Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Saamu. Orin. Fún ìyàsímímọ́ Tẹmpili. Ti Dafidi.
30 Èmi yóò kókìkí i rẹ, Olúwa,
nítorí ìwọ ni ó gbé mi lékè
tí ìwọ kò sì jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi kí ó yọ̀ mí.
2 Olúwa Ọlọ́run mi, èmi ké pè ọ́, fún ìrànlọ́wọ́
ìwọ sì ti wò mí sàn.
3 Olúwa, ìwọ ti yọ ọkàn mi jáde kúrò nínú isà òkú,
mú mi padà bọ̀ sípò alààyè kí èmi má ba à lọ sínú ihò.
4 Kọ orin ìyìn sí Olúwa, ẹ̀yin olódodo;
kí ẹ sì fi ọpẹ́ fún orúkọ rẹ̀ mímọ́.
5 Nítorí pé ìbínú rẹ̀ wà fún ìgbà díẹ̀,
ojúrere rẹ̀ wà títí ayérayé;
Ẹkún lè pẹ́ títí di alẹ́,
Ṣùgbọ́n ayọ̀ yóò wá ní òwúrọ̀.
6 Ní ìgbà ayé mi, mo wí pé,
“a kì yóò ṣí mi ní ipò padà.”
7 Nípa ojúrere rẹ, Olúwa,
ìwọ ti gbé mi kalẹ̀ bí òkè tí ó ní agbára;
ìwọ pa ojú rẹ mọ́,
àyà sì fò mí.
8 Sí ọ Olúwa, ni mo ké pè é;
àti sí Olúwa ni mo sọkún fún àánú:
9 “Èrè kí ni ó wà nínú ikú ìparun mi,
nínú lílọ sí ihò mi?
Eruku yóò a yìn ọ́ bí?
Ǹjẹ́ yóò sọ nípa òdodo rẹ?
10 Gbọ́, Olúwa, kí o sì ṣàánú fún mi;
ìwọ Olúwa, jẹ́ olùrànlọ́wọ́ mi.”
11 Ìwọ ti yí ìkáàánú mi di ijó fún mi;
ìwọ sì ti bọ́ aṣọ ọ̀fọ̀ mi, o sì fi aṣọ ayọ̀ wọ̀ mí,
12 nítorí ìdí èyí ni kí ọkàn mi máa yìn ọ́, kí o má sì ṣe dákẹ́.
Ìwọ Olúwa Ọlọ́run mi, èmi yóò máa fi ọpẹ́ fún ọ títí láé.
Ìpè sí iṣẹ́ ìránṣẹ́ Isaiah
6 Ní ọdún tí ọba Ussiah kú, mo rí Olúwa tí ó jókòó lórí ìtẹ́ tí ó ga tí a gbé sókè, ìṣẹ́tí aṣọ ìgúnwà rẹ̀ sì kún inú tẹmpili. 2 Àwọn Serafu wà ní òkè rẹ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ìyẹ́ mẹ́fà, wọ́n fi ìyẹ́ méjì bo ojú wọn, wọ́n fi méjì bo ẹsẹ̀ wọn, wọ́n sí ń fi méjì fò. 3 (A)Wọ́n sì ń kọ sí ara wọn wí pé:
“Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun
gbogbo ayé kún fún ògo rẹ̀.”
4 (B)Nípa ìró ohùn un wọn, òpó ìlẹ̀kùn àti gbogbo ògiri ilé náà sì mì tìtì, gbogbo inú tẹmpili sì kún fún èéfín.
Ìtẹ́ Ọ̀run
4 (A)Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí èmi wò, sì kíyèsi i, ìlẹ̀kùn kan ṣí sílẹ̀ ní ọ̀run: Ohùn kìn-ín-ní tí mo gbọ́ bí ohùn ìpè tí ń bá mi sọ̀rọ̀, tí ó wí pé, “Gòkè wá níhìn-ín, èmi ó sì fi ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn èyí hàn ọ́.” 2 (B)Lójúkan náà, mo sì wà nínú Ẹ̀mí: sì kíyèsi i, a tẹ́ ìtẹ́ kan ní ọ̀run, ẹnìkan sì jókòó lórí ìtẹ́ náà. 3 Ẹni tí ó sì jókòó náà dàbí òkúta jasperi àti kaneliani lójú. Ni àyíká ìtẹ́ náà ni òṣùmàrè kan wà tí ó dàbí òkúta emeradi lójú. 4 Yí ìtẹ́ náà ká sì ni ìtẹ́ mẹ́rìnlélógún mìíràn; àti lórí àwọn ìtẹ́ náà mo rí àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún jókòó, tí a wọ̀ ni aṣọ àlà; adé wúrà sì wà ni orí wọn. 5 (C)Àti láti ibi ìtẹ́ náà ni ìró mọ̀nàmọ́ná àti ohùn àti àrá ti jáde wá: níwájú ìtẹ́ náà ni fìtílà iná méje sì ń tàn, èyí tí ń ṣe Ẹ̀mí méje ti Ọlọ́run. 6 (D)Àti láti ibi ìtẹ́ náà ni òkun bi dígí wà tí o dàbí kristali.
Àti yí ìtẹ́ náà ká ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan ni ẹ̀dá alààyè mẹ́rin tí ó kún fún ojú níwájú àti lẹ́yìn wọn. 7 (E)Ẹ̀dá kìn-ín-ní sì dàbí kìnnìún, ẹ̀dá kejì si dàbí ọmọ màlúù, ẹ̀dá kẹta sì ni ojú bi ti ènìyàn, ẹ̀dá kẹrin sì dàbí idì tí ń fò. 8 (F)Àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, tí olúkúlùkù wọn ni ìyẹ́ mẹ́fà, kún fún ojú yíká ara àti nínú; wọn kò sì sinmi lọ́sàn àti lóru, láti wí pé:
“Mímọ́, mímọ́, mímọ́,
Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè,
tí ó ti wà, tí ó sì ń bẹ, tí ó sì ń bọ̀ wá!”
9 (G)Nígbà tí àwọn ẹ̀dá alààyè náà bá sì fi ògo àti ọlá, àti ọpẹ́ fún ẹni tí o jókòó lórí ìtẹ́, tí o ń bẹ láààyè láé àti láéláé. 10 Àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún náà yóò sì wólẹ̀ níwájú ẹni tí o jókòó lórí ìtẹ́, wọn yóò sì tẹríba fún ẹni tí ń bẹ láààyè láé àti láéláé, wọn yóò sì fi adé wọn lélẹ̀ níwájú ìtẹ́ náà, wí pé:
11 “Olúwa àti Ọlọ́run, ìwọ ni o yẹ,
láti gba ògo àti ọlá àti agbára:
nítorí pé ìwọ ni o dá ohun gbogbo,
àti nítorí ìfẹ́ inú rẹ̀ ni
wọn fi wà tí a sì dá wọn.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.