Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 56

Fún adarí orin. Ti ohùn “Àdàbà lórí Óákù òkè réré.” Ti Dafidi. Miktamu. Nígbà tí àwọn ará Filistini ka mọ́ ní Gati.

56 Ṣàánú fún mi, Ọlọ́run, nítorí àwọn ènìyàn ń fi ìgbónára lépa mi;
    ní gbogbo ọjọ́ ni wọn ń kọjú ìjà
    sí mi, wọn ń ni mi lára.
Àwọn ọ̀tá mi ń lé mi ní gbogbo ọjọ́,
    àwọn ènìyàn ń kọjú ìjà sí mi nínú ìgbéraga wọn.

Nígbà tí ẹ̀rù bà ń bà mí,
    èmi o gbẹ́kẹ̀lé ọ.
Nínú Ọlọ́run èmi yóò máa yìn ọ̀rọ̀ rẹ,
    nínú Ọlọ́run ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi; ẹ̀rù kì yóò bà mí
kí ni ẹran-ara lè ṣe sí mi?

Wọn ń yí ọ̀rọ̀ mí ní gbogbo ọjọ́,
    wọn ń gbèrò nígbà gbogbo láti ṣe mí níbi.
Wọn kó ara wọn jọ, wọ́n ba
    Wọ́n ń ṣọ́ ìgbésẹ̀ mi
wọn ń làkàkà láti gba ẹ̀mí mi.
San ẹ̀san iṣẹ́ búburú wọ́n fún wọn;
    Ní ìbínú rẹ, Ọlọ́run, wọ́ àwọn ènìyàn náà bọ́ sílẹ̀.

Kọ ẹkún mi sílẹ̀;
    kó omijé mi sí ìgò rẹ,
wọ́n kò ha sí nínú ìkọ̀sílẹ̀ rẹ bí?
Nígbà náà ni àwọn ọ̀tá mi yóò pẹ̀yìndà
    nígbà tí mo bá pè fún ìrànlọ́wọ́
    nípa èyí ni mo mọ̀ pé Ọlọ́run ń bẹ fún mi.

10 Nínú Ọlọ́run, ẹni tí mo yìn ọ̀rọ̀ rẹ̀
    nínú Olúwa, ẹni tí mo yin ọ̀rọ̀ rẹ̀:
11 Nínú Ọlọ́run ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi:
    ẹ̀rù kì yóò bà mí.
Kí ni ènìyàn lè ṣe sí mi?

12 Mo jẹ́ ẹ̀jẹ́ lábẹ́ rẹ Ọlọ́run:
    èmi o mú ìyìn mi wá fún ọ.
13 Nítorí ìwọ tí gbà mí lọ́wọ́ ikú
    àti ẹsẹ̀ mi lọ́wọ́ ìṣubú,
kí èmí lè máa rìn níwájú Ọlọ́run
    ní ìmọ́lẹ̀ àwọn alààyè.

Jeremiah 1:11-19

11 Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ mí wá wí pé:

“Kí ni o rí Jeremiah?”

Mo sì dáhùn wí pé “Mo rí ẹ̀ka igi almondi.”

12 Olúwa sì wí fún mi pé, “Ó ti rí i bí ó ṣe yẹ, nítorí pé mo ti ń ṣọ láti rí i pé ọ̀rọ̀ mi wá sí ìmúṣẹ.”

13 Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tún tọ̀ mi wá ní ẹ̀ẹ̀kejì pé, “Kí ni o rí?” Mo sì dáhùn pé mo rí ìkòkò gbígbóná, tí ó ń ru láti apá àríwá.

14 Olúwa, sì wí fún mi pé, “Láti apá àríwá ni a ó ti mu ìdààmú wá sórí gbogbo àwọn tí ó ń gbé ní ilẹ̀ náà. 15 Mo sì ti ṣetán láti pe gbogbo àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè àríwá níjà,” ni Olúwa wí.

Àwọn ọba wọn yóò wá
    gbé ìtẹ́ wọn ró ní ojú ọ̀nà àbáwọlé
Jerusalẹmu. Wọn ó sì dìde sí gbogbo
    àyíká wọn àti sí gbogbo àwọn
    ìlú Juda.
16 Èmi yóò sì kéde ìdájọ́ mi lórí àwọn ènìyàn mi
    nítorí ìwà búburú wọn nípa kíkọ̀ mí sílẹ̀,
nípa rírúbọ sí ọlọ́run mìíràn
    àti sínsin àwọn ohun tí wọ́n fi ọwọ́ wọn ṣe.

17 “Wà ní ìmúrasílẹ̀! Dìde dúró kí o sì sọ fún wọn ohunkóhun tí mo bá pàṣẹ fún wọn. Má ṣe jẹ́ kí wọ́n dẹ́rùbà ọ́, èmi yóò sì sọ ọ́ di ẹ̀rù níwájú wọn. 18 Ní òní èmi ti sọ ọ́ di ìlú alágbára, òpó irin àti odi idẹ sí àwọn ọba Juda, àwọn ìjòyè rẹ̀, sí àwọn àlùfáà àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà. 19 Wọn yóò dojú ìjà kọ ọ́, wọn kì yóò borí rẹ, nítorí wí pé èmi wà pẹ̀lú rẹ, èmi yóò sì gbà ọ́,” ni Olúwa wí.

Luku 19:41-44

41 (A)Nígbà tí ó sì súnmọ́ etílé, ó ṣíjú wo ìlú náà, ó sọkún sí i lórí, 42 Ó ń wí pé, “Ìbá ṣe pé ìwọ mọ̀, lónìí yìí, àní ìwọ, ohun tí í ṣe tí Àlàáfíà rẹ! Ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n pamọ́ kúrò lójú rẹ. 43 (B)Nítorí ọjọ́ ń bọ̀ fún ọ, tí àwọn ọ̀tá rẹ yóò mọ odi bèbè yí ọ ká, àní tí wọn yóò sì yí ọ ká, wọn ó sì ká ọ mọ́ níhà gbogbo. 44 (C)Wọn ó sì wó ọ palẹ̀ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ pẹ̀lú rẹ; wọn kì yóò sì fi òkúta kan sílẹ̀ lórí ara wọn; nítorí ìwọ kò mọ ọjọ́ ìbẹ̀wò rẹ.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.