Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Saamu. Fún ọpẹ́
100 Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Olúwa, gbogbo ayé
2 Ẹ fi ayọ̀ sin Olúwa:
Ẹ wá síwájú rẹ̀ pẹ̀lú orin dídùn
3 Olúwa Ọlọ́run ni ó dá wa,
kí ẹ̀yin kí ó mọ̀ pé
tirẹ̀ ni àwa; Àwa ní ènìyàn rẹ̀
àti àgùntàn pápá rẹ̀.
4 Ẹ lọ sí ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́
àti sí àgbàlá rẹ̀ pẹ̀lú ìyìn;
ẹ fi ọpẹ́ àti ìyìn fún orúkọ rẹ̀.
5 Nítorí tí Olúwa pọ̀ ní oore
ìfẹ́ rẹ̀ sì wà títí láé;
àti òtítọ́ rẹ̀ láti ìran de ìran.
Ilẹ̀ pínpín
45 “ ‘Nígbà ti ẹ̀yin bá pín ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ogún, ẹ gbọdọ̀ gbé ìpín ilẹ̀ kan kalẹ̀ fún Olúwa gẹ́gẹ́ bí ibi mímọ́, ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn àti ogún ẹgbẹ̀rún ìgbọ̀nwọ́ ni ìbú; gbogbo agbègbè rẹ̀ yíká ni yóò jẹ́ mímọ́. 2 Lára inú èyí, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta yóò jẹ́ ti ibi mímọ́ ní gígùn, pẹ̀lú ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ní ìbú, ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin yíká, àti àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ fún gbangba rẹ̀ yíká. 3 Ní agbègbè ibi mímọ́, wọn ya ibi kan sọ́tọ̀ kí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ní ìbú. Ní inú rẹ ni ilẹ̀ ti a yà sọ́tọ̀ fún Olúwa yóò wà, ìyẹn ibi mímọ́ jùlọ. 4 Yóò jẹ́ ibi mímọ́ lára ilẹ̀ náà fún àwọn àlùfáà, tí ó ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ ní ibi mímọ́ àti àwọn tí ó súnmọ́ àlùfáà ní iwájú Olúwa. Ibẹ̀ yóò jẹ ibi tí yóò wà fún ilé gbígbé wọn, bákan náà ni yóò jẹ́ ibi mímọ́ fún ilé Olúwa. 5 Agbègbè kan tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ní ìbú yóò jẹ́ ti àwọn ọmọ Lefi, tí ó ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ nínú tẹmpili, gẹ́gẹ́ bi ìní wọn fún ìlú wọn láti máa gbé ibẹ̀.
6 “ ‘Ìwọ yóò fi ìlú náà ti agbègbè rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ni ìbú àti ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, papọ̀ mọ́ ibi mímọ́ fún àwọn ilé Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìní: yóò jẹ́ ti gbogbo ilé Israẹli.
7 “ ‘Àwọn ọmọ-aládé ni yóò bá ibi mímọ́ pààlà ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan agbègbè tí ó jẹ ibi mímọ́ àti ohun tí ó jẹ́ ti ìlú. Yóò fẹ̀ sẹ́yìn sí ìhà ìwọ̀-oòrùn láti apá ìwọ̀-oòrùn àti si ìlà-oòrùn, láti apá ìlà-oòrùn, gígùn rẹ̀ yóò jẹ́ láti ìwọ̀-oòrùn sí ààlà ìlà-oòrùn, ti ìṣe déédé rẹ̀ yóò jẹ́ ti ọ̀kan lára àwọn ìpín ẹ̀yà. 8 Ilẹ̀ yìí ni yóò jẹ́ ìpín rẹ̀ ní Israẹli. Àwọn ọmọ-aládé mìíràn kò ní rẹ́ àwọn ènìyàn mi jẹ mọ́, ṣùgbọ́n wọn yóò jẹ́ kí àwọn ilé Israẹli gba ilẹ̀ wọn gẹ́gẹ́ bi ẹ̀yà wọn.
9 “ ‘Èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Ẹ̀yin ti rìn jìnnà tó, Ẹ̀yin ọmọ-aládé tí Israẹli! Ẹ fi ìwà ipá àti ìrẹ́jẹ yín sílẹ̀ kí ẹ̀yin sì ṣe èyí tí ó tọ́ àti èyí tí ó yẹ. Ẹ dáwọ́ gbígbà ní ọwọ́ àwọn ènìyàn mi dúró, ni Olúwa Ọlọ́run wí.
Aenea àti Dọkasi
32 Ó sì ṣe, bí Peteru ti ń kọjá lọ káàkiri láàrín wọn, ó sọ̀kalẹ̀ lọ pẹ̀lú si ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ ti ń gbé ni Lida. 33 Níbẹ̀ ni ó rí ọkùnrin kan ti a pè ní Aenea tí ó ti dùbúlẹ̀ lórí àkéte ni ọdún mẹ́jọ, ó ní ààrùn ẹ̀gbà. 34 Peteru sì wí fún un pé, “Aenea, Jesu Kristi mú ọ láradá; dìde kí ó sì tún àkéte rẹ ṣe.” Ó sì dìde lójúkan náà. 35 Gbogbo àwọn tí ń gbé Lida àti Ṣaroni sì rí i, wọn sì yípadà sí Olúwa.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.