Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
ÌWÉ KEJÌ
Saamu 42–72
Fún adarí orin. Maskili ti àwọn ọmọ Kora.
42 Bí àgbọ̀nrín ti ń mí hẹlẹ sí ipa odò omi,
bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mi ń mí hẹlẹ sí ọ Ọlọ́run.
2 Òùngbẹ Ọlọ́run ń gbẹ ọkàn mi, fún Ọlọ́run alààyè.
Nígbà wo ni èmi ó lọ bá Ọlọ́run?
3 Oúnjẹ mi ni omijé mi
ní ọ̀sán àti ní òru,
nígbà tí àwọn ènìyàn ń wí fún mi ní gbogbo ọjọ́ pé,
“Ọlọ́run rẹ dà?”
4 Nígbà tí mo bá rántí nǹkan yìí,
èmi tú ọkàn mi jáde nínú mi:
èmi ti bá ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn lọ,
èmi bá wọn lọ sí ilé Ọlọ́run
pẹ̀lú ohùn ayọ̀ àti ìyìn,
pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń pa ọjọ́ mímọ́ mọ́.
5 Èéṣe tí o fi ń rẹ̀wẹ̀sì, ìwọ ọkàn mi?
Èéṣe tí ara rẹ kò fi lélẹ̀ nínú mi?
Ìwọ ṣe ìrètí ní ti Ọlọ́run,
nítorí èmi yóò sá à máa yìn ín,
Olùgbàlà mi àti Ọlọ́run mi.
6 Ọlọ́run mi, ọkàn mi ń rẹ̀wẹ̀sì nínú mi:
nítorí náà, èmi ó rántí rẹ
láti ilẹ̀ Jordani wá,
láti Hermoni láti òkè Mibsari.
7 Ibú omi ń pe ibú omi
nípa híhó omi ṣíṣàn rẹ̀
gbogbo rírú omi àti bíbì omi rẹ̀
bò mí mọ́lẹ̀.
8 Ní ọ̀sán ní Olúwa ran ìfẹ́ rẹ̀,
àti ni àṣálẹ́ ni orin rẹ̀ wà pẹ̀lú mi
àdúrà sí Ọlọ́run ayé mi.
9 Èmi wí fún Ọlọ́run àpáta mi,
“Èéṣe tí ìwọ fi gbàgbé mi?
Èéṣe tí èmi o fi máa rìn nínú ìbànújẹ́,
nítorí ìnilára ọ̀tá?”
10 Bí ẹni pé idà egungun mi ni ẹ̀gàn tí
àwọn ọ̀tá mi ń gàn mí,
Bí wọn ti ń béèrè ní gbogbo ọjọ́.
“Níbo ni Ọlọ́run rẹ wà?”
11 Èéṣe tí ìwọ fi ń rẹ̀wẹ̀sì, ìwọ ọkàn mi?
Èéṣe tí ara rẹ kò fi lélẹ̀ nínú mi?
Fi ìrètí rẹ sínú Ọlọ́run,
nítorí èmi yóò sì máa yìn ín, Òun ni
Olùgbàlà mi àti Ọlọ́run mi.
43 Dá mi láre, Ọlọ́run mi,
kí o sì gba ọ̀rọ̀ mi rò lọ́dọ̀ àwọn aláìláàánú orílẹ̀-èdè:
yọ mí kúrò lọ́wọ́ ẹlẹ́tàn àti àwọn ènìyàn búburú.
2 Ìwọ ni Ọlọ́run ibi agbára mi.
Èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mi sílẹ̀?
Èéṣe tí èmi yóò máa rìn nínú ìbìnújẹ́,
nítorí ìnilára lọ́dọ̀ àwọn ọ̀tá?
3 Rán ìmọ́lẹ̀ àti òtítọ́ rẹ jáde,
jẹ́ kí wọn ó máa dáàbò bò mí;
jẹ́ kí wọn mú mi wá sí òkè mímọ́ rẹ,
sí ibi tí ìwọ ń gbé.
4 Nígbà náà ni èmi ó lọ sí ibi pẹpẹ Ọlọ́run,
sí Ọlọ́run ayọ̀ mi àti ìdùnnú mi,
èmi yóò yìn ọ́ pẹ̀lú dùùrù,
ìwọ Ọlọ́run, Ọlọ́run mi.
5 Èéṣe tí o fi ń rẹ̀wẹ̀sì, ìwọ ọkàn mí?
Èéṣe tí ó fi ń ru sókè nínú mi?
Fi ìrètí rẹ sínú Ọlọ́run,
nítorí èmi yóò máa yìn ín, Òun ni
Olùgbàlà mi àti Ọlọ́run mi.
Isaaki àti Rebeka
24 Abrahamu sì ti di arúgbó ní àkókò yìí, Olúwa sì ti bùkún fún un ni gbogbo ọ̀nà, 2 Abrahamu wí fún olórí àwọn ìránṣẹ́ ilẹ̀ rẹ̀, tí ó jẹ́ alábojútó ohun gbogbo tí ó ní pé, “Fi ọwọ́ rẹ sí abẹ́ itan mi. 3 Èmi yóò mú ọ búra lórúkọ Olúwa Ọlọ́run ọ̀run àti ayé, pé, ìwọ kì yóò fẹ́ aya fún ọmọ mi nínú àwọn ọmọbìnrin ará Kenaani, láàrín àwọn ẹni tí èmi ń gbé. 4 Ṣùgbọ́n, ìwọ yóò lọ sí orílẹ̀-èdè mi, láàrín àwọn ará mi láti fẹ́ aya fún Isaaki, ọmọ mi.”
5 Ìránṣẹ́ náà bi í wí pé, “Ǹjẹ́ bí ọmọbìnrin náà bá kọ̀ láti bá mi wá sí ilẹ̀ yìí ńkọ́? Ǹjẹ́ mo lè mú ọmọ rẹ padà lọ sí orílẹ̀-èdè níbi tí ìwọ ti wá?”
6 Abrahamu sì wí fún un pé, “Rí i dájú pé ìwọ kò mú ọmọ mi padà lọ sí ibẹ̀.” 7 “Olúwa, Ọlọ́run ọ̀run tí ó mú mi jáde láti ilẹ̀ baba mi àti ní ilẹ̀ tí a bí mi, tí ó bá mi sọ̀rọ̀ tí ó sì búra fún mi pé, ‘Irú-ọmọ rẹ ni n ó fi ilẹ̀ yìí fún,’ yóò rán angẹli rẹ̀ ṣáájú rẹ, kí ìwọ kí ó lè rí aya fẹ́ wá fún ọmọ mi láti ibẹ̀. 8 Bí obìnrin náà kò bá fẹ́ tẹ̀lé ọ wá, nígbà náà ni a tú ọ sílẹ̀ kúrò nínú ìbúra yìí, ṣùgbọ́n pàtàkì ni pé ìwọ kò gbọdọ̀ mú ọmọ mi padà lọ sí ibẹ̀.” 9 Ìránṣẹ́ náà sì fi ọwọ́ rẹ̀ sí abẹ́ itan Abrahamu olúwa rẹ̀, ó sì búra fún nítorí ọ̀rọ̀ náà.
10 Ìránṣẹ́ náà sì mú ìbákasẹ mẹ́wàá, pẹ̀lú onírúurú ohun dáradára láti ọ̀dọ̀ olúwa rẹ̀, ó sì dìde ó sì lọ sí Aramu-Naharaimu, sí ìlú Nahori, 11 Ó sì mú àwọn ìbákasẹ náà kúnlẹ̀ nítòsí kànga lẹ́yìn ìlú, ó ti ń di ọwọ́ ìrọ̀lẹ́ ní àkókò tí àwọn obìnrin máa ń lọ pọn omi.
12 Ó sì gbàdúrà wí pé, “Olúwa, Ọlọ́run Abrahamu olúwa à mi; jẹ́ kí n ṣe àṣeyọrí lónìí, sì fi àánú hàn fún Abrahamu olúwa mi. 13 Kíyèsi i, mo dúró ní ẹ̀bá kànga omi yìí, àwọn ọmọbìnrin ìlú yìí sì ń jáde wá pọn omi. 14 Jẹ́ kí ó ṣe pé nígbà tí mo bá wí fún ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin pe, ‘Jọ̀wọ́ sọ ládugbó rẹ kalẹ̀, kí n le mu omi,’ tí ó bá sì wí pé, ‘mu ún, èmi ó sì fún àwọn ìbákasẹ rẹ náà mu pẹ̀lú,’ jẹ́ kí ó ṣe èyí tí o yàn fún ìránṣẹ́ rẹ Isaaki. Nípa èyí ni n ó fi mọ̀ pé o ti fi àánú hàn fún olúwa mi.”
15 Kí o tó di pé, ó parí àdúrà, Rebeka dé pẹ̀lú ìkòkò omi rẹ̀ ní èjìká rẹ̀. Ọmọ Betueli ni. Betueli yìí ni Milka bí fún Nahori arákùnrin Abrahamu. 16 Ọmọbìnrin náà rẹwà, wúńdíá ni, kò sì tí ì mọ ọkùnrin, ó lọ sí ibi ìsun omi náà, ó sì pọn omi sínú ìkòkò omi, ó sì gbé e, ó ń gòkè bọ̀ kúrò níbi omi.
17 Ìránṣẹ́ náà súré lọ pàdé rẹ̀, ó sì wí fun un pé, “Jọ̀wọ́ fún mi ni omi díẹ̀ nínú ìkòkò omi rẹ.”
18 Òun náà dáhùn pé, “Mu, olúwa mi,” ó sì yára sọ ìkòkò omi náà ka ọwọ́ rẹ̀, ó sì fún un mu.
19 Lẹ́yìn tí ó ti fún un ni omi mu tán, ó wí pé, “Èmi ó bu omi fún àwọn ìbákasẹ rẹ pẹ̀lú títí wọn yóò fi mu àmutẹ́rùn.” 20 Ó sì yára da omi inú ìkòkò omi rẹ̀ sínú ìbùmu, ó sáré padà lọ sí ibi omi láti pọn sí i wá fún àwọn ìbákasẹ, títí tí ó fi pọn fún gbogbo wọn. 21 Láìsọ ọ̀rọ̀ kan, ìránṣẹ́ yìí ń wo ọmọbìnrin náà fínní fínní láti mọ̀ bóyá Ọlọ́run ti ṣe ìrìnàjò òun ní rere tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́.
Àwọn Júù àti òfin
17 Ṣùgbọ́n bí a bá ń pe ìwọ ní Júù, tí o sì sinmi lé òfin, tí o sì ń ṣògo nínú ìbálòpọ̀ rẹ̀ sí Ọlọ́run, 18 (A)tí o sì mọ ìfẹ́ rẹ̀, tí o sì fọwọ́sí ohun tí ó dára jùlọ, nítorí tí a ti kọ́ ọ ní òfin; 19 tí o sì dá ara rẹ lójú pé ìwọ ni amọ̀nà àwọn afọ́jú, ìmọ́lẹ̀ fún àwọn tí ó wà ni òkùnkùn, 20 (B)Olùkọ́ àwọn aláìmòye, olùkọ́ àwọn ọmọdé, ẹni tí ó ní ètò ìmọ̀ àti òtítọ́ òfin lọ́wọ́, 21 (C)Ǹjẹ́ ìwọ tí o ń kọ́ ẹlòmíràn, ìwọ kò kọ́ ara rẹ? Ìwọ tí ó ń wàásù kí ènìyàn má jalè, ìwọ ha ń jalè bí? 22 Ìwọ tí o wí pé, kí ènìyàn má ṣe panṣágà, ìwọ ń ṣe panṣágà bí? Ìwọ tí o kórìíra òrìṣà, ìwọ ń ja tẹmpili ní olè bí? 23 Ìwọ ti ń ṣògo nínú òfin, ìwọ ha ń bu Ọlọ́run ni ọlá kù nípa rírú òfin? 24 (D)Nítorí gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́, “Orúkọ Ọlọ́run sá à di ìsọ̀rọ̀-òdì sí láàrín àwọn aláìkọlà nítorí yín.”
25 (E)Nítorí ìkọlà ní èrè nítòótọ́, bí ìwọ bá pa òfin mọ́; ṣùgbọ́n bí ìwọ bá jẹ́ arúfin, ìkọlà rẹ di àìkọlà. 26 (F)Nítorí náà bí àwọn aláìkọlà bá pa ìlànà òfin mọ́, a kì yóò ha kà wọ́n sí àwọn tí a kọ nílà bí? 27 (G)Aláìkọlà nípa àdánidá, bí ó bá pa òfin mọ́, yóò dá ẹ̀bi fún ìwọ tí ó jẹ́ arúfin nípa ti àkọsílẹ̀ òfin àti ìkọlà.
28 (H)Kì í ṣe èyí tí ó farahàn ní òde ni Júù, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe èyí tí ó farahàn ní ara ni ìkọlà: 29 (I)Ṣùgbọ́n Júù ti inú ni Júù, àti ìkọlà sì ni ti ọkàn nínú ẹ̀mí tí kì í ṣe ti àkọsílẹ̀, ìyìn ẹni tí kò sí lọ́dọ̀ ènìyàn, bí kò ṣe lọ́dọ̀ Ọlọ́run.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.