Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 23

Saamu ti Dafidi.

23 Olúwa ni Olùṣọ́ èmi àgùntàn rẹ̀, èmi kì yóò ṣe aláìní.
    (A)Ó mú mi dùbúlẹ̀ sí ibi pápá oko tútù
Ó mú mi lọ sí ibi omi dídákẹ́ rọ́rọ́;
    Ó mú ọkàn mi padà bọ̀ sípò
Ó mú mi lọ sí ọ̀nà òdodo
    nítorí orúkọ rẹ̀.
Bí mo tilẹ̀ ń rìn
    Láàrín àfonífojì òjìji ikú,
èmi kì yóò bẹ̀rù ibi kan;
    nítorí ìwọ wà pẹ̀lú mi;
ọ̀gọ rẹ àti ọ̀pá à rẹ
    wọ́n ń tù mí nínú.

Ìwọ tẹ́ tábìlì oúnjẹ sílẹ̀ níwájú mi
    ní ojú àwọn ọ̀tá à mi;
ìwọ ta òróró sí mi ní orí;
    ago mí sì kún àkúnwọ́sílẹ̀.
Nítòótọ́, ìre àti àánú ni yóò máa tọ̀ mí lẹ́yìn
    ní ọjọ́ ayé è mi gbogbo,
èmi yóò sì máa gbé inú ilé Olúwa
    títí láéláé.

Esekiẹli 20:39-44

39 “ ‘Ní tí ẹ̀yin, ilé Israẹli, èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Kí olúkúlùkù yín lọ máa sìn òrìṣà rẹ̀, ṣùgbọ́n lẹ́yìn èyí, ẹ̀yin yóò gbọ́ tèmi, ẹ̀yin kò sí ní i bá orúkọ mímọ́ mi jẹ́ pẹ̀lú ọrẹ àti àwọn òrìṣà yín mọ́. 40 Nítorí lórí òkè mímọ́ mi, lórí òkè gíga Israẹli, ni Olúwa Olódùmarè wí, níbẹ̀ ni ilẹ̀ náà ní gbogbo ilé Israẹli yóò sìn mí; èmi yóò sì tẹ́wọ́ gba wọ́n níbẹ̀. Níbẹ̀ èmi yóò béèrè ọrẹ àti ẹ̀bùn nínú àkọ́so yín pẹ̀lú gbogbo ẹbọ mímọ́ yín 41 Èmi yóò tẹ́wọ́ gbà yín gẹ́gẹ́ bí tùràrí olóòórùn dídùn nígbà tí mo ba mú yín jáde láàrín àwọn orílẹ̀-èdè tí a fọ́n yín ká sí, èmi yóò sì fi ìwà mímọ́ mi hàn láàrín yín lójú àwọn orílẹ̀-èdè. 42 Nígbà náà ni ẹ o mọ̀ pé èmi ní Olúwa, nígbà tí mo bá mú yín wa sí ilẹ̀ Israẹli; sí ilẹ̀ tí mo gbọ́wọ́ mí sókè nínú ẹ̀jẹ́ láti fún àwọn baba yín. 43 (A)Níbẹ̀ ni ẹ ó wa rántí ìwà àti gbogbo ìṣesí yín, èyí tí ẹ̀yin fi sọ ara yín di aláìmọ́, ẹ̀yin yóò sì kórìíra ara yín fún gbogbo ibi tí ẹ̀yin ti ṣe. 44 Nígbà náà ní ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa, nígbà tí mo bá hùwà sí yín nítorí orúkọ mi ni, tí ń kò hùwà sí yín gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ibi àti ìwà ìríra yín. Ẹ̀yin Ilé Israẹli, ni Olúwa Olódùmarè wí.’ ”

Ìfihàn 6:1-7:4

Ṣí àwọn èdìdì ìwé náà

Èmi sì rí i nígbà tí Ọ̀dọ́-àgùntàn náà ṣí ọkàn nínú èdìdì wọ̀nyí, mo sì gbọ́ ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà ń wí bí sísán àrá pé, “Wá, wò ó!” (A)Mo sì wò ó, kíyèsi i, ẹṣin funfun kan: ẹni tí ó sì jókòó lórí i rẹ̀ ní ọfà kan; a sì fi adé kan fún un: ó sì jáde lọ láti ìṣẹ́gun dé ìṣẹ́gun.

Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì kejì, mo gbọ́ ohùn ẹ̀dá alààyè wí pé, “Wá, wò ó!” Ẹṣin mìíràn tí ó pupa sì jáde: a sì fi agbára fún ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀, láti gba àlàáfíà kúrò lórí ilẹ̀ ayé, àti pé kí wọn kí ó máa pa ara wọn: A sì fi idà ńlá kan lé e lọ́wọ́.

Nígbà tí ó sì di èdìdì kẹta, mo gbọ́ ohùn ẹ̀dá alààyè kẹta wí pé, “Wá wò ó”. Mo sì wò ó, sì kíyèsi i, ẹṣin dúdú kan; ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ ní ìwọ̀n aláwẹ́ méjì ní ọwọ́ rẹ̀. (B)Mo sì gbọ́ bí ẹni pé ohùn kan ní àárín àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rẹ̀ẹ̀rin nì ti ń wí pé, òṣùwọ̀n alikama kan fún owó idẹ kan, àti òṣùwọ̀n ọkà barle mẹ́ta fún owó idẹ kan, sì kíyèsi i, kí ó má sì ṣe pa òróró àti ọtí wáìnì lára.

Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì kẹrin, mo gbọ́ ohùn ẹ̀dá alààyè kan wí pé, Wá wò ó. (C)Mo sì wò ó, kíyèsi, ẹṣin ràndànràndàn kan: orúkọ ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ ni ikú, àti ipò òkú sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. A sì fi agbára fún wọn lórí ìdámẹ́rin ayé, láti fi idà, àti ebi, àti ikú, àti ẹranko lu orí ilẹ̀ ayé pa.

Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì karùn-ún, mo rí lábẹ́ pẹpẹ, ọkàn àwọn tí a ti pa nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àti nítorí ẹ̀rí tí wọ́n dìímú: 10 (D)Wọ́n kígbe ní ohùn rara, wí pé, “Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa Olódùmarè, ẹni mímọ́ àti olóòtítọ́ ìwọ kì yóò ṣe ìdájọ́ kí o sì gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ wa mọ́ lára àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé?” 11 A sì fi aṣọ funfun fún gbogbo wọn; a sì wí fún wọn pé, kí wọn kí ó sinmi fún ìgbà díẹ̀ ná, títí iye àwọn ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wọn àti arákùnrin wọn tí a o pa bí wọn, yóò fi dé.

12 (E)Nígbà tí ó sì ṣí èdìdì kẹfà mo sì rí i, sì kíyèsi i, ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá kan ṣẹ̀; oòrùn sì dúdú bí aṣọ ọ̀fọ̀ onírun, òṣùpá sì dàbí ẹ̀jẹ̀; 13 (F)àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run sì ṣubú sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí igi ọ̀pọ̀tọ́ tí ń rẹ̀ àìgbó èso rẹ̀ dànù, nígbà tí ẹ̀fúùfù ńlá bá mì í. 14 A sì ká ọ̀run kúrò bí ìwé tí a ká, àti olúkúlùkù òkè àti erékùṣù ní a sì ṣí kúrò ní ipò wọn.

15 (G)Àwọn ọba ayé àti àwọn ọlọ́lá àti àwọn olórí ogun, àti àwọn ọlọ́rọ̀ àti àwọn alágbára, àti olúkúlùkù ẹrú, àti olúkúlùkù òmìnira, sì fi ara wọn pamọ́ nínú ihò ilẹ̀, àti nínú àpáta orí òkè; 16 (H)Wọ́n sì ń wí fún àwọn òkè àti àwọn àpáta náà pé, “Ẹ wó lù wá, kí ẹ sì fi wá pamọ́ kúrò lójú ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́, àti kúrò nínú ìbínú Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà: 17 (I)Nítorí ọjọ́ ńlá ìbínú wọn dé; ta ni sì le dúró?”

Ọ̀kẹ́ méje-olé-ẹgbàá-méjì èdìdì ìwé

(J)Lẹ́yìn èyí ni mo rí angẹli mẹ́rin dúró ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé, wọ́n di afẹ́fẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé mú, kí ó má ṣe fẹ́ sórí ilẹ̀, tàbí sórí Òkun, tàbí sára igikígi. Mo sì rí angẹli mìíràn tí ó ń ti ìhà ìlà-oòrùn gòkè wá, ti òun ti èdìdì Ọlọ́run alààyè lọ́wọ́ rẹ. Ó sì kígbe ní ohùn rara sí àwọn angẹli mẹ́rin náà tí a fi fún un láti pa ayé, àti Òkun, lára, (K)wí pé, “Ẹ má ṣe pa ayé, tàbí Òkun, tàbí igi lára, títí àwa ó fi fi èdìdì sàmì sí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run wa ní iwájú wọn.” Mo sì gbọ́ iye àwọn tí a fi èdìdì sàmì si: Àwọn tí a sàmì sí jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó-lé-ẹgbàajì láti inú gbogbo ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli wá.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.