Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 48

Orin. Saamu ti àwọn ọmọ Kora.

48 Ẹni ńlá ní Olúwa, tí ó sì yẹ láti máa yìn
    ní ìlú Ọlọ́run wa, lórí òkè mímọ́ rẹ̀.

(A)Ó dára nínú ipò ìtẹ́ rẹ̀,
    ayọ̀ gbogbo ayé
òkè Sioni, ní ìhà àríwá
    ní ìlú ọba ńlá.
Ọlọ́run wà nínú ààbò ààfin rẹ̀;
    ó fi ara rẹ̀ hàn láti jẹ́ odi alágbára.

Nígbà tí àwọn ọba kógun jọ pọ̀,
    wọ́n jùmọ̀ ń kọjá lọ.
Wọn rí i bẹ́ẹ̀ ni ẹnu sì yà wọ́n
    a yọ wọ́n lẹ́nu, wọ́n yára lọ
Ẹ̀rù sì bà wọ́n níbẹ̀,
    ìrora gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó wà nínú ìrọbí.
Ìwọ bà wọ́n jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọkọ̀ orí omi Tarṣiṣi,
    wọ́n fọ́nká láti ọwọ́ ìjì ìlà-oòrùn.

Gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ́,
    Bẹ́ẹ̀ ni àwa rí,
Ní inú Olúwa àwọn ọmọ-ogun
    ní ìlú Ọlọ́run wa,
    Ọlọ́run jẹ́ kí ó wà ní abẹ́ ààbò títí láéláé. Sela.

Láàrín tẹmpili rẹ, Ọlọ́run,
    àwa ti ń sọ ti ìṣeun ìfẹ́ rẹ.
10 Gẹ́gẹ́ bí orúkọ rẹ Ọlọ́run,
    ìyìn rẹ̀ dé òpin ayé,
    ọwọ́ ọ̀tún rẹ kún fún òdodo.
11 Jẹ́ kí òkè Sioni kí ó yọ̀
    kí inú àwọn ọmọbìnrin Juda kí ó dùn
    nítorí ìdájọ́ rẹ.

12 Rìn Sioni kiri lọ yíká rẹ̀,
    ka ilé ìṣọ́ rẹ̀.
13 Kíyèsi odi rẹ̀,
    kíyèsi àwọn ààfin rẹ̀
kí ẹ̀yin lè máa wí fún ìran tí ń bọ̀.

14 Nítorí Ọlọ́run yìí Ọlọ́run wà ní títí ayé,
    Òun ni yóò ṣe amọ̀nà wa títí dè òpin ayé.

Numeri 24:1-14

24 Nísinsin yìí nígbà tí Balaamu rí i wí pé ó tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn láti bùkún àwọn Israẹli, kò lo ọ̀nà ìṣoṣó gẹ́gẹ́ bí ti ìgbà ìṣáájú, ṣùgbọ́n ó yí ojú rẹ̀ sí apá aginjù. Nígbà tí Balaamu wo ìta ó sì rí Israẹli tí wọ́n pàgọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn, Ẹ̀mí Ọlọ́run sì bà sórí rẹ̀ ó sì bẹ̀rẹ̀ òwe rẹ̀:

“Ó wí pé Balaamu ọmọ Beori,
    òwe ẹni tí ojú rẹ̀ mọ́lẹ̀,
Òwe ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,
    ẹni tí ó ríran láti ọ̀dọ̀ Olódùmarè,
    ẹni tí ó dojúbolẹ̀, tí ojú rẹ̀ sì là:

“Àgọ́ rẹ ti dára tó, ìwọ Jakọbu,
    àti ibùgbé rẹ, ìwọ Israẹli!

“Gẹ́gẹ́ bí Àfonífojì tí ó tàn jáde,
    gẹ́gẹ́ bí ọgbà tí ó wà ní ẹ̀bá odò ńlá,
gẹ́gẹ́ bí igi aloe tí Olúwa gbìn,
    gẹ́gẹ́ bí igi kedari tí ó wà lẹ́bàá odò.
Omi yóò sàn láti inú garawa:
    èso wọn yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi.

“Ọba wọn yóò ga ju Agagi lọ;
    ìjọba wọn yóò di gbígbéga.

“Ọlọ́run mú wọn jáde láti Ejibiti wá;
    wọ́n ní agbára gẹ́gẹ́ bí i ti àgbáǹréré.
Wọ́n jẹ orílẹ̀-èdè tí ń ṣe ọ̀tá rẹ̀ run,
    wọ́n sì fọ́ egungun wọn sí túútúú;
    wọ́n ó sì fi ọfà wọn ta wọ́n ní àtapòyọ.
(A)Ó tẹríba ó sì dùbúlẹ̀ bí kìnnìún,
    bí abo kìnnìún: ta ni ó gbọdọ̀ jí wọn?

“Ìbùkún ni fún ẹni tí ó bùkún fún ọ,
    kí ìfibú jẹ́ ti ẹni tí ó fi ọ́ bú!”

10 Nígbà náà ni ìbínú Balaki sì dé sí Balaamu. Ó sì fi ọwọ́ lu ọwọ́ ó wí pé, “Mo pè ọ́ láti bú àwọn ọ̀tá mi ṣùgbọ́n o tún bùkún fún wọn nígbà mẹ́ta yìí. 11 Nísinsin yìí sálọ sí ibùjókòó rẹ! Èmi ti rò láti sọ ọ́ di ẹni ńlá, ṣùgbọ́n Olúwa tí fà ọ́ sẹ́yìn láti gba èrè yìí.”

12 Balaamu dá Balaki lóhùn, “Ǹjẹ́ èmi kò sọ fún àwọn ìránṣẹ́ tí o rán sí mi wí pé, 13 ‘Kódà bí Balaki bá fún mi ní ààfin rẹ̀ tí ó kún fún fàdákà àti wúrà, èmi kò le ṣe ohunkóhun lọ́wọ́ ara mi, yálà búburú tàbí rere, láti kọjá òfin Olúwa: ohun tí Olúwa bá wí ni èmi ó sọ’? 14 Nísinsin yìí mò ń padà lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn mi, ṣùgbọ́n jẹ́ kí èmi kí ó kìlọ̀ fún ọ nítorí nǹkan tí àwọn ènìyàn wọ̀nyí yóò ṣe sí àwọn ènìyàn rẹ ní ọjọ́ iwájú.”

Luku 1:26-38

Ìsọtẹ́lẹ̀ ibi Jesu

26 Ní oṣù kẹfà Ọlọ́run sì rán angẹli Gabrieli sí ìlú kan ní Galili, tí à ń pè ní Nasareti, 27 sí wúńdíá kan tí a ṣèlérí láti fẹ́ fún ọkùnrin kan, tí a ń pè ní Josẹfu, ti ìdílé Dafidi; orúkọ wúńdíá náà a sì máa jẹ́ Maria. 28 Angẹli náà sì tọ̀ ọ́ wá, ó ní, “Àlàáfíà fun ọ, ìwọ ẹni tí a kọjú sí ṣe ní oore, Olúwa ń bẹ pẹ̀lú rẹ.”

29 Ṣùgbọ́n ọkàn Maria kò lélẹ̀ nítorí ọ̀rọ̀ náà, ó sì rò nínú ara rẹ̀ pé, irú kíkí kín ni èyí. 30 (A)Ṣùgbọ́n angẹli náà wí fún un pé, “Má bẹ̀rù, Maria: nítorí ìwọ ti rí ojúrere lọ́dọ̀ Ọlọ́run. 31 (B)Ìwọ yóò lóyún nínú rẹ, ìwọ ó sì bí ọmọkùnrin kan, ìwọ ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jesu. 32 Òun ó pọ̀, Ọmọ Ọ̀gá-ògo jùlọ ni a ó sì máa pè é: Olúwa Ọlọ́run yóò sì fi ìtẹ́ Dafidi baba rẹ̀ fún: 33 (C)Yóò sì jẹ ọba lórí ilé Jakọbu títí láé; ìjọba rẹ̀ kì yóò sì ní ìpẹ̀kun.”

34 (D)Nígbà náà ni Maria béèrè lọ́wọ́ angẹli náà pé, “Èyí yóò ha ti ṣe rí bẹ́ẹ̀, nígbà tí èmi kò tí ì mọ ọkùnrin.”

35 (E)Angẹli náà sì dáhùn ó sì wí fún un pé, “Ẹ̀mí Mímọ́ yóò tọ̀ ọ́ wá, agbára Ọ̀gá-ògo jùlọ yóò ṣíji bò ọ́. Nítorí náà ohun mímọ́ tí a ó ti inú rẹ bí, Ọmọ Ọlọ́run ni a ó máa pè é. 36 Sì kíyèsi i, Elisabeti ìbátan rẹ náà yóò sì ní ọmọkùnrin kan ní ògbólógbòó rẹ̀. Èyí sì ni oṣù kẹfà fún ẹni tí à ń pè ní àgàn. 37 (F)Nítorí kò sí ohun tí Ọlọ́run kò le ṣe.”

38 Maria sì dáhùn wí pé, “Wò ó ọmọ ọ̀dọ̀ Olúwa; kí ó rí fún mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.” Angẹli náà sì fi í sílẹ̀ lọ.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.