Add parallel Print Page Options

Jesu jẹ́ Ọ̀dọ́-Àgùntàn Ọlọ́run

29 (A)Ní ọjọ́ kejì, Johanu rí Jesu tí ó ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Wò ó, Ọ̀dọ́-àgùntàn Ọlọ́run, ẹni tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ!

Read full chapter

14 (A)Bí Mose sì ti gbé ejò sókè ní aginjù, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni a kò le ṣe aláìgbé Ọmọ Ènìyàn sókè pẹ̀lú: 15 Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́, kí ó má bà á ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó le ní ìyè àìnípẹ̀kun.”

16 (B)“Nítorí Ọlọ́run fẹ́ aráyé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, tí ó fi ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo fún ni, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́, má bà á ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.

Read full chapter

51 Kì í ṣe fún ara rẹ̀ ni ó sọ èyí ṣùgbọ́n bí ó ti jẹ́ olórí àlùfáà ní ọdún náà, ó sọtẹ́lẹ̀ pé, Jesu yóò kú fún orílẹ̀-èdè náà: 52 (A)Kì sì í ṣe kìkì fún orílẹ̀-èdè náà nìkan, ṣùgbọ́n fún àwọn ọmọ Ọlọ́run tí ó fọ́nká kiri, kí ó le kó wọn papọ̀, kí ó sì sọ wọ́n di ọ̀kan.

Read full chapter

10 (A)Nínú èyí ni ìfẹ́ wà, kì í ṣe pé àwa fẹ́ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n òun fẹ́ wá, ó sì rán Ọmọ rẹ̀ láti jẹ́ ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ wa.

Read full chapter