Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 39

Fún adarí orin. Fún Jedutuni. Saamu Dafidi.

39 Mo wí pé, “èmi yóò ṣọ́ ọ̀nà mi
    kí èmi kí ó má fi ahọ́n mi ṣẹ̀;
èmi yóò fi ìjánu kó ara mi ní ẹnu
    níwọ̀n ìgbà tí ènìyàn búburú bá ń bẹ ní iwájú mi.”
Mo fi ìdákẹ́ ya odi;
    mo tilẹ̀ pa ẹnu mi mọ́ kúrò nínú ọ̀rọ̀ rere;
ìbànújẹ́ mi sì pọ̀ sí i.
    Àyà mi gbóná ní inú mi.
Nígbà tí mo ń ṣàṣàrò, iná ràn;
    nígbà náà ni mo fi ahọ́n mi sọ̀rọ̀:

Olúwa, jẹ́ kí èmi kí ó mọ òpin mi,
    àti ìwọ̀n ọjọ́ mi, bí ó ti rí
    kí èmi kí o le mọ ìgbà tí mó ní níhìn-ín.
Ìwọ ti ṣe ayé mi
    bí ìbú àtẹ́lẹwọ́,
ọjọ́ orí mi sì dàbí asán
    ní iwájú rẹ:
Dájúdájú olúkúlùkù ènìyàn nínú
    ìjókòó rere rẹ̀ jásí asán pátápátá. Sela.

“Nítòótọ́ ni olúkúlùkù ń rìn kiri bí òjìji.
    Nítòótọ́ ni wọ́n ń yọ ara wọn lẹ́nu lórí asán;
wọ́n ń kó ọrọ̀ jọ,
    wọn kò sì mọ ẹni tí yóò ko lọ.

“Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí,
    Olúwa,
kín ni mo ń dúró dè?
    Ìrètí mí ń bẹ ní ọ̀dọ̀ rẹ.
Gbà mí lọ́wọ́ ìrékọjá mi gbogbo.
    Kí o má sì sọ mí di ẹni ẹ̀gàn
àwọn ènìyàn búburú.
Mo dákẹ́ jẹ́ẹ́;
    èmi kò sì ya ẹnu mi,
nítorí wí pé ìwọ ni ó ṣe é.
10 Mú pàṣán rẹ kúrò ní ara mi;
    èmí ṣègbé tán nípa lílù ọwọ́ rẹ.
11 Ìwọ fi ìbáwí kìlọ̀
    fún ènìyàn nítorí ẹ̀ṣẹ̀,
ìwọ a mú ẹwà rẹ parun
    bí kòkòrò aṣọ;
nítòótọ́ asán ni ènìyàn gbogbo.

12 “Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa,
    kí o sì fetí sí igbe mi;
kí o má ṣe di etí rẹ sí ẹkún mi
    nítorí àlejò ni èmi lọ́dọ̀ rẹ
àti àtìpó, bí gbogbo àwọn baba mi ti rí.
13 Dá mi sí, kí èmi lè ní agbára,
    kí èmi tó lọ kúrò níhìn-ín yìí,
    àti kí èmi ó tó ṣe aláìsí.”

Esekiẹli 17:1-10

Ẹyẹ idì méjì àti àjàrà

17 Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ ní wá wí pé: “Ọmọ ènìyàn pa àlọ́ kan, sì pa òwe kan fún ilé Israẹli. Sọ fún wọn pé, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Idì ńlá kan tó ní apá títóbi àti ìyẹ́ gígùn tó kún fún àwọ̀ oríṣìíríṣìí wa si Lebanoni, ó sì mu ẹ̀ka igi Kedari tó ga jùlọ, ó gé ọ̀mùnú orí ẹ̀ka yìí kúrò, ó mú un lọ sí ilẹ̀ oníṣòwò, ó sì gbìn ín sí ìlú àwọn oníṣòwò.

“ ‘Ó mú lára irúgbìn ilẹ̀ náà, ó gbìn ín sí ilẹ̀ ọlọ́ràá, lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi, ó gbìn ín bí igi wílóò. Ó dàgbà, ó sì di àjàrà tó kúrú ṣùgbọ́n to bolẹ̀. Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ kọjú sí i, gbòǹgbò rẹ̀ sì dúró lábẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó di àjàrà, ó sì mu ẹ̀ka àti ewé jáde.

“ ‘Ṣùgbọ́n ẹyẹ idì ńlá mìíràn tún wá, tó ní apá títóbi pẹ̀lú ìyẹ́ púpọ̀. Gbòǹgbò àjàrà náà sì ta lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ láti orí ilẹ̀ tí wọn gbìn ín sí, ó wá pẹ̀ka lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ kí ó le fún un ni omi. Orí ilẹ̀ tó dára lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi ni a gbìn ín sí, kí ó bá à le pẹ̀ka, kò sì so èso, ó sì wá di igi àjàrà tó lọ́lá púpọ̀.’

“Sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Olúwa Olódùmarè wí nìyí: Yóò wá gbilẹ̀ bí? A kò wá ní i wú gbòǹgbò rẹ̀, ki a si gé èso rẹ̀ kúrò kí ó bá à le rọ? Gbogbo ewé rẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ ni yóò rẹ̀. Kò sì nígbà agbára tàbí ènìyàn púpọ̀ láti fà gbòǹgbò rẹ̀ tu. 10 Bí a tilẹ̀ tún un gbìn, yóò wa gbilẹ̀ bí? Kò wá ní i rọ pátápátá nígbà ti afẹ́fẹ́ láti ìlà-oòrùn bá kọlù ú. Gbogbo ewé rẹ̀ yóò rẹ̀ lórí ilẹ̀ tó ti dàgbà?’ ”

Romu 2:12-16

12 (A)Gbogbo àwọn tí ó ṣẹ̀ ní àìlófin wọn ó sì ṣègbé láìlófin: àti iye àwọn tí ó ṣẹ̀ lábẹ́ òfin, àwọn ni a ó fi òfin dá lẹ́jọ́; 13 (B)Nítorí kì í ṣe àwọn olùgbọ́ òfin ni ẹni ìdáláre lọ́dọ̀ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n àwọn olùṣe òfin ni a ó dá láre. 14 Nítorí nígbà tí àwọn aláìkọlà, tí kò ní òfin, bá ṣe ohun tí ó wà nínú òfin nípa ìwà ẹ̀dá, àwọn wọ̀nyí, jẹ́ òfin fún ara wọn bí wọn kò tilẹ̀ ní òfin. 15 Àwọn ẹni tí ó fihàn pé, a kọ̀wé iṣẹ́ òfin sí wọn lọ́kàn, tí ẹ̀rí ọkàn wọn pẹ̀lú sì tún ń jẹ́ wọn lẹ́rìí, àti pé, èrò ọkàn wọn tí ó jẹ́ ọ̀nà ìfinisùn, sì ń gbè wọ́n lẹ́yìn ní ìsinsin yìí. 16 (C)Èyí yóò farahàn ní ọjọ́ náà nígbà tí Ọlọ́run yóò tipasẹ̀ Jesu Kristi ṣe ìdájọ́ àwọn àṣírí ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ìhìnrere mi.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.