Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 148

148 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa láti ọ̀run wá,
    Ẹ fi ìyìn fún un níbi gíga.
Ẹ fi ìyìn fún un,
    gbogbo ẹ̀yin angẹli rẹ̀
Ẹ fi ìyìn fún un,
    gbogbo ẹ̀yin ọmọ-ogun rẹ̀
Ẹ fi ìyìn fún un,
    oòrùn àti òṣùpá
Ẹ fi ìyìn fún un,
    gbogbo ẹ̀yin ìràwọ̀ ìmọ́lẹ̀.
Ẹ fi ìyìn fún un,
    ẹ̀yin ọ̀run àti àwọn ọ̀run gíga
    àti ẹ̀yin omi tí ń bẹ ní òkè ọ̀run.

Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ Olúwa
    nítorí ó pàṣẹ a sì dá wọn
Ó fi ìdí wọn múlẹ̀ láé àti láéláé
    ó sì ti ṣe ìlànà kan tí kì yóò já.

Ẹ yin Olúwa láti ilẹ̀ ayé wá
    ẹ̀yin ẹ̀dá inú Òkun títóbi
    àti ẹ̀yin ibú Òkun
Mọ̀nàmọ́ná àti òjò yìnyín
    ìdí omi àti àwọn ìkùùkuu,
    ìjì líle tí ń mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ;
Òkè ńlá àti gbogbo òkè kéékèèkéé,
    igi eléso àti gbogbo igi kedari,
10 Àwọn ẹranko ńlá àti ẹran ọ̀sìn
    gbogbo ohun afàyàfà àti àwọn ẹyẹ abìyẹ́:
11 Àwọn ọba ayé àti ènìyàn ayé gbogbo
    àwọn ọmọ-aládé àti gbogbo àwọn onídàájọ́ ayé,
12 Ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin
    àwọn arúgbó àti àwọn ọmọdé.

13 Ẹ jẹ́ kí wọn kí ó yin orúkọ Olúwa
    nítorí orúkọ rẹ̀ nìkan ni ó ní ọlá
    ògo rẹ̀ kọjá ayé àti ọ̀run
14 Ó sì gbé ìwo kan sókè fún àwọn ènìyàn rẹ̀,
    ìyìn fún gbogbo ènìyàn mímọ́ rẹ̀ àní fún àwọn ọmọ Israẹli,
    àwọn ènìyàn tí ó súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀.

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Daniẹli 7:13-14

13 (A)“Nínú ìran mi ní òru mo wò, mo rí ẹnìkan tí ó dúró sí iwájú u mi, ó rí bí Ọmọ ènìyàn, ó ń bọ̀ wá nínú àwọsánmọ̀ ọ̀run, ó ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ ẹni ìgbàanì, a sì mú u wá sí iwájú rẹ̀. 14 (B)A sì fi ìjọba, ògo àti agbára ilẹ̀ ọba fún un; gbogbo ènìyàn, orílẹ̀-èdè àti èdè gbogbo wọn wólẹ̀ fún un. Ìjọba rẹ̀, ìjọba ayérayé ni, èyí tí kò le è kọjá, ìjọba rẹ̀ kò sì le è díbàjẹ́ láéláé.

Ìfihàn 11:15

Ìpè méje

15 (A)Angẹli keje sì fọn ìpè; a sì gbọ́ ohùn ńlá láti ọ̀run, wí pé,

“Ìjọba ayé di ti Olúwa wá, àti tí Kristi rẹ̀;
    òun yóò sì jẹ ọba láé àti láéláé!”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.