Add parallel Print Page Options

21 Nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ní Judea sálọ sórí òkè; àti àwọn tí ń bẹ láàrín rẹ̀ kí wọn jáde kúrò; kí àwọn tí ó sì ń bọ̀ ní ìgbèríko má ṣe wọ inú rẹ̀ wá. 22 Nítorí ọjọ́ ẹ̀san ni ọjọ́ wọ̀nyí, kì a lè mú ohun gbogbo tí a ti kọ̀wé rẹ̀ ṣẹ. 23 (A)Ṣùgbọ́n ègbé ni fún àwọn tí ó lóyún, àti àwọn tí ó fi ọyàn fún ọmọ mu ní ọjọ́ wọ̀nyí! Nítorí tí ìpọ́njú púpọ̀ yóò wà lórí ilẹ̀ àti ìbínú sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí. 24 (B)Wọn ó sì ti ojú idà ṣubú, a ó sì dìwọ́n ní ìgbèkùn lọ sí orílẹ̀-èdè gbogbo; Jerusalẹmu yóò sì di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ lẹ́sẹ̀ àwọn aláìkọlà, títí àkókò àwọn aláìkọlà yóò fi kún.

Read full chapter

(A)“Ohun tí ẹ̀yin ń wò wọ̀nyí, ọjọ́ ń bọ̀, nígbà tí a kì yóò fi òkúta kan sílẹ̀ lórí èkejì tí a kì yóò wó lulẹ̀.”

Read full chapter

Èmi yóò sì wà ní bùba yí ọ ká níbi gbogbo;
    Èmi yóò sì fi ilé ìṣọ́ yí ọ ká:
    èmi yóò sì fi iṣẹ́ ìdó ti ni mi dojúkọ ọ́.

Read full chapter

Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Àwọn ọmọ-ogun wí:

“Ẹ ké àwọn igi náà lulẹ̀
    kí ẹ sì mọ odi ààbò yí Jerusalẹmu ká.
Èyí ni ìlú títóbi tí a ó bẹ̀wò,
    nítorí pé ó kún fún ìninilára.

Read full chapter

Kí o sì dó tì í, kí o sì mọ ilé ìṣọ́ tì í, kí o sì mọ odi tì í, kí o sì gbé ogun sí i, kí o sì to òòlù yí i ká.

Read full chapter