Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 138

Ti Dafidi

138 Èmi yóò yìn ọ́ tinútinú mi gbogbo;
    níwájú àwọn òrìṣà ni èmi ó kọrin ìyìn sí ọ.
Èmi ó máa gbàdúrà sí ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ̀
    èmi ó sì máa yin orúkọ rẹ
nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ àti òtítọ́ rẹ;
    nítorí ìwọ gbé ọ̀rọ̀ rẹ ga ju orúkọ rẹ lọ.
Ní ọjọ́ tí mo ké pè é ọ́, ìwọ dá mi lóhùn,
    ìwọ sì fi ipa mú mi lára le ní ọkàn mi.

Gbogbo àwọn ọba ayé yóò yìn ọ́,
    Olúwa, ní ìgbà tí wọn bá gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ
Nítòótọ́, wọn ó máa kọrin ní ipa ọ̀nà Olúwa;
    nítorí pé ńlá ni ògo Olúwa.

Olúwa tilẹ̀ ga, síbẹ̀ ó júbà àwọn onírẹ̀lẹ̀;
    ṣùgbọ́n agbéraga ni ó mọ̀ ní òkèrè réré.
Bí èmi tilẹ̀ ń rìn nínú ìpọ́njú ìwọ ni yóò sọ mi di ààyè;
    ìwọ ó na ọwọ́ rẹ sí àwọn ọ̀tá mi,
    ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì gbà mí.
Olúwa yóò ṣe ohun tí ń ṣe tèmi láṣepé;
    Olúwa, àánú rẹ dúró láéláé;
    Má ṣe kọ iṣẹ́ ọwọ́ ara rẹ sílẹ̀.

Numeri 20:22-29

Ikú Aaroni

22 Gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli sì jáde láti Kadeṣi wọ́n sì wá sí orí òkè Hori. 23 Ní orí òkè Hori, ní ẹ̀gbẹ́ ààlà Edomu Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé, 24 “Aaroni yóò kú. Kò ní wọ ilẹ̀ tí mo fi fún àwọn ọmọ Israẹli, nítorí ẹ̀yin méjèèjì ṣe àìgbọ́ràn sí òfin mi níbi omi Meriba. 25 (A)Mú Aaroni àti ọmọ rẹ̀ Eleasari lọ sí orí òkè Hori. 26 Bọ́ aṣọ Aaroni kí o sì gbe wọ ọmọ rẹ̀ Eleasari, nítorí pé Aaroni yóò kú síbẹ̀.”

27 Mose sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ: Wọ́n lọ sí orí òkè Hori ní ojú gbogbo ìjọ ènìyàn. 28 Mose bọ́ aṣọ Aaroni ó sì gbe wọ ọmọ rẹ̀ Eleasari, Aaroni sì kú sí orí òkè. Nígbà náà Mose àti Eleasari sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, 29 Nígbà tí gbogbo ìjọ ènìyàn sì gbọ́ pé Aaroni ti kú, gbogbo ilé Israẹli ṣe ìdárò rẹ̀ fún ọgbọ̀n (30) ọjọ́.

Ìṣe àwọn Aposteli 9:19-25

19 Nígbà tí ó sì jẹun, ara rẹ̀ mókun.

Saulu ní Damasku àti Jerusalẹmu

Saulu sì wá pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ní Damasku ní ọjọ́ púpọ̀ 20 Lójúkan náà ó sì ń wàásù Kristi nínú àwọn Sinagọgu pé, Jesu ni Ọmọ Ọlọ́run. 21 Ẹnu sì yà gbogbo àwọn ti ó ń gbọ́, wọn sì wí pé, “Èyí ha kọ ẹni ti ó ti fóòro àwọn ti ń pe orúkọ yìí ni Jerusalẹmu? Nítorí èyí náà ni ó sa ṣe wá sí ìhín yìí, láti mú wọn ní dìde lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà.” 22 Ṣùgbọ́n Saulu ń pọ̀ sí i ní agbára ó sì ń dààmú àwọn Júù tí ó ń gbé Damasku, ó fihàn pé, èyí ni Kristi náà.

23 Lẹ́yìn ìgbà tí ọjọ́ púpọ̀ kọjá, àwọn Júù ń gbìmọ̀ láti pa á 24 (A)Ṣùgbọ́n ìdìtẹ̀ wọn di mí mọ̀ fún Saulu. Wọ́n sì ń ṣọ́ ẹnu ibodè pẹ̀lú lọ́sàn àti lóru, wọ́n ń wá ọ̀nà láti pa á. 25 Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbé ní òru, wọ́n sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ lára odi nínú agbọ̀n.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.