi jẹ ọba lórí ilẹ̀ náà.

Ní ọdún keje, Jehoiada ránṣẹ́ ó sí mú àwọn olórí lórí ọ̀rọ̀ọ̀rún, pẹ̀lú àwọn balógun àti àwọn olùṣọ́, ó sì mú wọn wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa. Ó ṣe májẹ̀mú pẹ̀lú wọn, ó sì fi wọ́n sí abẹ́ ìbúra nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa. Níbẹ̀ ni ó fi ọmọkùnrin ọba hàn wọ́n. Ó pàṣẹ fún wọn, wí pé, “Ìwọ tí ó wà nínú àwọn ẹgbẹ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí ó ń lọ fún iṣẹ́ ìsìn ní ọjọ́ ìsinmi—ìdámẹ́ta yín fún ṣíṣọ́ ààfin ọba. Ìdámẹ́ta ní ẹnu ìlẹ̀kùn huri, àti ìdámẹ́ta ní ẹnu ìlẹ̀kùn ní ẹ̀yìn olùṣọ́, tí ó yípadà ní ṣíṣọ́ ilé tí a kọ́, Àti ẹ̀yin tí ó wà ní ẹgbẹ́ kejì yòókù tí kì í lọ ibi iṣẹ́ ìsìn ní ọjọ́ ìsinmi gbogbo ni kí ó ṣọ́ ilé tí a kọ́ fún Olúwa fún ọba. Ẹ mú ibùjókòó yín yí ọba ká, olúkúlùkù ọkùnrin pẹ̀lú ohun ìjà rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá súnmọ́ ọgbà yìí gbọdọ̀ kú. Ẹ dúró súnmọ́ ọba ní ibikíbi tí ó bá lọ.”

Olórí àwọn ọ̀rọ̀ọ̀rún ṣe gẹ́gẹ́ bí Jehoiada àlùfáà ti pa á láṣẹ. Olúkúlùkù mú àwọn ọkùnrin rẹ̀ àwọn tí ó ń lọ sí iṣẹ́ ìsìn ní ọjọ́ ìsinmi àti àwọn tí wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ Jehoiada àlùfáà. 10 Nígbà náà, ó fún àwọn olórí ní àwọn ọ̀kọ̀ àti àwọn apata tí ó ti jẹ́ ti ọba Dafidi tí ó sì wà nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa. 11 Àwọn olùṣọ́, olúkúlùkù pẹ̀lú ohun ìjà rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀, wọ́n sì dúró ṣinṣin yìí ọba ká—lẹ́bàá pẹpẹ àti ilé ìhà gúúsù sí ìhà àríwá ilé tí a kọ́ fun Olúwa náà.

12 Jehoiada mú ọmọkùnrin ọba jáde, ó sì gbé adé náà lé e: ó fún un ní ẹ̀dà májẹ̀mú, wọ́n sì kéde ọba rẹ̀. Wọ́n fi ààmì òróró yàn án, àwọn ènìyàn pa àtẹ́wọ́, wọ́n sì kígbe, “Kí ẹ̀mí ọba kí ó gùn.”

13 Nígbà tí Ataliah gbọ́ ariwo tí àwọn olùṣọ́ àti àwọn ènìyàn ń pa, ó lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa. 14 Ó wò ó, níbẹ̀ ni ọba, tí ó dúró lẹ́bàá òpó, gẹ́gẹ́ bí àṣà ti rí. Àwọn balógun àti àwọn afùnpè wà ní ẹ̀bá ọba, gbogbo àwọn ènìyàn ilé náà sì ń yọ̀, wọ́n sì ń fun ìpè pẹ̀lú. Nígbà náà Ataliah fa aṣọ ìgúnwà rẹ̀ ya. Ó sì kégbe pé, “Ọ̀tẹ̀! Ọ̀tẹ̀!”

15 Jehoiada àlùfáà pàṣẹ fún olórí ọ̀rọ̀ọ̀rún, ta ni ó wà ní ìkáwọ́ ọ̀wọ́ ogun: “Mú u jáde láàrín àwọn ẹgbẹ́ ogun yìí kí o sì fi sí ipa idà ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé.” Nítorí àlùfáà ti sọ, “A kò gbọdọ̀ pa á nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa.” 16 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fi agbára mú un bí ó ti dé ibi tí àwọn ẹṣin tí ń wọ ilẹ̀ ààfin ọba àti níbẹ̀ ni a ti pa á.

17 Nígbà náà ni Jehoiada dá májẹ̀mú láàrín Olúwa àti ọba àti àwọn ènìyàn tí yóò jẹ́ ènìyàn Olúwa. Ó dá májẹ̀mú láàrín ọba àti àwọn ènìyàn pẹ̀lú. 18 Gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà lọ sí ilé tí a kọ́ fún òrìṣà Baali wọ́n sì ya á bolẹ̀. Wọ́n fọ́ àwọn pẹpẹ àti òrìṣà sí wẹ́wẹ́. Wọ́n sì pa Mattani àlùfáà Baali níwájú àwọn pẹpẹ.

Nígbà náà, Jehoiada àlùfáà náà sì yan àwọn olùṣọ́ sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa. 19 Ó mú pẹ̀lú u rẹ̀ àwọn olórí ọ̀rọ̀ọ̀rún àti gbogbo balógun àti àwọn olùṣọ́ àti gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà àti lápapọ̀, wọ́n mú ọba sọ̀kalẹ̀ wá láti ilé tí a kọ́ fún Olúwa. Wọ́n sì wọ inú ààfin lọ, wọ́n sì wọlé nípa ìlẹ̀kùn ti àwọn olùṣọ́. Ọba sì mú ààyè rẹ̀ ní orí ìtẹ́ ọba. 20 Gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà sì yọ̀, pẹ̀lú ìlú ńlá náà sì dákẹ́ jẹ́ẹ́. Nítorí a pa Ataliah pẹ̀lú idà náà ní ààfin ọba.

1 Kọrinti 7:10-24

10 Àwọn ti ó ti gbéyàwó àti àwọn tí ó lọ́kọ, ni mo fẹ́ pa á láṣẹ fún kì í ṣe láti ọ̀dọ̀ mi ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Olúwa: “Obìnrin kò gbọdọ̀ kọ́ fi ọkọ rẹ̀ sílẹ̀.” 11 Ṣùgbọ́n tí ó bá fi ọkọ rẹ̀ sílẹ̀; jẹ́ kí ó wà láìní ọkọ mọ́, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí ó bá ọkọ rẹ̀ làjà, kí ọkọ kí ó má ṣe aya rẹ̀ sílẹ̀.

12 (A)Mo fẹ́ fi àwọn ìmọ̀ràn kan kún ún fún un yín, kì í ṣe àṣẹ láti ọ̀dọ̀ Olúwa. Bí arákùnrin bá fẹ́ aya tí kò gbàgbọ́, tí aya náà sá á fẹ́ dúró tí ọkọ náà, ọkọ náà tí í ṣe onígbàgbọ́ kò gbọdọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀. 13 Tí ó bá sì jẹ́ obìnrin ló fẹ́ ọkọ tí kò gbàgbọ́, ṣùgbọ́n tí ọkọ náà ń fẹ́ kí obìnrin yìí dúró tí òun, aya náà kò gbọdọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀. 14 Nítorí pé ó ṣe é ṣe kí a lè mú ọkọ tí kò gba Kristi gbọ́ súnmọ́ Ọlọ́run nípa aya tí í ṣe onígbàgbọ́, a sì le mú ìyàwó tí kò gba Kristi gbọ́ súnmọ́ Ọlọ́run nípa ọkọ tí í ṣe onígbàgbọ́. Bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ wọn yóò jẹ́ aláìmọ́. Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá kọ ara wọn sílẹ̀, ó ṣe é ṣe kí àwọn ọmọ wọn di mímọ́.

15 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin tí i ṣe aláìgbàgbọ́ náà bá fẹ́ láti lọ, jẹ́ kí ó máa lọ. Arákùnrin tàbí arábìnrin náà kò sí lábẹ́ ìdè mọ́; Ọlọ́run ti pè wá láti gbé ní àlàáfíà. 16 (B)Báwo ni ẹ̀yin aya ṣe le mọ̀ pé bóyá ẹ̀yin ni yóò gba ọkọ yín là? Bákan náà ni a lè wí nípa ọkọ tí í ṣe onígbàgbọ́ pé, kò sí ìdánilójú pé aya aláìgbàgbọ́ le yípadà láti di onígbàgbọ́ nípa dídúró ti ọkọ.

Ọ̀rọ̀ nípa ipò ti a wa

17 (C)Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí olúkúlùkù máa gbé ìgbé ayé tí Ọlọ́run ń fẹ́ yín fún, àti nínú èyí tí Olúwa pè é sí. Ìlànà àti òfin mi fún gbogbo ìjọ ni èyí. 18 (D)Ǹjẹ́ ọkùnrin kan ha ti kọlà nígbà tí a pè é? Kí ó má sì ṣe di aláìkọlà. Ǹjẹ́ ọkùnrin kan ha ti kọlà nígbà tí a pè é? Kí ó ma ṣe kọlà. 19 (E)Ìkọlà kò jẹ́ nǹkan àti àìkọlà kò jẹ́ nǹkan, bí kò ṣe pípa òfin Ọlọ́run mọ́. 20 Ó yẹ kí ẹnìkọ̀ọ̀kan máa ṣe iṣẹ́ tí ó ń ṣe tẹ́lẹ̀, kí Ọlọ́run tó pé é sínú ìgbàgbọ́ nínú Kristi.

21 Ǹjẹ́ ẹrú ni ọ́ bí nígbà ti a pè ọ́? Má ṣe kà á sí. Ṣùgbọ́n tí ìwọ bá le di òmìnira, kúkú ṣe èyí nì. 22 (F)Tí ó bá jẹ́ ẹrú, ti Olúwa sì pé ọ, rántí pé Kristi ti sọ ọ́ di òmìnira kúrò lọ́wọ́ agbára búburú ti ẹ̀ṣẹ̀. Tí ó bá sì ti pé ọ̀ nítòótọ́ tí ó sì ti di òmìnira, ó ti di ẹrú Kristi. 23 (G)A sì ti rà yín ní iye kan, nítorí náà ẹ má ṣe di ẹrú ènìyàn. 24 Ará, jẹ́ kí olúkúlùkù ènìyàn, nínú èyí tí a pè é, kí ó dúró nínú ọ̀kan náà pẹ̀lú Ọlọ́run.

Matiu 6:19-24

Títo ìṣúra jọ sí Ọ̀run

19 (A)“Má ṣe to àwọn ìṣúra jọ fún ara rẹ ní ayé yìí, níbi tí kòkòrò ti le jẹ ẹ́, tí ó sì ti le bàjẹ́ àti ibi tí àwọn olè lè fọ́ tí wọ́n yóò sì jí i lọ. 20 Dípò bẹ́ẹ̀ to ìṣúra rẹ jọ sí ọ̀run, níbi ti kòkòrò àti ìpáàrà kò ti lè bà á jẹ́, àti ní ibi tí àwọn olè kò le fọ́ wọlé láti jí í lọ. 21 Nítorí ibi tí ìṣúra yín bá wà níbẹ̀ náà ni ọkàn yín yóò wà pẹ̀lú.

22 (B)“Ojú ni fìtílà ara. Bí ojú rẹ bá mọ́lẹ̀ kedere, gbogbo ara rẹ yóò jẹ́ kìkì ìmọ́lẹ̀. 23 Ṣùgbọ́n bí ojú rẹ kò bá dára, gbogbo ara rẹ ni yóò kún fún òkùnkùn. Bí ìmọ́lẹ̀ ti ó wà nínú rẹ bá wá jẹ́ òkùnkùn, òkùnkùn náà yóò ti pọ̀ tó!

24 (C)“Kò sì í ẹnìkan tí ó lè sin ọ̀gá méjì. Òun yóò yà kórìíra ọ̀kan tí yóò fẹ́ràn èkejì, tàbí kí ó fi ara mọ́ ọ̀kan kí ó sì yan èkejì ní ìpọ̀sí. Ẹ̀yin kò lè sin Ọlọ́run àti owó papọ̀.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.