Add parallel Print Page Options

(A)(B)Ó sì pe àwọn méjìlá náà sọ́dọ̀ rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí rán wọn lọ ní méjì méjì, Ó sì fi àṣẹ fún wọn lórí ẹ̀mí àìmọ́.

Read full chapter

16 (A)Wọ̀nyí ni àwọn méjìlá náà tí ó yàn:

Simoni (ẹni ti ó sọ àpèlé rẹ̀ ní Peteru)

17 Jakọbu ọmọ Sebede àti Johanu arákùnrin rẹ̀ (àwọn ẹni tí Jesu sọ àpèlé wọ́n ní Boanaji, èyí tí ó túmọ̀ sí àwọn ọmọ àrá).

18 Àti Anderu,

Filipi,

Bartolomeu,

Matiu,

Tomasi,

Jakọbu ọmọ Alfeu,

Taddeu,

Simoni tí ń jẹ́ Sealoti (ọ̀kan nínú àwọn ẹgbẹ́ tí o ń ja fun òmìnira àwọn Júù).

19 (B)Àti Judasi Iskariotu, ẹni tí ó fi í hàn níkẹyìn.

Read full chapter

Jesu rán ọmọ-ẹ̀yìn méjìlá lọ wàásù

(A)Ó sì pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá jọ, ó sì fún wọn ní agbára àti àṣẹ lórí àwọn ẹ̀mí èṣù gbogbo, àti láti wo ààrùn sàn.

Read full chapter

14 Simoni (ẹni tí a pè ní Peteru) àti Anderu arákùnrin rẹ̀,

Jakọbu,

Johanu,

Filipi,

Bartolomeu,

15 Matiu,

Tomasi,

Jakọbu ọmọ Alfeu,

Simoni tí a ń pè ní Sealoti,

16 Judea arákùnrin Jakọbu,

àti Judasi Iskariotu tí ó di ọ̀dàlẹ̀.

Read full chapter

13 (A)Nígbà tí wọn sì wọlé, wọn lọ sí iyàrá òkè, níbi tí wọ́n ń gbé. Àwọn tó wà níbẹ̀ ni:

Peteru, Jakọbu, Johanu àti Anderu;

Filipi àti Tomasi;

Bartolomeu àti Matiu;

Jakọbu ọmọ Alfeu, Simoni Sealoti, àti Judasi arákùnrin Jakọbu.

Read full chapter