Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Òwe 8:1-4

Ọgbọ́n n fi ìpè síta

(A)Ǹjẹ́ ọgbọ́n kò ha ń kígbe síta?
    Òye kò ha ń gbé ohùn rẹ sókè?
Ní ibi gíga ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà
    ní ìkóríta, ní ó dúró;
Ní ẹgbẹ́ ibodè tí ó wọ ìlú,
    ní ẹnu ibodè ni ó ń kígbe sókè:
Sí i yín ẹ̀yin ènìyàn, ní mo ń kígbe pè;
    Mo gbé ohun mi sókè sí gbogbo ènìyàn,

Òwe 8:22-31

22 “Èmi ni Olúwa kọ́kọ́ dá nínú iṣẹ́ rẹ̀.
    Ṣáájú àwọn iṣẹ́ rẹ̀ àtijọ́;
23 A ti yàn mí láti ayérayé,
    láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, kí ayé tó bẹ̀rẹ̀.
24 Nígbà tí kò tí ì sí Òkun, ni a ti bí mi
    nígbà tí kò tí ì sí ìsun tí ó ní omi nínú;
25 kí a tó fi àwọn òkè sí ipò wọn,
    ṣáájú àwọn òkè ni a ti bí mi,
26 kí ó tó dá ilẹ̀ ayé tàbí àwọn oko rẹ̀
    tàbí èyíkéyìí nínú eruku ayé.
27 Mo wà níbẹ̀ nígbà tí ó fi àwọn ọ̀run sí ipò wọn,
    nígbà tí ó fi òṣùwọ̀n àyíká sórí ibú omi,
28 Nígbà tí ó ṣẹ̀dá òfúrufú lókè
    tí ó sì fi orísun ibú omi sí ipò rẹ̀ láì le è yẹsẹ̀,
29 Nígbà tí ó ṣe ààlà fún omi Òkun
    kí omi má ba à kọjá ààlà àṣẹ rẹ̀,
    àti nígbà tí ó pààlà ìpìlẹ̀ ayé.
30 Nígbà náà èmi ni gbẹ́nàgbẹ́nà ẹ̀gbẹ́ rẹ̀
    mo kún fún inú dídùn lójoojúmọ́,
    mo ń yọ̀ nígbà gbogbo níwájú rẹ̀.
31 Mo ń yọ̀ nínú gbogbo àgbáyé tí ó dá
    mo sì ní inú dídùn sí àwọn ọmọ ènìyàn.

Saamu 8

Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti gittiti. Saamu ti Dafidi.

Olúwa, Olúwa wa,
    orúkọ rẹ̀ ti ní ìyìn tó ní gbogbo ayé!

Ìwọ ti gbé ògo rẹ ga
    ju àwọn ọ̀run lọ.
(A)Láti ẹnu ọmọ ọwọ́ àti ọmọ ọmú
    ni o ti yan ìyìn nítorí àwọn ọ̀tá rẹ,
    láti pa àwọn ọ̀tá àti àwọn olùgbẹ̀san lẹ́nu mọ́.
Nígbà tí mo ro ọ̀run rẹ,
    iṣẹ́ ìka rẹ,
òṣùpá àti ìràwọ̀,
    tí ìwọ tí gbé kalẹ̀,
kí ni ènìyàn tí ìwọ ń rò nípa rẹ̀,
    àní ọmọ ènìyàn tí ìwọ ń ṣe ìtọ́jú rẹ̀?

Ìwọ ṣe é ní onírẹ̀lẹ̀ díẹ̀ ju Ọlọ́run lọ,
    ìwọ sì dé e ní adé ògo àti ọlá.
Ìwọ mú un jẹ ọba lórí gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ;
    ìwọ sì fi ohun gbogbo sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀:
àwọn agbo àgùntàn àti àwọn màlúù,
    àti ẹranko igbó,
ẹyẹ ojú ọrun,
    àti ẹja inú Òkun,
    àti ohun tí ń wẹ nínú ipa Òkun.

Olúwa, Olúwa wa,
    Orúkọ rẹ ti ní ìyìn tó ní gbogbo ayé!

Romu 5:1-5

Àlàáfíà àti ayọ̀

(A)Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí a ti dá wa láre nípa ìgbàgbọ́, àwa ní àlàáfíà lọ́dọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ Olúwa wa Jesu Kristi. (B)Nípasẹ̀ ẹni tí àwa sì ti rí ọ̀nà gbà nípa ìgbàgbọ́ sí inú oore-ọ̀fẹ́ yìí nínú èyí tí àwa gbé dúró. Àwa sì ń yọ̀ nínú ìrètí ògo Ọlọ́run. (C)Kì í sì ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n àwa tún ń ṣògo nínú ìjìyà pẹ̀lú: bí a ti mọ̀ pé ìjìyà ń ṣiṣẹ́ sùúrù; àti pé sùúrù ń ṣiṣẹ́ ìwà rere; àti pé ìwà rere ń ṣiṣẹ́ ìrètí: (D)Ìrètí kì í sì í dójúti ni nítorí a ti dá ìfẹ́ Ọlọ́run sí wa lọ́kàn láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ tí a fi fún wa.

Johanu 16:12-15

12 “Mo ní ohun púpọ̀ láti sọ fún yín pẹ̀lú, ṣùgbọ́n ẹ kò lè gbà wọ́n nísinsin yìí. 13 Ṣùgbọ́n nígbà tí òun, àní Ẹ̀mí òtítọ́ náà bá dé, yóò tọ́ yín sí ọ̀nà òtítọ́ gbogbo; nítorí kì yóò sọ ti ara rẹ̀; ṣùgbọ́n ohunkóhun tí ó bá gbọ́, òun ni yóò máa sọ: yóò sì sọ ohun tí ń bọ̀ fún yín. 14 (A)Òun ó máa yìn mí lógo: nítorí tí yóò gbà nínú ti èmi, yóò sì máa sọ ọ́ fún yín. 15 Ohun gbogbo tí Baba ní tèmi ni: nítorí èyí ni mo ṣe wí pé, òun ó gba nínú tèmi, yóò sì sọ ọ́ fún yín.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.