Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 38

Saamu Dafidi. Ẹ̀bẹ̀.

38 Olúwa, Má ṣe bá mi wí nínú ìbínú rẹ,
    bẹ́ẹ̀ ni kí o má ṣe fi ìyà jẹ mí nínú ìrunú rẹ̀.
Nítorí tí ọfà rẹ kàn mọ́ mi ṣinṣin,
    ọwọ́ rẹ sì kì mí mọ́lẹ̀.
Kò sí ibi yíyè ní ara à mi, nítorí ìbínú rẹ;
    kò sí àlàáfíà nínú egungun mi nítorí i ẹ̀ṣẹ̀ mi.
Nítorí àìṣedéédéé mi ti borí mi mọ́lẹ̀;
    wọ́n tó ìwọ̀n bi àjàgà tí ó wúwo jù fún mi.

Ọgbẹ́ mi ń rùn ó sì díbàjẹ́
    nítorí òmùgọ̀ mi.
Èmi ń jòwèrè, orí mi tẹ̀ ba gidigidi
    èmi ń ṣọ̀fọ̀ rìn kiri ní gbogbo ọjọ́.
Nítorí ẹ̀gbẹ́ mi kún fún ìgbóná tí ń jóni
    kò sì ṣí ibi yíyè ní ara mi,
Ara mi hù, a sì wó mi jẹ́gẹjẹ̀gẹ;
    mo kérora nítorí ìrúkèrúdò àyà mi.

Olúwa, gbogbo ìfẹ́ mi ń bẹ níwájú rẹ;
    ìmí ẹ̀dùn mi kò sápamọ́ fún ọ.
10 Àyà mi ń mí hẹlẹ, agbára mi yẹ̀ mí sílẹ̀;
    bí ó ṣe ti ìmọ́lẹ̀ ojú mi ni, ó ti lọ kúrò lára mi.
11 Àwọn ọ̀rẹ́ mi àti àwọn ẹlẹgbẹ́ mi dúró lókèèrè réré kúrò níbi ìpọ́njú mi,
    àwọn alábágbé mi, dúró lókèèrè.
12 Àwọn tí n wá ẹ̀mí mi dẹ okùn sílẹ̀ fún mi;
    àti àwọn tí ó fẹ́ pa mí lára ń sọ̀rọ̀ nípa ìparun,
    wọ́n sì ń gbèrò ẹ̀tàn ní gbogbo ọjọ́.

13 Ṣùgbọ́n mo dàbí adití odi, èmi kò gbọ́ ọ̀rọ̀;
    àti bí odi, tí kò le sọ̀rọ̀.
14 Nítòótọ́, mo rí bí ọkùnrin tí kò gbọ́rọ̀,
    àti bí ẹnu ẹni tí kò sí ìjiyàn.
15 Ṣùgbọ́n sí ọ Olúwa, ìwọ ni mo dúró dè;
    ìwọ ni, Olúwa Ọlọ́run mi, ẹni tí yóò dáhùn.
16 Nítorí tí mo gbàdúrà, “Gbóhùn mi, kí wọn má ba à yọ̀ mí;
    nígbà tí ẹsẹ̀ mi bá yọ̀ wọn yóò máa gbé ara wọn ga sí mi.”

17 Nítorí tí mo ti ṣetán láti ṣubú,
    ìrora mi sì wà pẹ̀lú mi nígbà gbogbo.
18 Mo jẹ́wọ́ ìrékọjá mi;
    àánú sì ṣe mí fún ẹ̀ṣẹ̀ mi.
19 Àwọn tí ó jẹ́ ọ̀tá mi láìnídìí pàtàkì, wọ́n lágbára púpọ̀,
    ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí ó kórìíra mi lọ́nà òdì.
20 Àwọn tí wọn ń fi ibi san rere fún mi
    àwọn ni ọ̀tá mi
    nítorí pé mò ń tọ ìre lẹ́yìn.

21 Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀, ìwọ Olúwa!
    Ọlọ́run mi, Má ṣe jìnnà sí mi.
22 Yára láti ràn mí lọ́wọ́,
    Olúwa, Olùgbàlà mi.

Saamu 119:25-48

Àdúrà láti ní òye ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

25 Ọkàn mí lẹ̀ mọ́ erùpẹ̀;
    ìwọ sọ mí di ààyè gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
26 Èmi tún ọ̀nà mi ṣírò ìwọ sì dá mi lóhùn;
    kọ́ mi ní àṣẹ rẹ.
27 Jẹ́ kí n mọ ẹ̀kọ́ ìlànà rẹ:
    nígbà náà ni èmi yóò ṣe àṣàrò iṣẹ́ ìyanu rẹ.
28 Ọkàn mi ń ṣe àárẹ̀ pẹ̀lú ìbànújẹ́;
    fi agbára fún mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
29 Pa mí mọ́ kúrò nínú ọ̀nà ẹ̀tàn
    fún mi ní oore-ọ̀fẹ́ nípa òfin rẹ.
30 Èmi ti yan ọ̀nà òtítọ́
    èmi ti gbé ọkàn mi lé òfin rẹ.
31 Èmi yára di òfin rẹ mú. Olúwa
    má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí.
32 Èmi sáré ní ipa ọ̀nà àṣẹ rẹ,
    nítorí ìwọ, ti tú ọkàn mi sílẹ̀.

Ìlérí Ọlọ́run fún aláforítì

33 Kọ́ mi, Olúwa, láti tẹ̀lé àṣẹ rẹ;
    nígbà náà ni èmi yóò pa wọ́n mọ́ dé òpin.
34 Fún mi ní òye, èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́
    èmi yóò sì máa kíyèsi i pẹ̀lú ọkàn mi.
35 Fi ipa ọ̀nà àṣẹ rẹ hàn mí,
    nítorí nínú rẹ̀ ni èmi rí inú dídùn.
36 Yí ọkàn mi padà sí òfin rẹ
    kí ó má ṣe sí ojúkòkòrò mọ́.
37 Yí ojú mi padà kúrò láti máa wo ohun asán:
    pa ọ̀nà mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
38 Mú ìlérí rẹ sẹ sí ìránṣẹ́ rẹ,
    nítorí òfin rẹ dára.
39 Yí ẹ̀gàn mi padà tí mo bẹ̀rù
    nítorí tí ìdájọ́ rẹ dára.
40 Kíyèsi i, ọkàn mi ti fà sí ẹ̀kọ́ rẹ!
    Pa ayé mi mọ́ nínú òdodo rẹ.

Ìgbàlà láti inú òfin Ọlọ́run

41 Jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà wá bá mi, Olúwa,
    ìgbàlà rẹ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ;
42 Nígbà náà ni èmi yóò dá
    ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí mi lóhùn,
    nítorí èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ.
43 Má ṣe gba ọ̀rọ̀ òtítọ́ láti ẹnu mi
    nítorí èmi ti gbé ìrètí mi sínú àṣẹ rẹ
44 Èmi yóò máa gbọ́rọ̀ sí òfin rẹ nígbà gbogbo
    láé àti láéláé.
45 Èmi yóò máa rìn káàkiri ní òmìnira,
    nítorí èmi ti kígbe ẹ̀kọ́ rẹ jáde.
46 Èmi yóò sọ̀rọ̀ òfin rẹ níwájú àwọn ọba
    ojú kì yóò sì tì mí,
47 Nítorí èmi ní inú dídùn nínú àṣẹ rẹ
    nítorí èmi ní ìfẹ́ wọn.
48 Èmi gbé ọwọ́ mi sókè nítorí àṣẹ rẹ, èyí tí èmi fẹ́ràn,
    èmi sì ń ṣe àṣàrò òfin rẹ̀.

Ẹkun Jeremiah 2:8-15

Olúwa pinnu láti fa
    ògiri tí ó yí ọmọbìnrin Sioni ya.
Ó gbé wọn sórí òṣùwọ̀n,
    kò sì fa ọwọ́ rẹ̀ padà kúrò nínú ìparun wọn.
Ó mú kí ilé ìṣọ́ àti odi rẹ̀ ṣọ̀fọ̀
    wọ́n ṣòfò papọ̀.

Ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ ti wọ inú ilẹ̀;
    òpó rẹ̀ ni ó wó tí ó sì ti bàjẹ́.
Ọba àti ọmọ ọbakùnrin rẹ̀ wà ní ìgbèkùn láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,
    kò sí òfin mọ́,
àwọn wòlíì rẹ̀ kò rí
    ìran láti ọ̀dọ̀ Olúwa mọ́.

10 Àwọn àgbàgbà ọmọbìnrin Sioni
    jókòó sílẹ̀ ní ìdákẹ́rọ́rọ́;
wọ́n da eruku sí orí wọn
    wọ́n sì wọ aṣọ àkísà.
Àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin Jerusalẹmu
    ti tẹrí wọn ba sí ilẹ̀.

11 Ojú mi kọ̀ láti sọkún,
    mo ń jẹ ìrora nínú mi,
mo tú ọkàn mi jáde sí ilẹ̀
    nítorí a pa àwọn ènìyàn mí run,
nítorí àwọn ọmọdé àti ọmọ ọwọ́ ń kú
    ní òpópó ìlú.

12 Wọ́n wí fún àwọn ìyá wọn,
    “Níbo ni ọkà àti wáìnì wà?” Wò ó
bí wọ́n ṣe ń kú lọ bí àwọn ọkùnrin tí a ṣe léṣe
    ní àwọn òpópónà ìlú,
bí ayé wọn ṣe ń ṣòfò
    láti ọwọ́ ìyá wọn.

13 Kí ni mo le sọ fún ọ?
    Pẹ̀lú kí ni mo lè fi ọ́ wé,
    Ìwọ ọmọbìnrin Jerusalẹmu?
Kí sì ni mo lè fi ọ́ wé,
    kí n lè tù ọ́ nínú,
    Ìwọ wúńdíá obìnrin Sioni?
Ọgbẹ́ rẹ jì bí Òkun.
    Ta ni yóò wò ọ́ sàn?

14 Ìran àwọn wòlíì rẹ
    jẹ́ kìkì ẹ̀tàn láìní ìwọ̀n;
wọn kò sì fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ hàn
    tí yóò mú ìgbèkùn kúrò fún ọ.
Àwọn òrìṣà tí wọ́n fún ọ
    jẹ́ èké àti ìmúniṣìnà.

15 Àwọn tí ó gba ọ̀nà ọ̀dọ̀ rẹ
    pàtẹ́wọ́ lé ọ lórí;
wọ́n kẹ́gàn wọ́n ju orí wọn
    sí ọmọbìnrin Jerusalẹmu:
“Èyí ha ni ìlú tí à ń pè ní
    àṣepé ẹwà,
    ìdùnnú gbogbo ayé?”

1 Kọrinti 15:51-58

51 Kíyèsi í, ohun ìjìnlẹ̀ ni mo sọ fún un yín: gbogbo wá kì yóò sùn, ṣùgbọ́n gbogbo wá ní a ó paláradà, 52 Lọ́gán, ni ìṣẹ́jú kan, nígbà ìpè ìkẹyìn: nítorí ìpè yóò dún, a ó sì jí àwọn òkú dìde ní àìdíbàjẹ́, a ó sì pa wá láradà. 53 Nítorí pé ara ìdíbàjẹ́ yìí kò lè ṣàìgbé ìdíbàjẹ́ wọ̀, àti ara kíkú yìí kò lè ṣàìgbé ara àìkú wọ̀. 54 (A)Ṣùgbọ́n nígbà tí ará ìdíbàjẹ́ yìí bá ti gbé àìdíbàjẹ́ wọ̀, ti ara kíkú yìí bá sí ti gbé àìkú wọ̀ bẹ́ẹ̀ tan, nígbà náà ni ọ̀rọ̀ ti a kọ yóò ṣẹ pé, “A gbé ikú mí ní ìṣẹ́gun.”

55 “Ikú, oró rẹ dà?
    Ikú, ìṣẹ́gun rẹ́ dà?”

56 Oró ikú ni ẹ̀ṣẹ̀; àti agbára ẹ̀ṣẹ̀ ni òfin 57 Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ní fún Ọlọ́run ẹni tí ó fì ìṣẹ́gun fún wá nípa Olúwa wá Jesu Kristi!

58 Nítorí náà ẹ̀yin ará mi olùfẹ́ ẹ máa dúró ṣinṣin, láìyẹsẹ̀, kí ẹ máa pọ̀ si í ní iṣẹ́ Olúwa nígbà gbogbo, ní ìwọ̀n bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé iṣẹ́ yin kì í ṣe asán nínú Olúwa.

Matiu 12:1-14

Olúwa ọjọ́ ìsinmi

12 (A)(B) Ní àkókò náà ni Jesu ń la àárín oko ọkà kan lọ ní ọjọ́ ìsinmi, ebi sì ń pa àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí i ya orí ọkà, wọ́n sì ń jẹ ẹ́. Nígbà tí àwọn Farisi rí èyí. Wọ́n wí fún pé, “Wò ó! Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ ń ṣe ohun tí kò bá òfin mu ní ọjọ́ ìsinmi.”

(C)Jesu dáhùn pé, “Ẹ̀yin kò ha ka ohun tí Dafidi ṣe nígbà tí ebi ń pa á àti àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Ó wọ inú ilé Ọlọ́run, òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ jẹ àkàrà tí a yà sọ́tọ̀, èyí tí kò yẹ fún wọn láti jẹ, bí kò ṣe fún àwọn àlùfáà nìkan. Tàbí ẹ̀yin kò ti kà á nínú òfin pé ní ọjọ́ ìsinmi, àwọn àlùfáà tí ó wà ní tẹmpili ń ba ọjọ́ ìsinmi jẹ́ tí wọ́n sì wà láìjẹ̀bi. Ṣùgbọ́n mo wí fún yín, ẹni tí ó pọ̀ ju tẹmpili lọ wà níhìn-ín. Bí ó bá jẹ́ pé ẹ mọ ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ yìí, ‘Àánú ni èmi ń fẹ́ kì í ṣe ẹbọ,’ ẹ̀yin kì bá tí dá aláìlẹ́ṣẹ̀ lẹ́bi. Nítorí pé Ọmọ Ènìyàn jẹ́ Olúwa ọjọ́ ìsinmi.”

(D)Nígbà tí Jesu kúrò níbẹ̀ ó lọ sí Sinagọgu wọn, 10 ọkùnrin kan tí ọwọ́ rẹ̀ kan rọ wà níbẹ̀. Wọ́n ń wá ọ̀nà láti fi ẹ̀sùn kan Jesu, wọ́n béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ǹjẹ́ ó tọ́ láti mú ènìyàn láradá ní ọjọ́ ìsinmi?”

11 (E)Ó dá wọn lóhùn pé, “Bí ó bá jẹ́ wí pé bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ní àgùntàn kan ṣoṣo, tí ó sì bọ́ sínú kòtò ní ọjọ́ ìsinmi, ǹjẹ́ kì yóò dìímú, kí ó sì fà á jáde. 12 Ǹjẹ́ mélòó mélòó ní ènìyàn ní iye lórí ju àgùntàn kan lọ! Nítorí náà ó yẹ láti ṣe rere ní ọjọ́ ìsinmi.”

13 Nígbà náà, ó sì wí fún ọkùnrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ,” bí òun sì ti nà án, ọwọ́ rẹ̀ sì bọ̀ sí ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ èkejì. 14 (F)Síbẹ̀ àwọn Farisi jáde lọ pe ìpàdé láti dìtẹ̀ mú un àti bí wọn yóò ṣe pa Jesu.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.