Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
24 Iṣẹ́ rẹ ti pọ̀ tó, Olúwa!
Nínú ọgbọ́n ni ìwọ ṣe gbogbo wọn:
ayé kún fún àwọn ìṣẹ̀dá á rẹ.
25 Bẹ́ẹ̀ ni Òkun yìí tí ó tóbi, tí ó sì ni ìbú,
tí ó kún fún àwọn ẹ̀dá alààyè ní ìsàlẹ̀ láìníye
ohun alààyè tí tóbi àti kékeré.
26 Níbẹ̀ ni ọkọ̀ ń lọ síwá sẹ́yìn,
àti Lefitani, tí ìwọ dá láti ṣe àríyá nínú rẹ̀.
27 Àwọn wọ̀nyí ń wò ọ́
láti fún wọn ní oúnjẹ wọn lákòókò rẹ̀.
28 Nígbà tí ìwọ bá fi fún wọn,
wọn yóò kó jọ;
nígbà tí ìwọ bá la ọwọ́ rẹ̀,
a tẹ́ wọn lọ́rùn pẹ̀lú ohun rere.
29 Nígbà tí ìwọ bá pa ojú rẹ mọ́
ara kò rọ̀ wọ́n
nígbà tí ìwọ bá mú ẹ̀mí wọn lọ,
wọn ó kú, wọn ó sì padà sí erùpẹ̀.
30 Nígbà tí ìwọ rán ẹ̀mí rẹ,
ni a dá wọn,
ìwọ sì tún ojú ayé ṣe.
31 Jẹ́ kí ògo Olúwa wà pẹ́ títí láé;
kí inú Olúwa kí ó dùn ní ti iṣẹ́ rẹ̀
32 Ẹni tí ó wo ayé, tí ó sì wárìrì,
ẹni tí ó fọwọ́ tọ́ àwọn òkè, tí wọ́n yọ èéfín.
33 Ní gbogbo ayé mi ní n ó kọrin sí Olúwa:
èmi ó kọrin ìyìn sí Olúwa
níwọ̀n ìgbà tí mo wà láààyè.
34 Jẹ́ kí ẹ̀kọ́ mi kí ó tẹ́ ọ lọ́rùn
bí mo ti ń yọ̀ nínú Olúwa.
35 Ṣùgbọ́n kí ẹlẹ́ṣẹ̀ kúrò láyé
kí ènìyàn búburú má sì sí mọ́.
Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi.
Yin Olúwa.
11 Wárìrì, ẹ̀yin obìnrin onítẹ̀lọ́rùn
bẹ̀rù, ẹ̀yin ọ̀dọ́mọbìnrin tí ẹ rò pé ọkàn yín balẹ̀!
Ẹ bọ́ aṣọ yín kúrò,
ẹ ró aṣọ ọ̀fọ̀ mọ́ ẹ̀gbẹ́ yín.
12 Ẹ lu ọmú yín fún pápá ìgbádùn náà,
fún àwọn àjàrà eléso
13 àti fún ilẹ̀ àwọn ènìyàn mi
ilẹ̀ tí ó ti kún fún ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n—
bẹ́ẹ̀ ni, kẹ́dùn fún gbogbo ilé ìtura
àti fún ìlú àríyá yìí.
14 Ilé olódi ni a ó kọ̀sílẹ̀,
ìlù aláriwo ni a ó kọ̀ tì;
ilé olódi àti ilé ìṣọ́ ni yóò di ihò títí láéláé,
ìdùnnú àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti pápá
oko fún àwọn ẹran ọ̀sìn,
15 títí a ó fi tú Ẹ̀mí sí wa lórí láti òkè wá,
àti ti aṣálẹ̀ tí yóò dí pápá oko ọlọ́ràá
àti tí pápá ọlọ́ràá yóò dàbí ẹgàn.
16 Ẹ̀tọ́ yóò máa gbé ní inú aṣálẹ̀
àti òdodo yóò sì máa gbé ní pápá oko ọlọ́ràá.
17 Èso òdodo náà yóò sì jẹ́ àlàáfíà;
àbájáde òdodo yóò sì jẹ́ ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé títí láé.
Ìyè nípa ti ẹ̀mí
16 Ǹjẹ́ mo ní, Ẹ máa rìn nípa ti Ẹ̀mí, ẹ̀yin kì yóò sì mú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara ṣẹ. 17 (A)Nítorí ti ara ń ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ lòdì sí Ẹ̀mí, àti Ẹ̀mí lòdì sí ara: àwọn wọ̀nyí sì lòdì sí ara wọn; kí ẹ má ba à lè ṣe ohun tí ẹ̀yin ń fẹ́. 18 Ṣùgbọ́n bí a bá ń ti ọwọ́ Ẹ̀mí ṣamọ̀nà yín, ẹ̀yin kò sí lábẹ́ òfin.
19 (B)Ǹjẹ́ àwọn iṣẹ́ tí ara farahàn, tí í ṣe wọ̀nyí; panṣágà, àgbèrè, ìwà èérí, wọ̀bìà, 20 Ìbọ̀rìṣà, oṣó, ìkórìíra, ìjà, ìlara, ìbínú, ìmọtaraẹni nìkan, ìyapa, ẹ̀kọ́ òdì. 21 Àrankàn, ìpànìyàn, ìmutípara, ìréde òru, àti irú ìwọ̀nyí; àwọn ohun tí mo ń wí fún yín tẹ́lẹ̀, gẹ́gẹ́ bí mo ti wí fún yín tẹ́lẹ̀ rí pé, àwọn tí ń ṣe nǹkan báwọ̀nyí kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.
22 Ṣùgbọ́n èso ti Ẹ̀mí ni ìfẹ́, ayọ̀, àlàáfíà, ìpamọ́ra, ìwà pẹ̀lẹ́, ìṣoore, ìgbàgbọ́, 23 ìwà tútù, àti ìkóra-ẹni níjanu: òfin kan kò lòdì sí irú wọ̀nyí, 24 Àwọn tí í ṣe ti Kristi Jesu ti kan ara wọn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú ìfẹ́ àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀. 25 Bí àwa bá wà láààyè sípa ti Ẹ̀mí, ẹ jẹ́ kí a sì máa rìn nípa ti Ẹ̀mí.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.