Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Saamu. Fún ọpẹ́
100 Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Olúwa, gbogbo ayé
2 Ẹ fi ayọ̀ sin Olúwa:
Ẹ wá síwájú rẹ̀ pẹ̀lú orin dídùn
3 Olúwa Ọlọ́run ni ó dá wa,
kí ẹ̀yin kí ó mọ̀ pé
tirẹ̀ ni àwa; Àwa ní ènìyàn rẹ̀
àti àgùntàn pápá rẹ̀.
4 Ẹ lọ sí ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́
àti sí àgbàlá rẹ̀ pẹ̀lú ìyìn;
ẹ fi ọpẹ́ àti ìyìn fún orúkọ rẹ̀.
5 Nítorí tí Olúwa pọ̀ ní oore
ìfẹ́ rẹ̀ sì wà títí láé;
àti òtítọ́ rẹ̀ láti ìran de ìran.
17 “Israẹli jẹ́ àgùntàn tí ó ṣìnà kiri,
kìnnìún sì ti lé e lọ.
Níṣàájú ọba Asiria pa á jẹ,
àti níkẹyìn yìí Nebukadnessari ọba Babeli
fa egungun rẹ̀ ya.”
18 Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Alágbára, Ọlọ́run Israẹli wí;
“Ǹ ó fi ìyà jẹ ọba Babeli àti ilẹ̀ rẹ̀
gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe fìyà jẹ ọba, Asiria.
19 Ṣùgbọ́n, èmi yóò mú Israẹli
padà wá pápá oko tútù rẹ̀
òun yóò sì máa bọ́ ara rẹ̀ lórí Karmeli àti Baṣani,
a ó sì tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn ní òkè
Efraimu àti ní Gileadi
20 Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì,”
ni Olúwa wí,
“À ó wá àìṣedéédéé ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli,
ṣùgbọ́n a ki yóò rí ohun;
àti ẹ̀ṣẹ̀ Juda ni a ki yóò sì rí mọ kankan
nítorí èmi yóò dáríjì àwọn tí ó ṣẹ́kù tí mo dá sí.
31 (A)Àwọn Júù sì tún mú òkúta, láti sọ lù ú. 32 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ rere ni mo fihàn yín láti ọ̀dọ̀ Baba mi wá; nítorí èwo nínú iṣẹ́ wọ̀nyí ni ẹ̀yin ṣe sọ mí ní òkúta?”
33 (B)Àwọn Júù sì dá a lóhùn pé, “Àwa kò sọ ọ́ lókùúta nítorí iṣẹ́ rere, ṣùgbọ́n nítorí ọ̀rọ̀-òdì: àti nítorí ìwọ tí í ṣe ènìyàn ń fi ara rẹ pe Ọlọ́run.”
34 (C)Jesu dá wọn lóhùn pé, “A kò ha tí kọ ọ́ nínú òfin yín pé, ‘Mo ti wí pé, Ọlọ́run ni ẹ̀yin jẹ́’? 35 Bí ó bá pè wọ́n ní Ọlọ́run, àwọn ẹni tí a fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún, a kò sì lè ba ìwé mímọ́ jẹ́. 36 Kín ni ẹyin ha ń wí ní ti ẹni tí Baba yà sọ́tọ̀, tí ó sì rán sí ayé kín lo de ti ẹ fi ẹ̀sùn kàn mi pé mò ń sọ̀rọ̀-òdì nítorí pé mo sọ pé, ‘Èmi ni ọmọ Ọlọ́run.’ 37 Bí èmi kò bá ṣe iṣẹ́ Baba mi, ẹ má ṣe gbà mí gbọ́. 38 Ṣùgbọ́n bí èmi bá ṣe wọ́n, bí ẹ̀yin kò tilẹ̀ gbà mí gbọ́, ẹ gbà iṣẹ́ náà gbọ́: kí ẹ̀yin ba à lè mọ̀, kí ó sì lè yé yín pé, Baba wà nínú mi, èmi sì wà nínú rẹ̀.” 39 (D)Wọ́n sì tún ń wá ọ̀nà láti mú un: ó sì bọ́ lọ́wọ́ wọn.
40 (E)Ó sì tún kọjá lọ sí apá kejì Jordani sí ibi tí Johanu ti kọ́kọ́ ń bamitiisi; níbẹ̀ ni ó sì jókòó. 41 Àwọn ènìyàn púpọ̀ sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì wí pé, “Johanu kò ṣe iṣẹ́ ààmì kan: Ṣùgbọ́n òtítọ́ ni ohun gbogbo tí Johanu sọ nípa ti ọkùnrin yìí.” 42 (F)Àwọn ènìyàn púpọ̀ níbẹ̀ sì gbà á gbọ́.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.