Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Saamu Dafidi. Ẹ̀bẹ̀.
38 Olúwa, Má ṣe bá mi wí nínú ìbínú rẹ,
bẹ́ẹ̀ ni kí o má ṣe fi ìyà jẹ mí nínú ìrunú rẹ̀.
2 Nítorí tí ọfà rẹ kàn mọ́ mi ṣinṣin,
ọwọ́ rẹ sì kì mí mọ́lẹ̀.
3 Kò sí ibi yíyè ní ara à mi, nítorí ìbínú rẹ;
kò sí àlàáfíà nínú egungun mi nítorí i ẹ̀ṣẹ̀ mi.
4 Nítorí àìṣedéédéé mi ti borí mi mọ́lẹ̀;
wọ́n tó ìwọ̀n bi àjàgà tí ó wúwo jù fún mi.
5 Ọgbẹ́ mi ń rùn ó sì díbàjẹ́
nítorí òmùgọ̀ mi.
6 Èmi ń jòwèrè, orí mi tẹ̀ ba gidigidi
èmi ń ṣọ̀fọ̀ rìn kiri ní gbogbo ọjọ́.
7 Nítorí ẹ̀gbẹ́ mi kún fún ìgbóná tí ń jóni
kò sì ṣí ibi yíyè ní ara mi,
8 Ara mi hù, a sì wó mi jẹ́gẹjẹ̀gẹ;
mo kérora nítorí ìrúkèrúdò àyà mi.
9 Olúwa, gbogbo ìfẹ́ mi ń bẹ níwájú rẹ;
ìmí ẹ̀dùn mi kò sápamọ́ fún ọ.
10 Àyà mi ń mí hẹlẹ, agbára mi yẹ̀ mí sílẹ̀;
bí ó ṣe ti ìmọ́lẹ̀ ojú mi ni, ó ti lọ kúrò lára mi.
11 Àwọn ọ̀rẹ́ mi àti àwọn ẹlẹgbẹ́ mi dúró lókèèrè réré kúrò níbi ìpọ́njú mi,
àwọn alábágbé mi, dúró lókèèrè.
12 Àwọn tí n wá ẹ̀mí mi dẹ okùn sílẹ̀ fún mi;
àti àwọn tí ó fẹ́ pa mí lára ń sọ̀rọ̀ nípa ìparun,
wọ́n sì ń gbèrò ẹ̀tàn ní gbogbo ọjọ́.
13 Ṣùgbọ́n mo dàbí adití odi, èmi kò gbọ́ ọ̀rọ̀;
àti bí odi, tí kò le sọ̀rọ̀.
14 Nítòótọ́, mo rí bí ọkùnrin tí kò gbọ́rọ̀,
àti bí ẹnu ẹni tí kò sí ìjiyàn.
15 Ṣùgbọ́n sí ọ Olúwa, ìwọ ni mo dúró dè;
ìwọ ni, Olúwa Ọlọ́run mi, ẹni tí yóò dáhùn.
16 Nítorí tí mo gbàdúrà, “Gbóhùn mi, kí wọn má ba à yọ̀ mí;
nígbà tí ẹsẹ̀ mi bá yọ̀ wọn yóò máa gbé ara wọn ga sí mi.”
17 Nítorí tí mo ti ṣetán láti ṣubú,
ìrora mi sì wà pẹ̀lú mi nígbà gbogbo.
18 Mo jẹ́wọ́ ìrékọjá mi;
àánú sì ṣe mí fún ẹ̀ṣẹ̀ mi.
19 Àwọn tí ó jẹ́ ọ̀tá mi láìnídìí pàtàkì, wọ́n lágbára púpọ̀,
ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí ó kórìíra mi lọ́nà òdì.
20 Àwọn tí wọn ń fi ibi san rere fún mi
àwọn ni ọ̀tá mi
nítorí pé mò ń tọ ìre lẹ́yìn.
21 Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀, ìwọ Olúwa!
Ọlọ́run mi, Má ṣe jìnnà sí mi.
22 Yára láti ràn mí lọ́wọ́,
Olúwa, Olùgbàlà mi.
Dafidi da ẹ̀mí Saulu sí
24 Nígbà tí Saulu padà kúrò lẹ́yìn àwọn Filistini a sì sọ fún un pé, “Wò ó, Dafidi ń bẹ́ ni aginjù En-Gedi.” 2 Saulu sì mú ẹgbẹ̀ẹ́dógún akọni ọkùnrin tí a yàn nínú gbogbo Israẹli ó sì lọ láti wá Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ lórí òkúta àwọn ewúrẹ́ igbó.
3 Ó sì dé ibi àwọn agbo àgùntàn tí ó wà ní ọ̀nà, ihò kan sì wà níbẹ̀, Saulu sì wọ inú rẹ̀ lọ láti bo ẹsẹ̀ rẹ̀, Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì ń bẹ lẹ́bàá ihò náà. 4 Àwọn ọmọkùnrin Dafidi sì wí fún un pé, “Wò ó, èyí ni ọjọ́ náà tí Olúwa wí fún ọ pé, ‘Wò ó, èmi fi ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́, ìwọ ó sì ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ lójú rẹ.’ ” Dafidi sì dìde, ó sì yọ́ lọ gé etí aṣọ Saulu.
5 Ó sì ṣe lẹ́yìn èyí, àyà já Dafidi nítorí tí ó gé etí aṣọ Saulu. 6 Òun sì wí fún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pé, “Èèwọ̀ ni fún mi láti ọ̀dọ́ Olúwa wá bí èmi bá ṣe nǹkan yìí sí ẹni tí a ti fi ààmì òróró Olúwa yàn, láti nawọ́ mi sí i, nítorí pé ẹni ààmì òróró Olúwa ni.” 7 Dafidi sì fi ọ̀rọ̀ wọ̀nyí dá àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ dúró, kò sì jẹ́ kí wọn dìde sí Saulu, Saulu sì dìde kúrò ní ihò náà, ó sì bá ọ̀nà rẹ̀ lọ.
8 Dafidi sì dìde lẹ́yìn náà, ó sì jáde kúrò nínú ihò náà ó sì kọ sí Saulu pé, “Olúwa mi, ọba!” Saulu sì wo ẹ̀yìn rẹ̀. Dafidi sì dojú rẹ́ bo ilẹ̀ ó sì tẹríba fún un. 9 Dafidi sì wí fún Saulu pé, “Èéha ti ṣe tí ìwọ fi ń gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn pé, ‘Wò ó, Dafidi ń wa ẹ̀mí rẹ́’? 10 Wò ó, ojú rẹ́ rí i lónìí, bí Olúwa ti fi ìwọ lé mi lọ́wọ́ lónìí nínú ihò; àwọn kan ní kí èmi ó pa ọ; ṣùgbọ́n èmi dá ọ sí; ‘Èmi sì wí pé, èmi kì yóò nawọ́ mi sí olúwa mi, nítorí pé ẹni ààmì òróró Olúwa ni òun jẹ́.’ 11 Pẹ̀lúpẹ̀lú, baba mi, wò ó, àní wo etí aṣọ rẹ lọ́wọ́ mi; nítorí èmi gé etí aṣọ rẹ, èmi kò sì pa ọ́, sì wò ó, kí o sì mọ̀ pé kò sí ibi tàbí ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́ mi, èmi kò sì ṣẹ̀ ọ̀, ṣùgbọ́n ìwọ ń dọdẹ ẹ̀mí mi láti gbà á. 12 Kí Olúwa ṣe ìdájọ́ láàrín èmi àti ìwọ, àti kí Olúwa ó gbẹ̀san mi lára rẹ; ṣùgbọ́n, ọwọ́ mi kì yóò sí lára rẹ. 13 Gẹ́gẹ́ bí òwe ìgbà àtijọ́ ti wí, ìwà búburú a máa ti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn búburú jáde wá; ṣùgbọ́n ọwọ́ mi kì yóò sí lára rẹ.
14 “Nítorí ta ni ọba Israẹli fi jáde? Ta ni ìwọ ń lépa? Òkú ajá, tàbí eṣinṣin? 15 Kí Olúwa ó ṣe onídàájọ́, kí ó sì dájọ́ láàrín èmi àti ìwọ, kí ó sì gbèjà mi, kí ó sì gbà mí kúrò lọ́wọ́ rẹ.”
16 Ó sì ṣe, nígbà tí Dafidi sì dákẹ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún Saulu, Saulu sì wí pé, “Ohùn rẹ ni èyí bí, Dafidi ọmọ mi?” Saulu sì gbé ohùn rẹ̀ sókè, ó sọkún. 17 Ó sì wí fún Dafidi pé, “Ìwọ ṣe olódodo jù mí lọ; nítorí pé ìwọ ti fi ìre san án fún mi, èmi fi ibi san án fún ọ. 18 Ìwọ sì fi oore tí ìwọ ti ṣe fún mi hàn lónìí: nígbà tí ó jẹ́ pé, Olúwa ti fi ẹ̀mí mi lé ọ lọ́wọ́, Ìwọ kò sì pa mí. 19 Nítorí pé bí ènìyàn bá rí ọ̀tá rẹ̀, ó lè jẹ́ kí ó lọ ní àlàáfíà bí? Olúwa yóò sì fi ìre san èyí ti ìwọ ṣe fún mi lónìí. 20 Wò ó, èmi mọ̀ nísinsin yìí pé, nítòótọ́ ìwọ ó jẹ ọba, àti pé ìjọba Israẹli yóò sì fi ìdí múlẹ̀ ní ọwọ́ rẹ. 21 Sì búra fún mi nísinsin yìí ní orúkọ Olúwa, pé, ìwọ kì yóò gé irú-ọmọ mi kúrò lẹ́yìn mi, àti pé, ìwọ kì yóò pa orúkọ mi run kúrò ní ìdílé baba mi.”
22 Dafidi sì búra fún Saulu. Saulu sì lọ sí ilé rẹ̀; ṣùgbọ́n Dafidi àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì gòkè lọ sí ihò náà.
Oúnjẹ alẹ́ Olúwa
17 Nínú àwọn àlàkalẹ̀ èmi ko ni yìn yín nítorí pé bí ẹ bá péjọ kì í ṣe fún rere bí ko ṣe fún búburú. 18 (A)Lọ́nà kìn-ín-ní, mo gbọ́ pe ìyapa máa ń wà láàrín yín ní ìgbà tí ẹ bá péjọpọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìjọ, mo sì gba èyí gbọ́ dé ààyè ibìkan. 19 Kò sí àní àní, ìyàtọ̀ gbọdọ̀ wa láàrín yín, kí àwọn tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run láàrín yín le farahàn kedere. 20 Nígbà tí ẹ bá pàdé láti jẹun, kì í ṣe oúnjẹ alẹ́ Olúwa ni ẹ máa ń jẹ. 21 Ṣùgbọ́n tí ara yín, nígbà tí ẹ bá fẹ́ jẹun, olúkúlùkù yín a máa sáré jẹ oúnjẹ rẹ̀ láìdúró de ẹnìkejì rẹ̀. Ebi a sì máa pa wọ́n, ẹlòmíràn wọ́n sì ń mu àmuyó àti àmupara. 22 Ṣé ẹ̀yin kò ní ilé tí ẹ ti lè jẹ, tí ẹ sì ti lè mu ni? Tàbí ẹ̀yin ń gan ìjọ Ọlọ́run ni? Ẹ̀yin sì ń dójútì àwọn aláìní? Kín ni kí èmi ó wí fún un yín? Èmi yóò ha yìn yín nítorí èyí? A! Rárá o. Èmi kọ́, n kò ní yìn yín.
27 Nítorí náà tí ẹnikẹ́ni bá jẹ lára àkàrà yìí, tí ẹ sì ń mu nínú ago Olúwa yìí, ní ọ̀nà tí kò bójúmu, yóò jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ sí ara àti ẹ̀jẹ̀ Olúwa. 28 Ìdí nìyìí tí ó fi yẹ kí ènìyàn yẹ ara rẹ̀ wò dáradára kí ó tó jẹ lára àkàrà nà án àti kí ó tó mu nínú ago náà. 29 Nítorí tí ẹ bá jẹ lára àkàrà, tí ẹ sì mu nínú ago láìyẹ, tí ẹ kò ronú ara Kristi àti nǹkan tí ó túmọ̀ sí, ẹ̀ ń jẹ, ẹ sì ń mú ẹ̀bi ìdájọ́ Ọlọ́run wá sórí ara yín. 30 Ìdí nìyìí tí ọ̀pọ̀ yín fi di ẹni tí kò lágbára mọ́, tí ọ̀pọ̀ yín sì ń ṣàìsàn, àwọn mìíràn nínú yín tilẹ̀ ti sùn. 31 Ṣùgbọ́n tí ẹ bá yẹ ara yín wò dáradára, kí ẹ tó jẹ ẹ́, a kì yóò dá yín lẹ́jọ́. 32 (A)Ṣùgbọ́n nígbà tí a bá dá wa lẹ́jọ́, láti ọwọ́ Olúwa ni a ti nà wá, kí a má ba à dá wa lẹ́bi pẹ̀lú ayé.
33 Nítorí náà, ẹ̀yin arákùnrin mi ọ̀wọ́n, nígbàkúgbà ti ẹ bá péjọ láti jẹ́ oúnjẹ alẹ́ Olúwa, tàbí fún ìsìn oúnjẹ alẹ́ Olúwa, ẹ dúró de ara yín.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.