Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 48

Orin. Saamu ti àwọn ọmọ Kora.

48 Ẹni ńlá ní Olúwa, tí ó sì yẹ láti máa yìn
    ní ìlú Ọlọ́run wa, lórí òkè mímọ́ rẹ̀.

(A)Ó dára nínú ipò ìtẹ́ rẹ̀,
    ayọ̀ gbogbo ayé
òkè Sioni, ní ìhà àríwá
    ní ìlú ọba ńlá.
Ọlọ́run wà nínú ààbò ààfin rẹ̀;
    ó fi ara rẹ̀ hàn láti jẹ́ odi alágbára.

Nígbà tí àwọn ọba kógun jọ pọ̀,
    wọ́n jùmọ̀ ń kọjá lọ.
Wọn rí i bẹ́ẹ̀ ni ẹnu sì yà wọ́n
    a yọ wọ́n lẹ́nu, wọ́n yára lọ
Ẹ̀rù sì bà wọ́n níbẹ̀,
    ìrora gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó wà nínú ìrọbí.
Ìwọ bà wọ́n jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọkọ̀ orí omi Tarṣiṣi,
    wọ́n fọ́nká láti ọwọ́ ìjì ìlà-oòrùn.

Gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ́,
    Bẹ́ẹ̀ ni àwa rí,
Ní inú Olúwa àwọn ọmọ-ogun
    ní ìlú Ọlọ́run wa,
    Ọlọ́run jẹ́ kí ó wà ní abẹ́ ààbò títí láéláé. Sela.

Láàrín tẹmpili rẹ, Ọlọ́run,
    àwa ti ń sọ ti ìṣeun ìfẹ́ rẹ.
10 Gẹ́gẹ́ bí orúkọ rẹ Ọlọ́run,
    ìyìn rẹ̀ dé òpin ayé,
    ọwọ́ ọ̀tún rẹ kún fún òdodo.
11 Jẹ́ kí òkè Sioni kí ó yọ̀
    kí inú àwọn ọmọbìnrin Juda kí ó dùn
    nítorí ìdájọ́ rẹ.

12 Rìn Sioni kiri lọ yíká rẹ̀,
    ka ilé ìṣọ́ rẹ̀.
13 Kíyèsi odi rẹ̀,
    kíyèsi àwọn ààfin rẹ̀
kí ẹ̀yin lè máa wí fún ìran tí ń bọ̀.

14 Nítorí Ọlọ́run yìí Ọlọ́run wà ní títí ayé,
    Òun ni yóò ṣe amọ̀nà wa títí dè òpin ayé.

Esekiẹli 11:14-25

14 Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé: 15 “Ọmọ ènìyàn, àwọn arákùnrin rẹ, àní àwọn ará rẹ, àwọn ọkùnrin nínú ìbátan rẹ, àti gbogbo ilé Israẹli pátápátá, ni àwọn ará Jerusalẹmu ti wí fún pé, ‘Ẹ jìnnà sí Olúwa, àwa ni a fi ilẹ̀ yìí fún yín ní ìní.’

Ìlérí pé Israẹli yóò padà

16 “Nítorí náà, sọ fún àwọn tó wà ní ìgbèkùn pé, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti fọ́n wọn káàkiri orílẹ̀-èdè, síbẹ̀ fún ìgbà díẹ̀, èmi yóò jẹ́ ibi mímọ́ fún wọn níbi tí wọ́n lọ.’

17 “Nítorí náà, wí pé: ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Èmi yóò kó wọn jọ kúrò láàrín àwọn orílẹ̀-èdè tí mo fọ́n wọn ká sí, Èmi yóò sì fún wọn ní ilẹ̀ Israẹli padà.’

18 “Wọn yóò padà síbẹ̀, wọn yóò sì mú gbogbo àwòrán ìríra rẹ̀ àti ìbọ̀rìṣà rẹ̀ kúrò. 19 (A)Èmi yóò fún wọn ní ọ̀kankan; èmi yóò sì fi ẹ̀mí tuntun sínú wọn; Èmi yóò mú ọkàn òkúta kúrò lára wọn, èmi yóò sì fún wọn ní ọkàn tó rọ̀ bí ara ẹran. 20 Kí wọn le tẹ̀lé àṣẹ mi, kí wọn sì le pa òfin mi mọ́. Wọ́n yóò jẹ́ ènìyàn mi, Èmi náà yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn. 21 Ṣùgbọ́n fún àwọn tí wọ́n ń fi gbogbo ọkàn wọn sin àwọn àwòrán ìríra àti àwọn òrìṣà, Èmi yóò mú ẹ̀san ohun tí wọ́n ṣe wá sí orí wọn bẹ́ẹ̀ ni Olúwa Olódùmarè wí.”

22 Àwọn kérúbù sì gbé ìyẹ́ wọn sókè pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn, ògo Ọlọ́run Israẹli sì wà lókè orí wọn. 23 Ògo Olúwa sì gòkè lọ kúrò láàrín ìlú, ó sì dúró lórí òkè tó wà ní ìlà-oòrùn ìlú náà. 24 Lẹ́yìn náà, ẹ̀mí gbé mi sókè, ó sì mú mi wá sí Kaldea lójú ìran, nípa ti ẹ̀mí Ọlọ́run sí ọ̀dọ̀ àwọn ti ìgbèkùn.

Bẹ́ẹ̀ ni ìran tí mo rí lọ kúrò ní ọ̀dọ̀ mi, 25 Mo sì sọ gbogbo ohun tí Olúwa fihàn mí fún àwọn tó wà ní ìgbèkùn.

1 Kọrinti 2:12-16

12 (A)Àwa kò gbà ẹ̀mí ti ayé yìí, bí kò ṣe Ẹ̀mí ẹni tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa, kí a lè ní òye ohun tí Ọlọ́run fi fún wa lọ́fẹ̀ẹ́. 13 (B)Èyí ni àwa ń wí, kì í ṣe èyí tí a ń kọ nípa ọ̀rọ̀ ọgbọ́n ènìyàn, ṣùgbọ́n èyí tí Ẹ̀mí Mímọ́ fi ń kọ ènìyàn, èyí tí a ń fi ohun Ẹ̀mí wé ohun Ẹ̀mí. 14 (C)Ṣùgbọ́n ènìyàn nípa ti ara kò gba ohun ti Ẹ̀mí Ọlọ́run wọ̀n-ọ́n-nì, nítorí pé wèrè ni wọ́n jásí fún un, òun kò sì le mọ̀ wọ́n, nítorí nípa tí Ẹ̀mí ní a fi ń wádìí wọn. 15 (D)Ṣùgbọ́n ẹni tí ó wà nípa ti ẹ̀mí ń wádìí ohun gbogbo, ṣùgbọ́n kò sí ẹnikẹ́ni tí í wádìí rẹ̀.

16 (E)“Nítorí ta ni ó mọ ọkàn Olúwa,
    ti yóò fi máa kọ́ Ọ?”

Ṣùgbọ́n àwa ní inú Kristi.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.