Book of Common Prayer
Àdúrà olùpọ́njú tí àárẹ̀ mú, tí ó sí ọkàn rẹ̀ payá níwájú Olúwa
102 Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa:
Jẹ́ kí igbe ẹ̀bẹ̀ mi kí ó wá sí ọ̀dọ̀ rẹ
2 Má ṣe pa ojú rẹ mọ́ kúrò lọ́dọ̀ mi
ní ọjọ́ tí èmi wà nínú ìpọ́njú.
Dẹ etí rẹ sí mi;
nígbà tí mo bá pè, dá mi lóhùn kíákíá.
3 Nítorí tí ọjọ́ mi run bí èéfín;
egungun mi sì jóná bí ààrò
4 Àyà mi lù, ó sì rọ bí i koríko;
mo gbàgbé láti jẹ oúnjẹ mi.
5 Nítorí ohùn ìkérora mi,
egungun mi lẹ̀ mọ́ ẹran-ara mi.
6 Èmi dàbí ẹyẹ igún ní ijù:
èmi dàbí òwìwí ibi ahoro.
7 Èmi dìde; èmi dàbí ẹyẹ lórí ilé.
8 Ní ọjọ́ gbogbo, àwọn ọ̀tá ológoṣẹ́ mi ń gàn mí;
àwọn tí ń ṣe ìkanra sí mi ń fi orúkọ mi bú.
9 Èmi jẹ eérú gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ mi, èmi sì da ohun mímu mi pọ̀ pẹ̀lú omijé.
10 Nítorí ìbínú ríru rẹ, nítorí ìwọ ti gbé mi sókè, ìwọ sì gbé mi ṣánlẹ̀.
11 Ọjọ́ mi dàbí òjìji àṣálẹ́
èmi sì rọ bí koríko.
12 Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, ni yóò dúró láéláé;
ìrántí rẹ láti ìran dé ìran.
13 Ìwọ ó dìde ìwọ ó sì ṣàánú fún Sioni,
nítorí ìgbà àti ṣe ojúrere sí i;
àkókò náà ti dé.
14 Nítorí tí àwọn òkúta jẹ́ inú dídùn sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ;
wọ́n sì káàánú erùpẹ̀ rẹ.
15 Àwọn kèfèrí yóò bẹ̀rù orúkọ Olúwa,
gbogbo ọba ayé yóò máa bẹ̀rù ògo rẹ.
16 Torí tí Olúwa yóò gbé Sioni ró, yóò farahàn nínú ògo rẹ̀.
17 Yóò dáhùn àdúrà àwọn aláìní;
kì yóò sì gan ẹ̀bẹ̀ wọn.
18 Jẹ́ kí a kọ èyí fún ìran tí ń bọ̀,
àwọn ènìyàn tí a kò tí ì dá yóò yin Olúwa:
19 “Olúwa wo ilẹ̀ láti òkè mímọ́ rẹ̀ wá
láti ọ̀run wá ni ó bojú wo ayé,
20 Láti gbọ́ ìrora ará túbú, láti tú
àwọn tí a yàn sí ikú sílẹ̀.”
21 Kí a lè sọ orúkọ Olúwa ní Sioni
àti ìyìn rẹ̀ ní Jerusalẹmu.
22 Ní ìgbà tí a kó àwọn ènìyàn àti
ìjọba pọ̀ láti máa sìn Olúwa.
23 Ní ipa ọ̀nà mi, ó rẹ agbára mi sílẹ̀,
ó gé ọjọ́ mi kúrú.
24 Èmi sì wí pé;
“Ọlọ́run mi, má ṣe mú mi kúrò ní agbede-méjì ọjọ́ mi; ọdún rẹ̀ ń lọ láti ìran dé ìran.
25 (A)Ní ìbẹ̀rẹ̀ ní ìwọ fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,
ọ̀run sì jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
26 Wọn yóò ṣègbé, wọn yóò parun, ṣùgbọ́n ìwọ yóò wà;
gbogbo wọn ni yóò gbó bí aṣọ.
Bí ẹ̀wù ni ìwọ yóò pààrọ̀ wọn
wọn yóò sì di àpatì.
27 Ṣùgbọ́n ìwọ wà digbí síbẹ̀,
ọdún rẹ kò sì ní òpin.
28 Àwọn ọmọ ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò dúró ní iwájú rẹ pẹ́;
a ó sì fi ẹsẹ̀ irú-ọmọ wọn sọlẹ̀ ní iwájú rẹ.”
ÌWÉ KARÙN-ÚN
Saamu 107–150
107 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó ṣeun;
nítorí ìfẹ́ rẹ̀ dúró láéláé.
2 Jẹ́ kí àwọn ẹni ìràpadà Olúwa kí ó wí báyìí, àwọn
ẹni tí ó rà padà kúrò lọ́wọ́ ọ̀tá,
3 Àwọn tí ó kójọ láti ilẹ̀ wọ̀n-ọn-nì
láti ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn,
láti àríwá àti Òkun wá.
4 Wọ́n ń rìn káàkiri ní aginjù ní ibi tí ọ̀nà kò sí,
wọn kò rí ọ̀nà lọ sí ìlú níbi tí
wọn ó máa gbé
5 Ebi ń pa wọn, òǹgbẹ gbẹ wọ́n,
ó sì rẹ ọkàn wọn nínú wọn.
6 Ní ìgbà náà, wọ́n kígbe sókè
sí Olúwa nínú ìdààmú wọn,
ó sì yọ wọ́n kúrò nínú ìrora wọn
7 Ó fi ọ̀nà títọ́ hàn wọ́n sí ìlú
tí wọn lè máa gbé
8 Ẹ jẹ́ kí wọn máa yin Olúwa nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti nítorí iṣẹ́
ìyanu rẹ̀ sí àwọn ọmọ ènìyàn,
9 Nítorí tí ó tẹ́ ìfẹ́ ọkàn lọ́run
ó sì fi ìre fún ọkàn tí ebi ń pa.
10 Ọ̀pọ̀ jókòó nínú òkùnkùn àti òjìji ikú,
a dè wọ́n ní ìrora àti ní irin,
11 Nítorí tí wọ́n ṣe àìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀
Ọlọ́run, wọ́n kẹ́gàn ìbáwí Ọ̀gá-ògo,
12 Ó sì fi ìkorò rẹ àyà wọn sílẹ̀;
wọn ṣubú, kò sì ṣí ẹni tí
yóò ràn wọ́n lọ́wọ́.
13 Ní ìgbà náà wọ́n ké pe
Olúwa nínú ìdààmú wọn,
ó sì gbà wọ́n nínú ìṣòro wọn
14 Ó mú wọn jáde kúrò nínú
òkùnkùn àti òjìji ikú,
ó sì fa irin tí wọ́n fi dè wọ́n já.
15 Ẹ jẹ́ kí wọn fi ọpẹ́ fún Olúwa! Nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti nítorí iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ sí ọmọ ènìyàn.
16 Nítorí tí ó já ìlẹ̀kùn idẹ wọ̀n-ọn-nì
ó sì ké irin wọn ní agbede-méjì.
17 Ọ̀pọ̀ di aṣiwèrè nítorí ìrékọjá wọn
wọ́n sì pọ́n wọn lójú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn
18 Wọ́n kọ gbogbo oúnjẹ
wọ́n sì súnmọ́ ẹnu-ọ̀nà ikú.
19 Nígbà náà wọ́n kígbe sí Olúwa nínú
ìṣòro wọn, ó sì yọ wọ́n nínú ìdààmú wọn
20 Ó rán ọ̀rọ̀ rẹ̀, ara wọn sì dá
ó sì yọ wọ́n nínú isà òkú.
21 Ẹ jẹ́ kí wọ́n fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ fún ọmọ ènìyàn.
22 Jẹ́ kí wọn rú ẹbọ ọpẹ́
kí wọn kí ó fi ayọ̀ sọ̀rọ̀ iṣẹ́ rẹ̀.
23 Àwọn tí ń sọ̀kalẹ̀ lọ sí Òkun nínú ọkọ̀
ojú omi, wọ́n jẹ́ oníṣòwò nínú omi ńlá.
24 Wọ́n rí iṣẹ́ Olúwa,
àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ nínú ibú
25 Nítorí tí ó pàṣẹ, ó sì mú ìjì fẹ́
tí ó gbé ríru rẹ̀ sókè.
26 Wọ́n gòkè lọ sí ọ̀run wọ́n sì
tún sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibú:
nítorí ìpọ́njú, ọkàn wọn di omi
27 Wọ́n ń ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n bí ọ̀mùtí ènìyàn:
ọgbọ́n wọn sì dé òpin.
28 Nígbà náà wọ́n ń kígbe sókè
sí Olúwa nínú ìdààmú wọn,
ó sì mú wọn jáde nínú ìṣòro wọn.
29 Ó sọ ìjì di ìdákẹ́rọ́rọ́
bẹ́ẹ̀ ni ríru omi rẹ̀ dúró jẹ́ẹ́;
30 Inú wọn dùn nígbà tí ara wọn balẹ̀,
ó mú wọn lọ sí ibi tí ọkàn wọn lọ,
31 Jẹ́ kí wọn fi ọpẹ́ fún
Olúwa nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀
àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ fún ọmọ ènìyàn.
32 Jẹ́ kí wọn gbé e ga ní àárín àwọn ènìyàn
kí wọn kí ó sì yìn ín ní ìjọ àwọn àgbàgbà.
Àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìgbàlà Jerusalẹmu
19 Nígbà tí ọba Hesekiah gbọ́ èyí, ó fa aṣọ rẹ̀ ya ó sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀ ó sì lọ sí àgọ́ Olúwa 2 Ó sì rán Eliakimu olùtọ́jú ààfin, Ṣebna akọ̀wé àti olórí àlùfáà gbogbo wọn sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀, sí ọ̀dọ̀ wòlíì Isaiah ọmọ Amosi. 3 Wọ́n sì sọ fún ún pé, “Èyí ni ohun tí Hesekiah sọ: ọjọ́ òní yí jẹ́ ọjọ́ ìpọ́njú àti ìbáwí àti ẹ̀gàn, gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí ọmọdé wá sí ojú ìbímọ tí kò sì sí agbára láti fi bí wọn. 4 Ó lè jẹ́ wí pé Olúwa Ọlọ́run yóò gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ olùdarí pápá, ẹni tí ọ̀gá rẹ̀, ọba Asiria, ti rán láti fi Ọlọ́run alààyè ṣẹ̀sín, yóò sì bá a wí fún ọ̀rọ̀ ti Olúwa Ọlọ́run rẹ ti gbọ́. Nítorí náà gbàdúrà fún ìyókù àwọn tí ó wà láààyè.”
5 Nígbà tí ìránṣẹ́ ọba Hesekiah lọ sí ọ̀dọ̀ Isaiah, 6 Isaiah wí fún wọn pé, “Sọ fún ọ̀gá rẹ, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa sọ pé: Ẹ má ṣe bẹ̀rù ohun tí ẹ̀yin ti gbọ́—àwọn ọ̀rọ̀ ìhàlẹ̀ pẹ̀lú èyí ti ọba Asiria ti sọ̀rọ̀-òdì sí mi. 7 Gbọ́! Èmi yóò rán ẹ̀mí kan sínú rẹ̀ nígbà tí ó bá sì gbọ́ ariwo, yóò sì padà sí ìlú rẹ̀, níbẹ̀ ni èmi yóò sì gbé gé e lulẹ̀ pẹ̀lú idà.’ ”
8 Nígbà tí olùdarí pápá gbọ́ wí pé ọba Asiria ti kúrò ní Lakiṣi ó sì padà ó sì rí ọba níbi ti ó gbé ń bá Libina jà.
9 Nísinsin yìí Sennakeribu sì gbọ́ ìròyìn wí pé Tirakah, ọba Etiopia ti Ejibiti wá ó sì ń yan jáde lọ láti lọ bá a jagun. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì tún rán oníṣẹ́ sí Hesekiah pẹ̀lú ọ̀rọ̀ yìí pé: 10 “Sọ fún Hesekiah ọba Juda pé: Má ṣe jẹ́ kí òrìṣà tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé kí ó tàn ó jẹ nígbà tí ó wí pé, ‘Jerusalẹmu a kò ní fi lé ọwọ́ ọba Asiria.’ 11 Lóòótọ́ ìwọ ti gbọ́ gbogbo ohun tí ọba Asiria tí ó ṣe sí gbogbo àwọn ìlú, ó pa wọ́n run pátápátá. Ìwọ yóò sì gbàlà? 12 Ṣé àwọn òrìṣà orílẹ̀-èdè tí a ti parun láti ọ̀dọ̀ àwọn baba ńlá mi gbà wọ́n là: òrìṣà Gosani, Harani Reṣefu àti gbogbo ènìyàn Edeni tí wọ́n wà ní Teli-Assari? 13 Níbo ni ọba Hamati wa, ọba Arpadi, ọba ìlú Sefarfaimi, ti Hena, tàbí ti Iffa gbé wà?”
Àdúrà Hesekiah
14 Hesekiah gba lẹ́tà láti ọ̀dọ̀ ìránṣẹ́ ó sì kà á. Nígbà náà ó sì lọ sí òkè ilé tí a kọ́ fún Olúwa ó sì tẹ́ ẹ síwájú Olúwa. 15 Hesekiah gbàdúrà sí Olúwa: “Olúwa Ọlọ́run Israẹli, tí ń gbé ní àárín àwọn kérúbù, ìwọ nìkan ni Ọlọ́run lórí gbogbo ìjọba tí ó wà láyé, ìwọ ti dá ọ̀run àti ayé. 16 Dẹtí sílẹ̀, Olúwa kí o sì gbọ́; la ojú rẹ, Olúwa, kí o sì rí i, gbọ́ ọ̀rọ̀ Sennakeribu tí ó rán láti fi bú Ọlọ́run alààyè.
17 “Òtítọ́ ni, Olúwa, wí pé ọba Asiria ti pa orílẹ̀-èdè wọ̀nyí run àti ilẹ̀ wọn. 18 Wọ́n ti ju òrìṣà wọn sínú iná wọn sì ti bà wọ́n jẹ́, nítorí pé wọn kì í ṣe ọlọ́run. Ṣùgbọ́n, wọ́n jẹ́ igi àti òkúta tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú ọwọ́ ènìyàn. 19 Nísinsin yìí Olúwa Ọlọ́run wa, gbà wá kúrò lọ́wọ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ìjọba lórí ilẹ̀ ayé le mọ̀ pé ìwọ nìkan ṣoṣo ni, Olúwa Ọlọ́run wa.”
Isaiah sọtẹ́lẹ̀ nípa ìṣubú Sennakeribu
20 Nígbà náà Isaiah ọmọ Amosi rán oníṣẹ́ sí Hesekiah pé: “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli sọ: Mo ti gbọ́ àdúrà rẹ nípa ti Sennakeribu ọba Asiria.
16 Nítorí pé bí mo ti ń wàásù ìhìnrere, kì í ṣe ohun tí mo lè máa ṣògo lè. Èmi kò tilẹ̀ le è ṣe é ní, kí a tilẹ̀ sọ pé mo fẹ́ kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Ègbé ni fún mi tí mo bá kọ̀ láti wàásù ìhìnrere. 17 (A)Tó bá jẹ́ pé mò ń wàásù tinútinú mi, mo ní èrè kan, ṣùgbọ́n tí ń kò bá ṣe tinútinú mi, a ti fi iṣẹ́ ìríjú lé mi lọ́wọ́. 18 (B)Ní irú ipò báyìí, kín ni ẹ rò pé yóò jẹ èrè mi ni láti jẹ́? Èrè mi ní àgbàyanu ayọ̀ tí mo ń rí gbà nípa ìwàásù ìhìnrere láìgba owó lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, láìbéèrè ẹ̀tọ́ mi lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni.
19 Bí mo ti jẹ́ òmìnira tí ń kò sì darapọ̀ mọ́ ẹnikẹ́ni, mo sọ ara mi di ẹrú lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn, láti lè jèrè ọ̀pọ̀lọpọ̀ sí i. 20 (C)Nígbà tí mó wà lọ́dọ̀ àwọn Júù, mo dàbí ọ̀kan nínú wọn, kí wọn ba à lè tẹ́tí sí ìwàásù ìhìnrere mi àti ki n le jèrè wọn fún Kristi. Nígbà tí mo bá wà láàrín àwọn tó wà lábẹ́ òfin èmi kì í bá wọn jiyàn rárá (bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kò sí lábẹ́ òfin), kí èmi lè jèrè àwọn ti ń bẹ lábẹ́ òfin. 21 (D)Nígbà tí mo bá wà láàrín àwọn tí kò sí lábẹ́ òfin, èmi náà yóò dàbí ẹni tí kò sí lábẹ́ òfin (èmi kì í ṣe aláìlófin sí Ọlọ́run, ṣùgbọ́n èmí ń bẹ lábẹ́ òfin Kristi), kí èmi le jèrè àwọn tí kò sí lábẹ́ òfin. 22 (E)Nígbà tí mo bá wà láàrín àwọn aláìlera, èmi náà yóò di aláìlera, kí èmi lé jèrè àwọn aláìlera. Mo di ohun gbogbo fún gbogbo ènìyàn, kí èmi ba à lè gba díẹ̀ là lábẹ́ bí ó ti wù kí ó rí. 23 Èmi sì ń ṣe ohun gbogbo nítorí ti ìhìnrere, kí èmi kí ó lè jẹ́ alábápín nínú rẹ̀ pẹ̀lú yín.
24 (F)Ẹ̀yin kò mọ̀ pé, olúkúlùkù ẹni tí ó ní ipa nínú eré ìje ni ó máa ń sáré, ṣùgbọ́n ẹnìkan ṣoṣo ni ń gba ipò ẹ̀bùn tí ó ga jù. Nítorí náà, ẹ sá eré ìje yín kí ẹ ba à le borí. 25 (G)Gbogbo ẹni tí ó ń sáré ìje a máa lọ nínú ìsẹ́ra-ẹni tí ó lágbára. Wọ́n ń ṣe èyí láti gba adé ìdíbàjẹ́. Ṣùgbọ́n àwa ń sá eré ìje tiwa láti fi gba adé ọ̀run àìdíbàjẹ́ láéláé. 26 Nítorí náà, mo ń sá eré ìje lọ sójú ààmì, kì í ṣe bí ẹni ti kò dá lójú. Mò ń jà kí n lè borí, kì í ṣe bí ẹni tí ń bá afẹ́fẹ́ jà. 27 Ṣùgbọ́n èmi ń kó ara mi ní ìjánu, mo sì ń mú un wá sí abẹ́ ìtẹríba, pé lẹ́yìn tí mo ti wàásù fún àwọn ẹlòmíràn, nítorí ohunkóhun, kí èmi fún rara mi má ṣe di ẹni ìtanù fún ẹ̀bùn náà.
Ọkùnrin adẹ́tẹ̀
8 Nígbà tí ó ti orí òkè sọ̀kalẹ̀, ọ̀pọ̀ ènìyàn ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. 2 (A)(B)Sì wò ó, adẹ́tẹ̀ kan wà, ó wá ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀ ó wí pé, “Olúwa, bí ìwọ bá fẹ́, ìwọ lè sọ mi di mímọ́.”
3 Jesu sì nà ọwọ́ rẹ̀, ó fi bà á, ó wí pé, “Mo fẹ́, ìwọ di mímọ́.” Lójúkan náà, ẹ̀tẹ̀ rẹ̀ sì mọ́! 4 (C)Jesu sì wí fún pé, “Wò ó, má ṣe sọ fún ẹnìkan. Ṣùgbọ́n máa ba ọ̀nà rẹ̀ lọ, fi ara rẹ̀ hàn fún àlùfáà, kí o sì san ẹ̀bùn tí Mose pàṣẹ ní ẹ̀rí fún wọn.”
Ìgbàgbọ́ balógun ọ̀rún
5 (D)Nígbà tí Jesu sì wọ̀ Kapernaumu, balógun ọ̀rún kan tọ̀ ọ́ wá, ó bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́. 6 O sì wí pé, “Olúwa, ọmọ ọ̀dọ̀ mi dùbúlẹ̀ ààrùn ẹ̀gbà ni ilé, tòun ti ìrora ńlá.”
7 Jesu sì wí fún un pé, “Èmi ń bọ̀ wá mú un láradá.”
8 Balógun ọ̀rún náà dáhùn, ó wí pé, “Olúwa, èmi kò yẹ ní ẹni tí ìwọ ń wọ̀ abẹ́ òrùlé rẹ̀, ṣùgbọ́n sọ kìkì ọ̀rọ̀ kan, a ó sì mú ọmọ ọ̀dọ̀ mi láradá. 9 Ẹni tí ó wà lábẹ́ àṣẹ sá ni èmi, èmi sí ní ọmọ-ogun lẹ́yìn mi. Bí mo wí fún ẹni kan pé, ‘Lọ,’ a sì lọ, àti fún ẹni kejì pé, ‘Wá,’ a sì wá, àti fún ọmọ ọ̀dọ̀ mi pé, ‘Ṣe èyí,’ a sì ṣe é.”
10 Nígbà tí Jesu gbọ́ èyí ẹnu yà á, ó sì wí fún àwọn tí ó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, èmi kò rí ẹnìkan ni Israẹli tó ní ìgbàgbọ́ ńlá bí irú èyí. 11 Mo sì wí fún yín, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni yóò ti ìhà ìlà-oòrùn àti ìhà ìwọ̀-oòrùn wá, wọ́n á sì bá Abrahamu àti Isaaki àti Jakọbu jẹun ní ìjọba ọ̀run. 12 Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ìjọba ni a ó sọ sínú òkùnkùn lóde, níbẹ̀ ni ẹkún àti ìpayínkeke yóò gbé wà.”
13 Nítorí náà Jesu sì wí fún balógun ọ̀run náà pé, “Máa lọ ilé, ohun tí ìwọ gbàgbọ́ ti rí bẹ́ẹ̀.” A sì mú ọmọ ọ̀dọ̀ náà láradá ní wákàtí kan náà.
Jesu wo ọ̀pọ̀ aláìsàn sàn
14 (E)Nígbà tí Jesu sì dé ilé Peteru, ìyá ìyàwó Peteru dùbúlẹ̀ àìsàn ibà. 15 Ṣùgbọ́n nígbà tí Jesu fi ọwọ́ kan ọwọ́ rẹ̀, ibà náà fi í sílẹ̀, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ó sì dìde ó ń ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.
16 Nígbà tí ó di àṣálẹ́, ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó ní ẹ̀mí èṣù ni a mú wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ lé àwọn ẹ̀mí èṣù náà jáde. A sì mú gbogbo àwọn ọlọ́kùnrùn láradá. 17 (F)Kí èyí tí a ti sọ láti ẹnu wòlíì Isaiah lè ṣẹ pé:
“Òun tìkára rẹ̀ gbà àìlera wa,
ó sì ń ru ààrùn wa.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.