Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 18:1-6

Fún adarí orin. Ti Dafidi ìránṣẹ́ Olúwa tí ó kọ sí Olúwa, ọ̀rọ̀ orin tí ó kọ sí Olúwa fún ìdáǹdè kúrò lọ́wọ́ Saulu ọ̀tá rẹ̀. Ó wí pé

18 (A)Mo fẹ́ ọ, Olúwa, agbára mi.

Olúwa ni àpáta àti odi mi, àti olùgbàlà mi;
    Ọlọ́run mi ni àpáta mi, ẹni tí mo fi ṣe ibi ìsádi mi.
    Òun ni àpáta ààbò àti ìwo ìgbàlà mi àti ibi ìsádi mi.

Mo ké pe Olúwa, ẹni tí ìyìn yẹ fún,
    a ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá à mi.
Ìrora ikú yí mi kà,
    àti ìṣàn omi àwọn ènìyàn búburú dẹ́rùbà mí.
Okùn isà òkú yí mi ká,
    ìkẹ́kùn ikú dojúkọ mí.

Nínú ìpọ́njú mo ké pe Olúwa;
    Mo sọkún sí Olúwa mi fún ìrànlọ́wọ́.
Láti inú tẹmpili rẹ̀, ó gbọ́ igbe mi;
    ẹkún mi wá sí iwájú rẹ̀, sí inú etí rẹ̀.

Saamu 18:43-50

43 Ìwọ ti gbà mí lọ́wọ́ ìkọlù àwọn ènìyàn;
    Ìwọ ti fi mí ṣe olórí àwọn orílẹ̀-èdè.
Àwọn ènìyàn ti èmi kò mọ, yóò sì máa sìn mí,
44     ni wéré ti wọ́n gbọ́ ohùn mi, wọ́n pa àṣẹ mi mọ́;
    àwọn ọmọ àjèjì yóò tẹríba fún mi.
45 Àyà yóò pá àlejò;
    wọn yóò sì fi ìbẹ̀rù jáde láti ibi kọ́lọ́fín wọn.

46 Olúwa wà láààyè! Olùbùkún ni àpáta mi!
    Gbígbéga ní Ọlọ́run Olùgbàlà mi.
47 Òun ni Ọlọ́run tí ó ń gbẹ̀san mi,
    tí ó sì ń ṣẹ́gun àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wà ní abẹ́ mi,
48     tí ó pa mí mọ́ kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mí.
Ìwọ gbé mi ga ju àwọn ọ̀tá tí ó dìde sí mi lọ;
    lọ́wọ́ àwọn ènìyàn alágbára ni ìwọ ti gbà mí.
49 (A)Títí láéláé, èmi yóò máa yìn ọ́ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ìwọ Olúwa;
    Èmi yóò sì máa kọ orin ìyìn sí orúkọ rẹ.

50 Ó fún ọba rẹ̀ ni ìṣẹ́gun ńlá;
    ó fi ìkáàánú àìṣẹ̀tàn fún ẹni ààmì òróró rẹ̀,
    fún Dafidi àti ìran rẹ̀ títí láé.

1 Samuẹli 31

Saulu pa ara rẹ̀

31 (A)Nísinsin yìí, àwọn ará Filistini dojú ìjà kọ Israẹli, Àwọn ará Israẹli sì sálọ kúrò níwájú wọn, a sì pa ọ̀pọ̀ wọn sí orí òkè Gilboa Àwọn Filistini sì ń lépa Saulu àti àwọn ọmọ rẹ̀ kíkan; àwọn Filistini sì pa Jonatani àti Abinadabu, àti Malikiṣua, àwọn ọmọ Saulu. Ìjà náà sì burú fún Saulu gidigidi, àwọn tafàtafà si ta á ní ọfà, o sì fi ara pa púpọ̀ lọ́wọ́ àwọn tafàtafà.

Saulu sì wí fún ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ pé, “Fa idà rẹ yọ, kí ìwọ sì fi gún mi, kí àwọn aláìkọlà wọ̀nyí má ba à wá gún mi, àti kí wọn kí ó má bá à fi mí ṣe ẹlẹ́yà.”

Ṣùgbọ́n ẹni tí ó rú ẹ̀rù ìhámọ́ra rẹ̀ kò fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí pé ẹ̀rù bà á gidigidi. Nígbà náà ni Saulu mú idà, ó sì ṣubú lù ú. Nígbà tí ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀ si rí i pé Saulu kú, òun náà sì fi idà rẹ̀ pa ara rẹ̀, ó sì kú pẹ̀lú rẹ̀. Saulu sì kú, àti àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́ta, àti ẹni tí ó ru ìhámọ́ra rẹ̀, àti gbogbo àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ ní ọjọ́ kan náà.

Nígbà ti àwọn ọkùnrin Israẹli tí ó wà lápá kejì àfonífojì náà, àti àwọn ẹni tí ó wà lápá kejì Jordani, rí pé àwọn ọkùnrin Israẹli sá, àti pé Saulu àti àwọn ọmọkùnrin rẹ ti kú, wọ́n sì fi ìlú sílẹ̀, wọ́n sì sá, àwọn Filistini sì wá, wọ́n sì jókòó si ìlú wọn.

Ní ọjọ́ kejì, nígbà tí àwọn Filistini dé láti bọ́ nǹkan tí ń bẹ lára àwọn tí ó kù, wọ́n sì rí pé, Saulu àti àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́ta ṣubú ni òkè Gilboa. Wọ́n sì gé orí rẹ̀, wọ́n sì bọ ìhámọ́ra rẹ̀, wọ́n sì ránṣẹ́ lọ ilẹ̀ Filistini káàkiri, láti máa sọ ọ́ ní gbangba ni ilé òrìṣà wọn, àti láàrín àwọn ènìyàn. 10 Wọ́n sì fi ìhámọ́ra rẹ̀ sí ilé Aṣtoreti: wọ́n sì kan òkú rẹ̀ mọ́ odi Beti-Ṣani.

11 Nígbà tí àwọn ará Jabesi Gileadi sì gbọ́ èyí tí àwọn Filistini ṣe sí Saulu. 12 Gbogbo àwọn ọkùnrin alágbára sì dìde, wọ́n sì fi gbogbo òru náà rìn, wọ́n sì gbé òkú Saulu, àti òkú àwọn ọmọ bíbí rẹ̀ kúrò lára odi Beti-Ṣani, wọ́n sì wá sí Jabesi, wọ́n sì sun wọ́n níbẹ̀. 13 Wọ́n sì kó egungun wọn, wọ́n sì sin wọ́n lábẹ́ igi tamariski ní Jabesi, wọ́n sì gbààwẹ̀ ní ọjọ́ méje.

2 Kọrinti 9:1-5

(A)Nísinsin yìí, nípa ti ìpín fún ni fún àwọn ènìyàn mímọ́, kò tún yẹ mọ́ fún mi láti kọ̀wé sí yin ju bẹ́ẹ̀ lọ. (B)Nítorí mo mọ ìtara láti ṣe ìrànlọ́wọ́ yín, èyí tí mo ti ṣògo fún àwọn ará Makedonia nítorí yín, pé, àwọn ara Akaia ti múra tan níwọ̀n ọdún kan tí ó kọjá ìtara yín sì ti rú ọ̀pọ̀lọpọ̀ sókè. (C)Ṣùgbọ́n mo ti rán àwọn arákùnrin, kí ìṣògo wa nítorí yín má ṣe jásí asán ní ti ọ̀ràn yìí; pé gẹ́gẹ́ bí mó ti wí, kí ẹ̀yin lè múra tẹ́lẹ̀. Kí ó má ba à jẹ́ pé, bí àwọn nínú ara Makedonia bá bá mi wá, tí wọ́n sì bá yín ní àìmúra sílẹ̀, ojú a sì tì wá kì í ṣe ẹ̀yin, ní ti ìgbẹ́kẹ̀lé yìí. Nítorí náà ni mo ṣe rò pé ó yẹ láti gba àwọn arákùnrin níyànjú, kí wọn kọ́kọ́ tọ̀ yín wá, kí ẹ sì múra ẹ̀bùn yín, tí ẹ ti ṣe ìlérí tẹ́lẹ̀ sílẹ̀, kí ó lè ti wà ní lẹ́bi ẹ̀bùn gidi, kí ó má sì ṣe dàbí ohun ti a fi ìkùnsínú ṣe.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.