Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Dídán ojú Mose
29 (A)Nígbà tí Mose sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè Sinai pẹ̀lú wàláà ẹ̀rí méjì ní ọwọ́ rẹ̀, òun kò mọ̀ pé ojú òun ń dán nítorí ó bá Olúwa sọ̀rọ̀. 30 Nígbà tí Aaroni àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli rí Mose, ojú rẹ̀ ń dán, ẹ̀rù sì ń bà wọ́n láti súnmọ́ ọn. 31 Ṣùgbọ́n Mose pè wọn; Aaroni àti gbogbo àwọn olórí àjọ padà wá bá a, ó sì bá wọn sọ̀rọ̀. 32 Lẹ́yìn èyí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli súnmọ́ ọn, ó sì fún wọn ní gbogbo àṣẹ tí Olúwa fún un lórí òkè Sinai.
33 Nígbà tí Mose parí ọ̀rọ̀ sísọ fún wọn. Ó fi ìbòjú bo ojú rẹ̀. 34 Ṣùgbọ́n nígbàkígbà tí Mose bá wà níwájú Olúwa láti bá a sọ̀rọ̀, á ṣí ìbòjú náà títí yóò fi jáde. Nígbà tí ó bá sì jáde, á sì sọ fún àwọn ọmọ Israẹli ohun tí a ti pàṣẹ fún un, 35 Àwọn ọmọ Israẹli sì rí i pé ojú rẹ̀ ń dán. Mose á sì tún fi ìbòjú bo ojú rẹ̀ títí á fi lọ bá Olúwa sọ̀rọ̀.
99 Olúwa jẹ ọba;
jẹ́ kí ayé kí ó wárìrì
Ó jókòó lórí ìtẹ́ kérúbù
jẹ́ kí ayé kí ó wárìrì.
2 Olúwa tóbi ní Sioni;
Ó sì ga jù gbogbo orílẹ̀-èdè lọ.
3 Kí wọ́n sì yin orúkọ rẹ̀ tí ó tóbi
tí ó ni ẹ̀rù, Mímọ́ ni òun.
4 Ọba ní agbára, ó sì fẹ́ òdodo,
ìwọ fi ìdí àìṣègbè múlẹ̀;
ìwọ ṣe ohun tí ó tọ́ àti ohun tí ó yẹ nínú Jakọbu.
5 Gbígbéga ni Olúwa Ọlọ́run wa
ẹ foríbalẹ̀ níbi ẹsẹ̀ rẹ̀; ó jẹ́ mímọ́.
6 Mose àti Aaroni wà nínú àwọn àlùfáà rẹ̀
Samuẹli wà nínú àwọn tí ó ń ké pe orúkọ rẹ̀
wọ́n ké pe Olúwa, ó sì dá wọn lóhùn.
7 Ó sọ̀rọ̀ sí wọn nínú ọ̀wọ́n àwọsánmọ̀,
wọ́n pa ẹ̀rí rẹ̀ mọ́ àti ìlànà tí ó fún wọn.
8 Olúwa Ọlọ́run wa, ó dá wọn lóhùn;
ó jẹ́ Ọlọ́run tí ó ń dáríjì àwọn ọmọ Israẹli
ìwọ tí ó ń fi ìyà àìṣedéédéé wọn jẹ wọ́n
9 Gbígbéga ni Olúwa Ọlọ́run wa
kí a sìn ín ní òkè mímọ́ rẹ̀
nítorí Olúwa Ọlọ́run wa jẹ́ mímọ́.
12 Ǹjẹ́ nítorí náà bí a tí ní irú ìrètí bí èyí, àwa ń fi ìgboyà púpọ̀ sọ̀rọ̀. 13 Kì í sì í ṣe bí Mose, ẹni tí ó fi ìbòjú bo ojú rẹ̀, ki àwọn ọmọ Israẹli má ba à lè tẹjúmọ́ wíwo òpin èyí tí ń kọjá lọ 14 Ṣùgbọ́n ojú inú wọn fọ́; nítorí pé títí fi di òní olónìí nípa kíka májẹ̀mú láéláé, ìbòjú kan náà ṣì wà láìká kúrò; nítorí pé nínú Kristi ni a tí lè mú ìbòjú náà kúrò. 15 Ṣùgbọ́n títí di òní olónìí, nígbàkúgbà ti a bá ń ka Mose, ìbòjú náà ń bẹ lọ́kàn wọn. 16 Ṣùgbọ́n nígbà ti òun bá yípadà sí Olúwa, a ó mú ìbòjú náà kúrò. 17 (A)Ǹjẹ́ Olúwa ni Ẹ̀mí náà: níbi tí Ẹ̀mí Olúwa bá sì wà, níbẹ̀ ni òmìnira gbé wà 18 Ṣùgbọ́n gbogbo wa ń wo ògo Olúwa láìsí ìbòjú bí ẹni pé nínú àwòjìji, a sì ń pa wa dà sí àwòrán kan náà láti ògo dé ògo, àní bí láti ọ̀dọ̀ Olúwa tí í ṣe Ẹ̀mí.
Ìṣúra nínú ohun-èlò amọ̀
4 Nítorí náà, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé nípa àánú Ọlọ́run ni a rí iṣẹ́ ìránṣẹ́ yìí gba, àárẹ̀ kò mú ọkàn wa rara; 2 Ṣùgbọ́n àwa tí kọ gbogbo ohun ìkọ̀kọ̀ tí ó ní ìtìjú sílẹ̀, àwa kò rìn ní ẹ̀tàn, bẹ́ẹ̀ ni àwa kò fi ọwọ́ ẹ̀tàn mú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run; ṣùgbọ́n nípa fífi òtítọ́ hàn, àwa ń fi ara wa le ẹ̀rí ọkàn olúkúlùkù ènìyàn lọ́wọ́ níwájú Ọlọ́run.
Ìràpadà
28 (A)(B) Ó sì ṣe bí ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́jọ lẹ́yìn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó mú Peteru àti Johanu àti Jakọbu, ó gun orí òkè lọ láti lọ gbàdúrà. 29 Bí ó sì ti ń gbàdúrà, àwọ̀ ojú rẹ̀ yípadà, aṣọ rẹ̀ sì funfun gbòò, 30 (C)Sì kíyèsi i, àwọn ọkùnrin méjì, Mose àti Elijah, wọ́n ń bá a sọ̀rọ̀: 31 Tí wọ́n fi ara hàn nínú ògo, wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ ikú rẹ̀, tí òun yóò ṣe parí ní Jerusalẹmu. 32 (D)Ṣùgbọ́n ojú Peteru àti ti àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ wúwo fún oorun. Nígbà tí wọ́n sì tají, wọ́n rí ògo rẹ̀, àti ti àwọn ọkùnrin méjèèjì tí ó bá a dúró. 33 (E)Ó sì ṣe, nígbà tí wọ́n lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, Peteru wí fún Jesu pé, “Olùkọ́, ó dára fún wa kí a máa gbé ìhín yìí: jẹ́ kí àwa pa àgọ́ mẹ́ta; ọ̀kan fún ìwọ, àti ọ̀kan fún Mose, àti ọ̀kan fún Elijah.” (Kò mọ èyí tí òun ń wí.)
34 Bí ó ti ń sọ báyìí, ìkùùkuu kan wá, ó ṣíji bò wọ́n: ẹ̀rù sì bà wọ́n nígbà tí wọ́n ń wọ inú ìkùùkuu lọ. 35 (F)Ohùn kan sì ti inú ìkùùkuu wá wí pé, “Èyí yìí ni àyànfẹ́ ọmọ mi: ẹ máa gbọ́ tirẹ̀.” 36 (G)Nígbà tí ohùn náà sì dákẹ́, Jesu nìkan ṣoṣo ni a rí. Wọ́n sì pa á mọ́, wọn kò sì sọ ohunkóhun tí wọ́n rí fún ẹnikẹ́ni ní ọjọ́ wọ̀nyí.
Ìwòsàn ọmọkùnrin kan tí o ní ẹ̀mí èṣù
37 (A)Ó sì ṣe, ní ọjọ́ kejì, nígbà tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ wá láti orí òkè, ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn wá pàdé rẹ̀. 38 Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan nínú ìjọ ènìyàn kígbe sókè, pé “Olùkọ́ mo bẹ̀ ọ́, wo ọmọ mi: nítorí ọmọ mi kan ṣoṣo náà ni. 39 Sì kíyèsi i, ẹ̀mí èṣù a máa mú un, a sì máa kígbe lójijì; a sì máa nà án tàntàn títí yóò fi yọ ìfófó lẹ́nu, a máa pa á lára, kì í tilẹ̀ ń fẹ́ fi í sílẹ̀ lọ. 40 Mo sì bẹ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ láti lé e jáde: wọn kò sì lè ṣe é.”
41 Jesu sì dáhùn pé, “Ìran aláìgbàgbọ́ àti àrékérekè, èmi ó ti bá yín gbé pẹ́ tó? Èmi yóò sì ti ṣe sùúrù fún yín pẹ́ tó? Fa ọmọ rẹ wá níhìn-ín yìí.”
42 Bí ó sì ti ń bọ̀, ẹ̀mí èṣù náà gbé e ṣánlẹ̀, ó sì nà án tàntàn. Jesu sì bá ẹ̀mí àìmọ́ náà wí, ó sì mú ọmọ náà láradá, ó sì fà á lé baba rẹ̀ lọ́wọ́. 43 (B)Ẹnu sì ya gbogbo wọn sí iṣẹ́ títóbi Ọlọ́run, ṣùgbọ́n nígbà tí hà sì ń ṣe gbogbo wọn sí ohun gbogbo tí Jesu ṣe, ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé,
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.