Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Saamu. Orin. Fún ìyàsímímọ́ Tẹmpili. Ti Dafidi.
30 Èmi yóò kókìkí i rẹ, Olúwa,
nítorí ìwọ ni ó gbé mi lékè
tí ìwọ kò sì jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi kí ó yọ̀ mí.
2 Olúwa Ọlọ́run mi, èmi ké pè ọ́, fún ìrànlọ́wọ́
ìwọ sì ti wò mí sàn.
3 Olúwa, ìwọ ti yọ ọkàn mi jáde kúrò nínú isà òkú,
mú mi padà bọ̀ sípò alààyè kí èmi má ba à lọ sínú ihò.
4 Kọ orin ìyìn sí Olúwa, ẹ̀yin olódodo;
kí ẹ sì fi ọpẹ́ fún orúkọ rẹ̀ mímọ́.
5 Nítorí pé ìbínú rẹ̀ wà fún ìgbà díẹ̀,
ojúrere rẹ̀ wà títí ayérayé;
Ẹkún lè pẹ́ títí di alẹ́,
Ṣùgbọ́n ayọ̀ yóò wá ní òwúrọ̀.
6 Ní ìgbà ayé mi, mo wí pé,
“a kì yóò ṣí mi ní ipò padà.”
7 Nípa ojúrere rẹ, Olúwa,
ìwọ ti gbé mi kalẹ̀ bí òkè tí ó ní agbára;
ìwọ pa ojú rẹ mọ́,
àyà sì fò mí.
8 Sí ọ Olúwa, ni mo ké pè é;
àti sí Olúwa ni mo sọkún fún àánú:
9 “Èrè kí ni ó wà nínú ikú ìparun mi,
nínú lílọ sí ihò mi?
Eruku yóò a yìn ọ́ bí?
Ǹjẹ́ yóò sọ nípa òdodo rẹ?
10 Gbọ́, Olúwa, kí o sì ṣàánú fún mi;
ìwọ Olúwa, jẹ́ olùrànlọ́wọ́ mi.”
11 Ìwọ ti yí ìkáàánú mi di ijó fún mi;
ìwọ sì ti bọ́ aṣọ ọ̀fọ̀ mi, o sì fi aṣọ ayọ̀ wọ̀ mí,
12 nítorí ìdí èyí ni kí ọkàn mi máa yìn ọ́, kí o má sì ṣe dákẹ́.
Ìwọ Olúwa Ọlọ́run mi, èmi yóò máa fi ọpẹ́ fún ọ títí láé.
11 Ègbé ni fún àwọn tí wọ́n dìde
ní kùtùkùtù òwúrọ̀
láti lépa ọtí líle,
tí wọ́n sì mu ún títí alẹ́ fi lẹ́
títí wọ́n fi gbinájẹ pẹ̀lú wáìnì.
12 Wọ́n ní dùùrù àti ohun èlò orin olókùn níbi àsè wọn,
ṣaworo òun fèrè àti wáìnì,
ṣùgbọ́n wọn kò ka iṣẹ́ Olúwa sí,
wọn kò sí bọ̀wọ̀ fún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.
13 Nítorí náà àwọn ènìyàn mi yóò
lọ sí ìgbèkùn
nítorí òye kò sí fún wọn,
ebi ni yóò pa àwọn ọlọ́lá wọn kú;
ẹgbàágbèje wọn ni òǹgbẹ
yóò sì gbẹ.
14 Nítorí náà isà òkú ti ń dátọ́mì gidigidi,
ó sì ti ya ẹnu rẹ̀ sílẹ̀ gbagada,
nínú rẹ̀ ni àwọn gbajúmọ̀ àti mẹ̀kúnnù yóò sọ̀kalẹ̀ sí
pẹ̀lú ọlá àti ògo wọn.
15 Báyìí, ènìyàn yóò di ìrẹ̀sílẹ̀
àti ọmọ ènìyàn ni a sọ di onírẹ̀lẹ̀
ojú agbéraga ni a sì rẹ̀ sílẹ̀.
16 Ṣùgbọ́n Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni a ó gbéga nípa ẹ̀tọ́ rẹ̀,
Ọlọ́run ẹni mímọ́ yóò sì fi ara rẹ̀ hàn ní mímọ́ nípa òdodo rẹ̀.
17 Nígbà náà ni àwọn àgùntàn yóò máa jẹ́ ko ní ibùgbé e wọn,
àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn yóò máa jẹ nínú ahoro àwọn ọlọ́rọ̀.
Sí ìjọ Laodikea
14 (A)“Àti sí angẹli ìjọ ní Laodikea kọ̀wé:
Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni ẹni tí ń jẹ́ Àmín wí, ẹlẹ́rìí olódodo àti olóòtítọ́, olórí ìṣẹ̀dá Ọlọ́run:
15 Èmi mọ̀ iṣẹ́ rẹ, pé ìwọ kò gbóná bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò tútù: èmi ìbá fẹ́ pé kí ìwọ kúkú tutù, tàbí kí ìwọ kúkú gbóná. 16 Ǹjẹ́ nítorí tí ìwọ lọ wọ́ọ́rọ́, tí o kò si gbóná, bẹ́ẹ̀ ni tí o kò tutù, èmi yóò pọ̀ ọ́ jáde kúrò ni ẹnu mi. 17 (B)Nítorí tí ìwọ wí pé, Èmi ní ọrọ̀, èmi sì ń pọ̀ sí i ni ọrọ̀, èmi kò sì ṣe aláìní ohunkóhun; tí ìwọ kò sì mọ̀ pé, òsì ni ìwọ, ẹni-ìkáàánú, tálákà, afọ́jú, àti ẹni ìhòhò: 18 Èmi fún ọ ni ìmọ̀ràn pé kí o ra wúrà lọ́wọ́ mi tí a ti dà nínú iná, kí ìwọ lè di ọlọ́rọ̀; àti aṣọ funfun, kí ìwọ lè fi wọ ara rẹ̀, àti kí ìtìjú ìhòhò rẹ̀ má ba hàn kí ìwọ sì fi ohun ìkunra kun ojú rẹ̀, kí ìwọ lè ríran.
19 (C)Gbogbo àwọn ti èmi bá fẹ́ ni èmi ń bá wí, tí mo sì ń nà: nítorí náà, ní ìtara, kì ìwọ sì ronúpìwàdà. 20 Kíyèsi i, èmi dúró ni ẹnu ìlẹ̀kùn, èmi sì ń kànkùn, bí ẹnikẹ́ni bá gbọ́ ohun mi, tí ó sì ṣí ìlẹ̀kùn, èmi yóò sì wọlé tọ̀ ọ́ wá, èmi yóò sì máa bá a jẹun, àti òun pẹ̀lú mi.
21 Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun ni èmi yóò fi fún láti jókòó pẹ̀lú mi lórí ìtẹ́ mi, bí èmi pẹ̀lú ti ṣẹ́gun, tí mo sì jókòó pẹ̀lú Baba mi lórí ìtẹ́ rẹ̀. 22 Ẹni tí ó bá létí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.