Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Book of Common Prayer

Daily Old and New Testament readings based on the Book of Common Prayer.
Duration: 861 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 20-21

Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.

20 Olúwa kí ó gbóhùn rẹ ní ọjọ́ ìpọ́njú;
    kí orúkọ Ọlọ́run Jakọbu kí ó dáàbò bò ọ́.
Kí ó rán ìrànlọ́wọ́ sí ọ, láti ibi mímọ́
    kí ó sì tì ọ́ lẹ́yìn láti Sioni wá.
Kí ó sì rántí gbogbo ẹbọ rẹ
    kí ó sì gba ẹbọ sísun rẹ. Sela
Kí ó fi fún ọ gẹ́gẹ́ bi ti èrò ọkàn rẹ
    kí ó sì mú gbogbo ìmọ̀ rẹ ṣẹ.
Àwa yóò hó fún ayọ̀ nígbà tí o bá di aṣẹ́gun
    àwa yóò gbé àsíá wa sókè ní orúkọ Ọlọ́run wa.

Kí Ọlọ́run kí ó mú gbogbo ìbéèrè rẹ̀ ṣẹ.

Nísinsin yìí, èmi mọ̀ wí pé:
    Olúwa pa ẹni ààmì òróró rẹ̀ mọ́.
Yóò gbọ́ láti ọ̀run mímọ́ rẹ̀ wá
    pẹ̀lú agbára ìgbàlà ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀.
Àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀ wọn lé kẹ̀kẹ́, àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀ wọn lé ẹṣin,
    ṣùgbọ́n àwa gbẹ́kẹ̀lé orúkọ Olúwa Ọlọ́run wa.
Wọ́n wólẹ̀, ní eékún, wọ́n sì ṣubú,
    ṣùgbọ́n àwa dìde, a sì dúró ṣinṣin.
Olúwa, fi ìṣẹ́gun fún ọba!
    Dá wa lóhùn nígbà tí a bá ń kígbe pè!

Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.

21 Háà! Olúwa, ọba yóò yọ̀ nínú agbára rẹ,
    àti ní ìgbàlà rẹ, yóò ti yọ̀ pẹ́ tó!

Nítorí pé ìwọ ti fi ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ fún un,
    bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò sì dùn ún ní ìbéèrè ẹnu rẹ̀. Sela.
Ìwọ ti fi àwọn ìbùkún oore kò ó ni ọ̀nà
    ìwọ fi adé wúrà dé e ní orí.
Ó béèrè fún ìyè, ìwọ sì fi fún un,
    àní ọjọ́ gígùn títí ayérayé.
Ògo rẹ̀ pọ̀ nípasẹ̀ ìṣẹ́gun tí o fi fún un;
    ìwọ sì jẹ́ kí iyì ọláńlá rẹ̀ wà lára rẹ.
Dájúdájú, ìwọ ti fi ìbùkún ayérayé fún un:
    ìwọ sì mú inú rẹ̀ dùn pẹ̀lú ayọ̀ ojú u rẹ̀.
Ọba ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa;
    nípasẹ̀ ìfẹ́ Ọ̀gá-ògo tí kì í kùnà
    kì yóò sípò padà.

Ọwọ́ rẹ yóò wá gbogbo àwọn ọ̀tá a rẹ rí;
    ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò wá àwọn tí o kórìíra rẹ rí.
Nígbà tí ìwọ bá yọ
    ìwọ yóò mú wọn dàbí iná ìléru.
Olúwa yóò gbé wọn mì nínú ìbínú rẹ̀,
    àti pé iná rẹ̀ yóò jó wọn run.
10 Ìwọ yóò pa ìrandíran wọn run kúrò lórí ilẹ̀,
    àti irú-ọmọ wọn kúrò láàrín àwọn ọmọ ènìyàn.
11 Bí o tilẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n ro èrò ibi sí ọ
    wọ́n sì ń pète ìwà ìkà, wọn kì yóò ṣe àṣeyọrí.
12 Nítorí pé ìwọ yóò mú wọn yí ẹ̀yìn wọn padà
    nígbà tí o bá pinnu láti ta wọ́n ní ọfà.

13 Gbígbéga ni ọ́ Olúwa, nínú agbára rẹ;
    a ó kọrin, a ó yín agbára a rẹ̀.

Saamu 110

Ti Dafidi. Saamu.

110 (A)Olúwa sọ fún Olúwa mi pé:

“Ìwọ jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi,
    títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ
    di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.”

Olúwa yóò na ọ̀pá agbára rẹ̀
    láti Sioni wá, ìwọ jẹ ọba láàrín àwọn ọ̀tá rẹ.
Àwọn ènìyàn rẹ jẹ́ ọ̀rẹ́ àtinúwá
    ní ọjọ́ ìjáde ogun rẹ, nínú ẹwà mímọ́,
    láti inú òwúrọ̀ wá ìwọ ni ìrì ẹwà rẹ.

(B)Olúwa ti búra,
    kò sì í yí ọkàn padà pé,
“Ìwọ ni àlùfáà,
    ní ipasẹ̀ Melkisedeki.”

Olúwa, ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ni
    yóò lu àwọn ọba bolẹ̀ ni ọjọ́ ìbínú rẹ̀
Yóò ṣe ìdájọ́ láàrín kèfèrí,
    yóò kún ibùgbé wọn pẹ̀lú òkú ara;
    yóò fọ́n àwọn olórí ká sí orí ilẹ̀ ayé tí ó gbòòrò.
Yóò mu nínú odò ṣíṣàn ní ọ̀nà:
    nítorí náà ni yóò ṣe gbé orí sókè.

Saamu 116-117

116 Èmi fẹ́ràn Olúwa, nítorí ó gbọ́ ohùn mi;
    ó gbọ́ ẹkún mi fún àánú.
Nítorí ó yí etí rẹ̀ padà sí mi,
    èmi yóò máa pè é ni wọ́n ìgbà tí mo wà láààyè.

Okùn ikú yí mi ká,
    ìrora isà òkú wá sórí mi;
    ìyọnu àti ìbànújẹ́ borí mi.
Nígbà náà ni mo ké pe orúkọ Olúwa:
    Olúwa, èmi bẹ̀ ọ́, gba ọkàn mi!”

Olúwa ní oore-ọ̀fẹ́, ó sì ní òdodo;
    Ọlọ́run wa kún fún àánú.
Olúwa pa àwọn ọlọ́kàn fífúyẹ́ mọ́
    nígbà tí mo wà nínú àìní ńlá, ó gbà mí.

Padà, ìwọ ọkàn mi, sí ibi ìsinmi rẹ,
    nítorí Olúwa ṣe dáradára sí ọ.

Nítorí ìwọ, Olúwa, ti gba ọkàn mi
    kúrò lọ́wọ́ ikú,
ojú mi kúrò lọ́wọ́ omijé,
    àti ẹsẹ̀ mi kúrò lọ́wọ́ ìṣubú,
Nítorí èmi yóò máa rìn níwájú Olúwa
    ní ilẹ̀ alààyè.

10 (A)Èmi gbàgbọ́; nítorí náà mo wí pé,
    “èmi rí ìpọ́njú púpọ̀”.
11 Àti nínú ìdààmú mi mo wí pé
    “Èké ni gbogbo ènìyàn”.

12 Kí ni èmi yóò san fún Olúwa
    nítorí gbogbo rere rẹ̀ sí mi?

13 Èmi yóò gbé ago ìgbàlà sókè
    èmi yóò sì máa ké pe orúkọ Olúwa.
14 Èmi yóò mú ìlérí mi ṣẹ sí Olúwa
    ní ojú àwọn ènìyàn rẹ̀.

15 Iyebíye ní ojú Olúwa
    àti ikú àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀.
16 Olúwa, nítòótọ́ ìránṣẹ́ rẹ ni mo jẹ́;
    èmi ni ìránṣẹ́ rẹ, ọmọ ìránṣẹ́bìnrin rẹ;
    ó ti tú mi sílẹ̀ nínú ìdè mi.

17 Èmi yóò rú ẹbọ ọpẹ́ sí ọ
    èmi yóò sì ké pe orúkọ Olúwa
18 Èmi yóò mú ìlérí mi sẹ sí Olúwa
    ní ojú gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀,
19 Nínú àgbàlá ilé Olúwa
    ní àárín rẹ̀, ìwọ Jerusalẹmu.

Ẹ yin Olúwa.
117 (B)Ẹ yin Olúwa, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè;
    ẹ pòkìkí rẹ̀, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn.
Nítorí ìfẹ́ ńlá rẹ̀ tí ó ní sí wa,
    àti òtítọ́ Olúwa dúró láéláé.

Ẹ yin Olúwa!

2 Ọba 25:8-12

Ní ọjọ́ keje ní oṣù karùn-ún, ní ọdún ìkọkàn-dínlógún ti Nebukadnessari ọba Babeli, Nebusaradani olórí ẹ̀ṣọ́, ìránṣẹ́ ọba Babeli wá sí Jerusalẹmu; ó sì finá sí ilé Olúwa, ilé ọba àti gbogbo àwọn tí ó wà ní Jerusalẹmu àti gbogbo ilé ńláńlá ni ó dáná sun. 10 Gbogbo àwọn ogun Babeli, tí ó wà lọ́dọ̀ olórí ẹ̀ṣọ́, wó ògiri tí ó yí Jerusalẹmu ká lulẹ̀. 11 Nebusaradani olórí ẹ̀ṣọ́ kó gbogbo àwọn tálákà àti gbogbo àwọn tí ó kù ní ìlú, ní ìgbèkùn lọ sí Babeli, pẹ̀lú àwọn tí ó ya lọ, tí ó sì ya tọ ọba Babeli lọ, àti ìyókù àwọn ènìyàn náà. 12 Ṣùgbọ́n olórí ẹ̀ṣọ́ fi àwọn tálákà ènìyàn ilẹ̀ náà sílẹ̀ láti máa bojútó àjàrà àti láti máa ṣe aroko.

2 Ọba 25:22-26

22 Nebukadnessari ọba Babeli ó mú Gedaliah ọmọ Ahikamu ọmọ Ṣafani, láti jẹ baálẹ̀ lórí àwọn ènìyàn tí ó kù sílẹ̀ ní ilẹ̀ Juda. 23 Nígbà tí gbogbo àwọn olórí ogun àti àwọn ọkùnrin wọn gbọ́ pé ọba Babeli ti yan Gedaliah gẹ́gẹ́ bí baálẹ̀, wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ Gedaliah ni Mispa. Iṣmaeli ọmọ Netaniah, Johanani ọmọ Karea, Seraiah ọmọ Tanhumeti ará Netofa, Jaaṣaniah ọmọ ará Maakati, àti àwọn ọkùnrin wọn. 24 Gedaliah sì búra láti fi dá àwọn ènìyàn rẹ̀ lójú. “Ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn ìjòyè ará Babeli,” ó wí pé, “Ẹ máa gbé ilẹ̀ náà kí ẹ sì sin ọba Babeli, yóò sì dára fún un yín.”

25 Ní oṣù keje, ni Iṣmaeli ọmọ Netaniah, ọmọ Eliṣama, nínú irú-ọmọ ọba, wá pẹ̀lú àwọn ọkùnrin mẹ́wàá, ó sì kọlù Gedaliah àti pẹ̀lú àwọn ọkùnrin mẹ́wàá ará Juda àti àwọn ará Babeli tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ ní Mispa. 26 Nítorí èyí, gbogbo àwọn ènìyàn láti ẹni kékeré títí dé ẹni ńlá, àti pẹ̀lú àwọn olórí ogun, sálọ si Ejibiti nítorí ẹ̀rù àwọn ará Babeli.

1 Kọrinti 15:12-29

Àjíǹde òkú

12 Ǹjẹ́ bí a bá wàásù Kristi pé ó tí jíǹde kúrò nínú òkú, èéha tí ṣe tí àwọn mìíràn nínú yín fi wí pé, àjíǹde òkú kò sí. 13 Ṣùgbọ́n bí àjíǹde òkú kò sí, ǹjẹ́ Kristi kò jíǹde. 14 (A)Bí Kristi kò bá sì jíǹde, ǹjẹ́ asán ni ìwàásù wà, asán sì ni ìgbàgbọ́ yín pẹ̀lú. 15 Ṣùgbọ́n jù bẹ́ẹ̀ lọ, a mú wa ni ẹlẹ́rìí èké fún Ọlọ́run; nítorí ti àwa jẹ́rìí Ọlọ́run pé ó jí Kristi dìde kúrò nínú òkú: ẹni tí òun kò jí dìde bí ó bá ṣe pé àwọn òkú kò jíǹde? 16 Nítorí pé bi á kò bá jí àwọn òkú dìde, ǹjẹ́ a kò jí Kristi dìde, 17 bí a kò bá sì jí Kristi dìde, asán ní ìgbàgbọ́ yín; ẹ̀yin wà nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín síbẹ̀. 18 (B)Ǹjẹ́ àwọn pẹ̀lú tí ó sùn nínú Kristi ṣègbé. 19 Bí ó bá ṣe pé kìkì ayé yìí nìkan ní àwa ní ìrètí nínú Kristi, àwa jásí òtòṣì jùlọ nínú gbogbo ènìyàn.

20 Ǹjẹ́ nísinsin yìí Kristi tí jíǹde kúrò nínú òkú, ó sì dí àkọ́bí nínú àwọn tí ó sùn. 21 (C)Nítorí ìgbà tí ó jẹ́ pé nípa ènìyàn ní ikú ti wá, nípa ènìyàn ní àjíǹde òkú sì ti wá pẹ̀lú. 22 (D)Nítorí bí gbogbo ènìyàn ti kú nínú Adamu, bẹ́ẹ̀ ní a ó sì sọ gbogbo ènìyàn dí alààyè nínú Kristi. 23 (E)Ṣùgbọ́n olúkúlùkù ènìyàn ní ipá tirẹ̀: Kristi àkọ́bí; lẹ́yìn èyí àwọn tí ó jẹ́ tí Kristi ni wíwá rẹ̀. 24 Nígbà náà ni òpin yóò dé, nígbà tí ó bá ti fi ìjọba fún Ọlọ́run Baba, nígbà tí ó bá pa gbogbo àṣẹ àti gbogbo ọlá àti agbára run. 25 (F)Nítorí ti òun gbọdọ̀ ti jẹ ọba kí òun to fi gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀. 26 Ikú ní ọ̀tá ìkẹyìn tí a ó parun 27 (G)“Nítorí ó ti fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.” Ṣùgbọ́n nígbà tí ó wí pé, “Ohun gbogbo ni á fi sí abẹ́ rẹ̀,” o dájú pé Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ní kò sí ní abẹ́ rẹ̀, Òun ní ó fi ohun gbogbo sí abẹ́ àkóso Kristi. 28 (H)Nígbà tí a bá sì fi ohun gbogbo sí abẹ́ rẹ̀ tán, nígbà náà ni á ó fi ọmọ tìkára rẹ̀ pẹ̀lú sábẹ́ Ẹni tí ó fi ohun gbogbo sí abẹ́ rẹ̀, kí Ọlọ́run lè jásí ohun gbogbo nínú ohun gbogbo.

29 Ní báyìí, bí kò bá sí àjíǹde, kín ní ète àwọn ènìyàn tí wọn ń tẹ bọ omi nítorí òkú? Bí àwọn òkú kò bá jíǹde rárá, nítorí kín ni a ṣe ń bamitiisi wọn nítorí wọn?

Matiu 11:7-15

Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu ti lọ tán, Jesu bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún ọ̀pọ̀ ènìyàn nípa ti Johanu: “Kí ni ẹ̀yin jáde lọ wò ní aginjù? Ewéko tí afẹ́fẹ́ ń mi? Bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, kí ni ẹ̀yin lọ òde lọ í wò? Ọkùnrin tí a wọ̀ ni aṣọ dáradára? Rárá àwọn ti ó wọ aṣọ dáradára wà ní ààfin ọba. Àní kí ní ẹ jáde láti lọ wò? Wòlíì? Bẹ́ẹ̀ ni, mo wí fún yín, ó sì ju wòlíì lọ.” 10 Èyí ni ẹni tí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé:

“ ‘Èmi yóò rán ìránṣẹ́ mi síwájú rẹ,
    ẹni tí yóò tún ọ̀nà rẹ ṣe níwájú rẹ.’

11 Lóòótọ́ ni mó wí fún yín, nínú àwọn tí a bí nínú obìnrin, kò sí ẹni tí ó tí í dìde tí ó ga ju Johanu onítẹ̀bọmi lọ, síbẹ̀ ẹni tí ó kéré jù ní ìjọba ọ̀run ni ó pọ̀jù ú lọ. 12 Láti ìgbà ọjọ́ Johanu onítẹ̀bọmi títí di àkókò yìí ni ìjọba ọ̀run ti di à fi agbára wọ̀, àwọn alágbára ló ń fi ipá gbà á. 13 Nítorí náà gbogbo òfin àti wòlíì ni ó sọtẹ́lẹ̀ kí Johanu kí ó tó dé. 14 Bí ẹ̀yin yóò bá gbà á, èyí ni Elijah tó ń bọ̀ wá. 15 Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.