Add parallel Print Page Options

(A)Olúwa wí fún Mose pé, “Èmi ti rí àwọn ènìyàn wọ̀nyí, wọ́n sì jẹ́ ọlọ́rùn líle ènìyàn. 10 Ǹjẹ́ nísinsin yìí fi mí sílẹ̀, nítorí kí ìbínú mi lè gbóná sí wọn, kí èmi sì lè pa wọ́n run. Nígbà náà ni èmi yóò sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá.”

11 Ṣùgbọ́n Mose kígbe fún ojúrere Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, ó wí pé, “Olúwa, èéṣe tí ìbínú rẹ yóò ṣe gbóná sí àwọn ènìyàn rẹ, tí ìwọ mú jáde láti Ejibiti wá pẹ̀lú agbára ńlá àti ọwọ́ agbára? 12 Èéṣe tí àwọn ará Ejibiti yóò ṣe wí pé, ‘Nítorí ibi ni ó ṣe mọ̀ ọ́n mọ̀ mú wọn jáde, láti pa wọ́n ní orí òkè àti láti gbá wọn kúrò lórí ayé’? Yípadà kúrò nínú ìbínú rẹ tí ó múná, yí ọkàn padà, kí o má sì ṣe mú ìparun wá sórí àwọn ènìyàn rẹ. 13 Rántí àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ Abrahamu, Isaaki àti Israẹli, ẹni tí ìwọ búra fún fúnrarẹ̀: ‘tí o wí fún wọn pé, èmi yóò mú irú-ọmọ rẹ pọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, èmi yóò sì fún irú-ọmọ rẹ ní gbogbo ilẹ̀ tí mo ti pinnu fún wọn, yóò sì jẹ́ ogún ìní wọn láéláé.’ ” 14 Nígbà náà ni Olúwa dáwọ́ ìbínú rẹ̀ dúró, kò sì mú ìparun náà tí ó sọ wá sórí àwọn ènìyàn rẹ̀ mọ́.

Read full chapter

31 Bẹ́ẹ̀ ni Mose padà tọ Olúwa lọ, ó sì wí pé, “Yé, kí ni ẹ̀ṣẹ̀ ńlá tí àwọn ènìyàn ti dá yìí! Wọ́n ti ṣe òrìṣà wúrà fún ara wọn. 32 (A)Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, jọ̀wọ́ dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n ṣùgbọ́n tí kò bá sì ṣe bẹ́ẹ̀, pa orúkọ mi rẹ́ kúrò nínú ìwé tí ìwọ ti kọ.”

33 Olúwa dá Mose lóhùn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá dẹ́ṣẹ̀ sí mi, èmi yóò pa á rẹ́ kúrò nínú ìwé mi. 34 Ǹjẹ́ nísinsin yìí lọ, máa darí àwọn ènìyàn yìí lọ sí ibi ti mo sọ, angẹli mi yóò sì máa lọ ṣáájú yín. Ìgbà ń bọ̀ fún mi tì èmi yóò ṣe ìbẹ̀wò, èmi yóò fi yà jẹ wọ́n fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”

35 Olúwa sì yọ àwọn ènìyàn náà lẹ́nu, pẹ̀lú ààrùn nítorí ohun tí wọ́n ṣe ní ti ẹgbọrọ màlúù tí Aaroni ṣe.

Read full chapter