Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Fún adarí orin. Fún Jedutuni. Saamu Dafidi.
39 Mo wí pé, “èmi yóò ṣọ́ ọ̀nà mi
kí èmi kí ó má fi ahọ́n mi ṣẹ̀;
èmi yóò fi ìjánu kó ara mi ní ẹnu
níwọ̀n ìgbà tí ènìyàn búburú bá ń bẹ ní iwájú mi.”
2 Mo fi ìdákẹ́ ya odi;
mo tilẹ̀ pa ẹnu mi mọ́ kúrò nínú ọ̀rọ̀ rere;
ìbànújẹ́ mi sì pọ̀ sí i.
3 Àyà mi gbóná ní inú mi.
Nígbà tí mo ń ṣàṣàrò, iná ràn;
nígbà náà ni mo fi ahọ́n mi sọ̀rọ̀:
4 “Olúwa, jẹ́ kí èmi kí ó mọ òpin mi,
àti ìwọ̀n ọjọ́ mi, bí ó ti rí
kí èmi kí o le mọ ìgbà tí mó ní níhìn-ín.
5 Ìwọ ti ṣe ayé mi
bí ìbú àtẹ́lẹwọ́,
ọjọ́ orí mi sì dàbí asán
ní iwájú rẹ:
Dájúdájú olúkúlùkù ènìyàn nínú
ìjókòó rere rẹ̀ jásí asán pátápátá. Sela.
6 “Nítòótọ́ ni olúkúlùkù ń rìn kiri bí òjìji.
Nítòótọ́ ni wọ́n ń yọ ara wọn lẹ́nu lórí asán;
wọ́n ń kó ọrọ̀ jọ,
wọn kò sì mọ ẹni tí yóò ko lọ.
7 “Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí,
Olúwa,
kín ni mo ń dúró dè?
Ìrètí mí ń bẹ ní ọ̀dọ̀ rẹ.
8 Gbà mí lọ́wọ́ ìrékọjá mi gbogbo.
Kí o má sì sọ mí di ẹni ẹ̀gàn
àwọn ènìyàn búburú.
9 Mo dákẹ́ jẹ́ẹ́;
èmi kò sì ya ẹnu mi,
nítorí wí pé ìwọ ni ó ṣe é.
10 Mú pàṣán rẹ kúrò ní ara mi;
èmí ṣègbé tán nípa lílù ọwọ́ rẹ.
11 Ìwọ fi ìbáwí kìlọ̀
fún ènìyàn nítorí ẹ̀ṣẹ̀,
ìwọ a mú ẹwà rẹ parun
bí kòkòrò aṣọ;
nítòótọ́ asán ni ènìyàn gbogbo.
12 “Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa,
kí o sì fetí sí igbe mi;
kí o má ṣe di etí rẹ sí ẹkún mi
nítorí àlejò ni èmi lọ́dọ̀ rẹ
àti àtìpó, bí gbogbo àwọn baba mi ti rí.
13 Dá mi sí, kí èmi lè ní agbára,
kí èmi tó lọ kúrò níhìn-ín yìí,
àti kí èmi ó tó ṣe aláìsí.”
17 Nígbà tí Mose rán wọn lọ láti yẹ ilẹ̀ Kenaani wò, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ gba ọ̀nà gúúsù lọ títí dé àwọn ìlú olókè 18 Ẹ wò ó bí ilẹ̀ náà ti rí, bóyá àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà jẹ́ alágbára tàbí aláìlágbára, bóyá wọ́n pọ̀ tàbí wọn kéré. 19 Irú ilẹ̀ wo ni wọ́n gbé? Ṣé ilẹ̀ tó dára ni àbí èyí tí kò dára? Báwo ni ìlú wọn ti rí? Ṣé ìlú olódi ni àbí èyí tí kò ní odi? 20 Báwo ni ilẹ̀ náà ti rí? Ṣé ilẹ̀ ọlọ́ràá ni tàbí aṣálẹ̀? Ṣé igi wà níbẹ̀ àbí kò sí? E sa ipá yín láti rí i pé ẹ mú díẹ̀ nínú èso ilẹ̀ náà wá.” (Ìgbà náà sì jẹ́ àkókò àkọ́pọ́n èso àjàrà gireepu.)
21 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gòkè lọ láti yẹ ilẹ̀ náà wò, wọ́n lọ láti Aginjù Sini títí dé Rehobu lọ́nà Lebo-Hamati. 22 Wọ́n gba gúúsù lọ sí Hebroni níbi tí Ahimani, Ṣeṣai àti Talmai tí í ṣe irú-ọmọ Anaki ń gbé. (A ti kọ́ Hebroni ní ọdún méje ṣáájú Ṣoani ní Ejibiti.) 23 Nígbà tí wọ́n dé Àfonífojì Eṣkolu, wọ́n gé ẹ̀ka kan tó ní ìdì èso àjàrà gireepu kan. Àwọn méjì sì fi ọ̀pá kan gbé e; wọ́n tún mú èso pomegiranate àti èso ọ̀pọ̀tọ́ pẹ̀lú. 24 Wọ́n sì sọ ibẹ̀ ní Àfonífojì Eṣkolu nítorí ìdì èso gireepu tí àwọn ọmọ Israẹli gé níbẹ̀. 25 Wọ́n padà sílé lẹ́yìn ogójì ọjọ́ tí wọ́n ti lọ yẹ ilẹ̀ náà wò.
Ìròyìn nípa ilẹ̀ tí wọ́n yẹ̀ wò
26 Wọ́n padà wá bá Mose àti Aaroni àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ní ijù Kadeṣi Parani. Wọ́n mú ìròyìn wá fún wọn àti fún gbogbo ìjọ ènìyàn, wọ́n fi èso ilẹ̀ náà hàn wọ́n. 27 Wọ́n sì fún Mose ní ìròyìn báyìí: “A lọ sí ilẹ̀ ibi tí o rán wa, lóòtítọ́ ló sì ń sàn fún wàrà àti fún oyin! Èso ibẹ̀ nìyìí.
Òwe irúgbìn tó kéré jùlọ àti ohun tí n mú ìyẹ̀fun wú
18 (A)Ó sì wí pé, “Kín ni ìjọba Ọlọ́run jọ? Kín ni èmi ó sì fiwé? 19 Ó dàbí hóró musitadi, tí ọkùnrin kan mú, tí ó sì sọ sínú ọgbà rẹ̀; tí ó sì hù, ó sì di igi ńlá; àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ń gbé orí ẹ̀ka rẹ̀.”
20 (B)Ó sì tún wí pé, “Kín ni èmi ìbá fi ìjọba Ọlọ́run wé? 21 Ó dàbí ìwúkàrà, tí obìnrin kan mú, tí ó fi sínú òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun mẹ́ta, títí gbogbo rẹ̀ ó fi di wíwú.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.