Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 17

Àdúrà ti Dafidi

17 Gbọ́, Olúwa, ẹ̀bẹ̀ òtítọ́ mi;
    fi etí sí igbe mi.
Tẹ́tí sí àdúrà mi
    tí kò ti ètè ẹ̀tàn jáde.
Kí ìdáláre mi wá láti ọ̀dọ̀ rẹ;
    kí ojú rẹ kí ó rí ohun tí ó tọ́.

Ìwọ ti dán àyà mi wò,
    ìwọ sì bẹ̀ mí wò ní òru, o sì ti wádìí mi,
ìwọ kì yóò rí ohunkóhun èmi ti pinnu pé,
    ẹnu mi kì yóò ṣẹ̀.
Bí ó ṣe ti iṣẹ́ ènìyàn nípa ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ,
    èmi ti pa ara mi mọ́
    kúrò ní ọ̀nà àwọn ìkà.
Ìrìn mí ti jẹ mọ́ ọ̀nà rẹ;
    ẹsẹ̀ mi kì yóò yọ̀.

Èmi ké pè ọ́, Ọlọ́run, nítorí tí ìwọ yóò dá mi lóhùn
    dẹ etí rẹ sí mi kí o sì gbọ́ àdúrà mi.
Fi ìṣeun ìyanu ìfẹ́ ńlá rẹ hàn
    ìwọ tí ó fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ gba àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ là
    lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá tí ó dìde sí wọn.
Pa mí mọ́ bí ẹyin ojú rẹ;
    fi mí pamọ́ sí abẹ́ òjìji ìyẹ́ apá rẹ,
lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú tí ń fóròó mi,
    kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá apani tí ó yí mi ká.

10 Wọ́n pa ọkàn aláìláàánú wọn mọ́,
    wọ́n sì fi ẹnu wọn sọ̀rọ̀ ìgbéraga.
11 Wọ́n sì mú mi mọ́lẹ̀, wọ́n sì yí mi ká,
    pẹ̀lú ojú ìṣọ́ra láti ṣọ́ mi sílẹ̀.
12 Wọn dàbí i kìnnìún tí ebi ń pa fún ìjẹ,
    àní bí kìnnìún ńlá tí ó ń ba níbi ìkọ̀kọ̀.

13 Dìde, Olúwa, dojúkọ wọ́n, rẹ̀ wọ́n sílẹ̀;
    gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹni búburú nípa idà rẹ.
14 Olúwa, nípa ọwọ́ rẹ, gbà mí kúrò lọ́wọ́ irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀,
    kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn ayé yìí, tí èrè wọn wà nínú ayé yìí.
Ìwọ ń pa ebi àwọn tí ìwọ fẹ́ràn lẹ́nu mọ́;
    àwọn ọmọ wọn sì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀,
    wọ́n sì kó ọrọ̀ jọ fún àwọn ọmọ wọn.

15 Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi yóò máa wo ojú rẹ ní òdodo;
    nígbà tí èmi bá jí, èmi yóò ní ìtẹ́lọ́rùn nígbà tí èmi bá rí àwòrán rẹ.

1 Kronika 21:1-17

Dafidi ṣe ètò ìkànìyàn

21 Satani sì dúró ti Israẹli, ó sì ti Dafidi láti ka iye Israẹli. Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi sì wí fún Joabu àti àwọn olórí àwọn ènìyàn pé, “Lọ kí o ka iye àwọn ọmọ Israẹli láti Beerṣeba títí dé Dani. Kí o sì padà mú iye wọn fún mi wa, kí èmi kí ó le mọ iye tí wọ́n jẹ́.”

Ṣùgbọ́n Joabu dá a lóhùn pé, “Kí Olúwa kí ó mú àwọn ènìyàn rẹ̀ pọ̀ sí ní ìgbà ọgọ́rùn-ún ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, ọba olúwa mi, gbogbo wọn kì í ha ṣe ìránṣẹ́ olúwa ni? Kí ni ó dé tí olúwa mi ṣe fẹ́ ṣè yìí? Kí ni ó de tí yóò fi mú ẹ̀bi wá sórí Israẹli?”

Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ọba borí tí Joabu. Bẹ́ẹ̀ ni Joabu jáde lọ, ó sì la gbogbo Israẹli já, ó sí dé Jerusalẹmu. Joabu sì fi àpapọ̀ iye àwọn ènìyàn náà fún Dafidi. Ní gbogbo Israẹli, ó sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ̀rún àti ọ̀kẹ́ márùn-ún ènìyàn (1,100,000) tí ń kọ́ idà, Juda sì jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́tàlélógún lé ẹgbàárùn-ún ọkùnrin tí ń kọ́ idà.

Ṣùgbọ́n Joabu kó àwọn Lefi àti Benjamini mọ́ iye wọn, nítorí àṣẹ ọba jẹ́ ìríra fún un. Àṣẹ yìí pẹ̀lú sì jẹ́ búburú lójú Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni ó sì díyàjẹ Israẹli.

Nígbà náà Dafidi sọ fún Ọlọ́run pé, Èmi ti dẹ́ṣẹ̀ gidigidi nípa ṣíṣe èyí. Nísinsin yìí, èmi bẹ̀ ọ́, mú ìjẹ̀bi àwọn ìránṣẹ́ rẹ kúrò. Èmi ti hùwà aṣiwèrè gidigidi.

Olúwa sì fi fún Gadi, aríran Dafidi pé. 10 “Lọ kí o sì wí fún Dafidi pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí, èmi fi nǹkan mẹ́ta lọ̀ ọ́; yan ọ̀kan nínú wọn, kí èmi ó sì ṣe é sí ọ.’ ”

11 Bẹ́ẹ̀ ni Gadi tọ Dafidi wá, ó sì wí fún un pé, “Báyìí ni Olúwa wí: ‘Yan fún ara rẹ: 12 Ọdún mẹ́ta ìyàn, tàbí ìparun ní oṣù mẹ́ta níwájú àwọn ọ̀tá rẹ, pẹ̀lú idà wọn láti lé ọ bá, tàbí ọjọ́ mẹ́ta idà Olúwa ọjọ́ àjàkálẹ̀-ààrùn ní ilẹ̀ náà, pẹ̀lú àwọn angẹli Olúwa láti pa gbogbo agbègbè Israẹli run.’ Nísinsin yìí ǹjẹ́, rò ó wò, èsì wo ni èmi yóò mú padà tọ ẹni tí ó rán mi.”

13 Dafidi sì wí fún Gadi pé, “Ìyọnu ńlá bá mi. Jẹ́ kí èmi kí ó ṣubú sí ọwọ́ Olúwa nísinsin yìí, nítorí tí àánú rẹ̀ pọ̀ gidigidi; Ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí èmi kí o ṣubú sí ọwọ́ àwọn ènìyàn.”

14 Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa rán àjàkálẹ̀-ààrùn lórí Israẹli, àwọn tí ó ṣubú ní Israẹli jẹ́ ẹgbàá-márùn-dínlógójì (70,000) ènìyàn. 15 Ọlọ́run sì rán angẹli kan sí Jerusalẹmu láti pa wọ́n run. Ṣùgbọ́n bí angẹli ti ń pa wọ́n run, Olúwa sì wò. Ó sì káàánú nítorí ibi náà, ó sì wí fún angẹli tí ó pa àwọn ènìyàn náà run pé, “Ó ti tó! Dá ọwọ́ rẹ dúró.” Angẹli Olúwa náà sì dúró níbi ilẹ̀ ìpakà Arauna ará Jebusi.

16 Dafidi sì wòkè ó sì rí angẹli Olúwa dúró láàrín ọ̀run àti ayé pẹ̀lú idà fífàyọ ní ọwọ́ rẹ̀ tí ó sì nà án sórí Jerusalẹmu. Nígbà náà Dafidi àti àwọn àgbàgbà, sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀, wọ́n sì da ojú wọn bolẹ̀.

17 Dafidi sì wí fún Ọlọ́run pé, “Èmi ha kọ́ ni mo pàṣẹ àti ka àwọn jagunjagun ènìyàn? Èmi ni ẹni náà tí ó dẹ́ṣẹ̀ tí ó sì ṣe ohun búburú pàápàá, ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti àgùntàn wọ̀nyí, kí ni wọ́n ṣe? Èmí bẹ̀ ọ́ Olúwa Ọlọ́run mi, jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó wà lára mi àti àwọn ìdílé baba mi, ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí àjàkálẹ̀-ààrùn yìí kí ó dúró lórí àwọn ènìyàn rẹ.”

1 Johanu 2:1-6

(A)Ẹ̀yin ọmọ mi ọ̀wọ́n, mo kọ ìwé nǹkan wọ̀nyí sí yín, kí ẹ̀yin má bà á dẹ́ṣẹ̀. Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni bá sì dẹ́ṣẹ̀, àwa ni alágbàwí lọ́dọ̀ Baba: Jesu Kristi, olódodo nìkan. (B)Òun sì ní ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ wa, kì í tilẹ̀ ṣe fún tiwa nìkan ṣùgbọ́n fún ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo aráyé.

Àwa mọ̀ pé àwa ti wá mọ̀ ọ́n, bí àwa bá ń pa òfin rẹ̀ mọ́. (C)Ẹni tí ó bá wí pé, “Èmi mọ̀ ọ́n,” tí kò sì pa òfin rẹ̀ mọ́, èké ni, òtítọ́ kò sì ṣí nínú rẹ̀. (D)Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá ń pa òfin rẹ̀ mọ́, lára rẹ̀ ni a gbé mú ìfẹ́ Ọlọ́run pé nítòótọ́. Nípa èyí ni àwa mọ̀ pé àwa ń wà nínú rẹ̀. (E)Ẹnikẹ́ni tí ó bá wí pé òun ń gbé inú rẹ̀, òun náà pẹ̀lú sì yẹ láti máa rìn gẹ́gẹ́ bí Jesu ti rìn.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.