Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Deuteronomi 26:1-11

Àkọ́so àti ìdámẹ́wàá

26 (A)Nígbà tí ìwọ bá wọ ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fi fún ọ gẹ́gẹ́ bí ohun ìní tí ìwọ sì ti jogún, tí ìwọ sì ti ń gbé níbẹ̀, mú díẹ̀ nínú ohun tí o pèsè láti inú erùpẹ̀ ilẹ̀ náà tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fi fún ọ, kó wọn sínú agbọ̀n. Nígbà náà kí o lọ sí ibi tí Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò yàn gẹ́gẹ́ bí ibi tí orúkọ rẹ̀ yóò máa gbé. Kí o sì sọ fun àlùfáà tí ó wà ní ibi iṣẹ́ ní àsìkò náà, pé “Mo sọ ọ́ di mí mọ̀ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ pé mo ti wá sí ilẹ̀ tí Olúwa búra fún àwọn baba wa.” Àlùfáà yóò gbé agbọ̀n náà kúrò ní ọwọ́ rẹ, yóò sì gbé e kalẹ̀ níwájú pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run rẹ. Nígbà náà ni ìwọ yóò sọ ní iwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ pé, “Baba mi jẹ́ alárìnkiri ará Aramu, ó sì sọ̀kalẹ̀ wá sí Ejibiti pẹ̀lú ènìyàn díẹ̀, ó sì ń gbé níbẹ̀, ó sì wá di orílẹ̀-èdè olókìkí, alágbára, tí ó kún fún ọ̀pọ̀ ènìyàn. Ṣùgbọ́n àwọn ará Ejibiti ṣe àìdára sí wa, wọ́n jẹ wá ní yà, wọ́n fún wa ní iṣẹ́ líle ṣe. Nígbà náà ni a kégbe pe Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wa, Olúwa sì gbọ́ ohùn wa, ó sì rí ìrora, làálàá àti ìnira wa. Nígbà náà ni Olúwa mú wa jáde wá láti Ejibiti pẹ̀lú ọwọ́ agbára àti apá nínà, pẹ̀lú ẹ̀rù ńlá àti iṣẹ́ ààmì àti iṣẹ́ ìyanu. Ó mú wa wá síbí, ó sì fún wa ní ilẹ̀ yìí, ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin; 10 àti pé ní báyìí, mo mú àkọ́so ilẹ̀ tí ìwọ Olúwa ti fún mi wá.” Ìwọ yóò gbé agbọ̀n náà síwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ, kí o sì wólẹ̀ níwájú u rẹ̀. 11 Ìwọ àti àwọn ọmọ Lefi àti àjèjì láàrín yín yóò máa yọ̀ nínú gbogbo oore tí Olúwa ti fi fún ọ àti fún àwọn ará ilé rẹ.

Saamu 91:1-2

91 Ẹni tí ó gbé ibi ìkọ̀kọ̀ Ọ̀gá-ògo
    ni yóò sinmi ní ibi òjìji Olódùmarè.
Èmi yóò sọ nípa ti Olúwa pé,
    “Òun ni ààbò àti odi mi,
    Ọlọ́run mi, ẹni tí èmi gbẹ́kẹ̀lé”.

Saamu 91:9-16

Nítorí ìwọ fi Olúwa ṣe ààbò rẹ,
    ìwọ fi Ọ̀gá-ògo ṣe ibùgbé rẹ.
10 Búburú kan ki yóò ṣubú lù ọ́
    Bẹ́ẹ̀ ni ààrùnkárùn kì yóò súnmọ́ ilé rẹ.
11 (A)Nítorí yóò fi àṣẹ fún àwọn angẹli nípa tìrẹ
    láti pa ọ́ mọ́ ní gbogbo ọ̀nà rẹ;
12 Wọn yóò gbé ọ sókè ní ọwọ́ wọn,
    nítorí kí ìwọ má ba à fi ẹsẹ̀ rẹ gún òkúta.
13 (B)Ìwọ yóò rìn lórí kìnnìún àti paramọ́lẹ̀;
    ìwọ yóò tẹ kìnnìún ńlá àti ejò ńlá ni ìwọ yóò fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀.

14 “Nítorí ti ìfẹ́ rẹ sí mi, èmi yóò gbà ọ́;
    èmi yóò pa ọ́ mọ́, nítorí ìwọ jẹ́wọ́ orúkọ mi.
15 Òun yóò pè mí, èmi yóò sì dá a lóhùn;
    èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìpọ́njú,
    èmi yóò gbà á, èmi yóò sì bu ọlá fún un
16 Pẹ̀lú ẹ̀mí gígùn ni èmi yóò fi tẹ́ ẹ lọ́rùn
    èmi yóò sì fi ìgbàlà mi hàn án.”

Romu 10:8-13

(A)Ṣùgbọ́n kí ni ó wí? “Ọ̀rọ̀ náà wà létí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ní ẹnu rẹ̀, àti ní ọkàn rẹ̀,” èyí nì ni ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́, tí àwa ń wàásù; (B)Pé, bí ìwọ bá fi ẹnu rẹ̀ jẹ́wọ́ “Jesu ní Olúwa,” tí ìwọ si gbàgbọ́ ní ọkàn rẹ pé, Ọlọ́run jí i dìde kúrò nínú òku, a ó gbà ọ́ là. 10 Nítorí ọkàn ni a fi ìgbàgbọ́ sí òdodo; ẹnu ni a sì ń fi ìjẹ́wọ́ sí ìgbàlà. 11 (C)Nítorí ìwé Mímọ́ wí pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà a gbọ́ ojú kò yóò tì í.” 12 (D)Nítorí kò si ìyàtọ̀ nínú Júù àti Helleni: nítorí Olúwa kan náà ni Olúwa gbogbo wọn, o si pọ̀ ni ọrọ̀ fún gbogbo àwọn ti ń ké pe e. 13 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá sá à ti pe orúkọ Olúwa ni a ó gbàlà.”

Luku 4:1-13

Ìdánwò Jesu

(A)Jesu sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó padà ti Jordani wá, a sì ti ọwọ́ Ẹ̀mí darí rẹ̀ sí ijù; (B)Ogójì ọjọ́ ni a fi dán an wò lọ́wọ́ èṣù. Kò sì jẹ ohunkóhun ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì: nígbà tí wọ́n sì parí, lẹ́yìn náà ni ebi wá ń pa á.

Èṣù sì wí fún un pé, “Bí ìwọ bá ṣe Ọmọ Ọlọ́run, pàṣẹ fún òkúta yìí kí ó di àkàrà.”

(C)Jesu sì dáhùn, ó wí fún un pé, “A ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Ènìyàn kì yóò wà láààyè nípa àkàrà nìkan.’ ”

Lójúkan náà, èṣù sì mú un lọ sí orí òkè gíga, ó sì fi gbogbo ilẹ̀ ọba ayé hàn án. (D)Èṣù sì wí fún un pé, “Ìwọ ni èmi ó fi gbogbo agbára yìí àti ògo wọn fún: nítorí á sá ti fi fún mi. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì wù mí, èmi a fi í fún. Ǹjẹ́ bí ìwọ bá foríbalẹ̀ fún mi, gbogbo rẹ̀ ni yóò jẹ́ tìrẹ.”

(E)Jesu sì dáhùn ó sì wí fún un pé, “Kúrò lẹ́yìn mi, Satani, nítorí tí a kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ìwọ foríbalẹ̀ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, òun nìkan ṣoṣo ni kí ìwọ kí ó sì máa sìn.’ ”

Èṣù sì mú un lọ sí Jerusalẹmu, ó sì gbé e lé ibi ṣóńṣó tẹmpili, ó sì wí fún un pé, “Bí ìwọ bá ṣe Ọmọ Ọlọ́run, bẹ́ sílẹ̀ fún ara rẹ láti ibí yìí: 10 (F)A sá ti kọ̀wé rẹ̀ pé:

“ ‘Yóò pàṣẹ fún àwọn angẹli rẹ̀ nítorí rẹ,
    láti máa ṣe ìtọ́jú rẹ:
11 Àti pé ní ọwọ́ wọn ni wọn ó gbé ọ sókè,
    kí ìwọ kí ó má ba à fi ẹsẹ̀ rẹ gbún òkúta.’ ”

12 (G)Jesu sì dáhùn ó wí fún un pé, “A ti kọ́ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ dán Olúwa Ọlọ́run rẹ wò.’ ”

13 (H)Nígbà tí èṣù sì parí ìdánwò náà gbogbo, ó fi í sílẹ̀ lọ fun sá à kan.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.