Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
ÌWÉ KÌN-ÍN-NÍ
Saamu 1–41
1 (A)Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà,
tí kò rìn ní ìmọ̀ àwọn ènìyàn búburú,
ti kò dúró ní ọ̀nà àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,
tàbí tí kò sì jókòó ní ibùjókòó àwọn ẹlẹ́gàn.
2 Ṣùgbọ́n ayọ̀ inú rẹ̀ wà nínú òfin Olúwa
àti nínú òfin rẹ̀ ni ó ń ṣe àṣàrò ní ọ̀sán àti òru.
3 Ó dàbí igi tí a gbìn sí etí odò tí ń sàn,
tí ń so èso rẹ̀ jáde ní àkókò rẹ̀
tí ewé rẹ̀ kì yóò rẹ̀.
Ohunkóhun tí ó dáwọ́lé, ni yóò máa yọrí sí rere.
4 Kò le rí bẹ́ẹ̀ fún àwọn ènìyàn búburú!
Wọn yóò dàbí ìyàngbò ọkà
tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ dànù.
5 Nítorí náà àwọn ènìyàn búburú kì yóò le è dìde dúró ní ìdájọ́,
bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kì yóò le è dúró ní àwùjọ àwọn olódodo.
6 Nítorí Olúwa ń ṣọ́ ọ̀nà àwọn olódodo,
ṣùgbọ́n ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú ni yóò ṣègbé.
Ọtí Wáìnì
12 “Sọ fún wọn, ‘Èyí ni Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ Israẹli wí: Gbogbo ìgò ni à ó fi ọtí wáìnì kún.’ Bí wọ́n bá sì sọ fún ọ pé, ‘Ṣé a kò mọ̀ pé gbogbo ìgò ni ó yẹ láti bu ọtí wáìnì kún?’ 13 Nítorí náà sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Èmi yóò fi ìmutípara kún gbogbo olùgbé ilẹ̀ yìí pẹ̀lú ọba tí ó jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi, àwọn àlùfáà, àwọn wòlíì gbogbo àwọn tó ń gbé ní Jerusalẹmu. 14 Èmi yóò ti èkínní lu èkejì, àwọn baba àti ọmọkùnrin pọ̀ ni Olúwa wí: Èmi kì yóò dáríjì, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò ṣàánú, èmi kì yóò ṣe ìyọ́nú láti máa pa wọ́n run.’ ”
Ìkìlọ̀ oko ẹrú
15 Gbọ́ kí o sì fetísílẹ̀,
ẹ má ṣe gbéraga,
nítorí Olúwa ti sọ̀rọ̀.
16 Ẹ fi ògo fún Olúwa Ọlọ́run yín,
kí ó tó mú òkùnkùn wá,
àti kí ó tó mú ẹsẹ̀ yín tàsé
lórí òkè tí ó ṣókùnkùn,
Nígbà tí ẹ̀yin sì ń retí ìmọ́lẹ̀,
òun yóò sọ ọ́ di òjìji yóò sì ṣe bi òkùnkùn biribiri.
17 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá fetísílẹ̀,
Èmi yóò sọkún ní ìkọ̀kọ̀
nítorí ìgbéraga yín;
Ojú mi yóò sun ẹkún kíkorò,
tí omi ẹkún, yóò sì máa sàn jáde,
nítorí a kó agbo Olúwa lọ ìgbèkùn.
18 Sọ fún ọba àti ayaba pé,
“Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀,
ẹ sọ̀kalẹ̀ láti orí ìtẹ́ yín,
adé ògo yín bọ́ sí ilẹ̀ láti orí yín.”
19 Àwọn ìlú tí ó wà ní gúúsù ni à ó tì pa,
kò sì ní sí ẹnikẹ́ni láti ṣí wọn.
Gbogbo Juda ni a ó kó lọ sí ilẹ̀ ìgbèkùn,
gbogbo wọn ni a ó kó lọ ní ìgbèkùn pátápátá.
26 (A)“Ará, ẹ̀yin ọmọ ìran Abrahamu, àti ẹ̀yin ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run, àwa ni a rán ọ̀rọ̀ ìgbàlà yìí sí. 27 Nítorí àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu, àti àwọn olórí wọn, nítorí tiwọn kò mọ̀ Jesu, tí wọn kò sì ní òye ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì, tí a ń kà ní ọjọọjọ́ ìsinmi fún wọn, kò yé wọn, wọ́n mú ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì yìí ṣẹ nípa dídá a lẹ́bi. 28 Àti bí wọn kò tilẹ̀ ti rí ọ̀ràn ikú sí i, síbẹ̀ wọn rọ Pilatu láti pa á. 29 Bí wọ́n ti mú nǹkan gbogbo ṣẹ ti a kọ̀wé nítorí rẹ̀, wọn sì sọ̀ ọ́ kalẹ̀ kúrò lórí igi, wọ́n sì tẹ́ ẹ sí ibojì. 30 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run jí i dìde kúrò nínú òkú, 31 o sì farahàn lọ́jọ́ púpọ̀ fún àwọn tí ó bá a gòkè láti Galili wá sí Jerusalẹmu, àwọn tí í ṣe ẹlẹ́rìí rẹ̀ nísinsin yìí fún àwọn ènìyàn.
32 “Àwa sì mú ìhìnrere wá fún yín pé: Ìlérí èyí tí Ọlọ́run ti ṣe fún àwọn baba wa, 33 (B)èyí ni Ọlọ́run ti mú ṣẹ fún àwa ọmọ wọn, nípa gbígbé Jesu dìde: Bí a sì ti kọ̀wé rẹ̀ nínú Saamu kejì pé:
“ ‘Ìwọ ni Ọmọ mi;
lónìí ni mo bí ọ.’
34 (C)Àti ni tí pé Ọlọ́run jí i dìde kúrò nínú òkú, ẹni tí kì yóò tún padà sí ìbàjẹ́ mọ́, ó wí báyìí pé:
“ ‘Èmi ó fún yín ní ọ̀rẹ́ mímọ́ Dafidi, tí ó dájú.’
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.