Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 38

Saamu Dafidi. Ẹ̀bẹ̀.

38 Olúwa, Má ṣe bá mi wí nínú ìbínú rẹ,
    bẹ́ẹ̀ ni kí o má ṣe fi ìyà jẹ mí nínú ìrunú rẹ̀.
Nítorí tí ọfà rẹ kàn mọ́ mi ṣinṣin,
    ọwọ́ rẹ sì kì mí mọ́lẹ̀.
Kò sí ibi yíyè ní ara à mi, nítorí ìbínú rẹ;
    kò sí àlàáfíà nínú egungun mi nítorí i ẹ̀ṣẹ̀ mi.
Nítorí àìṣedéédéé mi ti borí mi mọ́lẹ̀;
    wọ́n tó ìwọ̀n bi àjàgà tí ó wúwo jù fún mi.

Ọgbẹ́ mi ń rùn ó sì díbàjẹ́
    nítorí òmùgọ̀ mi.
Èmi ń jòwèrè, orí mi tẹ̀ ba gidigidi
    èmi ń ṣọ̀fọ̀ rìn kiri ní gbogbo ọjọ́.
Nítorí ẹ̀gbẹ́ mi kún fún ìgbóná tí ń jóni
    kò sì ṣí ibi yíyè ní ara mi,
Ara mi hù, a sì wó mi jẹ́gẹjẹ̀gẹ;
    mo kérora nítorí ìrúkèrúdò àyà mi.

Olúwa, gbogbo ìfẹ́ mi ń bẹ níwájú rẹ;
    ìmí ẹ̀dùn mi kò sápamọ́ fún ọ.
10 Àyà mi ń mí hẹlẹ, agbára mi yẹ̀ mí sílẹ̀;
    bí ó ṣe ti ìmọ́lẹ̀ ojú mi ni, ó ti lọ kúrò lára mi.
11 Àwọn ọ̀rẹ́ mi àti àwọn ẹlẹgbẹ́ mi dúró lókèèrè réré kúrò níbi ìpọ́njú mi,
    àwọn alábágbé mi, dúró lókèèrè.
12 Àwọn tí n wá ẹ̀mí mi dẹ okùn sílẹ̀ fún mi;
    àti àwọn tí ó fẹ́ pa mí lára ń sọ̀rọ̀ nípa ìparun,
    wọ́n sì ń gbèrò ẹ̀tàn ní gbogbo ọjọ́.

13 Ṣùgbọ́n mo dàbí adití odi, èmi kò gbọ́ ọ̀rọ̀;
    àti bí odi, tí kò le sọ̀rọ̀.
14 Nítòótọ́, mo rí bí ọkùnrin tí kò gbọ́rọ̀,
    àti bí ẹnu ẹni tí kò sí ìjiyàn.
15 Ṣùgbọ́n sí ọ Olúwa, ìwọ ni mo dúró dè;
    ìwọ ni, Olúwa Ọlọ́run mi, ẹni tí yóò dáhùn.
16 Nítorí tí mo gbàdúrà, “Gbóhùn mi, kí wọn má ba à yọ̀ mí;
    nígbà tí ẹsẹ̀ mi bá yọ̀ wọn yóò máa gbé ara wọn ga sí mi.”

17 Nítorí tí mo ti ṣetán láti ṣubú,
    ìrora mi sì wà pẹ̀lú mi nígbà gbogbo.
18 Mo jẹ́wọ́ ìrékọjá mi;
    àánú sì ṣe mí fún ẹ̀ṣẹ̀ mi.
19 Àwọn tí ó jẹ́ ọ̀tá mi láìnídìí pàtàkì, wọ́n lágbára púpọ̀,
    ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí ó kórìíra mi lọ́nà òdì.
20 Àwọn tí wọn ń fi ibi san rere fún mi
    àwọn ni ọ̀tá mi
    nítorí pé mò ń tọ ìre lẹ́yìn.

21 Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀, ìwọ Olúwa!
    Ọlọ́run mi, Má ṣe jìnnà sí mi.
22 Yára láti ràn mí lọ́wọ́,
    Olúwa, Olùgbàlà mi.

Lefitiku 5:1-13

“ ‘Bí ẹnìkan bá dẹ́ṣẹ̀ nítorí pé kò sọ̀rọ̀ nígbà tí a bi í ní gbangba pé kó jẹ́rìí nípa nǹkan tó rí tàbí nǹkan tó mọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ kan, a ó di ẹ̀bi rẹ̀ rù ú.

“ ‘Tàbí bí ẹnìkan bá fọwọ́ kan ohun tí a kà sí àìmọ́ yálà òkú ẹranko aláìmọ́ tàbí òkú ẹran ọ̀sìn aláìmọ́ tàbí òkú ẹ̀dá yówù tó ń rìn lórí ilẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni náà kò mọ̀, ó ti di aláìmọ́, ó sì ti jẹ̀bi. Tàbí bí ó bá fọwọ́ kan ohun àìmọ́ ti ènìyàn, ohunkóhun tó lè mú ènìyàn di aláìmọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni náà kò mọ̀, nígbà tí ó bá mọ̀ nípa rẹ̀ yóò jẹ̀bi. Tàbí bí ẹni kan bá búra láti ṣe ohun kan láì ronú lé e lórí, yálà ohun tó dára tàbí ohun búburú, nínú ọ̀rọ̀ yówù tó ti búra láì kíyèsi ara, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, kò mọ̀ nípa rẹ̀ tẹ́lẹ̀, bí ó ti wù kó rí, nígbà tó bá mọ̀ yóò jẹ̀bi. Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ̀bi ọ̀kan nínú àwọn nǹkan wọ̀nyí, ó gbọdọ̀ jẹ́wọ́ irú ọ̀nà tó ti dẹ́ṣẹ̀ àti pé gẹ́gẹ́ bí ìtánràn fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀, ó gbọdọ̀ mú wa fún Ọlọ́run, abo àgùntàn tàbí abo ewúrẹ́ láti inú agbo ẹran wá gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àlùfáà yóò sì ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀.

“ ‘Bí kò bá lágbára àti mú ọ̀dọ́-àgùntàn wá, kí ó mú àdàbà méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì fún Olúwa gẹ́gẹ́ bí ìtánràn fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀—ọ̀kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, èkejì fún ẹbọ sísun. Kí ó kó wọn wá fún àlùfáà tí yóò kọ́kọ́ rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ kí ó yín in lọ́rùn, ṣùgbọ́n kí ó má já orí rẹ̀ tan, kí ó sì wọ́n díẹ̀ lára ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà sí ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ, ìyókù ẹ̀jẹ̀ náà ni kí ó ro sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ. Ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni. 10 Lẹ́yìn èyí àlùfáà yóò wá rú ẹbọ sísun gẹ́gẹ́ bí ìlànà, yóò sì ṣe ètùtù fún un nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀, a ó sì dáríjì í.

11 “ ‘Bí ó bá sì jẹ́ pé kò ní agbára àti mú àdàbà méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì wá, kí ó mú ìdámẹ́wàá òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná dáradára wá fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, kò gbọdọ̀ fi òróró tàbí tùràrí sí i nítorí pé ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni. 12 Kí ó gbé e wá sí ọ̀dọ̀ àlùfáà, àlùfáà yóò sì bu ẹ̀kúnwọ́ ìyẹ̀fun gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìrántí, kí ó sì sun ún lórí pẹpẹ, gẹ́gẹ́ bí ẹbọ tí a fi iná sun sí Olúwa. Ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni 13 Báyìí ni àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún ẹni náà fún èyíkéyìí nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá, a ó sì dáríjì í: ìyókù sì jẹ́ ti àlùfáà, bí ẹbọ ohun jíjẹ.’ ”

Luku 17:1-4

Ẹ̀ṣẹ̀, ìgbàgbọ́, àti iṣẹ́

17 (A)Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Kò le ṣe kí ohun ìkọ̀sẹ̀ máa wa: ṣùgbọ́n ègbé ni fún ẹni tí ó ti ipasẹ̀ rẹ̀ dé. Ìbá sàn fún un kí a so ọlọ mọ́ ọn ní ọrùn, kí a sì gbé e jù sínú Òkun, ju kí ó mú ọ̀kan nínú àwọn kékeré wọ̀nyí kọsẹ̀. (B)Ẹ máa kíyèsára yín.

“Bí arákùnrin rẹ bá ṣẹ̀, bá a wí; bí ó bá sì ronúpìwàdà, dáríjì ín. Bí ó bá sì ṣẹ̀ ọ́ ní igba méje ní òòjọ́, tí ó padà tọ̀ ọ́ wá ní ìgbà méje ní òòjọ́ pé, ‘Mo ronúpìwàdà,’ dáríjì ín.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.