Add parallel Print Page Options

34 (A)Bí Jesu ti ń sọ̀kalẹ̀ láti inú ọkọ̀ náà, ó bá ọ̀pọ̀ ènìyàn bí i tí àtẹ̀yìnwá, tí wọ́n ti ń dúró dè e. Ó káàánú fún wọn, nítorí wọ́n dàbí àgùntàn tí kò ní olùtọ́jú. Ó sì kọ́ wọn ni ọ̀pọ̀ nǹkan tí ó yẹ kí wọ́n mọ̀.

Read full chapter

14 Nígbà ti Jesu gúnlẹ̀, tí ó sì rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, inú rẹ̀ yọ́ sí wọn, ó sì mú àwọn aláìsàn láradá.

Read full chapter

32 (A)(B) Jesu pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ́dọ̀, ó wí pé, “Àánú àwọn ènìyàn wọ̀nyí ṣe mí; nítorí wọ́n ti wà níhìn-ín pẹ̀lú mi fún ọjọ́ mẹ́ta gbáko báyìí. Wọn kò sì tún ní oúnjẹ mọ́. Èmi kò fẹ́ kí wọn padà lébi, nítorí òyì lè kọ́ wọn lójú ọ̀nà.”

Read full chapter

17 Láti máa darí wọn, ẹni tí yóò mú wọn jáde, tí yóò sì mú wọn wọlé, gbogbo ènìyàn Olúwa kí yóò dàbí àgùntàn tí kò ní olùṣọ́.”

Read full chapter

Nítorí àwọn òrìṣà tí sọ̀rọ̀ asán,
    àwọn aláfọ̀ṣẹ sì tí rí èké,
wọn sì tí rọ àlá èké;
    wọ́n ń tu ni nínú lásán,
nítorí náà àwọn ènìyàn náà ṣáko lọ bí àgùntàn,
    a ṣẹ wọn níṣẹ̀ẹ́, nítorí Olùṣọ́-àgùntàn kò sí.

Read full chapter