Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 29

Saamu ti Dafidi.

29 Ẹ fi fún Olúwa, ẹ̀yin ẹ̀dá ọ̀run,
    Ẹ fi fún Olúwa, ògo àti alágbára.
Fi fún Olúwa, àní ògo orúkọ rẹ̀;
    sin Olúwa nínú ẹwà ìwà mímọ́.

Ohùn Olúwa n ré àwọn omi kọjá;
    Ọlọ́run ògo sán àrá,
    Olúwa san ara.
Ohùn Olúwa ní agbára;
    ohùn Olúwa kún fún ọláńlá.
Ohùn Olúwa fa igi kedari;
    Olúwa náà ló fọ́ igi kedari Lebanoni ya.
Ó mú Lebanoni fo bí i ọmọ màlúù,
    àti Sirioni bí ọmọ àgbáǹréré.
Ohùn Olúwa ń ya
    bí ọwọ́ iná mọ̀nà
Ohùn Olúwa ń mi aginjù.
    Olúwa mi aginjù Kadeṣi.
Ohùn Olúwa ní ó lọ igi óákù, ó n mú abo àgbọ̀nrín bí,
    ó sì bọ́ igi igbó sí ìhòhò.
Àti nínú tẹmpili rẹ̀ gbogbo ohùn wí pé “Ògo!”

10 Olúwa jókòó, Ó sì jẹ ọba lórí ìṣàn omi;
    Olúwa jókòó lórí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba títí láéláé.
11 Olúwa fi agbára fún àwọn ènìyàn rẹ̀;
    bùkún àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú àlàáfíà.

Esekiẹli 3:12-21

12 Nígbà náà ni Ẹ̀mí gbé mi sókè, mo sì gbọ́ ohùn ìró ńlá lẹ́yìn mi tó sọ pé, kí a gbé ògo Olúwa ga láti ibùgbé rẹ̀ wá! 13 Bẹ́ẹ̀ ni mo tún gbọ́ ariwo ìyẹ́ apá àti kẹ̀kẹ́ àwọn ẹ̀dá alààyè náà pẹ̀lú ariwo tó dàbí àrá ńlá. 14 Ẹ̀mí náà sì gbé mi sókè, ó sì mú mi lọ, mo lọ pẹ̀lú ọkàn kíkorò àti ìbínú nínú ẹ̀mí mi, pẹ̀lú ọwọ́ líle Olúwa ni ara mi. 15 Nígbà náà ni mo lọ sí etí odò Kebari níbi tí àwọn ìgbèkùn ń gbé ni Teli-Abibu. Níbẹ̀ níbi tí wọ́n ń gbé, mo jókòó láàrín wọn pẹ̀lú ìyanu, fún ọjọ́ méje.

Ìkìlọ̀ sí Israẹli

16 (A)Lẹ́yìn ọjọ́ méje, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: 17 “Ọmọ ènìyàn, mo ti fi ọ́ ṣe olùṣọ́ fún ilé Israẹli; nítorí náà gbọ́ ọ̀rọ̀ tí mo ń sọ, fún wọn ní ìkìlọ̀ láti ọ̀dọ̀ mi. 18 Bí mo bá sọ fún ènìyàn búburú pé, dájúdájú, ‘Ìwọ yóò kú,’ tí ìwọ kò sì kìlọ̀ fún ènìyàn búburú yìí láti dáwọ́ ìwà ibi rẹ̀ dúró, kí o sì gba ẹ̀mí rẹ̀ là, ènìyàn búburú náà yóò kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ní ọwọ́ rẹ ni èmi yóò ti béèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. 19 Ṣùgbọ́n bí o bá kìlọ̀ fún ènìyàn búburú, tí ó kọ̀ tí kò fi ìwà búburú rẹ̀ sílẹ̀, yóò kú sínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀; ṣùgbọ́n ọrùn tìrẹ ti mọ́.

20 “Bákan náà, bí olódodo kan bá yípadà, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àìṣòdodo, tí mo sì fi ohun ìkọ̀sẹ̀ sí ọ̀nà rẹ̀, yóò kú sínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Nítorí pé ìwọ kọ̀ láti kìlọ̀ fún un, yóò kú sínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, a ó gbàgbé gbogbo ìwà rere tó ti hù tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n ní ọwọ́ rẹ̀ ni èmi yóò ti béèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. 21 Ṣùgbọ́n bí o bá kìlọ̀ fún olódodo tó sì dáwọ́ ìwà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ dúró, dájúdájú òun yóò yè nítorí pé ó ti gba ìkìlọ̀, ọrùn tìrẹ sì mọ́.”

Luku 9:18-27

Peteru pe Jesu ní ọmọ Ọlọ́run

18 (A)(B) Ó sì ṣe, nígbà tí ó ku òun nìkan ó gbàdúrà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀: ó sì bi wọ́n pé, “Ta ni àwọn ènìyàn ń fi mí pè?”

19 (C)Wọ́n sì dáhùn wí pé, “Johanu Onítẹ̀bọmi; ṣùgbọ́n ẹlòmíràn ní Elijah ni; àti àwọn ẹlòmíràn wí pé, ọ̀kan nínú àwọn wòlíì àtijọ́ ni ó jíǹde.”

20 Ó sì bi wọ́n pé, “Ṣùgbọ́n ta ni ẹ̀yin ń fi èmi pè?”

Peteru sì dáhùn, wí pe, “Kristi ti Ọlọ́run.”

21 Ó sì kìlọ̀ fún wọn, pé, kí wọn má ṣe sọ èyí fún ẹnìkan. 22 (D)Ó sì wí pé, “Ọmọ ènìyàn yóò jìyà ohun púpọ̀, a ó sì kọ̀ ọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn alàgbà, olórí àlùfáà àti láti ọ̀dọ̀ àwọn akọ̀wé, a ó sì pa á, ní ọjọ́ kẹta a ó sì jí i dìde.”

23 (E)Ó sì wí fún gbogbo wọn pé, “Bí ẹnìkan bá ń fẹ́ láti máa tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ ara rẹ̀, kí ó sì gbé àgbélébùú rẹ̀ ní ọjọ́ gbogbo, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn. 24 (F)Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ gba ọkàn rẹ̀ là, yóò sọ ọ́ nù: ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ọkàn rẹ̀ nù nítorí mi, òun náà ni yóò sì gbà á là. 25 Nítorí pé èrè kín ni fún ènìyàn, bí ó jèrè gbogbo ayé, tí ó sì sọ ara rẹ̀ nù tàbí kí ó fi ṣòfò. 26 (G)Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá tijú mi, àti ọ̀rọ̀ mi, òun ni ọmọ ènìyàn yóò tijú rẹ̀ nígbà tí ó bá dé inú ògo tirẹ̀, àti ti baba rẹ̀, àti ti àwọn angẹli mímọ́.

27 (H)“Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín nítòótọ́, ẹlòmíràn dúró níhìn-ín yìí, tí kì yóò rí ikú, títí wọn ó fi rí ìjọba Ọlọ́run.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.