Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti gittiti. Saamu ti Dafidi.
8 Olúwa, Olúwa wa,
orúkọ rẹ̀ ti ní ìyìn tó ní gbogbo ayé!
Ìwọ ti gbé ògo rẹ ga
ju àwọn ọ̀run lọ.
2 (A)Láti ẹnu ọmọ ọwọ́ àti ọmọ ọmú
ni o ti yan ìyìn nítorí àwọn ọ̀tá rẹ,
láti pa àwọn ọ̀tá àti àwọn olùgbẹ̀san lẹ́nu mọ́.
3 Nígbà tí mo ro ọ̀run rẹ,
iṣẹ́ ìka rẹ,
òṣùpá àti ìràwọ̀,
tí ìwọ tí gbé kalẹ̀,
4 kí ni ènìyàn tí ìwọ ń rò nípa rẹ̀,
àní ọmọ ènìyàn tí ìwọ ń ṣe ìtọ́jú rẹ̀?
5 Ìwọ ṣe é ní onírẹ̀lẹ̀ díẹ̀ ju Ọlọ́run lọ,
ìwọ sì dé e ní adé ògo àti ọlá.
6 Ìwọ mú un jẹ ọba lórí gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ;
ìwọ sì fi ohun gbogbo sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀:
7 àwọn agbo àgùntàn àti àwọn màlúù,
àti ẹranko igbó,
8 ẹyẹ ojú ọrun,
àti ẹja inú Òkun,
àti ohun tí ń wẹ nínú ipa Òkun.
9 Olúwa, Olúwa wa,
Orúkọ rẹ ti ní ìyìn tó ní gbogbo ayé!
13 Ìbùkún ni fún ẹni tí ó ní ìmọ̀,
ẹni tí ó tún ní òye sí i
14 Nítorí ó ṣe èrè ju fàdákà lọ
ó sì ní èrè lórí ju wúrà lọ.
15 Ó ṣe iyebíye ju iyùn lọ;
kò sí ohunkóhun tí a lè fiwé e nínú ohun gbogbo tí ìwọ fẹ́.
16 Ẹ̀mí gígùn ń bẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀;
ní ọwọ́ òsì rẹ sì ni ọrọ̀ àti ọlá.
17 Àwọn ọ̀nà rẹ jẹ́ ọ̀nà ìtura,
òpópónà rẹ sì jẹ́ ti àlàáfíà.
18 Igi ìyè ni ó jẹ́ fún gbogbo ẹni tí ó bá gbà á;
àwọn tí ó bá sì dìímú yóò rí ìbùkún gbà.
17 Mo sì ń béèrè nígbà gbogbo pé kí Ọlọ́run Jesu Kristi Olúwa wa, Baba ògo, lè fún yín ni Ẹ̀mí nípa ti ọgbọ́n àti ti ìfihàn kí ẹ̀yin kí ó tún lè mọ̀ ọ́n sí i. 18 (A)Mo tún ń gbàdúrà bákan náà wí pé kí ojú ọkàn yín lè mọ́lẹ̀; kí ẹ̀yin lè mọ ohun tí ìrètí ìpè rẹ̀ jẹ́, àti ọrọ̀ ògo rẹ̀ èyí tí í ṣe ogún àwọn ènìyàn mímọ́, 19 àti aláìlẹ́gbẹ́ títóbi agbára rẹ̀ fún àwa tí a gbàgbọ́. Gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ agbára rẹ̀,
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.