Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 1

ÌWÉ KÌN-ÍN-NÍ

Saamu 1–41

(A)Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà,
    tí kò rìn ní ìmọ̀ àwọn ènìyàn búburú,
ti kò dúró ní ọ̀nà àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,
    tàbí tí kò sì jókòó ní ibùjókòó àwọn ẹlẹ́gàn.
Ṣùgbọ́n ayọ̀ inú rẹ̀ wà nínú òfin Olúwa
    àti nínú òfin rẹ̀ ni ó ń ṣe àṣàrò ní ọ̀sán àti òru.
Ó dàbí igi tí a gbìn sí etí odò tí ń sàn,
    tí ń so èso rẹ̀ jáde ní àkókò rẹ̀
tí ewé rẹ̀ kì yóò rẹ̀.
    Ohunkóhun tí ó dáwọ́lé, ni yóò máa yọrí sí rere.

Kò le rí bẹ́ẹ̀ fún àwọn ènìyàn búburú!
    Wọn yóò dàbí ìyàngbò ọkà
    tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ dànù.
Nítorí náà àwọn ènìyàn búburú kì yóò le è dìde dúró ní ìdájọ́,
    bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kì yóò le è dúró ní àwùjọ àwọn olódodo.

Nítorí Olúwa ń ṣọ́ ọ̀nà àwọn olódodo,
    ṣùgbọ́n ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú ni yóò ṣègbé.

Jeremiah 13:20-27

20 Gbé ojú rẹ sókè,
    kí o sì wo àwọn tí ó ń bọ̀ láti àríwá.
Níbo ni agbo ẹran tí a fi sí abẹ́ àkóso rẹ wà;
    àgùntàn tí ò ń mú yangàn.
21 Kí ni ìwọ yóò wí nígbà tí Olúwa bá dúró lórí rẹ
    àwọn tí o mú bí ọ̀rẹ́ àtàtà.
Ǹjẹ́ kò ní jẹ́ ìrora fún ọ
    bí aboyún tó ń rọbí?
22 Tí o bá sì bi ara rẹ léèrè
    “Kí ni ìdí rẹ̀ tí èyí fi ṣẹlẹ̀ sí mi?”
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ tí o ṣẹ̀
    ni aṣọ rẹ fi fàya
    tí a sì ṣe é ní ìṣekúṣe.
23 Ǹjẹ́ Etiopia le yí àwọ̀ rẹ̀ padà?
    Tàbí ẹkùn lè yí àwọ̀ rẹ̀ padà?
Bí èyí kò ti lè rí bẹ́ẹ̀
    náà ni ẹ̀yin tí ìwà búburú bá ti mọ́ lára kò lè ṣe rere.

24 “N ó fọ́n ọn yín ká bí i ìyàngbò
    tí ẹ̀fúùfù ilẹ̀ aṣálẹ̀ ń fẹ́.
25 Èyí ni ìpín tìrẹ;
    tí mo ti fi sílẹ̀ fún ọ,”
    ni Olúwa wí,
“Nítorí ìwọ ti gbàgbé mi
    o sì gbẹ́kẹ̀lé àwọn ọlọ́run àjèjì.
26 N ó sí aṣọ lójú rẹ,
    kí ẹ̀sín rẹ le hàn síta—
27 ìwà àgbèrè àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́,
    àìlójútì panṣágà rẹ!
Mo ti rí ìwà ìríra rẹ,
    lórí òkè àti ní pápá.
Ègbé ni fún ọ ìwọ Jerusalẹmu!
    Yóò ti pẹ́ tó tí o ó fi máa wà ní àìmọ́?”

1 Peteru 1:17-2:1

17 Níwọ́n bí ẹ̀yin ti ń ké pe Baba, ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ olúkúlùkù láìṣe ojúsàájú, ẹ máa lo ìgbà àtìpó yin ni ìbẹ̀rù. 18 Níwọ̀n bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé a kò fi ohun ìdíbàjẹ́ rà yín padà, bí fàdákà tàbí wúrà kúrò nínú ìwà asán yín, tí ẹ̀yin ti jogún láti ọ̀dọ̀ àwọn baba yín. 19 Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ iyebíye, bí i ti ọ̀dọ́-àgùntàn ti kò lábùkù, tí kò sì lábàwọ́n, àní, ẹ̀jẹ̀ Kristi. 20 Ẹni tí a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ nítòótọ́ ṣáájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, ṣùgbọ́n tí a fihàn ní ìgbà ìkẹyìn wọ̀nyí nítorí yín, 21 Àní ẹ̀yin tí o tipasẹ̀ rẹ̀ gba Ọlọ́run gbọ́, ẹni ti ó jí i dìde kúrò nínú òkú, tí ó sì fi ògo fún un; kí ìgbàgbọ́ àti ìrètí yín lè wà lọ́dọ̀ Ọlọ́run.

22 Níwọ́n bí ẹ̀yin ti wẹ ọkàn yin mọ́ nípa ìgbọ́ràn yín sí òtítọ́ sí ìfẹ́ ará ti kò ní ẹ̀tàn, ẹ fẹ́ ọmọnìkejì yín gidigidi láti ọkàn wá. 23 Bí a ti tún yín bí, kì í ṣe láti inú ìdíbàjẹ́ wá, bí kò ṣe èyí ti kì í díbàjẹ́ nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ń bẹ láààyè tí ó sì dúró. 24 (A)Nítorí pé,

“Gbogbo ènìyàn dàbí koríko,
    àti gbogbo ògo rẹ̀ bi ìtànná koríko.
Koríko á máa gbẹ ìtànná a sì máa rẹ̀ dànù,
25     Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Olúwa dúró títí láé.”

Ọ̀rọ̀ náà yìí sì ni ìhìnrere tí a wàásù fún yín.

Nítorí náà, ẹ fi àrankàn gbogbo sílẹ̀ ni apá kan, àti ẹ̀tàn gbogbo, àti àgàbàgebè, àti ìlara, àti sísọ ọ̀rọ̀ búburú gbogbo.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.