Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 37:12-22

12 Ènìyàn búburú di rìkíṣí sí olóòtítọ́,
    wọ́n sì pa eyín wọn keke sí wọn;
13 ṣùgbọ́n Olúwa rẹ́rìn-ín sí àwọn ènìyàn búburú,
    nítorí tí ó rí wí pé ọjọ́ wọn ń bọ̀.

14 Ènìyàn búburú fa idà yọ,
    wọ́n sì tẹ àwọn ọrun wọn,
láti sọ tálákà àti aláìní kalẹ̀,
    láti pa àwọn tí ó dúró ṣinṣin.
15 Idà wọn yóò wọ àyà wọn lọ,
    àti wí pé ọrun wọn yóò sì ṣẹ́.

16 Ohun díẹ̀ tí olódodo ní,
    sàn ju ọ̀pọ̀ ọrọ̀ ènìyàn búburú;
17 nítorí pé a óò ṣẹ́ ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú,
    ṣùgbọ́n Olúwa gbé olódodo sókè.

18 Olúwa mọ àwọn ọjọ́ àwọn tó dúró ṣinṣin,
    àti wí pé ilẹ̀ ìní wọn yóò wà títí ayérayé;
19 Ojú kì yóò tì wọ́n ní àkókò ibi,
    àti ní ọjọ́ ìyàn, a ó tẹ́ wọn lọ́rùn.

20 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn búburú yóò ṣègbé.
    Àwọn ọ̀tá Olúwa yóò dàbí ẹwà oko tútù;
    wọn fò lọ; bi èéfín ni wọn yóò fò lọ kúrò.

21 Àwọn ènìyàn búburú yá, wọn kò sì san án padà,
    ṣùgbọ́n àwọn olódodo a máa ṣàánú, a sì máa fi fún ni;
22 Nítorí àwọn tí Olúwa bá bùkún ni yóò jogún ilẹ̀ náà,
    àwọn tí ó fi bú ni a ó gé kúrò.

2 Samuẹli 11:14-21

Dafidi pàṣẹ kí wọn ó pa Uriah ní ogun

14 Ó sì ṣe ní òwúrọ̀, Dafidi sì kọ̀wé sí Joabu, ó fi rán Uriah. 15 Ó sì kọ sínú ìwé pé, “Fi Uriah síwájú ibi tí ogun gbé le, kí ẹ sì fàsẹ́yìn, kí wọn lè kọlù ú, kí ó sì kú.”

16 Ó sì ṣe nígbà tí Joabu ṣe àkíyèsí ìlú náà, ó sì yan Uriah sí ibi kàn ní ibi tí òun mọ̀ pé àwọn alágbára ọkùnrin ń bẹ níbẹ̀. 17 Àwọn ọkùnrin ìlú náà sì jáde wá, wọ́n sì bá Joabu jà: díẹ̀ sì ṣubú nínú àwọn ènìyàn náà nínú àwọn ìránṣẹ́ Dafidi, Uriah ará Hiti sì kú pẹ̀lú.

18 Joabu sì ránṣẹ́ ó sì ro gbogbo nǹkan ogun náà fún Dafidi. 19 Ó sì pàṣẹ fún ìránṣẹ́ náà pé, “Nígbà tí ìwọ bá sì parí àti máa ro gbogbo nǹkan ogun náà fún ọba. 20 Bí ó bá ṣe pé, ìbínú ọba bá ru, ti òun sì wí fún ọ pé, ‘Èéṣe tí ẹ̀yin fi súnmọ́ ìlú náà láti bá wọn jà, ẹ̀yin kò mọ̀ pé wọn ó tafà láti orí odi wá. 21 Ta ni ó pa Abimeleki ọmọ Jerubu-Beṣeti? Kì í ṣe obìnrin ni ó yí òkúta-ọlọ lù ú láti orí odi wá, tí ó sì kú ní Tebesi? Èéha ti rí tí ẹ̀yin fi súnmọ́ odi náà? Ìwọ yóò sì wí fún un pé, Uriah ìránṣẹ́ rẹ ará Hiti kú pẹ̀lú.’ ”

Filipi 4:10-20

Àwọn ọpẹ́ fún àwọn ẹ̀bùn wọn

10 (A)Èmi yọ̀ gidigidi nínú Olúwa pé, nísinsin yìí, ẹ̀yin tún ti sọjí nínú àníyàn ọkàn yín sí mi, nítòótọ́ ọkàn yín ń fàmọ́ mi ṣùgbọ́n ẹ kò ní àǹfààní tó. 11 Kì í ṣe pé èmi ń sọ nítorí àìní: nítorí pé ni ipòkípò tí mo bá wà, mo tí kọ́ láti ní ìtẹ́lọ́rùn nínú rẹ̀. 12 Mo mọ̀ ohun tí o jẹ láti wa nínú àìní, mo sì mọ ohun tí ó jẹ láti ni lọ́pọ̀lọpọ̀. Nínú ohunkóhun àti nínú ohun gbogbo mo ti kọ́ àṣírí láti máa jẹ́ àjẹyó tàbí láti wà ni àìjẹun, láti máa ni ànító àti láti ṣe aláìní. 13 (B)Èmi le ṣe ohun gbogbo nínú Kristi ẹni ti ń fi agbára fún mi.

14 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ṣeun gidigidi ní ti pé ẹ̀yin ṣe alábápín nínú ìpọ́njú mi. 15 Ẹ̀yin pàápàá sì mọ̀ pẹ̀lú, ẹ̀yin ará Filipi, pé ni ìbẹ̀rẹ̀ ìhìnrere, nígbà tí mo kúrò ni Makedonia, kò sí ìjọ kan ti ó bá mi ń ṣe alábápín ní ti gbígbà àti fífún ni, bí kò ṣe ẹ̀yin nìkan ṣoṣo. 16 (C)Nítorí ní Tẹsalonika ẹ̀yin fi nǹkan ránṣẹ́, lẹ́ẹ̀kan fún àìní mi. 17 Kì í ṣe nítorí ti èmi ń fẹ́ ẹ̀bùn náà: ṣùgbọ́n èmi ń fẹ́ èso ti yóò máa di púpọ̀ nítorí yín 18 Ṣùgbọ́n mo ní ohun gbogbo, mo sì ti di púpọ̀: mo sì tún ni lọ́pọ̀lọpọ̀ nígbà ti mo tí gba nǹkan wọ̀nyí lọ́wọ́ Epafiroditu tí a ti rán wá láti lọ́dọ̀ yín, ọrẹ olóòórùn dídùn, ẹbọ ìtẹ́wọ́gbà, tì í ṣe inú dídùn gidigidi sí Ọlọ́run. 19 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run mi yóò pèsè ní kíkún fún gbogbo àìní yín, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú ògo nínú Kristi Jesu.

20 Ṣùgbọ́n ògo ni fún Ọlọ́run àti Baba wa láé àti láéláé. Àmín.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.