Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
93 Olúwa ń jẹ ọba, ọláńlá ni ó wọ̀ ní aṣọ;
ọláńlá ni Olúwa wọ̀ ní aṣọ
àti ìhámọ́ra rẹ̀ pẹ̀lú agbára.
Ó fi ìdí ayé múlẹ̀;
kò sì le è yí.
2 Ìjọba rẹ̀ wà láti ọjọ́ pípẹ́;
ìwọ wà títí ayérayé.
3 A ti gbé Òkun sókè, Olúwa,
Òkun ti gbé ohùn wọn sókè;
Òkun ti gbé rírú omi wọn sókè.
4 Ó ni ògo ju àrá omi ńlá lọ,
ó ni ògo ju Òkun rírú lọ
Olúwa ga ní ògo.
5 Ẹ̀rí rẹ̀ dúró ṣinṣin;
ìwà mímọ́ ni ó fi ṣe ilé rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́
fún ọjọ́ àìlópin, Olúwa.
16 Ìyókù ará Benjamini àti àwọn díẹ̀ ọkùnrin láti Juda lọ sí ọ̀dọ̀ Dafidi ní ibi gíga. 17 Dafidi sì lọ láti lọ pàdé wọn ó sì wí fún wọn pé, “Tí ẹ bá wá sọ́dọ̀ mi lálàáfíà, láti ràn mí lọ́wọ́ mo ṣetán láti mú un yín wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi ṣùgbọ́n tí ẹ bá wá láti dá mi sí fún àwọn ọ̀tá mi nígbà tí ọwọ́ mi bá mọ́ kúrò nínú ìwà agbára, kí Ọlọ́run àwọn baba wa kí ó sì ri kí ó sì ṣe ìdájọ́.”
18 Nígbà náà Ẹ̀mí Mímọ́ wa sórí Amasai ìjòyè àwọn ọgbọ̀n, ó sì wí pé:
“Tìrẹ ni àwa ń ṣe, ìwọ Dafidi!
Àwa pẹ̀lú rẹ, ìwọ ọmọ Jese!
Àlàáfíà, àlàáfíà fún ọ,
àti àlàáfíà fún àwọn tí ó ràn ó lọ́wọ́,
nítorí Ọlọ́run rẹ̀ yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.”
Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi sì gbà wọ́n ó sì mú wọn jẹ olórí ẹgbẹ́ ogun.
19 Díẹ̀ nínú àwọn ọkùnrin Manase sì yà sí ọ̀dọ̀ Dafidi nígbà tí ó lọ pẹ̀lú àwọn ará Filistini láti bá Saulu jà. (Òun àti àwọn ọkùnrin rẹ̀ wọn kò sì ran ará Filistini lọ́wọ́ nítorí, lẹ́yìn tiwọn sọ̀rọ̀ papọ̀, àwọn olórí wọn rán wọn jáde, wọ́n sì wí pé, “Yóò jẹ́ ìparun fún wa tí ó bá padà tọ ọ̀gá rẹ̀ Saulu lọ.”) 20 Nígbà tí Dafidi lọ sí Siklagi, àwọn wọ̀nyí ni ọkùnrin ti Manase ẹni tí ó sì yà sọ́dọ̀ rẹ̀. Adina, Josabadi, Jediaeli, Mikaeli, Josabadi, Elihu àti Siletai, àwọn olórí ìrẹ́pọ̀ ti ẹgbẹgbẹ̀rún ní Manase. 21 Wọ́n sì ran Dafidi lọ́wọ́ lórí ẹgbẹ́ ogun náà, nítorí gbogbo wọn ni akọni ènìyàn àwọn sì tún ni olórí nínú àwọn ọmọ-ogun rẹ̀. 22 Ọjọ́ dé ọjọ́ ni àwọn ọkùnrin wá láti ran Dafidi lọ́wọ́, títí tí ó fi ní àwọn ológun ńlá, bí ogun Ọlọ́run.
5 (A)Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà, sì wí pé, “Kíyèsi i, mo sọ ohun gbogbo di ọ̀tun!” Ó sì wí fún mi pé, “Kọ̀wé rẹ̀: Nítorí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí òdodo àti òtítọ́ ni wọ́n.”
6 (B)Ó sì wí fún mi pé, “Ó parí. Èmi ni Alfa àti Omega, ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti òpin. Èmi ó sì fi omi fún ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ láti inú orísun omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́. 7 (C)Ẹni tí ó ba ṣẹ́gun ni yóò jogún nǹkan wọ̀nyí; èmi ó sì máa jẹ́ Ọlọ́run rẹ̀, òun ó sì máa jẹ ọmọ mi. 8 (D)Ṣùgbọ́n àwọn ojo, àti aláìgbàgbọ́, àti ẹni ìríra, àti apànìyàn, àti àgbèrè, àti oṣó, àti abọ̀rìṣà, àti àwọn èké gbogbo, ni yóò ni ipa tiwọn nínú adágún tí ń fi iná àti sulfuru jó: èyí tí i ṣe ikú kejì.”
9 Ọ̀kan nínú àwọn angẹli méje, tí wọ́n ni ago méje, tí ó kún fún ìyọnu méje ìkẹyìn sì wá, ó sì ba mi sọ̀rọ̀ wí pé, “Wá níhìn-ín, èmi ó fi ìyàwó, aya Ọ̀dọ́-àgùntàn hàn ọ́.” 10 (E)Ó sì mu mi lọ nínú Ẹ̀mí si òkè ńlá kan tí o sì ga, ó sì fi ìlú náà hàn mi, Jerusalẹmu mímọ́, tí ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, 11 Tí ó ní ògo Ọlọ́run: ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ sì dàbí òkúta iyebíye gidigidi, àní bí òkúta Jasperi, ó mọ́ bí Kirisitali; 12 (F)Ó sì ní odi ńlá àti gíga, ó sì ni ẹnu ibodè méjìlá, àti ní àwọn ẹnu ibodè náà angẹli méjìlá àti orúkọ tí a kọ sára wọn tí i ṣe orúkọ àwọn ẹ̀yà méjìlá tí àwọn ọmọ Israẹli; 13 Ní ìhà ìlà-oòrùn ẹnu ibodè mẹ́ta; ní ìhà àríwá ẹnu ibodè mẹ́ta; ní ìhà gúúsù ẹnu ibodè mẹ́ta; àti ní ìhà ìwọ̀-oòrùn ẹnu ibodè mẹ́ta. 14 Odi ìlú náà sì ni ìpìlẹ̀ méjìlá, àti lórí wọn orúkọ àwọn Aposteli méjìlá tí Ọ̀dọ́-Àgùntàn.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.