Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
93 Olúwa ń jẹ ọba, ọláńlá ni ó wọ̀ ní aṣọ;
ọláńlá ni Olúwa wọ̀ ní aṣọ
àti ìhámọ́ra rẹ̀ pẹ̀lú agbára.
Ó fi ìdí ayé múlẹ̀;
kò sì le è yí.
2 Ìjọba rẹ̀ wà láti ọjọ́ pípẹ́;
ìwọ wà títí ayérayé.
3 A ti gbé Òkun sókè, Olúwa,
Òkun ti gbé ohùn wọn sókè;
Òkun ti gbé rírú omi wọn sókè.
4 Ó ni ògo ju àrá omi ńlá lọ,
ó ni ògo ju Òkun rírú lọ
Olúwa ga ní ògo.
5 Ẹ̀rí rẹ̀ dúró ṣinṣin;
ìwà mímọ́ ni ó fi ṣe ilé rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́
fún ọjọ́ àìlópin, Olúwa.
20 Ó sì pa àṣẹ yìí fún Hilkiah, Ahikamu ọmọ Ṣafani, Abdoni ọmọ Mika, Ṣafani akọ̀wé àti Asaiah ìránṣẹ́ ọba. 21 “Ẹ lọ kí ẹ lọ béèrè lọ́wọ́ Olúwa fún mi nípa àwọn ìyókù Israẹli àti Juda nípa ohun tí wọ́n kọ sínú ìwé yìí tí a ti rí. Títóbi ni ìbínú Olúwa tí ó ti jáde sí orí wa nítorí àwọn baba wa kò ti pa ọ̀rọ̀ Olúwa mọ́, wọn kò sì tí ì ṣe gẹ́gẹ́ bí i gbogbo èyí tí a kọ sínú ìwé yìí.”
22 Hilkiah àti àwọn ènìyàn tí ọba yàn tọ Hulda wòlíì obìnrin láti ba sọ̀rọ̀, ẹni tí ó jẹ́ aya Ṣallumu ọmọ Tokhati tí a tún ń pè ní Tikfa, ọmọ Harhasi, olùtọ́jú ibi ìkáṣọsí. Ó sì ń gbé ní Jerusalẹmu, ní ìhà kejì.
23 Ó sì wí fún wọn wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli ti sọ: Sọ fún àwọn ọkùnrin tí ó rán ọ sí mi pé, 24 ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Èmi yóò sì mú ibi wá sí ìhín yìí àti àwọn ènìyàn rẹ̀ gbogbo àní ègún tí a kọ sínú ìwé tí wọ́n ti kà níwájú ọba Juda. 25 Nítorí tí wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀ wọ́n sì ti sun tùràrí sí ọlọ́run mìíràn wọ́n sì ti mú mi bínú pẹ̀lú gbogbo ohun tí wọ́n ti fi ọwọ́ wọn ṣe, ìbínú yóò tú jáde wá sórí ibí yìí, a kì yóò sì paná rẹ̀.’ 26 Sọ fún ọba Juda, ẹni tí ó rán yín láti béèrè lọ́wọ́ Olúwa, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa ti sọ, Ọlọ́run Israẹli, sọ nípa ọ̀rọ̀ wọ́n nì tí ìwọ gbọ́: 27 Nítorí ọkàn rẹ̀ dúró, ìwọ sì rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú Olúwa nígbà tí ó gbọ́ ohun tí ó sọ lórí ibí yìí àti ènìyàn rẹ, nítorí ìwọ rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú mi tí o sì fa aṣọ rẹ ya, tí o sì lọ níwájú mi. Èmi ti gbọ́ tìrẹ ni Olúwa wí. 28 Nísinsin yìí, Èmi ó kó ọ jọ pọ̀ sọ́dọ̀ àwọn baba rẹ, a ó sì sin ọ́ ní àlàáfíà. Ojú rẹ kò sì ní rí gbogbo ibi tí èmi ó mú wá sórí ibí yìí àti lórí àwọn tí ń gbé ibẹ̀.’ ”
Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n mún ìdáhùn rẹ̀ padà sí ọ̀dọ̀ ọba.
29 Nígbà náà ni ọba sì pe gbogbo àwọn àgbàgbà Juda jọ àti Jerusalẹmu. 30 Ó gòkè lọ sí ilé Olúwa pẹ̀lú àwọn ọkùnrin Juda, àwọn ènìyàn Jerusalẹmu, àwọn àlùfáà àti àwọn Lefi—gbogbo àwọn ènìyàn láti ibi kéékèèkéé sí ńlá. Ó kà á sí etí ìgbọ́ ọ wọn, gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú ìwé májẹ̀mú, tí a ti rí nínú ilé Olúwa. 31 Ọba sì dúró ní ipò rẹ̀ ó sì tún májẹ̀mú dá níwájú Olúwa láti tẹ̀lé Olúwa àti láti pa òfin rẹ̀ mọ́, àti ẹ̀rí rẹ̀ àti àṣẹ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ̀ àti gbogbo àyà rẹ̀ àti láti pa ọ̀rọ̀ májẹ̀mú tí a kọ sí inú ìwé yìí.
32 Nígbà náà, ó sì mú kí gbogbo ènìyàn ní Jerusalẹmu àti Benjamini dúró nínú ẹ̀rí fún ara wọn, àwọn ènìyàn Jerusalẹmu ṣe èyí gẹ́gẹ́ bi májẹ̀mú Ọlọ́run, Ọlọ́run Baba wọn.
33 Josiah sì kó gbogbo ohun ìríra kúrò nínú gbogbo ìlú tí ń ṣe ti àwọn tí ó wà ní Israẹli, ó sì mú kí gbogbo àwọn tí ó wà ní Israẹli sin Olúwa Ọlọ́run wọn gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe wà láyè wọn, kò yà kúrò láti máa tọ Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn lẹ́yìn.
25 (A)Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan wà ní Jerusalẹmu, orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Simeoni; ọkùnrin náà sì ṣe olóòtítọ́ àti olùfọkànsìn, ó ń retí ìtùnú Israẹli: Ẹ̀mí mímọ́ sì bà lé e. 26 A sì ti fihàn án láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ náà wá pé, òun kì yóò rí ikú, kí ó tó rí Kristi Olúwa. 27 Ó sì ti ipa Ẹ̀mí wá sínú tẹmpili: nígbà tí àwọn òbí rẹ̀ sì gbé Jesu wá, láti ṣe fún un bí ìṣe òfin, 28 Nígbà náà ni Simeoni gbé e ní apá rẹ̀, ó fi ìbùkún fún Ọlọ́run, ó ní:
29 “Olúwa Olódùmarè, nígbà yìí ni ó tó jọ̀wọ́ ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ lọ́wọ́ lọ,
ní Àlàáfíà, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ:
30 (B)Nítorí tí ojú mi ti rí ìgbàlà rẹ ná,
31 Tí ìwọ ti pèsè sílẹ̀ níwájú ènìyàn gbogbo;
32 (C)ìmọ́lẹ̀ láti mọ́ sí àwọn aláìkọlà,
àti ògo Israẹli ènìyàn rẹ̀.”
33 Ẹnu sì ya Josẹfu àti ìyá rẹ̀ sí nǹkan tí a ń sọ sí i wọ̀nyí. 34 Simeoni sì súre fún wọn, ó sì wí fún Maria ìyá rẹ̀ pé: “Kíyèsi i, a gbé ọmọ yìí kalẹ̀ fún ìṣubú àti ìdìde ọ̀pọ̀ ènìyàn ní Israẹli; àti fún ààmì tí a ń sọ̀rọ̀-òdì sí; 35 (Idà yóò sì gún ìwọ náà ní ọkàn pẹ̀lú) kí á lè fi ìrònú ọ̀pọ̀ ọkàn hàn.”
36 (D)Ẹnìkan sì ń bẹ, Anna wòlíì, ọmọbìnrin Penueli, nínú ẹ̀yà Aṣeri: ọjọ́ ogbó rẹ̀ pọ̀, ó ti bá ọkọ gbé ní ọdún méje láti ìgbà wúńdíá rẹ̀ wá; 37 Ó sì ṣe opó títí ó fi di ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin, ẹni tí kò kúrò ní tẹmpili, ṣùgbọ́n ó ń fi àwẹ̀ àti àdúrà sin Ọlọ́run lọ́sàn án àti lóru. 38 Ó sì wólẹ̀ ní àkókò náà, ó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pẹ̀lú, ó sì sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún gbogbo àwọn tí ó ń retí ìdáǹdè Jerusalẹmu.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.