Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
105 (A)Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, ké pe orúkọ rẹ̀:
Jẹ́ kí a mọ ohun tí ó ṣe láàrín àwọn orílẹ̀-èdè;
2 Kọrin sí i, kọrin ìyìn sí i;
sọ ti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ gbogbo.
3 Ṣògo nínú orúkọ mímọ́ rẹ̀:
Jẹ́ kí ọkàn àwọn tí ń wá Olúwa kí ó yọ̀.
4 Wá Olúwa àti ipá rẹ̀;
wa ojú rẹ̀ nígbà gbogbo.
5 Rántí àwọn ìyanu tí ó ti ṣe,
ìyanu rẹ̀, àti ìdájọ́ tí ó sọ,
6 Ẹ̀yin ìran Abrahamu ìránṣẹ́ rẹ̀,
ẹ̀yin ọmọkùnrin Jakọbu, àyànfẹ́ rẹ̀.
7 Òun ni Olúwa Ọlọ́run wa:
ìdájọ́ rẹ̀ wà ní gbogbo ayé.
8 (B)Ó rántí májẹ̀mú rẹ̀ láéláé,
ọ̀rọ̀ tí ó pàṣẹ, fún ẹgbẹgbẹ̀rún ìran,
9 májẹ̀mú tí ó dá pẹ̀lú Abrahamu,
ìbúra tí ó ṣe pẹ̀lú fún Isaaki.
10 Ó ṣe ìdánilójú u rẹ̀ fún Jakọbu gẹ́gẹ́ bí àṣẹ
sí Israẹli, gẹ́gẹ́ bi májẹ̀mú ayérayé:
11 “Fún ìwọ ni èmi ó fún ní ilẹ̀ Kenaani
gẹ́gẹ́ bí ìpín tí ìwọ ó jogún.”
12 Nígbà tí wọn kéré níye,
wọ́n kéré jọjọ, àti àwọn àjèjì níbẹ̀
13 wọ́n rìn kiri láti orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè,
láti ìjọba kan sí èkejì.
14 Kò gba ẹnikẹ́ni láààyè láti pọ́n wọn lójú;
ó fi ọba bú nítorí tiwọn:
15 “Má ṣe fọwọ́ kan ẹni ààmì òróró mi, má sì ṣe wòlíì mi níbi.”
16 Ó pe ìyàn sórí ilẹ̀ náà
ó sì pa gbogbo ìpèsè oúnjẹ wọn run;
17 Ó sì rán ọkùnrin kan síwájú wọn
Josẹfu tí a tà gẹ́gẹ́ bí ẹrú.
18 Wọn fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ bọ ẹsẹ̀ rẹ̀
a gbé ọrùn rẹ̀ sínú irin
19 Títí ọ̀rọ̀ tí ó sọtẹ́lẹ̀ fi ṣẹ
títí ọ̀rọ̀ Olúwa fi dá a láre.
20 Ọba ránṣẹ́ lọ tú u sílẹ̀
àwọn aláṣẹ ènìyàn tú u sílẹ̀
21 Ó fi jẹ olúwa lórí ilẹ̀ rẹ̀
aláṣẹ lórí ohun gbogbo tí ó ní,
22 Gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀, kí ó máa
ṣe àkóso àwọn ọmọ-aládé
kí ó sì kọ́ àwọn àgbàgbà rẹ̀ ní ọgbọ́n.
23 Israẹli wá sí Ejibiti;
Jakọbu sì ṣe àtìpó ní ilé Hamu.
24 Olúwa, sì mú àwọn ọmọ rẹ̀ bí sí i
ó sì mú wọn lágbára jù
àwọn ọ̀tá wọn lọ
25 Ó yí wọn lọ́kàn padà láti kórìíra àwọn ènìyàn
láti ṣe àrékérekè sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.
26 Ó rán Mose ìránṣẹ́ rẹ̀
àti Aaroni tí ó ti yàn
27 Wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ìyanu láàrín wọn
ó ṣe iṣẹ́ ìyanu ní Hamu.
28 Ó rán òkùnkùn, o sì mú ilẹ̀ ṣú
wọn kò sì sọ̀rọ̀-òdì sí ọ̀rọ̀ rẹ̀.
29 Ó sọ omi wọn di ẹ̀jẹ̀,
ó pa ẹja wọn.
30 Ilẹ̀ mú ọ̀pọ̀lọ́ jáde wá,
èyí tí ó lọ sí ìyẹ̀wù àwọn ọba wọn.
31 Ó sọ̀rọ̀, onírúurú eṣinṣin sì dìde,
ó sì hu kantíkantí ní ilẹ̀ wọn
32 Ó sọ òjò di yìnyín,
àti ọ̀wọ́-iná ní ilẹ̀ wọn;
33 Ó lu àjàrà wọn àti igi ọ̀pọ̀tọ́ wọn
ó sì dá igi orílẹ̀-èdè wọn.
34 Ó sọ̀rọ̀, eṣú sì dé,
àti kòkòrò ní àìníye,
35 Wọn sì jẹ gbogbo ewé ilẹ̀ wọn,
wọ́n sì jẹ èso ilẹ̀ wọn run
36 Nígbà náà, ó kọlu gbogbo àwọn ilẹ̀ wọn,
ààyò gbogbo ipá wọn.
37 Ó mú Israẹli jáde
ti òun ti fàdákà àti wúrà,
nínú ẹ̀yà rẹ̀ kò sí aláìlera kan.
38 Inú Ejibiti dùn nígbà tí wọn ń lọ,
nítorí ẹ̀rù àwọn Israẹli ń bá wọ́n.
39 Ó ta àwọsánmọ̀ fún ìbòrí,
àti iná láti fún wọn ní ìmọ́lẹ̀ lálẹ́
40 Wọn béèrè, ó sì mú ẹyẹ àparò wá,
ó sì fi oúnjẹ ọ̀run tẹ́ wọn lọ́rùn.
41 Ó sì la àpáta, ó sì mú omi jáde;
gẹ́gẹ́ bí odò tí ń sàn níbi gbígbẹ.
42 Nítorí ó rántí ìlérí mímọ́ rẹ̀
àti Abrahamu ìránṣẹ́ rẹ̀.
10 Ṣùgbọ́n gbogbo ìjọ ènìyàn sì ń sọ pé àwọn yóò sọ wọ́n lókùúta pa. Nígbà náà ni ògo Olúwa fi ara hàn ní àgọ́ ìpàdé níwájú àwọn ọmọ Israẹli.
Mose bẹ̀bẹ̀ fún àwọn ènìyàn
11 (A)Olúwa sọ fún Mose pé, “Fún ìgbà wo ni àwọn ènìyàn yìí yóò ti kẹ́gàn mi tó? Báwo ni yóò ti pẹ́ tó tí wọ́n ó fi kọ̀ jálẹ̀ láti gbà mí gbọ́, pẹ̀lú gbogbo iṣẹ́ ààmì tí mo ṣe láàrín wọn? 12 Èmi ó kọlù wọ́n pẹ̀lú àjàkálẹ̀-ààrùn, èmi ó gba ogún wọn lọ́wọ́ wọn, èmi ó sì pa wọ́n run ṣùgbọ́n èmi ó sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá tó sì lágbára jù wọ́n lọ.”
13 Ṣùgbọ́n Mose sọ fún Olúwa pé, “Nígbà náà ni àwọn ará Ejibiti yóò gbọ́; Nítorí pé nípa agbára rẹ ni ìwọ fi mú àwọn ènìyàn wọ̀nyí jáde kúrò láàrín wọn. 14 Wọ́n ó sì sọ fún àwọn olùgbé ilẹ̀ yìí. Àwọn tó ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé ìwọ Olúwa wà láàrín àwọn ènìyàn wọ̀nyí àti pé wọ́n rí ìwọ, Olúwa, ní ojúkojú, àti pé ìkùùkuu àwọsánmọ̀ rẹ dúró lórí wọn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ sì ń lọ níwájú wọn pẹ̀lú ìkùùkuu àwọsánmọ̀ ní ọ̀sán àti pẹ̀lú ọ̀wọ́n iná ní òru. 15 Bí ìwọ bá pa àwọn ènìyàn wọ̀nyí lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, àwọn orílẹ̀-èdè tó bá gbọ́ ìròyìn yìí nípa rẹ yóò wí pé, 16 ‘Nítorí pé Olúwa kò le è mú àwọn ènìyàn wọ̀nyí dé ilẹ̀ tí ó ṣèlérí fún wọn; torí èyí ló ṣe pa wọ́n sínú aginjù yìí.’
17 “Báyìí, mo gbàdúrà, jẹ́ kí agbára Olúwa tóbi gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti sọ pé: 18 ‘Olúwa lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́ tó dúró ṣinṣin, tí ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ àti ìrékọjá jì. Bẹ́ẹ̀ ni kì í jẹ́ kí ẹlẹ́bi lọ láìjìyà; tó ń fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba jẹ ọmọ títí dé ìran kẹta àti ìran kẹrin.’ 19 Dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn yìí jì wọ́n, mo bẹ̀ ọ́, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ńlá rẹ, bí o ti ṣe ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n láti ìgbà tí o ti kó wọn kúrò ní Ejibiti di ìsin yìí.”
20 Olúwa sì dáhùn pé: “Mo ti dáríjì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ; 21 Ṣùgbọ́n nítòótọ́ bí mo ti wà láààyè, gbogbo ayé yóò kún fún ògo Olúwa. 22 (B)Kò sí ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn tó rí ògo mi àti àwọn iṣẹ́ ààmì tí mo ṣe ní ilẹ̀ Ejibiti àti nínú aginjù ṣùgbọ́n tí wọ́n ṣe àìgbọ́ràn sí mi, tí wọn sì dán mi wò ní ìgbà mẹ́wàá yìí, 23 Ọ̀kan nínú wọn kò ní rí ilẹ̀ náà tí mo ṣe ìlérí ní ìbúra láti fún baba ńlá wọn. Kò sí ọ̀kan nínú àwọn tó kẹ́gàn mi tí yóò rí ilẹ̀ náà. 24 Ṣùgbọ́n nítorí pé Kalebu ìránṣẹ́ mi ní ẹ̀mí ọ̀tọ̀, tí ó sì tún tẹ̀lé mi tọkàntọkàn, èmi ó mu dé ilẹ̀ náà tó lọ yẹ̀ wò, irú àwọn ọmọ rẹ̀ yóò sì jogún rẹ̀.
Ìkìlọ̀ láti inú ìtàn àwọn ọmọ Israẹli
10 (A)Nítorí èmi kò fẹ́ kí ẹ̀yin jẹ́ òpè si òtítọ́, ẹ̀yin arákùnrin ọ̀wọ́n, a kó gbọdọ̀ gbàgbé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn wa nínú aginjù. Ọlọ́run ṣamọ̀nà wọn nípa rírán ìkùùkuu síwájú wọn, ó sì sìn wọ́n la omi Òkun pupa já. 2 (B)A lè pe eléyìí ní ìtẹ̀bọmi ti Mose nínú ìkùùkuu àti nínú omi Òkun. 3 (C)Nípa iṣẹ́ ìyanu, gbogbo wọn jẹ oúnjẹ ẹ̀mí kan náà. 4 (D)Wọ́n mu nínú omi tí Kristi fi fún wọn. Wọ́n mu omi ẹ̀mí láti inú àpáta tí ó ń tẹ̀lé wọn, àpáta náà ni Kristi. Ó wà pẹ̀lú wọn nínú aginjù náà, òun ni àpáta tí ń fi omi ẹ̀mí tu ọkàn lára. 5 (E)Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ni inú Ọlọ́run kò dún sí; nítorí a pa wọ́n run nínú aginjù.
6 (F)Àwọn nǹkan wọ̀nyí sì jásí àpẹẹrẹ fún àwa, kí a má ṣe ní ìfẹ́ sí àwọn ohun búburú gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn yìí ṣe ní ìfẹ́ si. 7 (G)Kí ẹ̀yin kí ó má ṣe jẹ́ abọ̀rìṣà gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Àwọn ènìyàn náà jókòó láti jẹ àti láti mu, wọ́n sì dìde dúró láti ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́.” 8 (H)Bẹ́ẹ̀ ni kí àwa kí ó má ṣe ṣe àgbèrè gẹ́gẹ́ bí àwọn mìíràn nínú wọn ti ṣe, tí ẹgbàá-mọ̀kànlá-lé-ẹgbẹ̀rún ènìyàn sì kú ní ọjọ́ kan. 9 (I)Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin má ṣe dán Olúwa wò, gẹ́gẹ́ bí àwọn mìíràn nínú wọn ti dán an wò, tí a sì fi ejò run wọ́n. 10 (J)Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin kí ó má ṣe kùn, gẹ́gẹ́ bí àwọn mìíràn nínú wọ́n ṣe kùn, tí a sì ti ọwọ́ olùparun run wọ́n.
11 Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣẹlẹ̀ sí wọn bí àpẹẹrẹ fún wa, a sì kọ̀wé wọn fún ìkìlọ̀ fún wa, àwa ẹni tí ìgbẹ̀yìn ayé dé bá. 12 Nítorí náà, ẹni tí ó bá rò pé òun dúró, kí ó kíyèsára kí ó ma ba à ṣubú. 13 (K)Kò sí ìdánwò kan tí ó ti bá yín, bí kò ṣe irú èyí tí ó mọ níwọ̀n fún ènìyàn, ṣùgbọ́n olódodo ni Ọlọ́run, ẹni ti kì yóò jẹ́ kí á dán an yín wò ju bí ẹ̀yin ti le gbà, ṣùgbọ́n tí yóò sì ṣe ọ̀nà àbáyọ pẹ̀lú nínú ìdánwò náà, kí ẹ̀yin ba à lè faradà á.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.