Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Isaiah 6:1-8

Ìpè sí iṣẹ́ ìránṣẹ́ Isaiah

Ní ọdún tí ọba Ussiah kú, mo rí Olúwa tí ó jókòó lórí ìtẹ́ tí ó ga tí a gbé sókè, ìṣẹ́tí aṣọ ìgúnwà rẹ̀ sì kún inú tẹmpili. Àwọn Serafu wà ní òkè rẹ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ìyẹ́ mẹ́fà, wọ́n fi ìyẹ́ méjì bo ojú wọn, wọ́n fi méjì bo ẹsẹ̀ wọn, wọ́n sí ń fi méjì fò. (A)Wọ́n sì ń kọ sí ara wọn wí pé:

“Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun
    gbogbo ayé kún fún ògo rẹ̀.”

(B)Nípa ìró ohùn un wọn, òpó ìlẹ̀kùn àti gbogbo ògiri ilé náà sì mì tìtì, gbogbo inú tẹmpili sì kún fún èéfín.

Mo kígbe pé “Ègbé ni fún mi! Mo ti gbé!” Nítorí mo jẹ́ ènìyàn aláìmọ́ ètè, mo sì ń gbé láàrín àwọn ènìyàn aláìmọ́ ètè, ojú mi sì ti rí ọba, Olúwa àwọn ọmọ-ogun jùlọ.

Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn Serafu wọ̀nyí fò wá sí ọ̀dọ̀ mi pẹ̀lú ẹ̀yín iná ní ọwọ́ rẹ̀, èyí tí ó ti fi ẹ̀mú mú ní orí pẹpẹ. Èyí ni ó fi kàn mí ní ẹnu tí ó sì wí pé, “Wò ó, èyí ti kan ètè rẹ; a ti mú ẹ̀bi rẹ kúrò, a sì ti wẹ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ nù.”

Nígbà náà ni mo sì gbọ́ ohùn Olúwa wí pé, “Ta ni èmi yóò rán? Ta ni yóò sì lọ fún wa?”

Nígbà náà ni èmi sì wí pé, “Èmi nìyí, rán mi!”

Isaiah 6:9-13

(A)Òun sì wí pé, “Tọ àwọn ènìyàn yìí lọ kí o sì wí fún wọn pé:

“ ‘Ní gbígbọ́ ẹ̀yin yóò gbọ́, kì yóò sì yé e yín;
    ní rí rí ẹ̀yin yóò ri, ẹ̀yin kì yóò mọ òye.’
10 Mú kí àyà àwọn ènìyàn wọ̀nyí yigbì,
    mú kí etí wọn kí ó wúwo,
    kí o sì dìwọ́n ní ojú.
Kí wọn kí ó má ba fi ojú wọn ríran,
    kí wọn kí ó má ba fi etí wọn gbọ́rọ̀,
kí òye kí ó má ba yé ọkàn wọn,
    kí wọn kí ó má ba yípadà
    kí a má ba mú wọn ní ara dá.”

11 Nígbà náà ni mo wí pé, “Báwo ni yóò ti pẹ́ tó Olúwa?”

Òun sì dáhùn pé:

“Títí àwọn ìlú ńlá yóò fi dahoro,
    láìsí olùgbé nínú rẹ̀ mọ́,
títí tí àwọn ilé yóò fi wà láìsí ènìyàn,
    títí tí ilẹ̀ yóò fi dahoro pátápátá.
12 Títí tí Olúwa yóò fi rán gbogbo wọn jìnnà réré
    tí ilẹ̀ náà sì di ìkọ̀sílẹ̀ pátápátá.
13 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdámẹ́wàá ṣẹ́kù lórí ilẹ̀ náà,
    yóò sì tún pàpà padà di rírun.
Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí igi tẹrẹbinti àti igi óákù,
    ti í fi kùkùté sílẹ̀ nígbà tí a bá gé wọn lulẹ̀,
bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni irúgbìn mímọ́ náà yóò di kùkùté ní ilẹ̀ náà.”

Saamu 138

Ti Dafidi

138 Èmi yóò yìn ọ́ tinútinú mi gbogbo;
    níwájú àwọn òrìṣà ni èmi ó kọrin ìyìn sí ọ.
Èmi ó máa gbàdúrà sí ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ̀
    èmi ó sì máa yin orúkọ rẹ
nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ àti òtítọ́ rẹ;
    nítorí ìwọ gbé ọ̀rọ̀ rẹ ga ju orúkọ rẹ lọ.
Ní ọjọ́ tí mo ké pè é ọ́, ìwọ dá mi lóhùn,
    ìwọ sì fi ipa mú mi lára le ní ọkàn mi.

Gbogbo àwọn ọba ayé yóò yìn ọ́,
    Olúwa, ní ìgbà tí wọn bá gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ
Nítòótọ́, wọn ó máa kọrin ní ipa ọ̀nà Olúwa;
    nítorí pé ńlá ni ògo Olúwa.

Olúwa tilẹ̀ ga, síbẹ̀ ó júbà àwọn onírẹ̀lẹ̀;
    ṣùgbọ́n agbéraga ni ó mọ̀ ní òkèrè réré.
Bí èmi tilẹ̀ ń rìn nínú ìpọ́njú ìwọ ni yóò sọ mi di ààyè;
    ìwọ ó na ọwọ́ rẹ sí àwọn ọ̀tá mi,
    ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì gbà mí.
Olúwa yóò ṣe ohun tí ń ṣe tèmi láṣepé;
    Olúwa, àánú rẹ dúró láéláé;
    Má ṣe kọ iṣẹ́ ọwọ́ ara rẹ sílẹ̀.

1 Kọrinti 15:1-11

Àjíǹde Kristi

15 Ǹjẹ́ ará, èmi ń sọ ìhìnrere náà dí mí mọ̀ fún un yín, tí mo ti wàásù fún un yín, èyí tí ẹ̀yin pẹ̀lú ti gbá, nínú èyí tí ẹ̀yin sì dúró. Nípasẹ̀ ìhìnrere yìí ni a fi ń gbà yín là pẹ̀lú, bí ẹ̀yin bá di ọ̀rọ̀ ti mo ti wàásù fún yín mú ṣinṣin. Bí bẹ́ẹ̀ kọ̀, ẹ̀yin kàn gbàgbọ́ lásán.

(A)Nítorí èyí tí mo rí gbà ṣáájú ohun gbogbo ní èmi pẹ̀lú ti fi lé e yín lọ́wọ́, bí Kristi ti kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bí ìwé mímọ́ tí wí. (B)Àti pé a sìnkú rẹ̀, àti pé ó jíǹde ní ọjọ́ kẹta gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ tí wí; (C)Àti pé ó farahàn Peteru, lẹ́yìn èyí, àwọn méjìlá Lẹ́yìn èyí, ó farahàn àwọn ará tí o jú ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta lọ lẹ́ẹ̀kan náà; ọ̀pọ̀ nínú wọn wà títí fi di ìsinsin yìí, ṣùgbọ́n àwọn díẹ̀ ti sùn. Lẹ́yìn èyí ni ó farahan Jakọbu; lẹ́yìn náà fún gbogbo àwọn aposteli. (D)Àti níkẹyìn gbogbo wọn ó farahàn mí pẹ̀lú, bí ẹni tí a bí ṣáájú àkókò rẹ̀.

(E)Nítorí èmi ni ẹni tí ó kéré jùlọ nínú àwọn aposteli, èmi ẹni tí kò yẹ láti pè ní aposteli, nítorí tí mo ṣe inúnibíni sí ìjọ ènìyàn Ọlọ́run. 10 Ṣùgbọ́n nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run mo rí bí mo ti rí: oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ tí a fi fún mi kò sì jẹ́ asán; ṣùgbọ́n mó ṣiṣẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀ jú gbogbo wọn lọ: ṣùgbọ́n kì í ṣe èmi, bí kò ṣe oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí ó wà pẹ̀lú mi. 11 Nítorí náà ìbá à ṣe èmí tàbí àwọn ni, èyí ní àwa wàásù, èyí ní ẹ̀yin sì gbàgbọ́.

Luku 5:1-11

Ìpè àwọn ọmọ-ẹ̀yìn àkọ́kọ́

(A)Ó sì ṣe, nígbà tí ìjọ ènìyàn súnmọ́ ọn láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí ó sì dúró létí adágún Genesareti. Ó rí ọkọ̀ méjì ti o wá létí adágún: èyí tí àwọn apẹja ti sọ̀kalẹ̀ kúrò nínú wọn, nítorí tí wọ́n ń fọ àwọ̀n wọn. (B)Ó sì wọ ọ̀kan nínú àwọn ọkọ̀ náà, tí í ṣe ti Simoni, ó sì bẹ̀ ẹ́ kí ó tì í sí ẹ̀yìn díẹ̀ kúrò ní ilẹ̀. Ó sì jókòó, ó sì ń kọ́ ìjọ ènìyàn láti inú ọkọ̀ náà.

Bí ó sì ti dákẹ́ ọ̀rọ̀ sísọ, ó wí fún Simoni pé, “Tì í sí ibú, kí o sì ju àwọ̀n yín sí ìsàlẹ̀ fún àkópọ̀.”

(C)Simoni sì dáhùn ó sì wí fún un pé, “Olùkọ́ni, gbogbo òru ni àwa fi ṣiṣẹ́, àwa kò sì mú nǹkan kan: ṣùgbọ́n nítorí ọ̀rọ̀ rẹ èmi ó ju àwọ̀n náà sí ìsàlẹ̀.”

Nígbà tí wọ́n sì ti ṣe èyí, wọ́n kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹja: àwọ̀n wọn sì ya. Wọ́n sì pe àwọn ẹgbẹ́ wọn, tí ó wà nínú ọkọ̀ kejì, kí wọn kí ó wá ràn wọ́n lọ́wọ́. Wọ́n sì wá, wọ́n kó ẹja ọkọ̀ méjèèjì sì kún, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í rì.

Nígbà tí Simoni Peteru sì rí i, ó wólẹ̀ lẹ́bàá eékún Jesu, ó wí pé, “Lọ kúrò lọ́dọ̀ mi Olúwa; nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mí.” Ẹnu sì yà wọ́n, àti gbogbo àwọn tí ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀, fún àkópọ̀ ẹja tí wọ́n kó: 10 Bẹ́ẹ̀ ni Jakọbu àti Johanu àwọn ọmọ Sebede, tí ń ṣe alábákẹ́gbẹ́ Simoni.

Jesu sì wí fún Simoni pé, “Má bẹ̀rù; láti ìsinsin yìí lọ ìwọ ó máa mú ènìyàn.” 11 Nígbà tí wọ́n sì ti mú ọkọ̀ wọn dé ilẹ̀, wọ́n fi gbogbo rẹ̀ sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn lọ.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.