Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Ìpè sí àwọn tí òrùngbẹ n gbẹ
55 (A)“Ẹ wá, gbogbo ẹ̀yin tí òǹgbẹ ń gbẹ,
ẹ wá sí ibi omi;
àti ẹ̀yin tí kò ní owó;
ẹ wá, ẹ rà kí ẹ sì jẹ!
Ẹ wá ra wáìnì àti wàrà
láìsí owó àti láìdíyelé.
2 Èéṣe tí ẹ fi ń ná owó fún èyí tí kì í ṣe àkàrà
àti làálàá yín lórí ohun tí kì í tẹ́nilọ́rùn?
Tẹ́tí sílẹ̀, tẹ́tí sí mi, kí ẹ sì jẹ èyí tí ó dára,
bẹ́ẹ̀ ni ọkàn yín yóò láyọ̀ nínú ọrọ̀ tí ó bójúmu.
3 (B)Tẹ́tí sílẹ̀ kí o sì wá sọ́dọ̀ mi
gbọ́ tèmi, kí ọkàn rẹ lè wà láààyè.
Èmi yóò dá májẹ̀mú ayérayé pẹ̀lú rẹ,
ìfẹ́ òtítọ́ tí mo ṣèlérí fún Dafidi.
4 Kíyèsi i, mo ti fi òun ṣe ẹlẹ́rìí fún àwọn ènìyàn,
olórí àti apàṣẹ fún àwọn ènìyàn.
5 Lóòtítọ́ ìwọ yóò ké sí àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ kò mọ̀
àti orílẹ̀-èdè tí ìwọ kò mọ̀ ni yóò sáré tọ̀ ọ́ wá,
Nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ
Ẹni Mímọ́ Israẹli
nítorí pé ó ti fi ohun dídára dá ọ lọ́lá.”
6 Ẹ wá Olúwa nígbà tí ẹ lè rí i;
ẹ pè é nígbà tí ó wà nítòsí.
7 Jẹ́ kí ìkà kí ó kọ ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀
àti ènìyàn búburú èrò rẹ̀.
Jẹ́ kí ó yípadà sí Olúwa, Òun yóò sì ṣàánú fún un,
àti sí Ọlọ́run wa, nítorí Òun yóò sì dáríjì.
8 “Nítorí èrò mi kì í ṣe èrò yín,
tàbí ọ̀nà yín a ha máa ṣe ọ̀nà mi,”
ni Olúwa wí.
9 “Gẹ́gẹ́ bí ọ̀run ti ga ju ayé lọ,
bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi ga ju ọ̀nà yín lọ
àti èrò mi ju èrò yín lọ.
Saamu ti Dafidi. Nígbà tí ó wà nínú aginjù Juda.
63 Ọlọ́run, ìwọ ni Ọlọ́run mi,
nígbà gbogbo ni mo ń ṣàfẹ́rí rẹ,
òǹgbẹ rẹ ń gbẹ ọkàn mi,
ara mi fà sí ọ,
ní ilẹ̀ gbígbẹ àti ilẹ̀ tí ń ṣàárẹ̀
níbi tí kò sí omi.
2 Èmi ti rí ọ ní ibi mímọ́,
mo rí agbára àti ògo rẹ.
3 Nítorí ìfẹ́ rẹ dára ju ayé lọ,
ètè mi yóò fògo fún ọ.
4 Èmi ó yìn ọ́ níwọ̀n ìgbà tí mo wà láààyè,
èmi ó gbé ọwọ́ sókè, èmi ó sì pe orúkọ rẹ.
5 A ó tẹ́ ọkàn mi lọ́rùn bí ọlọ́ràá oúnjẹ;
pẹ̀lú ètè ìyìn, ẹnu mi yóò yìn ọ́.
6 Nígbà tí mo rántí rẹ lórí ibùsùn mi;
èmi ń ronú rẹ títí ìṣọ́ òru.
7 Nítorí ìwọ ni ìrànlọ́wọ́ mi,
mo kọrin níbi òjìji ìyẹ́ apá rẹ.
8 Ọkàn mí fà sí ọ:
ọwọ́ ọ̀tún rẹ gbé mi ró.
Ìkìlọ̀ láti inú ìtàn àwọn ọmọ Israẹli
10 (A)Nítorí èmi kò fẹ́ kí ẹ̀yin jẹ́ òpè si òtítọ́, ẹ̀yin arákùnrin ọ̀wọ́n, a kó gbọdọ̀ gbàgbé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn wa nínú aginjù. Ọlọ́run ṣamọ̀nà wọn nípa rírán ìkùùkuu síwájú wọn, ó sì sìn wọ́n la omi Òkun pupa já. 2 (B)A lè pe eléyìí ní ìtẹ̀bọmi ti Mose nínú ìkùùkuu àti nínú omi Òkun. 3 (C)Nípa iṣẹ́ ìyanu, gbogbo wọn jẹ oúnjẹ ẹ̀mí kan náà. 4 (D)Wọ́n mu nínú omi tí Kristi fi fún wọn. Wọ́n mu omi ẹ̀mí láti inú àpáta tí ó ń tẹ̀lé wọn, àpáta náà ni Kristi. Ó wà pẹ̀lú wọn nínú aginjù náà, òun ni àpáta tí ń fi omi ẹ̀mí tu ọkàn lára. 5 (E)Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ni inú Ọlọ́run kò dún sí; nítorí a pa wọ́n run nínú aginjù.
6 (F)Àwọn nǹkan wọ̀nyí sì jásí àpẹẹrẹ fún àwa, kí a má ṣe ní ìfẹ́ sí àwọn ohun búburú gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn yìí ṣe ní ìfẹ́ si. 7 (G)Kí ẹ̀yin kí ó má ṣe jẹ́ abọ̀rìṣà gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Àwọn ènìyàn náà jókòó láti jẹ àti láti mu, wọ́n sì dìde dúró láti ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́.” 8 (H)Bẹ́ẹ̀ ni kí àwa kí ó má ṣe ṣe àgbèrè gẹ́gẹ́ bí àwọn mìíràn nínú wọn ti ṣe, tí ẹgbàá-mọ̀kànlá-lé-ẹgbẹ̀rún ènìyàn sì kú ní ọjọ́ kan. 9 (I)Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin má ṣe dán Olúwa wò, gẹ́gẹ́ bí àwọn mìíràn nínú wọn ti dán an wò, tí a sì fi ejò run wọ́n. 10 (J)Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin kí ó má ṣe kùn, gẹ́gẹ́ bí àwọn mìíràn nínú wọ́n ṣe kùn, tí a sì ti ọwọ́ olùparun run wọ́n.
11 Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣẹlẹ̀ sí wọn bí àpẹẹrẹ fún wa, a sì kọ̀wé wọn fún ìkìlọ̀ fún wa, àwa ẹni tí ìgbẹ̀yìn ayé dé bá. 12 Nítorí náà, ẹni tí ó bá rò pé òun dúró, kí ó kíyèsára kí ó ma ba à ṣubú. 13 (K)Kò sí ìdánwò kan tí ó ti bá yín, bí kò ṣe irú èyí tí ó mọ níwọ̀n fún ènìyàn, ṣùgbọ́n olódodo ni Ọlọ́run, ẹni ti kì yóò jẹ́ kí á dán an yín wò ju bí ẹ̀yin ti le gbà, ṣùgbọ́n tí yóò sì ṣe ọ̀nà àbáyọ pẹ̀lú nínú ìdánwò náà, kí ẹ̀yin ba à lè faradà á.
Ẹ ronúpìwàdà kí ẹ má bà á ṣègbé
13 Àwọn kan sì wá ní àkókò náà tí ó sọ ti àwọn ará Galili fún un, ẹ̀jẹ̀ ẹni tí Pilatu dàpọ̀ mọ́ ẹbọ wọn. 2 (A)Jesu sì dáhùn ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ṣe bí àwọn ará Galili wọ̀nyí ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀ ju gbogbo àwọn ará Galili lọ, nítorí wọ́n jẹ irú ìyà bá-wọ̀n-ọn-nì? 3 Mo wí fún yín, bẹ́ẹ̀ kọ́: bí kò ṣe pé ẹ̀yin pẹ̀lú ronúpìwàdà, gbogbo yín ni yóò ṣègbé bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́. 4 Tàbí àwọn méjì-dínlógún, tí ilé ìṣọ́ ní Siloamu wó lù, tí ó sì pa wọ́n, ẹ̀yin ṣe bí wọ́n ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀ ju gbogbo àwọn ènìyàn tí ń bẹ ní Jerusalẹmu lọ? 5 Mo wí fún yín, bẹ́ẹ̀ kọ́: bí kò ṣe pé ẹ̀yin ronúpìwàdà, gbogbo yín ni yóò ṣègbé bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́.”
6 (B)Ó sì pa òwe yìí fún wọn pé: “Ọkùnrin kan ní igi ọ̀pọ̀tọ́ kan tí a gbìn sí ọgbà àjàrà rẹ̀; ó sì dé, ó ń wá èso lórí rẹ̀, kò sì rí nǹkan. 7 (C)Ó sì wí fún olùṣọ́gbà rẹ̀ pé, ‘Sá à wò ó, láti ọdún mẹ́ta ni èmi ti ń wá í wo èso lórí igi ọ̀pọ̀tọ́ yìí, èmi kò sì rí nǹkan: ké e lulẹ̀; èéṣe tí ó fi ń gbilẹ̀ lásán pẹ̀lú?’
8 “Ó sì dáhùn ó wí fún un pé, ‘Olúwa, jọ̀wọ́ rẹ̀ ní ọdún yìí pẹ̀lú, títí èmi ó fi tu ilẹ̀ ìdí rẹ̀ yíká, títí èmi ó sì fi bu ìlẹ̀dú sí i: 9 Bí ó bá sì so èso, o dara bẹ́ẹ̀: bí kò bá sì so, ǹjẹ́ lẹ́yìn èyí nì kí ìwọ kí ó ké e lulẹ̀.’ ”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.